Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìran Tó Jẹ́ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìjọba Ọlọ́run Nímùúṣẹ

Ìran Tó Jẹ́ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìjọba Ọlọ́run Nímùúṣẹ

Ìran Tó Jẹ́ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìjọba Ọlọ́run Nímùúṣẹ

“Ẹ . . . ń ṣe dáadáa ní fífún [ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀] ní àfiyèsí gẹ́gẹ́ bí fún fìtílà tí ń tàn ní ibi tí ó ṣókùnkùn.”—2 PÉTÉRÙ 1:19.

1. Oríṣi àwùjọ èèyàn méjì wo ló wà lóde òní?

 YÁNPỌNYÁNRIN ló gbayé kan lóde òní. Bí àwọn kan ṣe ń ba omi àti afẹ́fẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀ làwọn apániláyà náà ń ṣọṣẹ́ káàkiri ayé, apá ò tiẹ̀ wá fẹ́ ká ìṣòro tí ń bẹ nínú ayé mọ́ báyìí. Kódà, àwọn ẹ̀sìn ayé pàápàá ò lè yanjú àwọn ìṣòro náà. Tá a bá tiẹ̀ ní ká sọ ọ́, ẹ̀sìn gan-an ló túbọ̀ ń dá kún àwọn ìṣòro náà nítorí pé òun ló ń gbin ẹ̀mí agídí, ẹ̀mí ìkórìíra àti ẹ̀mí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni sínú àwọn èèyàn. Àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ló sì ń fa ìpínyà. Òótọ́ pọ́ńbélé ni ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé, ‘ìṣúdùdù nínípọn ti bo àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.’ (Aísáyà 60:2) Àmọ́, bí òkùnkùn ṣe bò ayé yìí tó, ẹgbàágbèje àwọn èèyàn ṣì wà tí kò bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Kí nìdí tí wọn ò fi bẹ̀rù? Ìdí ni pé wọ́n kọbi ara sí àwọn ohun tí Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ tó dà bí “fìtílà tí ń tàn ní ibi tí ó ṣókùnkùn.” Wọ́n máa ń jẹ́ kí “ọ̀rọ̀” Ọlọ́run tí ń bẹ nínú Bíbélì tọ́ wọn sọ́nà.—2 Pétérù 1:19.

2. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa “àkókò òpin,” àwọn wo ni Ọlọ́run fún ní ìjìnlẹ̀ òye nípa tẹ̀mí?

2 Wòlíì Dáníẹ́lì kọ̀wé nípa “àkókò òpin” pé: “Ọ̀pọ̀ yóò máa lọ káàkiri, ìmọ̀ tòótọ́ yóò sì di púpọ̀ yanturu. Ọ̀pọ̀ yóò wẹ ara wọn mọ́, wọn yóò sì sọ ara wọn di funfun, a ó sì yọ́ wọn mọ́. Dájúdájú, àwọn ẹni burúkú yóò máa gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà burúkú, àwọn ẹni burúkú kankan kì yóò sì lóye; ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò lóye.” (Dáníẹ́lì 12:4, 10) Àwọn tó ń fi tọkàntọkàn “lọ káàkiri” nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ jinlẹ̀jinlẹ̀, tí wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà inú rẹ̀, tí wọ́n sì ń sapá láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nìkan ló láǹfààní láti ní ìjìnlẹ̀ òye nípa tẹ̀mí.—Mátíù 13:11-15; 1 Jòhánù 5:20.

3. Òtítọ́ tó ṣe pàtàkì wo làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóye láwọn ọdún 1870?

3 Láwọn ọdún 1870 ṣáájú kí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tó bẹ̀rẹ̀ ni Jèhófà Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ káwọn èèyàn yìí mọ ìtumọ̀ “àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìjọba ọ̀run.” (2 Tímótì 3:1-5; Mátíù 13:11) Ìgbà yẹn làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lóye pé a ò ní fojú rí Jésù nígbà tó bá padà wá. Òye yìí sì yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀ èèyàn. Lẹ́yìn tí Jésù bá gorí ìtẹ́ lọ́run, ìpadàbọ̀ rẹ̀ yóò jẹ́ láti pàfiyèsí sí ayé. Àwọn àmì kan tá a lè fojú rí yóò wá fara hàn láti jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ̀ pé ó ti padà wá lọ́nà tí kò ṣeé fojú rí.—Mátíù 24:3-14.

Ìgbà Tí Ìran Alásọtẹ́lẹ̀ Náà Nímùúṣẹ

4. Báwo ni Jèhófà ṣe ń mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní lágbára sí i?

4 Ìran ológo yìí ń ṣàpẹẹrẹ irú ògo tí Kristi yóò ní nígbà tó bá di Ọba. (Mátíù 17:1-9) Nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn kúrò lẹ́yìn Jésù nítorí kò ṣe ohun tí wọ́n retí pé yóò ṣe, tó sì jẹ́ pé àwọn nǹkan ọ̀hún ò bá Ìwé Mímọ́ mu, ńṣe ni ìran ológo náà túbọ̀ mú kí ìgbàgbọ́ Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù lágbára sí i. Bákan náà, lákòókò òpin yìí, Jèhófà ń mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní lágbára sí i nípa mímú kí wọ́n túbọ̀ lóye ìmúṣẹ ìran ológo yẹn àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wé mọ́ ọn. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn nǹkan tẹ̀mí tó ń fún ìgbàgbọ́ lókun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí.

5. Ta ni Ìràwọ̀ Ojúmọ́ náà, ìgbà wo ló “yọ,” báwo ló sì ṣe “yọ”?

5 Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa ìran ológo náà, ó kọ̀wé pé: “Nítorí náà, a ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a túbọ̀ mú dáni lójú; ẹ sì ń ṣe dáadáa ní fífún un ní àfiyèsí gẹ́gẹ́ bí fún fìtílà tí ń tàn ní ibi tí ó ṣókùnkùn, títí tí ojúmọ́ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ ojúmọ́ yóò sì yọ, nínú ọkàn-àyà yín.” (2 Pétérù 1:19) Jésù Kristi tá a ṣe lógo ni Ìràwọ̀ Ojúmọ́ tàbí “ìràwọ̀ òwúrọ̀ títànyòyò.” (Ìṣípayá 22:16) Ó “yọ” ní ọdún 1914 nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso ní ọ̀run, èyí sì bẹ̀rẹ̀ sànmánì tuntun. (Ìṣípayá 11:15) Nínú ìran ìyípadà ológo yẹn, Mósè àti Èlíjà fara hàn lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wá jọ ń sọ̀rọ̀. Àwọn wo ni Mósè àti Èlíjà ṣàpẹẹrẹ?

6, 7. Àwọn wo ni Mósè àti Èlíjà tó fara hàn nínú ìran ológo náà dúró fún, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé wo ni Ìwé Mímọ́ sì ṣe nípa àwọn tí wọ́n ṣàpẹẹrẹ?

6 Níwọ̀n bí a ti ṣe Mósè àti Èlíjà lógo pẹ̀lú Kristi, ó ní láti jẹ́ àwọn tó máa bá Jésù ṣàkóso nínú Ìjọba rẹ̀ làwọn ẹlẹ́rìí olóòótọ́ méjèèjì yìí ń ṣàpẹẹrẹ rẹ̀. Mímọ̀ tá a mọ̀ pé àwọn kan yóò bá Jésù ṣàkóso bá ìran tí Ọlọ́run fi han wòlíì Dáníẹ́lì mu. Ó rí Mèsáyà náà nínú ìran pé ó di ọba. Dáníẹ́lì rí “ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn” tó ń gba “ìṣàkóso tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin” lọ́wọ́ “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. Àmọ́, kíyè sí ohun tí wọ́n fi han Dáníẹ́lì lẹ́yìn ìgbà yẹn. Ó kọ̀wé pé: “Àti ìjọba àti agbára ìṣàkóso àti ìtóbilọ́lá àwọn ìjọba lábẹ́ gbogbo ọ̀run ni a sì fi fún àwọn tí í ṣe ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ.” (Dáníẹ́lì 7:13, 14, 27) Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún ṣáájú kí ìran ológo yìí tó wáyé ni Ọlọ́run ti sọ pé àwọn “ẹni mímọ́” kan máa wà nínú ògo ìjọba pẹ̀lú Kristi.

7 Àwọn wo ni ẹni mímọ́ tí Dáníẹ́lì rí nínú ìran? Àwọn ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wa pé àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Nígbà náà, bí àwa bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá pẹ̀lú: àwọn ajogún Ọlọ́run ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, kìkì bí a bá jọ jìyà pa pọ̀, kí a lè ṣe wá lógo pa pọ̀ pẹ̀lú.” (Róòmù 8:16, 17) Kò sí àní-àní pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tá a fẹ̀mí yàn ni àwọn ẹni mímọ́ yìí. Jésù sọ nínú ìwé Ìṣípayá pé: “Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò yọ̀ǹda fún láti jókòó pẹ̀lú mi lórí ìtẹ́ mi, àní gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀.” Àwọn ‘aṣẹ́gun’ tá a ji dìde yìí tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì yóò bá Jésù ṣàkóso lórí gbogbo ayé.—Ìṣípayá 3:21; 5:9, 10; 14:1, 3, 4; 1 Kọ́ríńtì 15:53.

8. Báwo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tá a fòróró yàn ṣe ń ṣe irú iṣẹ́ tí Mósè àti Èlíjà ṣe, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

8 Àmọ́, kí nìdí tá a fi sọ pé Mósè àti Èlíjà ṣàpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró? Ìdí ni pé nígbà táwọn Kristẹni wọ̀nyí wà láyé, irú iṣẹ́ tí Mósè àti Èlíjà ṣe làwọn náà ṣe. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ń jẹ́rìí nípa Jèhófà bí wọ́n tilẹ̀ ń fojú winá inúnibíni. (Aísáyà 43:10; Ìṣe 8:1-8; Ìṣípayá 11:2-12) Bíi ti Mósè àti Èlíjà, wọ́n ń fi ìgboyà táṣìírí ẹ̀sìn èké, wọ́n sì ń gba àwọn olóòótọ́ èèyàn níyànjú pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni kí wọ́n máa sìn. (Ẹ́kísódù 32:19, 20; Diutarónómì 4:22-24; 1 Àwọn Ọba 18:18-40) Ǹjẹ́ iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe so èso rere? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ ni! Yàtọ̀ sí pé wọ́n ṣèrànwọ́ láti kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró jọ, wọ́n tún ti ran àìmọye “àwọn àgùntàn mìíràn” lọ́wọ́ láti fi ara wọn sábẹ́ Jésù Kristi.—Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 7:4.

Kristi Ja Àjàṣẹ́gun

9. Báwo ní ìwé Ìṣípayá 6:2 ṣe ṣàpèjúwe irú ẹni tí Jésù jẹ́ nísinsìnyí?

9 Jésù ti di Ọba alágbára ní ọ̀run báyìí, kì í ṣe èèyàn tó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́. Bíbélì ṣàpèjúwe Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń gẹṣin, ogun sì ni ẹṣin gígùn dúró fún nínú Bíbélì. (Òwe 21:31) Ìṣípayá 6:2 sọ pé: “Wò ó! ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ sì ní ọrun kan; a sì fún un ní adé, ó sì jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” Ìyẹn nìkan kọ́ o, onísáàmù náà Dáfídì kọ ọ̀rọ̀ kan nípa Jésù, ó ní: “Ọ̀pá okun rẹ ni Jèhófà yóò rán jáde láti Síónì, pé: ‘Máa ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá rẹ’”—Sáàmù 110:2.

10. (a) Báwo ní ìṣẹ́gun Jésù ṣe bẹ̀rẹ̀? (b) Báwo ni ìṣẹ́gun tí Kristi kọ́kọ́ ní ṣe kan gbogbo aráyé?

10 Àwọn tí Jésù kọ́kọ́ ṣẹ́gun ni àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó lágbára jù lọ, ìyẹn Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. Jésù palẹ̀ wọn mọ́ ní ọ̀run, ó sì fi wọ́n sọ̀kò sórí ilẹ̀ ayé. Àwọn ẹ̀mí búburú wọ̀nyí mọ̀ pé àkókò àwọn kúrú, torí náà wọ́n wá ń fi ìkanra yẹn mọ́ aráyé, wọ́n ń fa ègbé sórí ayé. Ìwé Ìṣípayá fi àwọn ọkùnrin mẹ́ta tó ń gẹṣin ṣàpèjúwe ègbé yìí. (Ìṣípayá 6:3-8; 12:7-12) Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nípa “àmì wíwàníhìn-ín [rẹ̀] àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan,” ẹṣin táwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń gùn ti yọrí sí ogun, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn. (Mátíù 24:3, 7; Lúùkù 21:7-11) Bí ìrora tóbìnrin máa ń ní nígbà tó bá ń rọbí, bẹ́ẹ̀ ni “ìroragógó wàhálà” yìí yóò ṣe máa pọ̀ sí i títí dìgbà tí Kristi á fi “parí ìṣẹ́gun rẹ̀” nípa pípa ètò Sátánì tá a lè fojú rí run ráúráú. aMátíù 24:8.

11. Báwo ni ìtàn ìjọ Kristẹni ṣe jẹ́rìí sí i pé Kristi ti ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba?

11 Ohun mìíràn tó fi hàn pé Jésù ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba ni pé ó ń bójú tó àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ tá a gbé lé wọn lọ́wọ́ láti wàásù Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bábílónì Ńlá, ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, àti ìjọba ayé, ń ṣe inúnibíni rírorò sáwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù yìí, síbẹ̀ iṣẹ́ náà ń báa lọ láìdáwọ́dúró. Wọ́n tiẹ̀ ti wá bá iṣẹ́ náà lọ jìnnà gan-an dé ibi tí kò tíì dé rí láyé. (Ìṣípayá 17:5, 6) Ẹ ò rí i pé ẹ̀rí tó lágbára lèyí jẹ́ pé Kristi ti di ọba!—Sáàmù 110:3.

12. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi mọ̀ pé Kristi ti wà níhìn-ín bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè fojú rí i?

12 Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ̀ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tá ò lè fojú rí ló mú káwọn nǹkan pípabanbarì máa ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Kódà ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó pera wọn ní Kristẹni pàápàá ò mọ̀. Wọ́n tiẹ̀ tún ń fi àwọn tó ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run ṣẹ̀sín. (2 Pétérù 3:3, 4) Kí nìdí? Ìdí ni pé Sátánì ti fọ ojú inú wọn. (2 Kọ́ríńtì 4:3, 4) Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn ni Sátánì ti bẹ̀rẹ̀ sí í bo àwọn tó pera wọn ní Kristẹni lójú nípa tẹ̀mí, ó tún ń mú kí wọ́n ṣíwọ́ ríretí àwọn nǹkan tó ṣeyebíye tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe.

Wọn Ò Retí Ìjọba Náà Mọ́

13. Kí ni àbàjáde òkùnkùn tẹ̀mí táwọn tó pera wọn ní Kristẹni wà?

13 Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn apẹ̀yìndà yóò yọ́ wọnú ìjọ Kristẹni, bí ìgbà tí koríko bá hù láàárín àlìkámà, ó ní wọ́n á ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà. (Mátíù 13:24-30, 36-43; Ìṣe 20:29-31; Júúdà 4) Nígbà tó yá, àwọn tó pera wọn ní Kristẹni yìí bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ayẹyẹ táwọn abọ̀rìṣà máa ń ṣe, wọ́n tún ń tẹ̀ lé àwọn àṣà àti ẹ̀kọ́ wọn, wọ́n tiẹ̀ tún ń fi orúkọ “Kristẹni” pè wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, ìjọsìn òrìṣà tó ń jẹ́ Mithra àti Sátọ̀n ni wọ́n sọ di ayẹyẹ ọdún Kérésì. Àmọ́, kí ló mú káwọn tó pera wọn ní Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ayẹyẹ tí kò bá ìlànà ẹ̀sìn Kristẹni mu yìí? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica (1974) sọ pé: “Ohun tó mú káwọn èèyàn máa ṣayẹyẹ ọdún Kérésì, ìyẹn ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù Kristi, ni pé àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ retí pé Kristi á padà wá ní lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí.”

14. Báwo ni àwọn ẹ̀kọ́ Origen àti Augustine ṣe lọ́ òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run po?

14 Ẹ jẹ́ ká tún wo báwọn èèyàn ṣe dojú ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìjọba,” rú. Ìwé The Kingdom of God in 20th-Century Interpretation (Ìjọba Ọlọ́run ní Ìtumọ̀ Ti Ọ̀rúndún Ogún) sọ pé: “Origen [ọkùnrin ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan ní ọ̀rúndún kẹta] ló yí báwọn Kristẹni ṣe ń lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọba” padà. Ìtumọ̀ mìíràn tó wà fún un ni pé Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ọkàn èèyàn.” Ibo ni Origen ti mú ẹ̀kọ́ rẹ̀ jáde? Kì í ṣe inú Ìwé Mímọ́ ló ti mú un jáde bí kò ṣe látinú “ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti èrò àwọn èèyàn, èyí tó yàtọ̀ sí èrò Jésù àti ti ṣọ́ọ̀ṣì ìpilẹ̀ṣẹ̀.” Nínú ìwé De Civitate Dei (Ìlú Ọlọ́run) tí Augustine ti ìlú Hippo tó gbé láyé látọdún 354 sí 430 Sànmánì Tiwa kọ, ó sọ pé ṣọ́ọ̀ṣì gan-an ni Ìjọba Ọlọ́run. Irú èrò tí kò bá Ìwé Mímọ́ mú yìí ló mú káwọn oníṣọ́ọ̀ṣì bẹ̀rẹ̀ sí í di ipò òṣèlú mú. Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni wọ́n sì fi lo agbára tó wà lọ́wọ́ wọn yìí nílò ìkà.—Ìṣípayá 17:5, 18.

15. Báwo ni ohun tí Gálátíà 6:7 sọ ṣe ṣẹ sí ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì lára?

15 Àmọ́ lónìí, ṣọ́ọ̀ṣì ti ń ká ohun tó gbìn. (Gálátíà 6:7) Ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ni kò lágbára bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, àwọn ọmọ ìjọ wọn sì tún ń fi ìjọ sílẹ̀. Èyí ń ṣẹlẹ̀ gan-an nílẹ̀ Yúróòpù. Ìwé ìròyìn Christianity Today (Ẹ̀sìn Kristẹni Lónìí) sọ pé, “kì í ṣe ìsìn ni wọ́n ń ṣe láwọn kàtídírà gàgàrà tó wà nílẹ̀ Yúróòpù mọ́ báyìí, wọ́n ti di ibi tí wọ́n ń kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí, àwọn tó ń rìnrìn àjò afẹ́ lò sí sábà máa ń lọ síbẹ̀.” Irú nǹkan báyìí náà ló ń ṣẹlẹ̀ láwọn apá ibòmíràn lágbàáyé. Kí làwọn nǹkan wọ̀nyí fi hàn pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí ìsìn èké? Ṣé bó ṣe máa sojú dé nìyẹn láìsí alátìlẹyìn kankan? Báwo lèyí yóò sì ṣe kan ìsìn tòótọ́?

Múra Sílẹ̀ fún Ọjọ́ Ńlá Ọlọ́run

16. Kí nìdí tí inú tó ń bí àwọn èèyàn sí Bábílónì Ńlá fi yẹ fún àfiyèsí?

16 Bí èéfín tó ń rú níbi imú mọ́tò kan ṣe jẹ́ àmì pé mọ́tò ọ̀hún fẹ́ gbiná, bẹ́ẹ̀ náà ni báwọn èèyàn ṣe ń bínú sí ẹ̀sìn burúkú-burúkú níbi púpọ̀ láyé ṣe jẹ́ àmì pé ẹ̀sìn èké máa tó pa run. Láìpẹ́, Jèhófà yóò mú kí àwọn ìjọba ayé lẹ̀dí àpò pọ̀ láti táṣìírí aṣẹ́wó tẹ̀mí náà, ìyẹn Bábílónì Ńlá, Jèhófà á sì mú kí wọ́n pa á run pátápátá. (Ìṣípayá 17:15-17; 18:21) Ǹjẹ́ ó yẹ kí ẹ̀rù ba àwọn Kristẹni tòótọ́ nítorí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ yìí àtàwọn nǹkan tó máa bá “ìpọ́njú ńlá” rìn tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? (Mátíù 24:21) Rárá o! Inú wọn á dùn gan-an nígbà tí Ọlọ́run bá dá àwọn ẹni ibi lẹ́jọ́. (Ìṣípayá 18:20; 19:1, 2) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù ní ọ̀rúndún kìíní àtohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni tó gbé níbẹ̀.

17. Kí nìdí táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ olóòótọ́ kò fi ní láti bẹ̀rù nítorí òpin ètò àwọn nǹkan yìí?

17 Nígbà táwọn ọmọ ogun Róòmù wá gbógun ti Jerúsálẹ́mù lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa, kò ya àwọn Kristẹni tí wọ́n wà lójúfò nípa tẹ̀mí lẹ́nu, ẹ̀rù ò sì bà wọ́n. Nítorí pé wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, wọ́n mọ̀ “pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:20) Wọ́n tún mọ̀ pé Ọlọ́run máa ṣe ọ̀nà àbáyọ fún àwọn. Nígbà tí Ọlọ́run sì ṣe ọ̀nà àbáyọ fáwọn Kristẹni náà, wọ́n sá jáde kúrò nínú ìlú náà. (Dáníẹ́lì 9:26; Mátíù 24:15-19; Lúùkù 21:21) Bákan náà lónìí, àwọn tó mọ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń gbọ́rọ̀ sí Ọmọ rẹ̀ lẹ́nu kò bẹ̀rù òpin ètò àwọn nǹkan yìí. (2 Tẹsalóníkà 1:6-9) Àní nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, pẹ̀lú ayọ̀ ni wọ́n á fi ‘gbé ara wọn nà ró ṣánṣán, tí wọ́n á sì gbé orí wọn sókè, nítorí pé ìdáǹdè wọn ń sún mọ́lé.’—Lúùkù 21:28.

18. Kí ni yóò jẹ́ àbájáde ogun tí Gọ́ọ̀gù máa gbé wá bá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà?

18 Lẹ́yìn tí Bábílónì Ńlá bá ti pa run tán, Sátánì tó jẹ́ Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù yóò wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbógun ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jẹ́ èèyàn àlàáfíà. Àwọn ọmọ ogun Gọ́ọ̀gù yóò rọ́ dé “bí àwọsánmà láti bo ilẹ̀ náà,” wọ́n á rò pé ńṣe làwọn á kàn pa àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run run. Àmọ́, ẹnu á yà wọ́n nígbà tí wọ́n bá rí i pé nǹkan ò rí báwọn ṣe rò! (Ìsíkíẹ́lì 38:14-16, 18-23) Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Mo sì rí tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó! ẹṣin funfun kan. Ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni a ń pè ní Aṣeégbíyèlé àti Olóòótọ́, . . . Idà gígùn mímú sì yọ jáde láti ẹnu rẹ̀, kí ó lè fi í ṣá àwọn orílẹ̀-èdè.” “Ọba àwọn ọba” tí ẹnikẹ́ni ò lè ṣẹ́gun rẹ̀ yìí yóò gba àwọn adúróṣinṣin olùjọsìn Jèhófà là, yóò sì pa gbogbo àwọn ọ̀tá wọn run pátá. (Ìṣípayá 19:11-21) Bí ìran alásọtẹ́lẹ̀ náà yóò ṣe nímùúṣẹ tó kẹ́yìn nìyẹn!

19. Báwo ni ìṣẹ́gun Kristi tó kẹ́yìn ṣe máa kan àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ adúróṣinṣin, kí ló sì yẹ kí wọ́n sapá láti máa ṣe báyìí?

19 Jésù ni ‘a ó bojú wò ní ọjọ́ yẹn pẹ̀lú kàyéfì ní ìsopọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí wọ́n lo ìgbàgbọ́.’ (2 Tẹsalóníkà 1:10) Ǹjẹ́ kò wù ọ́ láti wà lára àwọn tó máa yọ̀ nígbà tí Ọmọ Ọlọ́run bá ṣẹ́gun? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, máa báa lọ láti mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára sí i, kí o sì ‘wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí o kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.’—Mátíù 24:43, 44.

Pa Agbára Ìmòye Rẹ Mọ́

20. (a) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tí Ọlọ́run pèsè fún wa? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?

20 “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà ń gba àwọn èèyàn Ọlọ́run níyànjú pé kí wọ́n wà lójúfò nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì pa agbára ìmòye wọn mọ́. (Mátíù 24:45, 46; 1 Tẹsalóníkà 5:6) Ǹjẹ́ o mọrírì àwọn ìránnilétí wọ̀nyí? Ṣé o máa ń fi wọ́n sọ́kàn nígbà tó o bá fẹ́ pinnu ohun tó yẹ kó o fi ṣáájú? O ò ṣe bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ ojú tẹ̀mí mi ń ríran kedere láti mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run ti ń ṣàkóso ní ọ̀run? Ǹjẹ́ mò ń rí i pé ó ti múra tán báyìí láti mú ìdájọ́ ṣẹ lórí Bábílónì Ńlá àti ìyókù ètò àwọn nǹkan Sátánì?’

21. Kí nìdí tójú àwọn kan fi ń ṣe bàìbàì nípa tẹ̀mí, kí ló sì yẹ kí wọ́n ṣe ní kánmọ́kánmọ́?

21 Àwọn kan lára àwọn èèyàn Jèhófà ti jẹ́ kí ojú wọn máa ṣe bàìbàì nípa tẹ̀mí. Ṣé kì í ṣe pé wọn ò lẹ́mìí sùúrù tàbí pé wọn ò lẹ́mìí ìfaradà bíi tàwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ìjímìjí? Àbí àníyàn ìgbésí ayé, ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì àti inúnibíni ti ń nípa tí kò dára lórí wọn? (Mátíù 13:3-8, 18-23; Lúùkù 21:34-36) Bóyá àwọn kan ò sì lè lóye àwọn ìsọfúnni tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà tẹ̀ jáde ni. Bí èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyẹn bá jẹ́ ìṣòro rẹ, a rọ̀ ọ́ pé kó o fi ìtara kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó o sì gbàdúrà sí Jèhófà kó o lè padà ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.—2 Pétérù 3:11-15.

22. Kí ni àwọn nǹkan tá a ti jíròrò nípa ìran ìyípadà ológo yìí àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn ti ṣe fún ọ?

22 Ìgbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù nílò ìṣírí gan-an la fi ìran ìyípadà ológo yẹn hàn wọ́n. Lónìí, a ní ohun kan tó jùyẹn lọ tó lè fún ìgbàgbọ́ wa lókun, ohun náà ni ìmúṣẹ ìran ológo yẹn àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn tó wé mọ́ ọn. Bá a ṣe ń ronú nípa àwọn nǹkan ológo tó ń ṣẹlẹ̀ yìí àti ohun tó máa túmọ̀ sí lọ́jọ́ iwájú, ẹ jẹ́ káwa náà fi gbogbo ọkàn wa sọ ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ yẹn pé: “Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.”—Ìṣípayá 22:20.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní ṣáńgílítí, ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a tú sí “ìroragógó wàhálà” túmọ̀ sí ni “ìrora ìrọbí.” (Mátíù 24:8, Kingdom Interlinear) Èyí fi hàn pé bí ìrora aláboyún ṣe máa ń le sí i nígbà tó bá ń rọbí, tí kò ní dáwọ́ dúró, bẹ́ẹ̀ náà ni ìṣòro ayé yìí yóò ṣe máa le sí i títí yóò fi jálẹ̀ sí ìpọ́njú ńlá.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Láwọn ọdún 1870, òye wo ni àwùjọ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní nípa ìpadàbọ̀ Kristi?

• Báwo ni ìran ìyípadà ológo náà ṣe nímùúṣẹ?

• Ipa wo ni ìṣẹ́gun Jésù ní lórí aráyé àti ìjọ Kristẹni?

• Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ wà lára àwọn tó máa yè bọ̀ nígbà tí Jésù bá parí ìṣẹ́gun rẹ̀?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Ìran tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ náà nímùúṣẹ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Kristi kọ́kọ́ ṣẹ́gun?