Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ọgbọ́n Wo Lo Dá Sí I?”

“Ọgbọ́n Wo Lo Dá Sí I?”

“Ọgbọ́n Wo Lo Dá Sí I?”

ÌBÉÈRÈ yìí ni bàbá àgbàlagbà kan béèrè lọ́wọ́ obìnrin kan tó ń jẹ́ Muriel nílé oúnjẹ kan. Ọmọ mẹ́tà lobìnrin náà ní, ìbéèrè náà sì bá a lójijì. Àtàárọ̀ ni Muriel ti kó àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ dókítà, ọjọ́ sì ti lọ tán. Kò sáyè mọ́ fún wọn láti lọ sílé láti lọ jẹun kí wọ́n to lọ sípàdé, níbi tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èyí ló mú kí Muriel kó àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sílé oúnjẹ kan tó wà nítòsí kí wọ́n lè wá nǹkan fi sẹ́nu.

Bó ṣe ku díẹ̀ kí wọ́n jẹun tán ni ọkùnrin kan wá bá Muriel, ó sì sọ pé: “Àtìgbà tẹ́ ẹ ti wọlé ni mo ti ń wò yín. Mo rí i pé àwọn ọmọ rẹ yàtọ̀ gan-an sáwọn ọmọ míì tó máa ń wá síbí. Tó o bá rí báwọn ọmọ wọ̀nyẹn ṣe máa ń ṣe àwọn tábìlì àtàwọn àga tó wà níbi yìí, ńṣe ni wọ́n máa kẹ́sẹ̀ sórí tábìlì tí wọ́n á sì máa ti àga kiri. Àmọ́ ńṣe làwọn ọmọ tìrẹ jókòó jẹ́ẹ́, wọn ò fàjọ̀gbọ̀n kankan. Ọgbọ́n wo lo dá sí i?”

Muriel fèsì, ó ní: “Èmi àti ọkọ mi máa ń kọ́ àwọn ọmọ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, a sì máa ń sapá láti fi ohun tá à ń kọ́ ṣèwà hù. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá.” Lọkùnrin náà bá sọ pé: “Júù ni mí, mo wà lára àwọn tó yè bọ́ nígbà tí wọ́n pa àwọn Júù nípakúpa. Mo rántí pé wọ́n ṣenúnibíni gan-an sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Jámánì lákòókò yẹn. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n yàtọ̀ sáwọn èèyàn tó kù gan-an. Ìwà àwọn ọmọ rẹ wú mi lórí púpọ̀. Màá fẹ́ láti túbọ̀ mọ̀ sí i nípa ìsìn rẹ yìí.”

Tó bá dọ̀rọ̀ ọmọ títọ́, ìwé atọ́nisọ́nà tí ò lẹ́gbẹ́ ni Bíbélì. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dùn gan-an láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní ìtọ́sọ́nà tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Inú wa yóò dùn tó o bá ṣe ohun tá a kọ sísàlẹ̀ yìí.