Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Àwọn Onídàájọ́

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Àwọn Onídàájọ́

Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Àwọn Onídàájọ́

KÍ NI Jèhófà máa ń ṣe nígbà táwọn èèyàn rẹ̀ bá kẹ̀yìn sí i tí wọ́n sì lọ ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run èké? Bí wọ́n bá ń ṣàìgbọràn sí i léraléra ńkọ́, tó jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro nìkan ni wọ́n máa ń ké pè é pé kó gba àwọn? Ṣé Jèhófà máa ń ṣọ̀nà àbáyọ fún wọn lákòókò yẹn náà? Ìwé Àwọn Onídàájọ́ dáhùn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè pàtàkì mìíràn. Nǹkan bí ọdún 1100 ṣáájú Sànmánì Tiwa ni wòlíì Sámúẹ́lì parí kíkọ ìwé yìí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú rẹ̀ sì gbà tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ọgbọ̀n [330] ọdún, ìyẹn lẹ́yìn ikú Jóṣúà sí ìgbà tí ọba àkọ́kọ́ jẹ ní Ísírẹ́lì.

Níwọ̀n bí ìwé Àwọn Onídàájọ́ ti jẹ́ apá kan Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó lágbára, a nílò rẹ̀ gan-an. (Hébérù 4:12) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amúni-ronú-jinlẹ̀ tó wà nínú rẹ̀ yóò jẹ́ ká túbọ̀ lóye irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Ẹ̀kọ́ táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú rẹ̀ yóò kọ́ wa á mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i, á sì ràn wá lọ́wọ́ láti di “ìyè tòótọ́” mú gírígírí, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. (1 Tímótì 6: 6:12, 19; 2 Pétérù 3:13) Àwọn ohun tí Jèhófà ṣe láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ là jẹ́ àpẹẹrẹ ìdáǹdè ńlá tí Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, ń mú bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.

KÍ NÌDÍ TÁWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ FI NÍLÒ ÀWỌN ONÍDÀÁJỌ́

(Àwọn Onídàájọ́ 1:1–3:6)

Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣẹ́gun àwọn ọba ilẹ̀ Kénáánì tán lábẹ́ ìdarí Jóṣúà, ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan lọ síbi tí ilẹ̀ tí wọ́n jogún wà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé inú rẹ̀. Àmọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò pa àwọn tó ń gbé ní ilẹ̀ náà run tán. Èyí sì wá di ìdẹkùn ńlá fún wọn.

Ìran tó dé lẹ́yìn ọjọ́ Jóṣúà “kò mọ Jèhófà tàbí iṣẹ́ tí ó ti ṣe fún Ísírẹ́lì.” (Àwọn Onídàájọ́ 2:10) Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ àwọn ará Kénáánì, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn. Ni Jèhófà bá fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè pọ́n wọn lójú. Àmọ́ nígbà tíyà pá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lórí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Ọlọ́run òtítọ́ pé kó gbà àwọn. Àárín àkókò tí ìbọ̀rìṣà àti ìwàkiwà gbilẹ̀ yìí, táwọn ọ̀tá sì ń fojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbolẹ̀ ni Jèhófà gbé àwọn onídàájọ́ dìde láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:

1:2, 4—Nígbà tí wọ́n pín ilẹ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí nìdí tó fi jẹ́ pé ẹ̀yà Júdà ni wọ́n kọ́kọ́ sọ fún pé kó lọ máa gbé lórí ilẹ̀ tirẹ̀? Níwọ̀n bí Rúbẹ́nì ti jẹ́ àkọ́bí Jákọ́bù, ẹ̀yà Rúbẹ́nì ló yẹ kí àǹfààní yìí tọ́ sí. Àmọ́, nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jákọ́bù sọ nígbà tó kù díẹ̀ kó kú, ó sọ pé Rúbẹ́nì kò ní ta yọ nítorí ó ti pàdánù ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí. Ó sì sọ pé Síméónì àti Léfì ní tiwọn yóò fọ́n káàkiri àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítorí ìwà òǹrorò tí wọ́n hù. (Jẹ́nẹ́sísì 49:3-5, 7) Nítorí náà, ẹni tó kàn ni Júdà, ọmọkùnrin kẹrin tí Jákọ́bù bí. Ẹ̀yà Síméónì bá ẹ̀yà Júdà lọ sórí ilẹ̀ rẹ̀, wọ́n sì rí ilẹ̀ díẹ̀ gbà káàkiri ìpínlẹ̀ Júdà, nítorí pé ilẹ̀ náà gbòòrò gan-an. aJóṣúà 19:9.

1:6, 7—Kí nìdí tí wọ́n fi máa ń gé àtàǹpàkò ọwọ́ àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ àwọn ọba tí wọ́n bá mú lójú ogun? Ó dájú pé ẹni tí kò bá ní àtàǹpàkò ọwọ́ àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ kò ní lè jagun. Tí sójà kan ò bá ní àtàǹpàkò ọwọ́, báwo ló ṣe máa di idà tàbí ọ̀kọ̀ mú? Téèyàn ò bá sì ní àtàǹpàkò ẹsẹ̀ mọ́, onítọ̀hún kò ní lè dúró dáadáa.

Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:

2:10-12. A gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé ká má bàa ‘gbàgbé gbogbo ìgbòkègbodò iṣẹ́ Jèhófà.’ (Sáàmù 103:2) Ó ṣe pàtàkì káwọn òbí gbin òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ́kàn àwọn ọmọ wọn dáadáa.—Diutarónómì 6:6-9.

2:14, 21, 22. Jèhófà máa ń gbà kí nǹkan burúkú ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn rẹ̀ tó bá jẹ́ aláìgbọràn kó lè fi kọ́ wọn lọ́gbọ́n, kó sì sọ wọ́n dọ̀tun, kí wọ́n lè padà sọ́dọ̀ rẹ̀.

JÈHÓFÀ GBÉ ÀWỌN ONÍDÀÁJỌ́ DÌDE

(Àwọn Onídàájọ́ 3:7–16:31)

Àwọn àkọsílẹ̀ tó wúni lórí nípa ìwà akin táwọn onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì hù fi hàn pé wọ́n ṣe gudugudu méje. Ótíníẹ́lì lẹni àkọ́kọ́ lára wọn, òun ló fòpin sí ìyà ọdún mẹ́jọ tí ọba ilẹ̀ Mesopotámíà kan fi jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ kan tí Éhúdù dá àti ìgboyà rẹ̀ mú kó ṣeé ṣe fún un láti pa Ẹ́gílónì ọba Móábù tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀. Ṣámúgárì, akíkanjú ọkùnrin, dá nìkan pa ẹgbàáta [600] àwọn Filísínì, ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù ló sì fi pa wọ́n. Nítorí ìṣírí tí Dèbórà tó jẹ́ wòlíì obìnrin fún Bárákì, pa pọ̀ pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn Jèhófà, òun àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọmọ ogun rẹ̀ tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ dira ogun ṣẹ́gun ẹgbẹ́ ogún alágbára ti Sísérà. Jèhófà lo Gídíónì, ó jẹ́ kí òun àtàwọn ọ̀ọ́dúnrún [300] ọkùnrin rẹ̀ ṣẹ́gun àwọn ará Mídíánì.

Jèhófà lo Jẹ́fútà láti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ámónì. Tólà, Jáírì, Íbísánì, Ẹ́lónì àti Ábídónì wà lára àwọn ọkùnrin méjìlá tí wọ́n ṣe onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì. Sámúsìnì tó bá àwọn Filísínì jà ló kẹ́yìn nínú àwọn onídàájọ́ wọ̀nyí.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:

4:8—Kí nìdí tí Bárákì fi sọ pé dandan ni kí Dèbórà tó jẹ́ wòlíì obìnrin bá òun lọ sójú ogun? Kò sí àní-àní pé ńṣe ni Bárákì ń ronú pé òun ò lè dá nìkan kojú ẹgbẹ́ ogun Sísérà. Bí wòlíì obìnrin náà bá bá a lọ, èyí á mú un dá òun àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ lójú pé Ọlọ́run ń tọ́ àwọn sọ́nà, ọkàn wọn á sì balẹ̀. Nítorí náà, bí Bárákì ṣe sọ pé dandan ni kí Dèbórà bá òun lọ kò túmọ̀ sí pé ojo èèyàn ni, ńṣe ló fi hàn pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára.

5:20—Báwo làwọn ìràwọ̀ ṣe jà fún Bárákì láti ọ̀run? Bíbélì kò sọ bóyá ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé àwọn áńgẹ́lì ran Bárákì lọ́wọ́, kò sọ bóyá ńṣe làwọn nǹkan kan jábọ́ látọ̀run táwọn amòye Sísérà kà sí àmì ohun burúkú, tàbí bóyá ó dúró fún àsọtẹ́lẹ̀ táwọn awòràwọ̀ sọ fún Sísérà, èyí tó já sírọ́. Àmọ́ ó dájú pé Ọlọ́run ran Bárákì lọ́wọ́ lọ́nà kan.

7:1-3; 8:10—Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n [32,000] ọkùnrin tó fẹ́ bá Gídíónì lọ sójú ogun ti pọ̀ jù láti bá ẹgbẹ̀rún márùnléláàádóje [135,000] ọmọ ogun ọ̀tá jà? Ìdí ni pé Jèhófà ló máa mú kí Gídíónì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣẹ́gun. Ọlọ́run kò fẹ́ kí wọ́n máa rò pé agbára àwọn làwọn fi ṣẹ́gun àwọn ará Mídíánì.

11:30, 31—Nígbà tí Jẹ́fútà ń jẹ́jẹ̀ẹ́, ṣé èèyàn ló ní lọ́kàn láti fi rúbọ? Jẹ́fútà ò lè ní irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́kàn láé, nítorí Òfin Mósè sọ pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ ẹnikẹ́ni tí ń mú ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ la iná kọjá.” (Diutarónómì 18:10) Àmọ́, Jẹ́fútà mọ̀ pé èèyàn ló máa wá pàdé òun kì í ṣe ẹran. Kò dájú pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń sin ẹran tí wọ́n fi ń rúbọ nínú ilé wọn. Kò sì ní jẹ́ nǹkan bàbàrà bó bá jẹ́ ẹran ló ṣèlérí láti fi rúbọ. Jẹ́fútà mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọmọbìnrin òun ló máa jáde wá pàdé òun látinú ilé. Ẹni tó bá wá pàdé rẹ̀ yìí ni yóò fi rúbọ “gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun,” ìyẹn ni pé yóò yọ̀ọ̀da onítọ̀hún pátápátá fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ní ibi mímọ́.

Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:

3:10. Ẹ̀mí Jèhófà ló lè jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ àwọn ohun tá à ń lé nípa tẹ̀mí, kì í ṣe ọgbọ́n tiwa.—Sáàmù 127:1.

3:21. Éhúdù lo ìdá rẹ̀ dáadáa ó sì tún ní ìgboyà. A gbọ́dọ̀ kọ́ bá a ṣe lè lo “idà ẹ̀mí” dáadáa, ìyẹn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí túmọ̀ sí pé á gbọ́dọ̀ máa fi ìgboyà lo Ìwé Mímọ́ nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí.—Éfésù 6:17; 2 Tímótì 2:15.

6:11-15; 8:1-3, 22, 23. Gídíónì jẹ́ ẹni tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, ẹ̀kọ́ pàtàkì mẹ́ta la sì rí kọ́ lára rẹ̀: (1) Bí ètò Jèhófà bá fún wa ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan, kò yẹ ká máa ronú nípa òkìkí tàbí iyì tá a máa rí nínú rẹ̀ bí kò ṣe iṣẹ́ tó wà nídìí rẹ̀. (2) Bí nǹkan bá da àwa àtàwọn tó máa ń tètè bínú pọ̀, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. (3) Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, ọ̀rọ̀ nípa ipò kó ní ká wa lára.

6:17-22, 36-40. Àwa náà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, ká má ṣe máa “gba gbogbo àgbéjáde onímìísí gbọ́.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká máa “dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (1 Jòhánù 4:1) Kí arákùnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di àlàgbà lè rí i dájú pé ìmọ̀ràn tí òun ń ronú láti fúnni jẹ́ èyí tó bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú dáadáa, ó bọ́gbọ́n mu kó fọ̀rọ̀ lọ àwọn alàgbà tó nírìírí jù ú lọ.

6:25-27. Gídíónì lo ọgbọ́n inú kó má bàa múnú bí àwọn alátakò rẹ̀ láìnídìí. Báwa náà ti ń wàásù ìhìn rere, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má ṣe múnú bí àwọn èèyàn nítorí ọ̀nà tá a gbà ń sọ̀rọ̀.

7:6. Bá a ti ń ṣe iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà, ó yẹ ká máa fara wé àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin tí Gídíónì yàn, ká sì wà lójúfò.

9:8-15. Kì í ṣe ìwà tó bọ́gbọ́n mu rárá láti máa gbéra ga ká sì máa ronú láti jẹ́ ọ̀gá tàbí láti jẹ́ ẹni tí agbára wà lọ́wọ́ rẹ̀!

11:35-37. Kò sí àní-àní pé àpẹẹrẹ rere Jẹ́fútà ló mú kí ọmọ rẹ̀ ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, tó sì mú kó fara rẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Àwọn òbí lóde òní lè firú àpẹẹrẹ rere bẹ́ẹ̀ lélẹ̀ fáwọn ọmọ wọn.

11:40. Tá a bá yin ẹnì kan tó yọ̀ọ̀da ara rẹ̀ tinútinú láti ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, èyí á fún onítọ̀hún níṣìírí.

13:8. Báwọn òbí ti ń kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́, ó yẹ kí wọ́n máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ àwọn sọ́nà, ó sì yẹ kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀.—2 Tímótì 3:16.

14:16, 17; 16:16. Béèyàn bá ń sunkún ṣáá tàbí tó ń fi ọ̀rọ̀ pin ẹlòmíràn lẹ́mìí torí kọ́wọ́ rẹ̀ lè tẹ ohun kan, èyí lè da àárín òun àti onítọ̀hún rú.—Òwe 19:13; 21:19.

ÀWỌN Ẹ̀ṢẸ̀ MÌÍRÀN TÁWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ DÁ

(Àwọn Onídàájọ́ 17:1–21:25)

Ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá méjì ló wà nínú apá tó kẹ́yìn ìwé Àwọn Onídàájọ́. Àkọ́kọ́ ni ti ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Míkà, tó ṣe ère kan sínú ilé rẹ̀ tó sì gba ọmọ Léfì kan pé kó máa ṣe àlùfáà fún òun. Lẹ́yìn táwọn ẹ̀yà Dánì pa ìlú Láíṣì tó tún ń jẹ́ Léṣémù run, wọ́n tún ìlú náà kọ́ wọ́n sì sọ ọ́ ní Dánì. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn ère tí Míkà ṣe, wọ́n sì ń lo àlùfáà Míkà, bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn mìíràn ní Dánì nìyẹn. Kò sí àní-àní pé kí Jóṣúà tó kú ni wọ́n ti gba ìlú Láíṣì yìí.—Jóṣúà 19:47.

Kò pẹ́ lẹ́yìn ikú Jóṣúà ni ìṣẹ̀lẹ̀ kejì wáyé. Àwọn ọkùnrin kan ní ìlú Gíbíà tó jẹ́ ìlú àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì para pọ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀ kan tó burú jáì, díẹ̀ ló sì kù kí wọ́n pa gbogbo ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì run nítorí ẹ̀ṣẹ̀ náà. Ẹgbẹ̀ta [600] ọkùnrin péré ló ṣẹ́ kù lára wọn. Àmọ́ àwọn tó ṣẹ́ kù náà ta ọgbọ́n kan tó jẹ́ kí wọ́n rí ìyàwó fẹ́, wọn sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ padà, débi pé, nígbà tó fi máa di àkókò tí Dáfídì jọba, wọ́n ti ní jagunjagun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀kẹ́ mẹ́ta [60,000].—1 Kíróníkà 7:6-11.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́

17:6; 21:25—Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ‘ohun tó tọ̀nà ní ojú kálukú tó sì ti mọ́ kálukú lára láti máa ṣe ló ń ṣe,’ ǹjẹ́ èyí dá wàhálà kankan sílẹ̀? Rárá o, nítorí Jèhófà ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètò tí yóò máa darí àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó fún wọn ní Òfin, ó tún ṣètò àwọn àlùfáà tí yóò máa kọ́ wọn ní ọ̀nà rẹ̀. Nígbà tí ọ̀ràn pàtàkì kan bá sì jẹ yọ, àlùfáà àgbà lè lo Úrímù àti Túmímù láti fi wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. (Ẹ́kísódù 28:30) Ìlú kọ̀ọ̀kan tún láwọn àgbà ọkùnrin tí wọ́n lè fún àwọn èèyàn nímọ̀ràn tó yè kooro. Ọmọ Ísírẹ́lì tó bá tẹ̀ lé àwọn ètò wọ̀nyí máa ń ní ẹ̀rí ọkàn tó dára. Bó bá wá ṣe “ohun tí ó tọ̀nà ní ojú tirẹ̀” níbàámu pẹ̀lú àwọn ètò náà, àbájáde rẹ̀ máa ń dára. Àmọ́ bí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá dágunlá sí Òfin Ọlọ́run tó sì ń fúnra rẹ̀ pinnu bó ṣe máa hùwà àti bó ṣe máa jọ́sìn, àbájáde rẹ̀ kì í dára.

20:17-48—Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣẹ́gun àwọn ẹ̀yà tó kù lẹ́ẹ̀mejì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni ìyà tọ́ sí? Ìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí wọ́n ṣe àwọn ẹ̀yà yòókù tó jẹ́ olóòótọ́ bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú lákọ̀ọ́kọ́ ni pé, ó fẹ́ mọ̀ bóyá wọn ò ní yí ìpinnu wọn padà láti mú ìwàkiwà kúrò ní Ísírẹ́lì.

Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:

19:14, 15. Báwọn èèyàn Gíbíà ò ṣe tọ́jú àlejò fi hàn pé wọn kì í ṣe ọmọlúwàbí rárá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n “máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò.”—Róòmù 12:13.

Ìdáǹdè Tó Ń Bọ̀ Lọ́nà

Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run tí Kristi Jésù yóò ṣàkóso rẹ̀ yóò pa ayé burúkú yìí run yóò sì gba àwọn adúróṣánṣán àtàwọn aláìlẹ́bi là. (Òwe 2:21, 22; Dáníẹ́lì 2:44) ‘Gbogbo ọ̀tá Jèhófà ni yóò ṣègbé nígbà yẹn, àwọn olùfẹ́ rẹ yóò sì rí bí ìgbà tí oòrùn bá jáde lọ nínú agbára ńlá rẹ̀.’ (Àwọn Onídàájọ́ 5:31) Ẹ jẹ́ ká fi hàn pé á wà lára àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nípa fífi àwọn ohun tá a kọ́ nínú ìwé Àwọn Onídàájọ́ sílò.

Kókó kan tó fára hàn lọ́pọ̀ ìgbà nínú ìwé Àwọn Onídàájọ́ tó sì jẹ́ òtítọ́ pọ́ńbélé ni pé: Ṣíṣègbọràn sí Jèhófà máa ń jẹ́ kéèyàn rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà, àìgbọràn sì máa ń kóni sí ìyọnu. (Diutarónómì 11:26-28) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ ‘onígbọràn láti inú ọkàn’ bá a ti ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run!—Róòmù 6:17; 1 Jòhánù 2:17.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wọn ò fún àwọn ọmọ Léfì ní ogún kankan ní Ilẹ̀ Ìlérí yàtọ̀ sí ìlú méjìdínláàádọ́ta [48] tó wà káàkiri ilẹ̀ Ísírẹ́lì.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 25]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

“Jèhófà a sì gbé àwọn onídàájọ́ dìde, wọn a sì gbà wọ́n là kúrò ní ọwọ́ àwọn tí ń kó wọn ní ìkógun.”—Àwọn Onídàájọ́ 2:16

ÀWỌN ONÍDÀÁJỌ́

1. Ótíníẹ́lì

2. Éhúdù

3. Ṣámúgárì

4. Bárákì

5. Gídíónì

6. Tólà

7. Jáírì

8. Jẹ́fútà

9. Íbísánì

10. Ẹ́lónì

11. Ábídónì

12. Sámúsìnì

DÁNÌ

MÁNÁSÈ

NÁFÚTÁLÌ

ÁṢÉRÌ

SÉBÚLÚNÌ

ÍSÁKÁRÌ

MÁNÁSÈ

GÁDÌ

ÉFÚRÁÍMÙ

DÁNÌ

BẸ́ŃJÁMÍNÌ

RÚBẸ́NÌ

JÚDÀ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ẹ̀kọ́ wo lo ri kọ́ nínú bí Bárákì ṣe sọ pé dandan ní kí Dèbórà bá òun lọ sójú ogun?