Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣọ́ra fún Àwọn Àṣà Ìbílẹ̀ Tí Inú Ọlọ́run Kò Dùn Sí

Ṣọ́ra fún Àwọn Àṣà Ìbílẹ̀ Tí Inú Ọlọ́run Kò Dùn Sí

Ṣọ́ra fún Àwọn Àṣà Ìbílẹ̀ Tí Inú Ọlọ́run Kò Dùn Sí

NÍ APÁ ibì kan nílẹ̀ Áfíríkà, wọ́n tẹ́ òkú ọkùnrin kan sínú pósí nínú àgbàlá kan, wọ́n sì ṣí pósí náà sílẹ̀ nínú oòrùn tó ń mú ganrínganrín. Báwọn abánikẹ́dùn ṣe ń tò tẹ̀ léra wọn kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ pósí náà ni bàbá kan lára wọn bá dúró. Ojú bàbá náà kọ́rẹ́ lọ́wọ́, ó sún mọ́ òkú náà, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ sí i pé: “Kí ló dé tó ò sọ fún mi pé ó ti ń lọ? Kí ló dé tó o wá fi mí sílẹ̀ báyìí? Bó o ṣe wá ń padà lọ yìí, ṣé o ò ní gbàgbé mi?”

Lápá ibòmíràn nílẹ̀ Áfíríkà kan náà, wọ́n bí ọmọ tuntun kan. Wọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni rí ọmọ náà. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ ni wọ́n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé e jáde sí gbangba tí wọ́n sì ṣe ayẹyẹ ìsọmọlórúkọ.

Ó lè jẹ́ ohun àjèjì pátápátá sáwọn kan pé àwọn èèyàn ń bá òkú sọ̀rọ̀ tàbí pé wọ́n ń gbé ọmọ tuntun pa mọ́ fáwọn èèyàn. Àmọ́, àwọn kan gbà gbọ́ gan-an pé ńṣe lẹni tó kú wulẹ̀ papò dà, pé ó ṣì mọ ohun tó ń lọ. Èyí ló fà á tí wọ́n fi láwọn ààtò tí wọ́n máa ń ṣe nígbà tẹ́nì kan bá kú tàbí nígbà tí wọ́n bá bímọ tuntun.

Ìgbàgbọ́ wọn yìí lágbára débi pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe nígbèésí ayé wọn ló ní àṣà kan tàbí ààtò kan tí ìgbàgbọ́ yìí ń darí rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló gbà gbọ́ pé àjò layé, àti pé nínú ìrìn àjò ẹ̀dá láyé, àwọn ìpele pàtàkì kan wà tí wọ́n máa là kọjá kí wọ́n tó padà sọ́dọ̀ àwọn alálẹ̀, ìyẹn àwọn baba ńlá tó ti kú. Àwọn ìpele náà ni àkókò tí wọ́n bí èèyàn, ìgbà tó bàlágà, ìgbà tó ṣègbéyàwó, ìgbà tó bímọ àti ìgbà ikú rẹ̀. Wọ́n gbà gbọ́ pé nígbà tẹni tó kú bá padà síbi tó ti wá náà, ó ṣì lè máa dá sí ọ̀ràn àwọn tó fi sílẹ̀. Wọ́n tún gbà gbọ́ pé ó tún lè tún ayé wa.

Kí láburú kankan má bàa ṣẹlẹ̀ lákòókò ìrìn-àjò yìí, wọ́n ní ọ̀pọ̀ àṣà tí wọ́n máa ń tẹ̀ lé àti ààtò tí wọ́n máa ń ṣe. Ohun tó sì ń mú wọn ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní pé nǹkan kan wà nínú èèyàn tí kì í kú. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í lọ́wọ́ sí àṣà èyíkéyìí tó bá dá lórí ìgbàgbọ́ yìí. Kí nìdí?

Ṣé Lóòótọ́ Lẹni Tó Ti Kú Mọ Nǹkan Kan?

Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn òkú, ohun tó sọ ṣe kedere. Ó ní: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá . . . Ìfẹ́ wọn àti ìkórìíra wọn àti owú wọn ti ṣègbé . . . Kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù [ibojì gbogbo aráyé], ibi tí ìwọ ń lọ.” (Oníwàásù 9:5, 6, 10) Ó ti pẹ́ táwọn Kristẹni tòótọ́ ti fọwọ́ pàtàkì mú ohun tí Bíbélì sọ yìí. Wọ́n mọ̀ pé ọkàn lè kú ó sì lè pa run. (Ísíkíẹ́lì 18:4) Wọ́n tún mọ̀ pé kò sóhun tó ń jẹ́ pé ẹ̀mí àwọn òkú wà níbì kan. (Sáàmù 146:4) Láyé ìgbàanì, Jèhófà dìídì pa á láṣẹ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí àṣà tàbí ààtò èyíkéyìí tó dá lórí ìgbàgbọ́ pé àwọn òkú wà níbì kan, pé wọ́n lè ran alààyè lọ́wọ́ tàbí pé wọ́n lè ṣe wọ́n níbi.—Diutarónómì 14:1; 18:9-13; Aísáyà 8:19, 20.

Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní náà yẹra fáwọn ìgbàgbọ́ àbáláyé àtàwọn ààtò tó wá látinú ìsìn èké. (2 Kọ́ríńtì 6:15-17) Lónìí, láìka ìran tàbí ẹ̀yà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wá sí tàbí irú èèyàn tí wọ́n jẹ́, wọn kì í ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àbáláyé tàbí àwọn àṣà tó jẹ mọ́ ẹ̀kọ́ èké náà pé ohun kan wà nínú èèyàn tí kì í kú.

Kí ló lè tọ́ àwa tá a jẹ́ Kristẹni sọ́nà láti mọ̀ bóyá ká lọ́wọ́ sí àṣà kan tàbí ká má lọ́wọ́ sí i? A gbọ́dọ̀ ronú lórí àṣà náà dáadáa, kó sì dá wa lójú pé kò jẹ mọ́ ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, irú bí ìgbàgbọ́ pé ẹ̀mí àwọn tó kú lè ṣe ẹni tó wà láàyè lóore tàbí kó ṣe wọ́n ní jàǹbá. Síwájú sí i, ó tún ṣe pàtàkì ká ronú bóyá lílọ́wọ́ sí irú àṣà tàbí ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ lè mú àwọn kan kọsẹ̀, ìyẹn àwọn tó mọ ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ àtohun tá a fi ń kọ́ni. Bá a ti ń ronú lórí àwọn kókó yìí, ẹ jẹ́ ká wo apá ibi méjì tó ń kọni lóminú, ìyẹn ni ọ̀rọ̀ ọmọ tuntun àti ọ̀rọ̀ ikú.

Ọmọ Tuntun àti Ayẹyẹ Ìsọmọlórúkọ

Púpọ̀ nínú nǹkan táwọn èèyàn ń ṣe tí wọ́n bá bímọ ni kò burú. Àmọ́ làwọn àgbègbè tí wọ́n ti ń wo ọmọ tuntun pé àtọ̀dọ̀ àwọn alálẹ̀ ló ti wá sáàárín àwọn ẹ̀dá èèyàn, àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ ṣọ́ra. Bí àpẹẹrẹ, láwọn apá ibì kan nílẹ̀ Áfíríkà, tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, ó di ẹ̀yìn ọjọ́ díẹ̀ kí wọ́n tó jẹ́ káwọn èèyàn rí ọmọ náà kí wọ́n sì tó fún un lórúkọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye ọjọ́ tí wọ́n fi máa ń dúró lápá ibì kan lè yàtọ̀ sí ti ibòmíràn, ayẹyẹ ìsọmọlórúkọ ni wọ́n máa ń fi kádìí rẹ̀. Wọ́n á gbé ọmọ náà jáde, wọ́n á sì fún un lórúkọ lójú tẹbí-tọ̀rẹ́.

Ìwé kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ghana—Understanding the People and Their Culture sọ ìtumọ̀ àṣà yìí, ó ní: “‘Àlejò ayé’ ni wọ́n ka ọmọ tuntun sí fún odindi ọjọ́ méje lẹ́yìn tí wọ́n bá bí i, wọ́n sì gbà pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń tọ̀run bọ̀ wá sáyé ni. . . . Ńṣe ni wọ́n máa gbé ọmọ náà pa mọ́ sínú ilé láìjẹ́ káwọn tí kì í ṣe ara ìdílé náà rí i.”

Kí nìdí tí wọ́n fi máa ń dúró díẹ̀ kí wọ́n tó sọ ọmọ lórúkọ? Ìwé tí wọ́n pè ní Ghana in Retrospect sọ pé: “Bí ọmọ náà ò bá tíì pé ọjọ́ mẹ́jọ, wọn ò tíì gbà pé èèyàn ni. Wọ́n gbà gbọ́ pé ara àwọn tó fi sílẹ̀ lọ́run ṣì ni.” Ìwé náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìgbàgbọ́ wọn ni pé orúkọ ló ń sọmọ dèèyàn, bí ẹ̀rù bá ń ba tọkọtaya kan pé ó ṣeé ṣe kí ọmọ àwọn kú, wọn ò ní sọ ọ́ lórúkọ àfìgbà tó bá dá wọn lójú pé ọmọ náà kò ní kú. . . . Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ka ayẹyẹ táwọn kan máa ń pè ní ìkómọjáde yìí sí ohun tó ṣe pàtàkì gan-an fún ọmọ náà àtàwọn òbí rẹ̀. Ayẹyẹ náà ni wọ́n gbà pé ó mú ọmọ náà wọ àárín alààyè.”

Olórí ẹbí ló sábà máa ń darí ayẹyẹ ìsọmọlórúkọ. Bí wọ́n ṣe ń ṣe é níbì kan yàtọ̀ sí ti ibòmíràn, àmọ́ lára àwọn ohun tí wọ́n sábà máa ń ṣe nígbà ayẹyẹ náà ni títú ọtí dà sílẹ̀ àti jíjúbà àwọn alálẹ̀, èyí tí wọ́n fi ń dúpẹ́ pé ọmọ náà délé ayé láyọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tún máa ń ṣe àwọn ààtò mìíràn.

Ohun táwọn èèyàn ti ń wọ̀nà fún ló wá kàn lẹ́yìn náà, ìyẹn ni pípe orúkọ ọmọ náà sétígbọ̀ọ́ wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí ló máa sọ ọmọ náà lórúkọ, àwọn ẹbí máa ń lẹ́nu gan-an nínú irú orúkọ tí ọmọ náà yóò máa jẹ́. Àwọn orúkọ kan lè nítumọ̀ kan pàtó, irú bí “Ìyábọ̀dé,” àti “Babátúndé.” Àwọn orúkọ mìíràn sì máa ń nítumọ̀ tó fi hàn pé wọ́n ò fẹ́ kí àwọn alálẹ̀ gba ọmọ tuntun náà padà sọ́dọ̀ wọn.

Lóòótọ́, kò sóhun tó burú nínú ṣíṣàjọyọ̀ téèyàn bá bímọ tuntun. Kò sì sí èèwọ̀ nínú sísọmọ lórúkọ tẹ́nì kan ti ń jẹ́ tẹ́lẹ̀ tàbí lórúkọ tó fi ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bí ọmọ náà hàn, kálukú ló sì lè pinnu ìgbà tí òun á fún ọmọ òun lórúkọ. Àmọ́, àwọn Kristẹni tó fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn máa ń rí i dájú pé àwọn yẹra fún àwọn àṣà tàbí ayẹyẹ tó ń fi hàn pé wọ́n fara mọ́ ìgbàgbọ́ táwọn èèyàn ní pé “àlejò” tó ti ọ̀run wá sílé ayé lọmọ tuntun jẹ́.

Láfikún sí i, bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lágbègbè wa bá tiẹ̀ gbà pé ayẹyẹ ìsọmọlórúkọ ṣe pàtàkì, ó yẹ káwa Kristẹni máa ronú nípa ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn àti èrò tí ṣíṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa gbé wá sọ́kàn àwọn aláìgbàgbọ́. Bí àpẹẹrẹ, kí làwọn kan máa sọ bí wọ́n bá rí ìdílé kan tó jẹ́ Kristẹni tí wọ́n gbé ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí pa mọ́ láìjẹ́ káwọn èèyàn rí i títí ọjọ́ tí wọ́n tó ṣayẹyẹ ìsọmọlórúkọ? Èrò wo ló máa gbé wá sọ́kàn àwọn èèyàn bí wọ́n bá sọ ọmọ náà lórúkọ tó ta ko ohun tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn látinú Bíbélì?

Nítorí náà, nígbà táwọn Kristẹni bá ń ronú bí wọ́n ṣe máa sọ ọmọ wọn lórúkọ àtìgbà tí yóò jẹ́, ó yẹ kí wọ́n rí i pé wọ́n “ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run” kí wọ́n má bàa mú àwọn mìíràn kọsẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 10:31-33) Wọn ò ní ‘pa àṣẹ Ọlọ́run tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan láti di òfin àtọwọ́dọ́wọ́ mú,’ èyí táwọn èèyàn fi ń buyì fún òkú. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run alààyè ni wọ́n á fi ògo àti ọlá fún.—Máàkù 7:9, 13.

Láti Òkú sí Alààyè

Bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe gbà gbọ́ pé ọ̀run lọmọ tuntun ti wá sáyé náà ni wọ́n gbà gbọ́ pé ńṣe lẹni tó kú fi ayé sílẹ̀ tó padà sọ́run. Ọ̀pọ̀ nígbàgbọ́ pé tí wọn ò bá ṣe àwọn ètùtù kan nígbà tẹ́nì kan bá kú, inú lè bí àwọn alálẹ̀ tí wọ́n gbà pé wọ́n lágbára láti jẹ alààyè níyà tàbí láti ṣe wọ́n lóore. Ìgbàgbọ́ yìí sì máa ń nípa gan-an lórí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà sin òkú.

Oríṣiríṣi nǹkan làwọn èèyàn máa ń ṣe nígbà ìsìnkú láti fi tu ẹni tó kú lójú. Bí wọ́n ti ń sunkún ṣùrùṣùrù ni wọ́n á máa kígbe níbi tí wọ́n tẹ́ òkú náà sí. Bí wọ́n bá sì ṣe ń sin òkú náà tán ni wọ́n á wá pagbo àríyá. Oúnjẹ àjẹkì, ọtí àmuyíràá, ijó jíjó àti orin tó ń dún kíkankíkan kì í sì í gbẹ́yìn níbi irú àwọn ayẹyẹ ìsìnkú bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ka ìsìnkú sí ohun pàtàkì débi pé, àwọn ìdílé tó jẹ́ akúṣẹ̀ẹ́ pàápàá máa ń wá owó níbikíbi tí wọ́n bá ti lè rí i láti ṣe ohun tí wọ́n kà sí ẹ̀yẹ ìkẹyìn fáwọn èèyàn wọn tó kú, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè kó wọn sí gbèsè àti ìnira.

Ọjọ́ pẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àwọn àṣà ìsìnkú kan wà tí Ìwé Mímọ́ ta kò. a Lára irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ ni àìsùn òkú, títú ọtí dà sílẹ̀, bíbá òkú sọ̀rọ̀ àti títọrọ nǹkan lọ́wọ́ òkú, ayẹyẹ ìrántí òkú, àtàwọn àṣà mìíràn táwọn èèyàn ń ṣe nítorí pé wọ́n gbà gbọ́ pé nǹkan kan wà lára èèyàn tí kì í kú. Ohun “àìmọ́” àti “ẹ̀tàn òfìfo” ni irú àwọn àṣà tí kò fògo fún Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ jẹ́, “òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn” ló sì dá lé, kò dá lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ òtítọ́.—Aísáyà 52:11; Kólósè 2:8.

Àwọn Èèyàn Máa Ń Fúngun Mọ́ Àwọn Kristẹni

Ṣíṣàì lọ́wọ́ sí àwọn àṣà ìbílẹ̀ ti fa ìṣòro ńlá fáwọn Kristẹni kan, àgàgà láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ka bíbọ̀wọ̀ fún òkú sí nǹkan tó ṣe pàtàkì gan-an. Nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lọ́wọ́ sí irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀, ojú tí kò dáa làwọn kan fi máa ń wò wọ́n, wọ́n kà wọ́n sẹ́ni tó kẹ̀yìn síbi táyé kọjú sí, pé wọn kì í yẹ́ òkú àwọn èèyàn wọn sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni kan lóye ohun tí Bíbélì sọ yékéyéké, àríwísí táwọn èèyàn ń ṣe àti bí wọ́n ṣé ń fúngun mọ́ wọn ti mú kí wọ́n lọ́wọ́ sáwọn àṣà tí kò bójú mu. (1 Pétérù 3:14) Èrò àwọn Kristẹni mìíràn sì ni pé ara àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn làwọn àṣà yìí kò sì sọ́gbọ́n táwọn fi lè yẹra fún un pátápátá. Àwọn mìíràn rò pé táwọn ò bá tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀, èyí lè mú káwọn èèyàn kórìíra àwọn èèyàn Ọlọ́run.

Lóòótọ́ la ò fẹ́ múnú bí àwọn èèyàn, síbẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá dúró lórí ohun tá a mọ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́, ayé tó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run yìí ò ní tẹ́wọ́ gbà wá. (Jòhánù 15:18, 19; 2 Tímótì 3:12; 1 Jòhánù 5:19) Tinútinú la fi fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ, nítorí a mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ yàtọ̀ sí àwọn tó wà nínú òkùnkùn tẹ̀mí. (Málákì 3:18; Gálátíà 6:12) Bí Jésù ò ṣe juwọ́ sílẹ̀ nígbà tí Sátánì dán an wò, tó fẹ́ kó ṣe ohun tí yóò múnú bí Ọlọ́run làwa náà ò ṣe gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀ táwọn èèyàn bá fẹ́ mu wa ṣe ohun tí kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. (Mátíù 4:3-7) Dípò káwọn Kristẹni tòótọ́ jẹ́ kí ìbẹ̀rù èèyàn sún wọ́n ṣe ohun tí kò tọ́, bí wọ́n ṣe máa múnú Jèhófà Ọlọ́run dùn tí wọ́n á sì máa bọ̀wọ̀ fún un torí pé ó jẹ́ Ọlọ́run òtítọ́ lohun tó jẹ wọ́n lógún. Wọ́n sì ń ṣe èyí nípa rírí i dájú pé àwọn ìlànà Bíbélì tó ń darí ìjọsìn mímọ́ ni wọ́n ń tẹ̀ lé nígbà táwọn èèyàn bá ń fúngun mọ́ wọn.—Òwe 29:25; Ìṣe 5:29.

Bíbọlá fún Jèhófà Nígbà Téèyàn Wa Bá Kú

Gbogbo wa ni inú wa máa ń bà jẹ́ gan-an nígbà téèyàn wa bá kú. (Jòhánù 11:33, 35) Kò sì sóhun tó burú nínú rírántí àwọn nǹkan dáadáa tẹ́ni náà ṣe nígbà tó wà láyé ká sì sin ín lọ́nà tó bójú mu, ńṣe lèyí ń fi ìfẹ́ tá a ní sírú ẹni bẹ́ẹ̀ hàn. Àmọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fara da ìbànújẹ́ yìí láìsí pé wọ́n ń lọ́wọ́ sáwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tí inú Ọlọ́run kò dùn sí. Èyí kò rọrùn rárá fáwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ pé àárín àwọn èèyàn tó bẹ̀rù òkú gan-an ni wọ́n dàgbà sí. Ó lè ṣòro láti tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ nígbà tí ìbànújẹ́ bá dorí wa kodò nítorí ikú èèyàn wa. Síbẹ̀, Jèhófà tó jẹ́ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” máa ń fún àwọn Kristẹni tó bá dúró ṣinṣin lókun, àwọn onígbàgbọ́ ẹgbẹ́ wọn sì máa ń dúró tì wọ́n. (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Wọ́n nígbàgbọ́ gan-an pé Ọlọ́run ò gbàgbé àwọn èèyàn wọn tó kú tí wọn ò mọ nǹkan kan mọ́ yìí, àti pé wọn yóò jíǹde lọ́jọ́ kan. Èyí jẹ́ ìdí pàtàkì tí wọn kì í fi í lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà ìsìnkú tí kò bá ìlànà Kristẹni mu, tó ń sọ àjíǹde di ohun tí kò nítumọ̀.

Ǹjẹ́ inú wa ò dùn pé Jèhófà pè wá jáde “kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀”? (1 Pétérù 2:9) Bí inú wa ti ń dùn nígbà tá a bá bímọ tuntun, tá a sì tún ń fara da ìbànújẹ́ nígbà téèyàn wa bá kú, ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní láti ṣe ohun tó tọ́ àti ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tá a ní sí Jèhófà Ọlọ́run sún wa láti “máa bá a lọ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀” nígbà gbogbo. Ẹ má ṣe jẹ́ káwọn àṣà tí kò bá ìlànà Kristẹni mu tí wọn ò sì dùn mọ́ Ọlọ́run nínú sọ wá di ẹlẹ́gbin nípa tẹ̀mí.—Éfésù 5:8.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Jọ̀wọ́ wo àwọn ìwé pẹlẹbẹ wọ̀nyí: Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi? àti Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ wọ́n jáde.