Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Fi Gbogbo Ọkàn Wa Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

A Fi Gbogbo Ọkàn Wa Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

Ìtàn Ìgbésí Ayé

A Fi Gbogbo Ọkàn Wa Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

GẸ́GẸ́ BÍ NATALIE HOLTORF ṢE SỌ Ọ́

Lọ́jọ́ kan nínú oṣù June ọdún 1945, ọkùnrin kan ti ara rẹ̀ ti ṣì wá sílé wa, ó rọra dúró síta lẹ́nu ọ̀nà. Nígbà tí Ruth, ọmọ mi obìnrin tó kéré jù rí ọkùnrin náà, ẹ̀rù bà á, ló bá kígbe pè mí, ó ní: “Mọ́mì, ẹ wá wo ọkùnrin kan tó dúró ṣẹ́nu ọ̀nà!” Kò mọ̀ pé bàbá tó bí òun lọ́mọ lòun ń pè ní ọkùnrin kan. Ọkọ mi tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ferdinand ni. Ní ọdún méjì ṣáájú àkókò yìí, ìyẹn lẹ́yìn ọjọ́ kẹta tí mo bí Ruth, Ferdinand jáde nílé, làwọn ọlọ́pàá bá mú un, ó sì lọ bára ẹ̀ ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Ìjọba Násì. Àmọ́ mo dúpẹ́, Ruth fojú kan bàbá rẹ̀ látọjọ́ yìí, gbogbo wa sì tún jọ wá ń gbé pa pọ̀. Èmi àti Ferdinand wá jọ kẹnu bọ̀ ìròyìn nípa ohun tójú kálukú wa rí!

ỌDÚN 1909 ni wọ́n bí Ferdinand nílùú Kiel, lórílẹ̀-èdè Jámánì. Wọ́n bí èmi lọ́dún 1907 nílùú Dresden, lórílẹ̀-èdè Jámánì yìí kan náà. Ọmọ ọdún méjìlá ni mí nígbà tí ìdílé mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jẹ́ láyé àtijọ́. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni mí nígbà tí mo fi Ṣọ́ọ̀ṣì Ajíhìnrere sílẹ̀, mo sì ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà.

Àmọ́ Ferdinand ni tiẹ̀ lọ sí kọ́lẹ́ẹ̀jì tí wọ́n ti ń kọ iṣẹ́ wíwa ọkọ̀ ojú omi, nígbà tó sì jáde ó di awakọ̀ òkun. Gbogbo ìgbà tó fi ń wakọ̀ òkun yẹn ló ń ronú nípa bóyá Ẹlẹ́dàá wà tàbí kò sí. Nígbà tí Ferdinand ti ìrìn àjò dé lọ́jọ́ kan, ó lọ sọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn nǹkan tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sọ fún un mú kó gbà pé Bíbélì lè dáhùn àwọn ìbéèrè tóun ò rójútùú rẹ̀. Bó ṣe fi Ìjọ Luther sílẹ̀ nìyẹn, tó sì pinnu pé òun ò ní ṣiṣẹ́ awakọ̀ òkun mọ́. Nígbà tó padà délé lọ́jọ́ tó kọ́kọ́ lọ sóde ẹ̀rí, ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé iṣẹ́ tóun máa fi gbogbo ọjọ́ ayé òun ṣe nìyẹn. Alẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà ni Ferdinand ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì ṣe ìrìbọmi ní oṣù August ọdún 1931.

Ó Ń Wakọ̀ Ojú Omi Ó Tún Ń Ṣiṣẹ́ Ìwàásù

Ní oṣù November ọdún 1931, Ferdinand wọ ọkọ̀ ojú irin lọ sórílẹ̀-èdè Netherlands láti lọ bá àwọn ará tó wà níbẹ̀ kí wọ́n lè jọ máa wàásù. Nígbà tí Ferdinand sọ fún arákùnrin tó ń darí iṣẹ́ ìwàásù níbẹ̀ pé iṣẹ́ awakọ̀ òkun lòun ń ṣe tẹ́lẹ̀, inú arákùnrin náà dùn, ó ní: “Èèyàn bíi tìẹ gan-an là ń wá!” Àwọn arákùnrin tó wà níbẹ̀ ti lọ háyà ọkọ̀ ojú omi tí àwọn aṣáájú ọ̀nà bíi mélòó kan (ìyẹn àwọn tó ń wàásù ní gbogbo ìgbà) máa fi lọ wàásù fáwọn tí ilé wọn wà lórí omi níhà àríwá orílẹ̀-èdè náà. Àwọn márùn-ún ló fẹ́ bá ọkọ̀ ojú omi náà lọ, àmọ́ kò sẹ́ni tó lè wa ọkọ̀ ojú omi nínú gbogbo wọn. Bí wọ́n ṣe ní kí Ferdinand wà wọ́n lọ nìyẹn.

Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n ní kí Ferdinand lọ máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà nílùú Tilburg, tó wà ní gúúsù orílẹ̀-èdè Netherlands. Àárín àkókó yẹn lèmi náà wá sí ìlú Tilburg láti wá ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, ibẹ̀ ni mo ti ba Ferdinand pàdé. Àmọ́, kò pẹ́ tí mo débẹ̀ tí wọ́n sọ pé kí èmi àti Ferdinand lọ sílùú Groningen, níhà àríwá orílẹ̀-èdè náà. Ibẹ̀ la ti ṣègbéyàwó ní oṣù October 1932. Inú ilé táwa àtàwọn aṣáájú ọ̀nà bíi mélòó kan ń gbé la ti gbádùn ìsinmi oníyọ̀tọ̀mì lẹ́yìn ìgbéyàwó wa, bá a sì ṣe ń gbádùn ìsinmi náà là ń bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà nìṣó!

Ní ọdún 1935, a bi ọmọbìnrin kan a sì sọ ọ́ ní Esther. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, síbẹ̀ a pinnu pé a óò máa bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà nìṣó. A ṣí lọ sábúlé kan, a wá ń gbé nínú ilé kékeré kan níbẹ̀. Nígbà tí ọkọ mi bá lọ sóde ẹ̀rí, èmi á máa tọ́jú ọmọ wa kékeré nílé. Tó bá sì di ọjọ́ kejì, èmi á lọ sóde ẹ̀rí, ọkọ mi á dúró sílé láti tọ́jú ọmọ wa. Báyìí la ṣe ṣe é títí Esther fi dàgbà tó láti tẹ̀ lé wa lọ sóde ẹ̀rí.

Láìpẹ́ sígbà yẹn, rògbòdìyàn òṣèlú bẹ̀rẹ̀ nílẹ̀ Yúróòpù. A gbọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Jámánì ń fojú winá inúnibíni, a sì mọ̀ pé kò ní pẹ́ dé ọ̀dọ́ wa. A bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé báwo la ṣe máa lè kojú irú inúnibíni tó lékenkà bẹ́ẹ̀. Lọ́dún 1938, ìjọba orílẹ̀-èdè Netherlands ṣòfin pé àwọn ò gbọ́dọ̀ rí àlejò kankan kó máa lọ káàkiri láti pín ìwé ìsìn fáwọn èèyàn. Ká lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà nìṣó, àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Netherlands fún wa ní orúkọ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ wa, bá a ṣe lọ ń kọ́ àwọn kan lára wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn.

Àkókò yẹn ni àpéjọ àgbègbè àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ wáyé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lówó tá a máa fi wọ ọkọ̀ ojú irin lọ sí àpéjọ náà, síbẹ̀ ó wù wá láti wà níbẹ̀. La bá gbé kẹ̀kẹ́ wa sójú ọ̀nà, a gbé Esther síwájú kẹ̀kẹ́, a sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò yìí tó gbà wá ní ọjọ́ mẹ́ta. Nígbà tí ilẹ̀ bá ṣú, ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tí ilé wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà la máa ń sùn. Inú wa dùn gan-an pé a lọ sí àpéjọ náà! Ìgbà àkọ́kọ́ wa sì nìyẹn! Àwọn ọ̀rọ̀ tá a gbọ́ nípàdé náà mú wa gbára dì fún inúnibíni tó ń bọ̀. Olórí ohun tá a sì gbádùn ní àpéjọ náà ní pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. A wá fi àwọn ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 31:6 ṣe atọ́nà wa, èyí tó sọ pé: “Ní tèmi, Jèhófà ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.”

Ìjọba Násì Ń Dọdẹ Wa Kiri

Ní oṣù May ọdún 1940, ìjọba Násì gbógun ti orílẹ̀-èdè Netherlands. Láìpẹ́ sígbà yẹn, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Gestapo wá sílé wa lákòókò tá à ń to àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a fẹ́ kó ránṣẹ́. Bí àwọn ọlọ́pàá náà ṣe mú Ferdinand lọ sí àgọ́ wọn tó tóbi jù nìyẹn. Gbogbo ìgbà lèmi àti Esther máa lọ ń wò ó, nígbà míì tá a bá débẹ̀, àwọn ọlọ́pàá á máa wádìí ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu rẹ̀ wọ́n á sì tún máa lù ú níṣojú wa. Nígbà tó di oṣù December, wọ́n kàn ṣàdédé dá Ferdinand sílẹ̀ ni, àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n tún wá mú un. Bá a ṣe padà dé láti ibi tá a lọ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan la rí mọ́tò àwọn ọlọ́pàá Gestapo nítòsí ilé wa. Ferdinand yáa wábi gbà kí wọ́n má bàa rí i mú, èmi àti Esther náà yáa sá wọlé. Àwa làwọn ọlọ́pàá Gestapo náà ń dúró dè. Wọ́n fẹ́ wá mú Ferdinand. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà lẹ́yìn táwọn ọlọ́pàá Gestapo lọ tán, àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Netherlands tún dé, wọ́n sì mú mi lọ kí wọ́n lè béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi. Lọ́jọ́ kejì, èmi àti Esther lọ sá pa mọ́ sílé àwọn Norder, ìyẹn àwọn tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi. Àwọn ló gbà wá sílé, wọ́n sì dáàbò bò wá.

Nígbà tó ku díẹ̀ kí oṣù January 1941 parí, àwọn ọlọ́pàá wá mú àwọn tọkọtaya aṣáájú ọ̀nà kan tí wọ́n ń gbé nínú ọkọ̀ ojú omi tó ní yàrá. Lọ́jọ́ kejì, alábòójútó àyíká kan (ìyẹn òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò) àti ọkọ mi jọ lọ síbẹ̀ láti lọ kó lára ẹrù tọkọtaya yìí, làwọn ọlọ́pàá Gestapo bá gbá wọn mú. Ferdinand bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́, ó sáré gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì sá lọ. Àmọ́, àwọn ọlọ́pàá lọ ju alábòójútó àyíká yìí sátìmọ́lé.

Àwọn arákùnrin tó wà ní ipò àbójútó sọ fún Ferdinand pé kó máa ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká yẹn lọ. Èyí sì túmọ̀ sí pé Ferdinand ò ní lè máa lò ju ọjọ́ mẹ́ta pẹ̀lú wa láàárín oṣù kan. Kò rọrùn o, àmọ́ mi ò fi iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà sílẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá Gestapo ń wá àwọn Ẹlẹ́rìí lójú méjèèjì, nítorí náà, a ní láti máa ṣí láti ibì kan sí ibòmíràn. Lọ́dún 1942, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la pààrọ̀ ibi tá à ń gbé. Níkẹyìn, a bára wa nílùú Rotterdam. Ibẹ̀ sì jìnnà gan-an síbi tí Ferdinand ti ń wàásù fáwọn èèyàn ní bòókẹ́lẹ́. Oyún ọmọ mi kejì wà nínú mi lákòókò tí mò ń wí yìí. Ìdílé Kamp táwọn ọlọ́pàá ṣẹ̀ṣẹ̀ fi àwọn ọmọ wọn ọkùnrin méjì sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ló ṣàánú wa tí wọ́n gbà wá sílé.

Àwọn Ọlọ́pàá Gestapo Ò Fi Wá Lọ́rùn Sílẹ̀

Oṣù July ọdún 1943 la bí Ruth, ọmọ wa kejì. Lẹ́yìn tá a bí i, Ferdinand lo ọjọ́ mẹ́ta lọ́dọ̀ wa, àmọ́ ó ní láti tún padà lọ, ó sì pẹ́ gan-an ká tó tún fojú kàn án. Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọlọ́pàá Gestapo mú Ferdinand nílùú Amsterdam. Wọ́n mú un lọ sí àgọ́ wọn. Ibẹ̀ ni wọ́n ti wá mọ irú ẹni tó jẹ́. Àwọn ọlọ́pàá Gestapo da oríṣiríṣi ìbéèrè bò ó, wọ́n ṣáà fẹ́ kó sọ nǹkan kan fún wọn nípa iṣẹ́ ìwàásù náà. Àmọ́, gbogbo ohun tí Ferdinand sọ fún wọn ò ju pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun, òun kì í sì í lọ́wọ́ nínú ìṣèlú. Inú bí àwọn ọlọ́pàá Gestapo gan-an pé Ferdinand, tó jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ Jámánì ò wọṣẹ́ ológun, wọ́n sọ pé ọ̀dàlẹ̀ ni, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í halẹ̀ mọ́ ọn pé pípa làwọn máa pá.

Odindi oṣù márùn-ún gbáko ni Ferdinand lò látìmọ́lé, gbogbo ìgbà ni wọ́n sì ń halẹ̀ mọ́ ọn pé àwọn máa fìbọn fọ́ orí ẹ̀. Bí wọ́n ṣe halẹ̀ mọ́ ọn tó, kò fi Jèhófà sílẹ̀. Kí ló ràn án lọ́wọ́ tó fi dúró gbọn-in nípa tẹ̀mí? Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni. Àmọ́ nítorí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Ferdinand, wọn ò gbà kó mú Bíbélì wọnú ọgbà, ṣùgbọ́n wọ́n gba àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù láyè láti ní Bíbélì. Nítorí náà, Ferdinand sọ fún ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n jọ wà lẹ́wọ̀n pé kó sọ fáwọn aráalé rẹ̀ pé kí wọ́n fi Bíbélì kan ránṣẹ́ sóun, ọkùnrin náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ńṣe ni inú Ferdinand máa ń dùn nígbàkigbà tó bá ń ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, á wá sọ pé: “Bíbélì yẹn ló tù mí nínú!”

Níbẹ̀rẹ̀ oṣù January ọdún 1944, ńṣe làwọn ọlọ́pàá kàn ṣàdédé mú Ferdinand lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà nílùú Vught lórílẹ̀-èdè Netherlands. Ìbùkún ni mímú tí wọ́n mú un lọ yìí jà sí fún un nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́rìndínláàádọ́ta ló bá níbẹ̀. Kò retí pé òun máa bá àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn pàdé níbẹ̀ rárá. Nígbà tí mo gbọ́ pé wọ́n ti gbé e kúrò níbi tó wà, inú mi dùn gan-an nítorí èyí jẹ́ kí n mọ̀ pé ó ṣì wà láàyè!

Ferdinand Ń Bá Iṣẹ́ Ìwàásù Nìṣó Ní Àgọ́ Ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́

Ìyà táwọn tí wọ́n kó sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ náà jẹ kì í ṣe kékeré. Wọn ò róúnjẹ jẹ kánú, kò sí aṣọ tí wọ́n lè fi gbòtútù, bẹ́ẹ̀ sì rèé òtútù ibẹ̀ kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Ọ̀nà ọ̀fun bẹ̀rẹ̀ sí í dun Ferdinand gan-an. Inú òtútù ni gbogbo wọn wà nígbà tí wọ́n ń pe orúkọ wọn níkọ̀ọ̀kan, ó sì pẹ́ gan-an kó tó kàn án, ni òtútù bá wọ̀ ọ́ lára, bó ṣe dèrò ọsibítù wọn níbẹ̀ nìyẹn. Àwọn tó ń ṣàìsàn ibà tí ara wọn gbóná kọjá ààlà ni wọ́n gbà kó dúró sí ọsibítù náà fún ìtọ́jú. Àmọ́, ó ṣì ku díẹ̀ ṣíún kí ara Ferdinand gbóná tó ìwọ̀n tí wọ́n fi lè dá a dúró, ni wọ́n bá ní kó padà sẹ́nu iṣẹ́! Ṣùgbọ́n àwọn kan lára àwọn tí wọ́n jọ wà lẹ́wọ̀n tí wọ́n lójú àánú bá a wá ibì kan tó móoru díẹ̀ tó lè fara pa mọ́ sí. Nígbà tí oòrùn sì ràn díẹ̀, ara ẹ̀ tún yá sí i. Nígbà táwọn kan lára àwọn arákùnrin tí wọ́n jọ wà nínú àgọ́ náà bá rí oúnjẹ gbà, wọ́n máa ń fún Ferdinand àtàwọn mìíràn lára oúnjẹ náà, èyí sì mú kí ara rẹ̀ túbọ̀ mókun.

Kó tó di pé wọ́n sọ ọkọ mi sẹ́wọ̀n, ó ti mọ́ ọn lára láti máa wàásù, torí náà nígbà tó dé àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ yẹn, kò yéé sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn mìíràn. Àwọn aláṣẹ àgọ́ náà máa ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ àlùkò tí wọ́n lẹ̀ mọ́ ara aṣọ rẹ̀. Àmì yìí sì ni wọ́n fi ń dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí mọ̀. Àmọ́, ńṣe ni Ferdinand ka yẹ̀yẹ́ táwọn aláṣẹ ń fòun ṣe yìí sí àǹfààní láti wàásù fún wọn. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ débẹ̀, ìwọ̀nba ẹlẹ́wọ̀n díẹ̀ ni wọ́n ń rí wàásù fún nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí ló pọ̀ jù nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi wọ́n sí. Èyí mú káwọn arákùnrin náà máa bi ara wọn pé, ‘Báwo lá ṣe máa rí àwọn ẹlẹ́wọ̀n púpọ̀ sí i láti wàásù fún?’ Ètò kan táwọn aláṣẹ àgọ́ náà ṣe ló yanjú ìṣòro yẹn. Wọn ò mọ̀ pé àǹfààní ni ètò náà yóò jẹ́ fáwọn arákùnrin wọ̀nyí. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?

Àwọn kan ko ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti Bíbélì méjìlá wá fáwọn arákùnrin wọ̀nyẹ́n ní bòókẹ́lẹ́. Lọ́jọ́ kan, àwọn ẹ̀ṣọ́ rí lára àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, àmọ́ wọn ò mọ ẹni tó ni wọ́n. Báwọn aláṣẹ àgọ́ náà ṣe pinnu pé àwọn máa fọ́n àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí ká nìyẹn. Láti lè wá ṣe ohun tó máa dun àwọn Ẹlẹ́rìí náà, wọ́n pín wọn sí àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n táwọn Ẹlẹ́rìí ò sí. Ìyẹn nìkan kọ́ o, wọn ò gbà káwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí jókòó tira wọn nígbà oúnjẹ. Ìbùkún ńlá ni ètò yìí jẹ́. Ní báyìí, àwọn arákùnrin wọ̀nyí lè wá máa ṣe ohun tó wà lọ́kàn wọn látọjọ́ yìí, ìyẹn láti wàásù fún ọ̀pọ̀ ẹlẹ́wọ̀n.

Èmi Nìkan Ń Dá Tọ́ Ọmọbìnrin Méjì

Ní gbogbo ìgbà yẹn, ìlú Rotterdam lèmi àtàwọn ọmọ mi obìnrin méjèèjì ń gbé. Òtútù ọdún 1943 àti 1944 yọyẹ́. Itòsí ẹ̀yìn ilé wa ni wọ́n máa ń kó àwọn ohun ìjà tí wọ́n fi ń já ọkọ̀ òfuurufú bọ́ sí, àwọn sójà orílẹ̀-èdè Jámánì ló sì jókòó síbẹ̀ tí wọ́n ń ṣọ́ ọ. Ilé wa ò tún jìnnà sí èbúté kan tó ń jẹ́ Waal, ibẹ̀ sì làwọn sójà kan fẹ́ gbógun tì. Torí náà, ewu níwá ewu lẹ́yìn ni. Yàtọ̀ síyẹn, kò fi bẹ́ẹ̀ sóúnjẹ. Kò tíì sígbà kan tá a fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà bíi tìgbà yẹn.—Òwe 3:5, 6.

Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni Esther lákòókò yẹn, òun ló sì máa lọ ń bá wa tò sórí ìlà láti gba oúnjẹ níbi tí wọ́n ti ń pín oúnjẹ lọ́fẹ̀ẹ́. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé tó bá kàn án báyìí ni wọ́n á sọ pé oúnjẹ ti tán. Lọ́jọ́ kan báyìí tó wá oúnjẹ lọ, ó kó sáàárín àwọn ọmọ ogun ojú òfuurufú tí wọ́n ń ju bọ́ǹbù. Ọkàn mi fẹ́rẹ̀ẹ́ domi nígbà tí mo gbọ́ ìró àwọn bọ́ǹbù náà, àmọ́ nígbà tí Esther dé láyọ̀ àtàlàáfíà, ọkàn mi wá balẹ̀, ó tiẹ̀ tún rí ewébẹ̀ díẹ̀ mú bọ̀. Nígbà tí mo fojú kàn án, ọ̀rọ̀ tó kọ́kọ́ jáde lẹ́nu mi ni “Kí ló ṣẹlẹ̀?” Ńṣe ló kàn rọra dá mi lóhùn pé: “Nígbà tí wọ́n ń ju bọ́ǹbù yẹn, nǹkan tí Dádì sọ pé kí n ṣe nígbà tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ ni mó ṣe, Dádì ní ‘Dùbúlẹ̀ gbalaja sílẹ̀ẹ́lẹ̀, máà gborí sókè o, kó o sì gbàdúrà.’ Ohun tó gbà mí nìyẹn!”

Tí mo bá ń sọ̀rọ̀, ó máa ń hàn pé ará Jámánì ni mi, nítorí náà, ààbò ló jẹ́ bí Esther ṣe lọ ń bá wa ra nǹkan lọ́jà. Àmọ́, àwọn sójà orílẹ̀-èdè Jámánì ò ṣaláì mọ̀ o, torí pé nígbà tí wọ́n rí Esther, ńṣe ni wọ́n da ìbéèrè bò ó. Àmọ́, Esther ò sọ àṣírí wa kankan fún wọn. Mo máa ń kọ́ Esther lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé, mo kọ́ ọ láti mọ̀ọ́kọ kó sì mọ̀ọ́kà nítorí pé kò láǹfààní àtilọ síléèwé, mó tún kọ́ ọ láwọn nǹkan míì pẹ̀lú.

Esther tún máa ń ràn mí lọ́wọ́ lóde ẹ̀rí. Kó tó di pé mo lọ sọ́dọ̀ àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Esther á rìn lọ ṣáájú wa láti wò bóyá á rẹ́ni tó ń wò wá. Á tún lọ wò ó bóyá ohun témi àtàwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi ṣe àmì wà níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tí ẹnì kan tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá fẹ́ kí n mọ̀ pé mo lè wá sọ́dọ̀ òun, onítọ̀hún á gbé òdòdó kékeré kan sí apá ibì kan lójú fèrèsé. Nígbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bá sì ń lọ lọ́wọ́, Esther á dúró síta, á máa ti Ruth àbúrò rẹ̀ káàkiri nínú kẹ̀kẹ́ ọmọdé, á máa fìyẹn ṣọ́nà láti mọ̀ bóyá ewu wà tàbí kò sí.

Wọ́n Mú Ferdinand Lọ sí Àgọ́ Ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Ti Sachsenhausen

Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí Ferdinand báyìí? Nígbà tó di oṣù September 1944, wọ́n ní kí Ferdinand àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn fẹsẹ̀ rìn lọ sí ibùdó ọkọ̀ ojú irin. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n kó gbogbo wọn tí iye wọn jẹ́ ọgọ́rin sínú ọkọ̀ ojú irin tí wọ́n fi ń kẹ́rù. Wọ́n fi korobá kọ̀ọ̀kan sínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn yàrá ọkọ̀ ojú irin náà láti yàgbẹ́ sí, wọ́n tún fi korobá kọ̀ọ̀kan pọnmi mímu sínú àwọn yàrá náà. Ìrìn àjò náà gbà wọ́n ní ọjọ́ mẹ́tà àti òru mẹ́ta pẹ̀lú bí wọ́n ṣe há wọn mọ́nú ọkọ̀ náà! Agbára káká ni atẹ́gùn fi ń wọlé. Àwọn ihò kéékèèké tó wà lára ọkọ̀ ojú irin náà nìkan latẹ́gùn ń gbà wọlé. Ooru tó mú wọn, ebi tó pa wọ́n, àti òùngbẹ tó gbẹ wọ́n kọjá ohun tá a lè fẹnu sọ ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti òórùn burúkú tó wà nínú ọkọ̀ ọ̀hún.

Ọkọ̀ ojú irin náà gúnlẹ̀ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Sachsenhausen tó burú jáì. Wọ́n gba gbogbo nǹkan táwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ní lọ́wọ́ wọn, àyàfi Bíbélì kékeré méjìlá táwọn Ẹlẹ́rìí kó dání wá!

Wọ́n kó Ferdinand àtàwọn arákùnrin mẹ́jọ kan lọ́ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Rathenow, tó jẹ́ ẹ̀ka ti Sachsenhausen kí wọ́n lè lọ máa ṣe ohun èlò ogun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n fi ikú halẹ̀ mọ́ wọn, síbẹ̀ wọ́n làwọn ò ní ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Láti lè fún ara wọn níṣìírí láti máa bá ìṣòtítọ́ wọn nìṣó, wọ́n máa ń ka ẹsẹ Bíbélì kan láràárọ̀, irú bíi Sáàmù 18:2, èyí ni wọ́n máa ronú lé lórí jálẹ̀ ọjọ́ náà. Èyí sì mú kí wọ́n lè máa ronú nípa nǹkan tẹ̀mí.

Níkẹyìn, ìró àwọn ohun ìjà ogun tí wọ́n ń gbọ́ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan àtàwọn ọmọ ogun Rọ́ṣíà ti sún mọ́ tòsí. Àgọ́ tí Ferdinand àtàwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ wà làwọn ọmọ ogún Rọ́ṣíà ti kọ́kọ́ dúró. Wọ́n fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà lóúnjẹ, wọ́n sì ní kí wọ́n kúrò ní àgọ́ náà. Nígbà tó fi máa di oṣù April ọdún 1945, àwọn ọmọ ogun Rọ́ṣíà sọ fáwọn ẹlẹ́wọ̀n náà pé kí kálukú máa lọ sílé rẹ̀.

Ìdílé Wa Tún Jọ Wà Pa Pọ̀

Nígbà tó di June 15, Ferdinand dé sórílẹ̀-èdè Netherlands. Àwọn arákùnrin tó wà nílùú Groningen gbà á tọwọ́ tẹsẹ̀. Kò pẹ́ tó fi mọ̀ pé a ò tíì kú, pé a wà níbi kan lórílẹ̀-èdè yẹn, àwọn ará sì fi tó wa létí pé Ferdinand ti padà dé. A wá ń fojú sọ́nà pé kódé-kódé. Bó ṣe di ọjọ́ kan nìyẹn, tí Ruth kígbe pè mí, ó ní: “Mọ́mì, ẹ wá wo ọkùnrin kan tó dúró sẹ́nu ọ̀nà!” Àṣé bàbá wa ni!

Ọ̀pọ̀ ìṣòro ló gba pé ká yanjú ká tó lè máa gbé pa pọ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀. A ò níbi tá a lè gbé, ìṣòro míì tún ni bá a ṣe máa forúkọ wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin pé a ti dọmọ ilẹ̀ Netherlands. Nítorí pé ilẹ̀ Jámánì ni ìlú ìbílẹ̀ wa, ojú ẹni ìtanù làwọn aláṣẹ Netherlands fi wò wá lọ́dún bíi mélòó kan. Àmọ́ níkẹyìn, gbogbo nǹkan lójú, a wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé irú ìgbésí ayé tó ti ń wù wá tipẹ́, ìyẹn kí ìdílé wa jọ máa sin Jèhófà pa pọ̀.

“Jèhófà Ni Mo Gbẹ́kẹ̀ Lé”

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí gbogbo nǹkan yìí ti ṣẹlẹ̀, ìgbàkigbà tí èmi àti Ferdinand bá wà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa táwọn náà fojú winá irú nǹkan tá a fojú winá rẹ̀, a máa ń rí i pé Jèhófà fi ìfẹ́ tọ́ wa sọ́nà láwọn àkókó ìṣòro yẹn. (Sáàmù 7:1) Inú wa dùn pé láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, Jèhófà jẹ́ ká lè máa gbárùkù ti iṣẹ́ Ìjọba náà. Nígbà tá a bá jọ ń sọ̀rọ̀, á sábà máa ń sọ pé ayọ̀ ńlá ló jẹ́ fún wa pé a fi ìgbà ọ̀dọ́ wa sin Jèhófà.—Oníwàásù 12:1.

Lẹ́yìn tí inúnibíni Ìjọba Násì ti kásẹ̀ nílẹ̀, ó lé ní àádọ́ta ọdún tí èmi àti Ferdinand fi jùmọ̀ sin Jèhófà kó tó di pé Ferdinand parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní December 20, 1995. Mo máa tó pé ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98]. Ojoojúmọ́ ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé àwọn ọmọ wa tì wá lẹ́yìn ní gbogbo àkókò tí nǹkan ò rọgbọ yẹn, mó sì ń dúpẹ́ pé mo ṣì lè ṣe ohun tí agbára mi ká nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà fún ògo orúkọ rẹ̀. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún gbogbo ohun tó ṣe fún mi, mo sì fẹ́ láti máa ṣe ohun tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì tí mo fi ṣe atọ́nà mi yẹn, tó sọ pé: “Ní tèmi, Jèhófà ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.”— Sáàmù 31:6.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Èmi àti Ferdinand rèé ní October ọdún 1932

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n ń pè ní “Almina” tí wọ́n fi ṣe iṣẹ́ ìwàásù àtàwọn tó wà nínú rẹ̀ rèé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Èmi, Ferdinand àtàwọn ọmọ wa