Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ Ìwàásù Mú Kí Wọ́n Ṣe Inúnibíni sí Sọ́ọ̀lù

Iṣẹ́ Ìwàásù Mú Kí Wọ́n Ṣe Inúnibíni sí Sọ́ọ̀lù

Iṣẹ́ Ìwàásù Mú Kí Wọ́n Ṣe Inúnibíni sí Sọ́ọ̀lù

Ọ̀RỌ̀ náà ò yé àwọn Júù tó ń gbé ìlú Damásíkù rárá. Báwo lẹni tó ti nítara fún ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wọn tẹ́lẹ̀ ṣe wá di apẹ̀yìndà? Sọ́ọ̀lù yìí ló ń fojú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rí màbo ní Jerúsálẹ́mù tẹ́lẹ̀. Ó tiẹ̀ ti wá sí Damásíkù nígbà kan rí láti han àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó wà níbẹ̀ léèmọ̀. Àmọ́ ní báyìí, òun gan-an ti wá dẹni tó ń wàásù pé Jésù ni Mèsáyà, ìyẹn Jésù táwọn èèyàn kà sí ọ̀daràn tí wọ́n sì kàn mọ́gi pé ó ń sọ̀rọ̀ òdì! Àbí Sọ́ọ̀lù ti ya wèrè ni kẹ̀?—Ìṣe 9:1, 2, 20-22.

Bí kò bá nídìí, ẹ̀ṣẹ́ kì í ṣẹ́ lásán. Ó ṣeé ṣe káwọn tó ń bá Sọ́ọ̀lù rìn bọ̀ láti Jerúsálẹ́mù ti ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú ọ̀nà. Bí wọ́n ti ń sún mọ́ Damásíkù, ìmọ́lẹ̀ ńlá kan ṣàdédé tàn yòò sí wọn, ni gbogbo wọn bá ṣubú lulẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún gbọ́ ohùn kan. Kò sí nǹkan tó ṣe àwọn èèyàn tó kù, àyàfi Sọ́ọ̀lù nìkan. Ńṣe ló sùn gbalaja sójú ọ̀nà. Nígbà tó sì jàjà dìde, àwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò ló mú un dé Damásíkù nítorí pé kò ríran mọ́.—Ìṣe 9:3-8; 26:13, 14.

Ọ̀tá Jésù Tẹ́lẹ̀ Wá Dẹni Tó Ń Wàásù Nípa Jésù

Kí la lè pe nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Sọ́ọ̀lù lójú ọ̀nà Damásíkù yẹn ná? Ṣé ìrìn ọ̀nà jíjìn tó rìn ló fà á ni àbí ooru tó mú nínú oòrùn ọ̀sán gangan ọjọ́ náà ni kò jẹ́ kó lókun nínú mọ́? Àwọn kan tó ń ṣiyèméjì lóde òní ti gbìyànjú láti sọ ohun tí wọ́n rò pé ó lè fa irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Wọ́n ní ó lè jẹ́ òòyì ló kọ́ Sọ́ọ̀lù tàbí kó jẹ́ pé ó ń ṣèrànrán ni, tàbí kẹ̀ kó jẹ́ pé ọkàn Sọ́ọ̀lù kò lélẹ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn tó ń dà á láàmú. Wọ́n sì tún ní ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdààmú ọkàn ló dá àìsàn sí i lára tàbí kó jẹ́ pé Sọ́ọ̀lù lárùn wárápá.

Àmọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé ńṣe ni Jésù Kristi yọ sí Sọ́ọ̀lù nínú ìmọ̀lẹ̀ tó fọ́ ọ lójú yẹn tó sì mú un dá Sọ́ọ̀lù lójú pé Òun ni Mèsáyà. Àwọn kan ti ya àwọn àwòrán kan láti fi hàn pé àtorí ẹṣin ni Sọ́ọ̀lù ti ṣubú lulẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èyí lè rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ kò ju pé Sọ́ọ̀lù “ṣubú lulẹ̀.” (Ìṣe 22:6-11) Síbẹ̀, ọ̀nà yòówù kí Sọ́ọ̀lù gbà ṣubú, a ò lè fi wé bó ṣe dẹni tí ò sí nípò gíga tó wà tẹ́lẹ̀ mọ́. Dandan ni kó wá gbà báyìí pé òótọ́ lohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń wáàsù rẹ̀. Kó sì sóhun mìíràn tó lè ṣe ju pé kó dara pọ̀ mọ́ wọn. Sọ́ọ̀lù tí kò fẹ́ gbọ́ nǹkan kan sétí tẹ́lẹ̀ nípa Jésù ló wá dí ọ̀kan lára àwọn tó ń wáàsù rẹ̀ lójú méjèèjì báyìí. Lẹ́yìn tójú Sọ́ọ̀lù là tó sì ṣèrìbọmi, ó “ń bá a nìṣó ní títúbọ̀ gba agbára, ó sì ń mú ẹnu àwọn Júù tí ń gbé ní Damásíkù wọhò bí ó ti fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu pé èyí ni Kristi náà.”—Ìṣe 9:22.

Wọn Ò Rí Sọ́ọ̀lù Pa

Lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù tá a wá mọ̀ sí Pọ́ọ̀lù di ọmọ ẹ̀yìn, ibo ló lọ? Nígbà tó ń kọ̀wé sáwọn ará Gálátíà, ó sọ pé: “Mo lọ sí Arébíà, mo sì tún padà wá sí Damásíkù.” (Gálátíà 1:17) “Arébíà” tó dárúkọ yìí fi hàn pé ibikíbi ní àgbègbè Arébíà ló lè jẹ́. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Aṣálẹ̀ Síríà tàbí ibòmíràn lágbègbè ilẹ̀ Nabataea tí Ọba Árétásì Kẹrin ń ṣàkóso lé lórí ni Pọ́ọ̀lù lọ. Àmọ́, àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ńṣe ni Sọ́ọ̀lù lọ ṣàṣàrò níbì kan tó pa rọ́rọ́ lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, bí Jésù ṣe lọ sínú aginjù lẹ́yìn ìrìbọmi rẹ̀.—Lúùkù 4:1.

Lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù padà sí Damásíkù, “àwọn Júù gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.” (Ìṣe 9:23) Ńṣe ni gómìnà tó ń ṣojú fún Ọba Árétásì ní Damásíkù ń ṣọ́ ìlú náà lójú méjèèjì kọ́wọ́ rẹ̀ lè tẹ Sọ́ọ̀lù. (2 Kọ́ríńtì 11:32) Àmọ́ bí àwọn ọ̀tá ṣe ń gbìmọ̀ bí wọ́n ṣe máa pa Sọ́ọ̀lù làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń wá ọ̀nà tó máa gbà sá lọ.

Lára àwọn tó ran Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́ tó fi rọ́nà sá lọ ni Ananíà àtàwọn ọmọlẹ́yìn tó wà pẹ̀lú àpọ́sítélì náà ní kété tó di Kristẹni. a (Ìṣe 9:17-19) Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára àwọn tí Sọ́ọ̀lù wàásù fún ní Damásíkù tí wọ́n sì di onígbàgbọ́ wà lára àwọn tó ràn án lọ́wọ́, nítorí Ìṣe 9:25 sọ pé: “Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbé e, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní òru gba ojú ihò kan lára ògiri, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ nínú apẹ̀rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ náà “àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀,” lè túmọ̀ sí àwọn tí Sọ́ọ̀lù kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Èyí ó wù kó jẹ́, àṣeyọrí tí Sọ́ọ̀lù ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ mú káwọn èèyàn túbọ̀ kórìíra rẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

Ẹ̀kọ́ Tá A Lè Rí Kọ́

Tá a bá gbé diẹ̀ yẹ̀ wò lára ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sọ́ọ̀lù lẹ́yìn tó yí padà tó si ṣe ìrìbọmi, a óò rí i pé kò jẹ́ kí ojú táwọn èèyàn fi ń wo òun kó ìdàámú bá òun ju bó ṣe yẹ lọ; bẹ́ẹ̀ ni kò bọ́hùn nítorí inúnibíni lílekoko tí wọ́n ṣe sí i. Ohun tó jẹ Sọ́ọ̀lù lógún jù lọ ni iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù gbé lé e lọ́wọ́.—Ìṣe 22:14, 15.

Ṣé ẹnu àìpẹ́ yìí ni ìwọ náà rí i pé iṣẹ́ ìwàásù ṣe pàtàkì? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ìwọ fúnra rẹ ti wá mọ̀ pé gbogbo Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ wàásù Ìjọba Ọlọ́run. Má ṣe jẹ́ kó yà ọ́ lẹ́nu bí iṣẹ́ ìwàásù tó ò ń ṣe bá mú káwọn èèyàn ṣenúnibíni sí ọ nígbà mìíràn. (Mátíù 24:9; Lúùkù 21:12; 1 Pétérù 2:20) Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ọ̀nà tí Sọ́ọ̀lù gbà kojú àtakò. Àwọn Kristẹni tó bá fara da ìdánwò láìbọ́hùn yóò rí ojú rere Ọlọ́run. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.” Síbẹ̀, ó mú un dá wọn lójú pé: “Nípasẹ̀ ìfaradà níhà ọ̀dọ̀ yín ni ẹ ó fi jèrè ọkàn yín.”—Lúùkù 21:17-19.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn tí Jésù wàásù ní Gálílì tàbí lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa ni ẹ̀sìn Kristẹni dé Damásíkù.—Mátíù 4:24; Ìṣe 2:5

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Sọ́ọ̀lù “ṣubú lulẹ̀” nígbà tí Jésù yọ sí i

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Sọ́ọ̀lù bọ́ lọ́wọ́ àwọn tó ń gbìmọ̀ láti pa á ní Damásíkù