Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Báwo ni Sámúsìnì ṣe lè fọwọ́ kan òkú èèyàn àti tẹran tó pa, kó ṣì tún jẹ́ Násírì?

Lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ọjọ́un, ẹnì kan lè fínnúfíndọ̀ jẹ́jẹ̀ẹ́ láti jẹ́ Násírì fún àkókò kan pàtó. a Ọ̀kan lára àwọn òfin tó de ẹni tó bá jẹ́ irú ẹ̀jẹ́ bẹ́ẹ̀ nìyí: “Ní gbogbo ọjọ́ yíya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Jèhófà, kò gbọ́dọ̀ sún mọ òkú ọkàn èyíkéyìí. Òun kò lè tìtorí baba rẹ̀ pàápàá tàbí ìyá rẹ̀ tàbí arákùnrin rẹ̀ tàbí arábìnrin rẹ̀ sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin nígbà tí wọ́n bá kú.” Ká lẹ́nì kan wá “kú lójijì lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀” ńkọ́? Bó bá ṣèèṣì fọwọ́ kan òkú lọ́nà yìí, jíjẹ́ tó jẹ́ Násírì bà jẹ́ nìyẹn. Ìdí rèé tí òfin náà fi sọ pé: “Àwọn ọjọ́ ti àtẹ̀yìnwá ni a kì yóò sì kà.” Ó di dandan kó ṣe ìwẹ̀mọ́ kó sì tún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ọjọ́ tó fẹ́ fi jẹ́ Násírì náà padà.—Númérì 6:6-12.

Àmọ́ Násírì ti Sámúsìnì yàtọ̀. Kí ìyá Sámúsínì tó lóyún rẹ̀ ni áńgẹ́lì Jèhófà ti sọ fún un pé: “Wò ó! dájúdájú, ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, kí abẹ fẹ́lẹ́ má sì kan orí rẹ̀, nítorí pé Násírì Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò dà bí ó bá ti jáde láti inú ikùn wá; òun sì ni ẹni tí yóò mú ipò iwájú nínú gbígba Ísírẹ́lì là kúrò ní ọwọ́ àwọn Filísínì.” (Onídàájọ́ 13:5) Sámúsìnì kò jẹ́jẹ̀ẹ́ láti di Násírì. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló yàn án, títí ọjọ́ ayé rẹ̀ ló sì máa fi jẹ́ Násírì. Òfin tó sọ pé ẹni tó jẹ́ Násírì kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan òkú kò de Sámúsínì. Bó bá dè é, tó sì wá lọ ṣèèṣì fọwọ́ kan òkú, báwo ló ṣe fẹ́ padà bẹ̀rẹ̀ Násírì tó ti jẹ́ látìgbà tí wọ́n ti bí i? Nítorí náà, a lè rí i pé ohun tí Ọlọ́run béèrè lọ́wọ́ àwọn tó fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn jẹ́ Násírì yàtọ̀ láwọn ọ̀nà kan sí tàwọn tó jẹ́ pé fúnra wọn ni wọ́n finnúfíndọ̀ di Násírì.

Wo àṣẹ tí Jèhófà pa fáwọn mẹ́ta kan tí Bíbélì dárúkọ wọn, tó jẹ́ pé gbogbo ọjọ́ ayé wọn ni wọ́n fi jẹ́ Násírì, ìyẹn Sámúsìnì, Sámúẹ́lì àti Jòhánù Oníbatisí. Bá a ti sọ níṣàájú, Ọlọ́run sọ pé Sámúsìnì kò gbọ́dọ̀ gé irun orí rẹ̀. Nígbà tí Hánà ń jẹ́ ẹ̀jẹ́ nípa ọmọ tí kò tíì lóyún rẹ̀, ìyẹn Sámúẹ́lì, ó sọ pé: “Èmi yóò fi í fún Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ fẹ́lẹ́ kì yóò sì kan orí rẹ̀.” (1 Sámúẹ́lì 1:11) Ní ti Jòhánù Oníbatisí, áńgẹ́lì Jèhófà sọ pé: “Kò gbọ́dọ̀ mu wáìnì àti ohun mímu líle rárá.” (Lúùkù 1:15) Ìyẹn nìkan kọ́ o, “aṣọ [Jòhánù] jẹ́ irun ràkúnmí àti àmùrè awọ yí ká abẹ́nú rẹ̀; oúnjẹ rẹ̀ pẹ̀lú jẹ́ eéṣú àti oyin ìgàn.” (Mátíù 3:4) Kò sí ìkankan nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí tí Jèhófà pàṣẹ fún pé kó má ṣe sún mọ́ òkú ohunkóhun.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Násírì ni Sámúsìnì, ó wà lára àwọn ònídàájọ́ tí Jèhófà gbé dìde láti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ àwọn tó ń fipá kó ẹrù wọn lọ. (Onídàájọ́ 2:16) Nígbà tó sì ń ṣe iṣẹ́ náà, ó fọwọ́ kan òkú èèyàn. Nígbà kan, Sámúsìnì pa ọgbọ̀n àwọn Filísínì ó sì bọ́ aṣọ tó wà lọ́rùn wọn. Lẹ́yìn náà, ó lọ fi idà pa àwọn ọ̀tá, “ní títo àwọn ẹsẹ̀ lórí àwọn itan jọ pelemọ pẹ̀lú ìpakúpa ńláǹlà.” Ó tún mú párì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì fi pa ẹgbẹ̀rún kan ọkùnrin. (Onídàájọ́ 14:19; 15:8, 15) Nípa ojú rere àti ìtìlẹ́yìn Jèhófà ni Sámúsìnì fi lè ṣe gbogbo èyí. Ìwé Mímọ́ sọ pé Sámúsìnì jẹ́ ọkùnrin tá a lè fara wé ìgbàgbọ́ rẹ̀.—Hébérù 11:32; 12:1.

Ǹjẹ́ ohun tí Bíbélì sọ pé Sámúsìnì ya kìnnìún kan sí méjì “bí ẹni ya akọ ọmọ ẹran sí méjì” fi hàn pé fífọwọ́ ya ọmọ ewúrẹ́ sí méjì jẹ́ àṣà tó wọ́pọ̀ nígbà ayé Sámúsìnì?

Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé fífọwọ́ ya ọmọ ewúrẹ́ sí méjì jẹ́ àṣà tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn lákòókò àwọn ònídàájọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Onídàájọ́ 14:6 sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára [Sámúsìnì], tí ó fi ya [ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ kan] sí méjì, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹni ya akọ ọmọ ẹran sí méjì, kò sì sí nǹkan kan rárá ní ọwọ́ rẹ̀.” Ó jọ pé àfiwé lásán ni gbólóhùn yìí.

Gbólóhùn náà ‘ó ya á sí méjì’ lè nítumọ̀ méjì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ párì ẹ̀rẹ̀kẹ̀ kìnnìún náà ni Sámúsìnì fọwọ́ ya sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ tàbí kó jẹ́ pé ó fa kìnnìún náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ lọ́nà kan ṣá. Bó bá jẹ́ fífa párì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kìnnìún náà ya ni gbólóhùn náà túmọ̀ sí, a jẹ́ pé ṣíṣe irú ohun kan náà fún ọmọ ewúrẹ́ kò lè ṣòro fún èèyàn tí ò lágbára bíi tirẹ̀. Ní ti Sámúsìnì, àfiwe náà fi hàn pé bó ṣe fọwọ́ lásán pa kìnnìún kò ṣòro fún un rárá, bí ẹni pé ọmọ ewúrẹ́ lásán ló fọwọ́ ya ni. Àmọ́ bó bá jẹ́ pé ńṣe ló fa kìnnìún náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ńkọ́? A jẹ́ pé àfiwé lásán ni gbólóhùn náà jẹ́. Ohun tí àfiwé náà yóò sì túmọ̀ sí ni pé ẹ̀mí Jèhófà ló fún Sámúsìnì lágbára tó fi lè ṣe nǹkan tó gba agbára àrà ọ̀tọ̀ yìí. Èyí ó wù kó jẹ́, ohun tí àfiwé inú Àwọn Onídàájọ́ 14:6 yìí dúró fún ni pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, kìnnìún ríròrò kò jẹ́ nǹkan kan sí Sámúsìnì, bí ọmọ ewúrẹ́ ò ṣe jẹ́ nǹkan kan sẹ́ni tí ò lágbára bíi Sámúsìnì.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ẹni tó jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣe Násírì ni yóò pinnu àkókò tí òun fẹ́ fi ṣe é. Àmọ́, níbàámu pẹ̀lú ìlànà àwọn Júù, àkókò téèyàn lè fi jẹ́ Násírì kò gbọ́dọ̀ dín sí ọgbọ̀n ọjọ́. Bó bá dín síyẹn, wọ́n gbà pé ẹ̀jẹ́ náà kò ní nítumọ̀ mọ́.