Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Ní Ẹ̀mí Aájò Àlejò fún Ara Yín”

“Ẹ Ní Ẹ̀mí Aájò Àlejò fún Ara Yín”

“Ẹ Ní Ẹ̀mí Aájò Àlejò fún Ara Yín”

NÍ Ọ̀RÚNDÚN kìíní, obìnrin kan wà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Fébè, Kristẹni ni, ó sì ní ìṣòro kan. Ó ń rin ìrìn àjò láti ìlú Kẹnkíríà tó wà ní orílẹ̀-èdè Gíríìsì lọ sí ìlú Róòmù, àmọ́ kò mọ àwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ ní ìlú yẹn. (Róòmù 16:1, 2) Atúmọ̀ Bíbélì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Edgar Goodspeed, sọ pé: “Ilẹ̀ Róòmù [ayé ìgbàanì] jẹ́ ibi tó burú tó sì rorò gan-an, àwọn ilé èrò ibẹ̀ pàápàá burú débi pé kì í ṣe ibi tó yẹ ká bá obìnrin tó jẹ́ ọmọlúwàbí, àgàgà obìnrin tó jẹ́ Kristẹni.” Ibo ni kí Fébè wá sùn sí?

Àwọn èèyàn máa ń rìnrìn àjò gan-an lákòókò tí wọ́n kọ Bíbélì. Jésù Kristi àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rìnrìn àjò kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere náà jákèjádò Jùdíà àti Gálílì. Kété lẹ́yìn ìyẹn làwọn Kristẹni tó jẹ́ míṣọ́nnárì bíi Pọ́ọ̀lù wá lọ wàásù láwọn àgbègbè tó yí òkun Mẹditaréníà ká, títí dé ìlú Róòmù, tó jẹ́ olú ìlú Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Ibo làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní máa ń gbé nígbà tí wọ́n bá rìnrìn àjò, yálà láàárín àwọn ìpínlẹ̀ tó jẹ́ tàwọn Júù tàbí tí wọ́n bá lọ sáwọn àgbègbè mìíràn? Ìṣòro wo ni wọ́n máa ń ní nígbà tí wọ́n bá ń wá ibi tí wọ́n máa dé sí? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára wọn tó bá kan bó ṣe yẹ kéèyàn máa ṣe aájò àlejò?

“Lónìí Mo Gbọ́dọ̀ Dúró ní Ilé Rẹ”

Ó ti pẹ́ gan-an táwọn olùjọsìn Jèhófà tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ti máa ń ṣe àwọn èèyàn lálejò. Bí àpẹẹrẹ, Ábúráhámù, Lọ́ọ̀tì, àti Rèbékà ṣe bẹ́ẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 18:1-8; 19:1-3; 24:17-20) Nígbà tí Jóòbù, baba ńlá nì, ń sọ nípa bóun ṣe máa ń ṣe sáwọn àlejò, ó ní: “Kò sí àtìpó tí yóò sùn mọ́jú ní òde; ilẹ̀kùn mi ni mo ṣí síhà ipa ọ̀nà.”—Jóòbù 31:32.

Táwọn arìnrìn-àjò bá fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi tiwọn gbà wọ́n lálejò, ohun tí wọ́n kàn máa ń ṣe ò ju pé kí wọ́n jókòó sí ojúde ìlú ńlá kan kí wọ́n sì máa retí ẹni tó máa gbà wọ́n sílé. (Àwọn Onídàájọ́ 19:15-21) Àwọn onílé sábà máa ń wẹ ẹsẹ̀ àwọn àlejò wọn, wọ́n á sì tún fún wọn lóúnjẹ àti ohun mímu, wọ́n tún máa ń fún àwọn ẹran wọn lóúnjẹ pẹ̀lú. (Jẹ́nẹ́sísì 18:4, 5; 19:2; 24:32, 33) Àwọn arìnrìn-àjò tí kò fẹ́ kó àwọn tó gbà wọ́n sílé sí wàhálà máa ń kó àwọn ohun tí wọ́n máa lò dání. Wọ́n á gbé oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ àti wáìnì tí wọ́n máa mu dání, wọ́n á tún kó èérún pòròpórò àti oúnjẹ ẹran dání fáwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Ohun tí wọ́n kàn fẹ́ ò ju pé káwọn ríbi sùn mọ́jú lọ.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa bí Jésù ṣe máa ń ríbi sùn nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀, síbẹ̀ a sáà mọ̀ pé ibì kan lòun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń sùn sí. (Lúùkù 9:58) Nígbà tí Jésù wá sí Jẹ́ríkò, ó kàn sọ fún Sákéù pé: “Lónìí mo gbọ́dọ̀ dúró ní ilé rẹ.” Inú Sákéù dùn, ó sì gbà á lálejò “tayọ̀tayọ̀.” (Lúùkù 19:5, 6) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù dé sọ́dọ̀ Màtá, Màríà, àti Lásárù tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní Bẹ́tánì. (Lúùkù 10:38; Jòhánù 11:1, 5, 18) Ó sì dà bíi pé ọ̀dọ̀ Símónì Pétérù ló máa ń dé sí tó bá wà ní Kápánáúmù.—Máàkù 1:21, 29-35.

Ìtọ́ni tí Jésù fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá nípa iṣẹ́ ìwàásù fi báwọn èèyàn Ísírẹ́lì ṣe máa ṣe sí wọn hàn nígbà tí wọ́n bá lọ wàásù fún wọn nínú ilé wọn. Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe wá wúrà tàbí fàdákà tàbí bàbà sínú àpò ara àmùrè yín, tàbí àsùnwọ̀n oúnjẹ fún ìrìnnà àjò náà, tàbí ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ méjì, tàbí sálúbàtà tàbí ọ̀pá; nítorí òṣìṣẹ́ yẹ fún oúnjẹ rẹ̀. Ìlú ńlá tàbí abúlé èyíkéyìí tí ẹ bá wọ̀, ẹ wá ẹni yíyẹ inú rẹ̀ kàn, kí ẹ sì dúró níbẹ̀ títí ẹ ó fi kúrò.” (Mátíù 10:9-11) Ó mọ̀ pé àwọn onínúure èèyàn á gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun sílé, wọ́n á sì fún wọn ní oúnjẹ, ilé, àtàwọn ohun mìíràn tí wọ́n nílò.

Àmọ́, àkókò ń bọ̀ táwọn ọmọlẹ́yìn tó ń wàásù yìí yóò máa kó gbogbo ohun tí wọ́n máa lò dání, owó ara wọn ni wọ́n á sì fi máa ra gbogbo ohun tí wọ́n bá nílò. Nítorí pé àwọn èèyàn máa kórìíra àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù àti pé iṣẹ́ ìwàásù náà máa dé àwọn ìlú tí kì í ṣe tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Jésù wá sọ fún wọn pé: “Kí ẹni tí ó ní àpò gbé e, bákan náà pẹ̀lú ni àsùnwọ̀n oúnjẹ.” (Lúùkù 22:36) Rírin ìrìn àjò àti dídé sílé àwọn èèyàn kò ní ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà.

“Ẹ Máa Tẹ̀ Lé Ipa Ọ̀nà Aájò Àlejò”

Ní ọ̀rúndún kìíní, kò fi bẹ́ẹ̀ sí ogun, bẹ́ẹ̀ sì làwọn ọ̀nà tó wà ní gbogbo Ilẹ̀ Ọba Róòmù dára gan-an, èyí wá mú káwọn èèyàn máa rìnrìn àjò gan-an. a Pípọ̀ táwọn arìnrìn-àjò pọ̀ yìí ló jẹ́ káwọn tó máa ń wá ibi tí wọ́n máa dé sí pọ̀ jaburata. Ìyẹn ló sì mú kí wọ́n kọ́ àwọn ilé táwọn èèyàn lè wọ̀ sí sáwọn ibi tí kò ju ìrìn ọjọ́ kan síra wọn lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ àwọn ojú títì ńlá. Àmọ́, ìwé kan tí wọ́n pè ní The Book of Acts in Its Graeco-Roman Setting (Ìwé Tó Sọ Nípa Bí Nǹkan Ṣe Rí Nílẹ̀ Gíríìsì àti Róòmù) sọ pé: “Ohun táwọn èèyàn mọ̀ nípa irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ohun tó fi bẹ́ẹ̀ múnú ẹni dùn. Ìtàn tó wà nínú àwọn ìwé àti ohun táwọn awalẹ̀pìtàn rí fi hàn pé ẹgẹrẹmìtì làwọn ilé náà, wọ́n sì dọ̀tí bí nǹkan míì. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí àga kankan nínú wọn, ìdún tún wà ní gbogbo ara ibùsùn wọn, oúnjẹ àti ohun mímu ibẹ̀ ò sì dára. Àwọn tó ni àwọn ilé táwọn èèyàn ń wọ̀ sí yìí àtàwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ ò ṣeé fọkàn tán, àwọn oníbàárà wọn ò lórúkọ rere, kò tiẹ̀ sóhun tó jọ ìwà ọmọlúwàbí níbẹ̀ rárá.” Láìsí àní-àní, àwọn arìnrìn-àjò tí wọ́n jẹ́ ọmọlúwàbí kò ní fẹ́ dúró ní irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀.

Abájọ tí Ìwé Mímọ́ fi rọ àwọn Kristẹni léraléra pé kí wọ́n máa ṣe ara wọn lálejò. Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù pé: “Ẹ máa ṣe àjọpín pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àìní wọn. Ẹ máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò.” (Róòmù 12:13) Ó rán àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù létí pé: “Ẹ má gbàgbé aájò àlejò, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀, àwọn kan ṣe àwọn áńgẹ́lì lálejò, láìjẹ́ pé àwọn fúnra wọn mọ̀.” (Hébérù 13:2) Pétérù náà gba àwọn olùjọsìn bíi tirẹ̀ níyànjú pé kí wọn ‘ní ẹ̀mí aájò àlejò fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì láìsí ìráhùn.’—1 Pétérù 4:9.

Àmọ́, àwọn kan wà táwọn Kristẹni ò gbọ́dọ̀ gbà lálejò o. Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ti ara rẹ̀ síwájú, tí kò sì dúró nínú ẹ̀kọ́ Kristi,” ó ní: “Ẹ má ṣe gbà á sí ilé yín láé tàbí kí ẹ kí i. Nítorí ẹni tí ó bá kí i jẹ́ alájọpín nínú àwọn iṣẹ́ burúkú rẹ̀.” (2 Jòhánù 9-11) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà, ó kọ̀wé pé: “Ẹ jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí a pè ní arákùnrin, tí ó jẹ́ àgbèrè tàbí oníwọra tàbí abọ̀rìṣà tàbí olùkẹ́gàn tàbí ọ̀mùtípara tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà, kí ẹ má tilẹ̀ bá irúfẹ́ ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹun.”—1 Kọ́ríńtì 5:11.

Nítorí pé àwọn Kristẹni tòótọ́ jẹ́ onínúure, àfàìmọ̀ káwọn afàwọ̀rajà àtàwọn míì má ti gbìyànjú láti rẹ́ wọ́n jẹ. Ìwé kan tó ń jẹ́ Teaching of the Twelve Apostles (Ẹ̀kọ́ Àwọn Àpọ́sítélì Méjìlá), ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni tí a kò mẹ́nu kàn nínú Bíbélì, ó sọ pé ó yẹ kéèyàn ṣe oníwàásù kan tó ń rìnrìn àjò lálejò fún “ọjọ́ kan. Tí àyè ẹ̀ bá sì yọ, kó tún lè ṣe é lálejò níjọ́ kejì pẹ̀lú.” Lẹ́yìn ìyẹn, tó bá wá ń lọ, “kò gbọ́dọ̀ gba ohun mìíràn ju oúnjẹ . . . Tó bá béèrè owó, wòlíì èké ni.” Ìwé náà tún sọ pé: “Tó bá fẹ́ máa gbé ilé rẹ, tó sì mọ iṣẹ́ ọwọ́ kan, jẹ́ kó máa ṣe iṣẹ́ táá fi jẹun. Àmọ́ tí kò bá mọ iṣẹ́ ọwọ́ kankan, kọ́ ọ níṣẹ́ tó o mọ̀, kó má bàa sí ẹnikẹ́ni láàárín yín tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́ nítorí pé ó jẹ́ Kristẹni. Àmọ́ tó bá kọ̀ tó sọ pé òun ò ṣiṣẹ́, ó fẹ́ máa fi ẹ̀sìn Kristẹni ṣe jẹunjẹun nìyẹn, ẹ ṣọ́ra fún irú ẹni bẹ́ẹ̀.”

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí i pé òun ò di ẹrù wíwúwo lé àwọn tó gba òun sílé lórí láwọn àkókò tó máa ń dúró pẹ́ láwọn ìlú kan. Ó ṣe iṣẹ́ pípa àgọ́ láti fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. (Ìṣe 18:1-3; 2 Tẹsalóníkà 3:7-12) Kí àwọn Kristẹni ìjímìjí lè ran àwọn tó bá fẹ́ rìnrìn àjò láàárín wọn lọ́wọ́, ó jọ pé ńṣe ni wọ́n máa ń kọ lẹ́tà sí ẹni tó máa gbà wọ́n sílé. Lẹ́tà yìí ni wọ́n á fi sọ irú ẹni tí arìnrìn àjò náà jẹ́. Irú lẹ́tà bẹ́ẹ̀ sì ni Pọ́ọ̀lù kọ nípa Fébè pé: “Mo dámọ̀ràn Fébè arábìnrin wa fún ìtẹ́wọ́gbà yín, . . . kí ẹ lè fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà á nínú Olúwa . . . kí ẹ sì lè ṣèrànwọ́ fún un nínú ọ̀ràn èyíkéyìí tí ó ti lè nílò yín.”—Róòmù 16:1, 2.

Ìbùkún Tí Ṣíṣaájò Àlejò Ń Mú Wá

Àwọn Kristẹni tó jẹ́ míṣọ́nnárì ní ọ̀rúndún kìíní gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á pèsè gbogbo ohun táwọn nílò. Àmọ́, ṣé wọ́n lè retí pé àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ á fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ hàn sí wọn? Lìdíà gba Pọ́ọ̀lù àtàwọn mìíràn sílé rẹ̀. Àpọ́sítélì náà gbé lọ́dọ̀ Ákúílà àti Pírísílà ní Kọ́ríńtì. Ọkùnrin kan tó ń ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ìlú Fílípì fún Pọ́ọ̀lù àti Sílà lóhun jíjẹ àtohun mímu. Jásónì ṣe Pọ́ọ̀lù lálejò ní Tẹsalóníkà, Fílípì gbà á lálejò ní Kesaréà, bẹ́ẹ̀ náà ni Mínásónì ṣe é lálejò nígbà tó ń ti Kesaréà lọ sí Jerúsálẹ́mù. Àwọn arákùnrin tó wà ní Pútéólì tún ṣe Pọ́ọ̀lù lálejò nígbà tó ń lọ sí Róòmù. Ẹ ò rí i pé àkókò ìgbádùn nípa tẹ̀mí làwọn àkókò wọ̀nyẹn ní láti jẹ́ fáwọn tó gbà á sílé!—Ìṣe 16:33, 34; 17:7; 18:1-3; 21:8, 16; 28:13, 14.

Ọ̀mọ̀wé Frederick F. Bruce sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn alábàáṣiṣẹ́ Pọ́ọ̀lù wọ̀nyí, àtàwọn tó gbà á sílé lọ́kùnrin lóbìnrin, kò ní èrò mìíràn lọ́kàn tó mú kí wọ́n ṣèrànwọ́ yìí ju ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Pọ́ọ̀lù àti ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Ọ̀gá rẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé táwọn bá ti ṣe nǹkan fún Pọ́ọ̀lù, Ọ̀gá rẹ̀ làwọn ṣe é fún yẹn.” Ohun tó yẹ kó máa múni ṣaájò àlejò gan-an nìyẹn.

Di bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, àǹfààní ṣì wà láti máa fìfẹ́ hàn sí àlejò. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arìnrìn-àjò tó ń ṣojú fún ètò Jèhófà ni àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ máa ń ṣe lálejò. Àwọn Ẹlẹ́rìí kan ń fi owó ara wọn wọkọ̀ lọ wàásù láwọn ibi tí ìhìn rere náà kì í sábà dé. Ìbùkún ńlá la máa rí tá a bá ń gba irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ sílé wa, bí ilé náà ò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ jọjú. Ṣíṣe àlejò tọ̀yàyàtọ̀yàyà, bí ò tiẹ̀ ju ka jọ jẹ oúnjẹ díẹ̀ lọ máa ń fúnni láǹfààní àtiṣe “pàṣípààrọ̀ ìṣírí.” Ó tún ń jẹ́ ká lè fìfẹ́ hàn sáwọn arákùnrin wa àti sí Ọlọ́run wa pàápàá. (Róòmù 1:11, 12) Àwọn tó gbani lálejò ni àkókò náà máa ń ṣe láǹfààní jù lọ, nítorí pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn kan fojú bù ú pé tá a bá ṣírò bí gbogbo àwọn ọ̀nà tó dáa ní ilẹ̀ Róòmù ní ọ̀rúndún kìíní ṣe gùn tó, ó tó ọ̀kẹ́ mẹ́rin [80,000] kìlómítà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ẹ̀yìn Kristẹni “ẹ máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò”