Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kristi Làwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Tọ́ka Sí

Kristi Làwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Tọ́ka Sí

Kristi Làwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Tọ́ka Sí

“Jíjẹ́rìí Jésù ni ohun tí ń mí sí ìsọtẹ́lẹ̀.”—ÌṢÍPAYÁ 19:10.

1, 2. (a) Bẹ̀rẹ̀ látọdún 29 Sànmánì Tiwa, ìpinnu wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti ṣe? (b) Kí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 NÍ ỌDÚN 29 Sànmánì Tiwa, ọ̀rọ̀ nípa Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí gba ilẹ̀ Ísírẹ́lì kan. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jòhánù Oníbatisí túbọ̀ wá fojú àwọn èèyàn sọ́nà fún Mèsáyà. (Lúùkù 3:15) Jòhánù sọ pé òun kọ́ ni Kristi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jésù ti ìlú Násárétì ni Kristi nígbà tó sọ pé: “Mo . . . ti jẹ́rìí pé ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run.” (Jòhánù 1:20, 34) Láìpẹ́ sígbà yẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé Jésù kí wọ́n lè fetí sáwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ kí wọ́n sì lè rí ìwòsàn.

2 Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn, Jèhófà fún àwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí nípa Ọmọ rẹ̀. Àwọn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n sì kíyè sí àwọn nǹkan tí Jésù ṣe ní ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti gba Jésù gbọ́. Àmọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú yìí ni kò gba Jésù gbọ́. Ìwọ̀nba díẹ̀ lára wọn ló gbà pé Jésù ni Kristi, Ọmọ Ọlọ́run. (Jòhánù 6:60-69) Ká sọ pé o wà láyé lákòókò tá à ń wí yìí, kí lò bá ṣe? Ṣé ò bá gbà pé Jésù ni Mèsáyà kó o sì di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀rí tí Jésù alára fi hàn láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun ni Mèsáyà nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó rú òfin Sábáàtì. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀rí tí Jésù tún fi han àwọn adúróṣinṣin ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kí ìgbàgbọ́ wọn lè túbọ̀ lágbára sí i.

Jésù Alára Fi Ẹ̀rí Hàn

3. Kí làwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ tó mú kí Jésù sọ irú ẹni tóun jẹ́?

3 Ọjọ́ àjọ̀dún Ìrékọjá lọ́jọ́ náà ní ọdún 31 Sànmánì Tiwa. Jésù wà ní Jerúsálẹ́mù. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wo ọkùnrin kan tó wà nídùbúlẹ̀ àìsàn fún ọdún méjìdínlógójì sàn ni. Àmọ́, inú àwọn Júù ò dùn rárá àti rárá pé Jésù ń wo àwọn èèyàn sàn lọ́jọ́ Sábáàtì. Wọ́n ní Jésù sọ̀rọ̀ òdì, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́nà àtipa á nítorí ó sọ pé Ọlọ́run ní Baba òun. (Jòhánù 5:1-9, 16-18) Àwọn nǹkan tí Jésù sọ láti fi gbèjà ara rẹ̀ jẹ́ ká rí ìdí mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Júù tó bá lọ́kàn tó dáa á fi mọ irú ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an.

4, 5. Kí nìdí tí Jòhánù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ṣe, ibo ló sì báṣẹ́ ọ̀hún dé?

4 Lákọ̀ọ́kọ́, Jésù tọ́ka sí ohun tí Jòhánù Oníbatisí tá a rán ṣíwájú rẹ̀ sọ nípa òun. Ó ní: “Ẹ ti rán àwọn ènìyàn lọ bá Jòhánù, ó sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́. Ọkùnrin yẹn jẹ́ fìtílà tí ń jó, tí ó sì ń tàn, fún àkókò kúkúrú, ẹ sì ń fẹ́ láti yọ̀ gidigidi nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.”—Jòhánù 5:33, 35.

5 Jòhánù Oníbatisí jẹ́ “fìtílà tí ń jó, tí ó sì ń tàn” nítorí pé ó parí iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an kí Hẹ́rọ́dù tó jù ú sẹ́wọ̀n láìṣẹ̀. Iṣẹ́ náà sì ni pé kó pa ọ̀nà mọ́ fún Mèsáyà náà. Jòhánù sọ pé: “Ìdí tí mo fi wá ń batisí nínú omi ni pé kí a lè fi [Mèsáyà náà] hàn kedere fún Ísírẹ́lì. . . . Mo rí tí ẹ̀mí ń sọ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àdàbà láti ọ̀run, ó sì bà lé e. Èmi pàápàá kò mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Ẹni náà gan-an tí ó rán mi láti batisí nínú omi sọ fún mi pé, ‘Ẹnì yòówù tí o bá rí tí ẹ̀mí ń sọ kalẹ̀ lé, tí ó sì dúró, èyí ni ẹni tí ń fi ẹ̀mí mímọ́ batisí.’ Mo sì ti rí i, mo sì ti jẹ́rìí pé ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run.” a (Jòhánù 1:26-37) Jòhánù sọ ní pàtó pé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run, ìyẹn Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. Àwọn nǹkan tí Jòhánù sọ nípa Jésù ṣe kedere débi pé ní nǹkan bí oṣù mẹ́jọ lẹ́yìn ikú Jòhánù, ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù tó lọ́kàn tó dáa ló sọ pé: “Gbogbo nǹkan tí Jòhánù sọ nípa ọkùnrin yìí jẹ́ òótọ́.”—Jòhánù 10:41, 42.

6. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn nǹkan tí Jésù ṣe mú káwọn èèyàn gbà pé Ọlọ́run ń tì í lẹ́yìn?

6 Jésù tún fún àwọn èèyàn ní ẹ̀rí mìíràn kí wọ́n lè mọ̀ pé òun ni Mèsáyà náà. Ó tọ́ka sáwọn iṣẹ́ rere tó ṣe láti fi hàn pé Ọlọ́run ń ti òun lẹ́yìn. Ó sọ pé: “Èmi ní ẹ̀rí tí ó tóbi ju ti Jòhánù lọ, nítorí pé àwọn iṣẹ́ náà gan-an tí Baba mi yàn lé mi lọ́wọ́ láti ṣe ní àṣeparí, àwọn iṣẹ́ náà tìkára wọn tí èmi ń ṣe, ń jẹ́rìí nípa mi pé Baba ni ó rán mi wá.” (Jòhánù 5:36) Kódà àwọn ọ̀tá Jésù pàápàá ò lè sọ pé kò ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyẹn. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu sì wà lára àwọn nǹkan tí Jésù ṣe. Nígbà tó yá, àwọn kan tiẹ̀ béèrè pé: “Kí ni kí a ṣe, nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì?” (Jòhánù 11:47) Àmọ́, àwọn kan dáhùn dáadáa, wọ́n ní: “Nígbà tí Kristi bá dé, kì yóò ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tí ó ju èyí tí ọkùnrin yìí ti ṣe, àbí yóò ṣe bẹ́ẹ̀?” (Jòhánù 7:31) Àwọn tó ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ Jésù lè rí i pé àwọn ànímọ́ Baba wà lára Ọmọ pẹ̀lú.—Jòhánù 14:9.

7. Báwo ni Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ṣe jẹ́rìí nípa Jésù?

7 Paríparí rẹ̀, Jésù tọ́ka sí ẹ̀rí mìíràn tí ẹnikẹ́ni ò lè já ní koro. Ó sọ pé: “Ìwé Mímọ́ . . . ni ó ń jẹ́rìí nípa mi.” Ó tún wá sọ pé: “Bí ẹ bá gba Mósè gbọ́ ni, ẹ̀yin ì bá gbà mí gbọ́, nítorí pé ẹni yẹn kọ̀wé nípa mi.” (Jòhánù 5:39, 46) Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí tó wà ṣáájú ìgbà Kristẹni ló kọ ọ̀rọ̀ nípa Kristi, Mósè wulẹ̀ jẹ́ ọkàn lára wọn ni. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àti kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn nípa ìlà ìdílé ni wọ́n kọ ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, gbogbo àwọn nǹkan tí wọ́n kọ yìí ló sì tọ́ka sí Mèsáyà náà. (Lúùkù 3:23-38; 24:44-46; Ìṣe 10:43) Òfin Mósè wá ń kọ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ ọ́ pé: “Òfin ti di akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi.” (Gálátíà 3:24) Bẹ́ẹ̀ ni, “jíjẹ́rìí Jésù ni ohun tí ń mí sí [tàbí ohun tó fa] ìsọtẹ́lẹ̀.”—Ìṣípayá 19:10.

8. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù ò fi nígbàgbọ́ nínú Mèsáyà náà?

8 Pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹ̀rí wọ̀nyí, bẹ̀rẹ̀ látorí ohun tí Jòhánù sọ, àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí ń bẹ lára rẹ̀, àti àìmọye ẹ̀rí tó wà nínú Ìwé Mímọ́, ǹjẹ́ o ò gbà pé Jésù ni Mèsáyà? Ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò rí àwọn ẹ̀rí wọ̀nyẹn, yóò sì gbà gbọ́ pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. Àmọ́ àwọn tó wà ní Ísírẹ́lì níjelòó kò nírú ìfẹ́ yẹn. Jésù sọ fáwọn alátakò rẹ̀ pé: “Èmi mọ̀ dunjú pé ẹ kò ní ìfẹ́ fún Ọlọ́run nínú yín.” (Jòhánù 5:42) Dípò tí wọn ì bá fi máa “wá ògo tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kan ṣoṣo náà wá,” ńṣe ni wọ́n ń “tẹ́wọ́ gba ògo láti ọ̀dọ̀ ara [wọn].” Abájọ tí wọ́n fi lòdì sí Jésù, ẹni tó jẹ́ pé kò fẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bí Baba rẹ̀ ò ṣe fẹ́ ẹ!—Jòhánù 5:43, 44; Ìṣe 12:21-23.

Ìran Alásọtẹ́lẹ̀ fún Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Lókun

9, 10. (a) Kí nìdí tí àmì tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi bọ́ sákòókò? (b) Kí ni ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí Jésù ṣèlérí pé òun máa ṣe fáwọn ọmọ ẹ̀yìn òun?

9 Àwọn Júù ṣàjọ̀dún Ìrékọjá ti ọdún 32 Sànmánì Tiwa. Ní ohun tó lé ní ọdún kan ṣáájú àjọ̀dún yìí ni Jésù sọ àwọn ẹ̀rí tá a mẹ́nu bà lókè yìí láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun ni Mèsáyà náà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó nígbàgbọ́ nínú Jésù tẹ́lẹ̀ kò tẹ̀ lé e mọ́, bóyá nítorí inúnibíni, ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì tàbí àníyàn ìgbésí ayé. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí Jésù ò ṣe gbà káwọn èèyàn fi òun jọba ló mú kí ọkàn àwọn kan dàrú tàbí ló múnú bí wọn. Nígbà táwọn aṣáájú ìsìn Júù ní kí Jésù fún àwọn ní àmì láti fi hàn pé òun ní Mèsáyà, kò fún wọn ní àmì kankan látọ̀run nítorí èyí yóò mú káwọn èèyàn máa fògo fún un. (Mátíù 12:38, 39) Ìdí tí Jésù ò fi fún wọn ní àmì lè má yé àwọn kan. Síwájú sí i, Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó ṣòro lóye fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé “òun gbọ́dọ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí òun sì jìyà ohun púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin, kí wọ́n sì pa òun.”—Mátíù 16:21-23.

10 Tó bá fi máa di nǹkan bí oṣù mẹ́sàn-án sí mẹ́wàá sígbà yẹn, àkókò á tó “fún [Jésù] láti lọ kúrò ní ayé yìí sọ́dọ̀ Baba.” (Jòhánù 13:1) Nítorí pé ọ̀rọ̀ àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù jẹ ẹ́ lọ́kàn gan-an, ó ṣèlérí pé òun máa fún àwọn kan lára wọn ní àmì kan látọ̀run, ìyẹn àmì tí kò fún àwọn Júù tó jẹ́ aláìṣòótọ́. Jésù sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé àwọn kan wà lára àwọn tí wọ́n dúró níhìn-ín tí kì yóò tọ́ ikú wò rárá títí wọn yóò fi kọ́kọ́ rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ nínú ìjọba rẹ̀.” (Mátíù 16:28) Dájúdájú, kì í ṣe pé Jésù ń sọ pé àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa wà láàyè títí dìgbà tí Ìjọba Mèsáyà yóò bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso lọ́dún 1914. Ńṣe ni Jésù fẹ́ fi ìran kan tó gbàfiyèsí han àwọn mẹ́ta kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ìran nípa ògo tó máa ní nígbà tó bá di Ọba ni. Ìran náà là ń pè ní ìran ìyípadà ológo.

11. Ṣàpèjúwe ìran ìyípadà ológo yẹn.

11 Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn ìyẹn, Jésù mú Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù gorí òkè ńlá kan lọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Òkè Hámónì. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, Jésù “yí . . . padà di ológo níwájú wọn, ojú rẹ̀ sì tàn bí oòrùn, ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ sì wá tàn yòò bí ìmọ́lẹ̀.” Mósè àti Èlíjà náà fara hàn, àwọn àti Jésù sì jọ ń sọ̀rọ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé alẹ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé yìí wáyé, èyí sì mú kí ìran náà hàn kedere gan-an sí wọn. Ìran yìí dà bí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi débi pé Pétérù sọ pé òun máa kọ́ àgọ́ mẹ́tà, ọ̀kan fún Jésù, ọ̀kan fún Mósè, ọ̀kan fún Èlíjà. Bí Pétérù ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìmọ́lẹ̀ kan tàn yòò sí wọn, wọ́n wá ń gbọ́ ohùn kan látinú sánmà tó sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà; ẹ fetí sí i.”—Mátíù 17:1-6.

12, 13. Ipa wo ni ìràn ìyípadà ológo náà ní lórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, kí sì nìdí tó fi ní irú ipa yẹn?

12 Pétérù tilẹ̀ ti jẹ́rìí sí i ṣáájú ìgbà ìyípadà ológo yẹn pé Jésù ni “Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.” (Mátíù 16:16) Àmọ́, ẹ wá wò ó nísinsìnyí, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ ẹni tí Jésù jẹ́, ó sì sọ ipa tí Ọmọ rẹ̀ tó ti fòróró yàn náà ń kó! Ìran ìyípadà ológo yìí ti ní láti fún Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù lókun gan-an ni! Ní báyìí tí ìgbàgbọ́ wọn tí lágbára sí i, wọ́n ti wá gbára dì fún àwọn nǹkan tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, àti fún ipa pàtàkì tí wọn máa kó nínú ìjọ ọjọ́ iwájú.

13 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí ò gbàgbé ìran ìyípadà ológo náà. Ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn tí ìyípadà ológo náà wáyé, Pétérù kọ̀wé pé: “[Jésù] gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, nígbà tí ògo ọlọ́lá ńlá gbé irú ọ̀rọ̀ báwọ̀nyí wá fún un pé: ‘Èyí ni ọmọ mi, olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹni tí èmi tìkára mi tẹ́wọ́ gbà.’ Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni a gbọ́ tí a gbé wá láti ọ̀run nígbà tí a wà pẹ̀lú rẹ̀ ní òkè ńlá mímọ́ náà.” (2 Pétérù 1:17, 18) Ìran náà wú Jòhánù lórí pẹ̀lú. Lẹ́yìn ọgọ́ta ọdún, Jòhánù mẹ́nu kan ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “A sì rí ògo rẹ̀, ògo kan irú èyí tí ó jẹ́ ti ọmọ bíbí kan ṣoṣo láti ọ̀dọ̀ baba kan.” (Jòhánù 1:14) Àmọ́ ṣá o, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tún rí ìran mìíràn yàtọ̀ sí ìran ìyípadà ológo yẹn.

Àwọn Adúróṣinṣin Ìránṣẹ́ Ọlọ́run Ní Òye Sí I

14, 15. Báwo ló ṣe jẹ́ pé àpọ́sítélì Jòhánù wà láyé títí Jésù fi dé?

14 Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nítòsí Òkun Gálílì. Ibẹ̀ ló ti sọ fún Pétérù pé: “Bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ mi pé kí [Jòhánù] wà títí èmi yóò fi dé, kí ni ó kàn ọ́ níbẹ̀?” (Jòhánù 21:1, 20-22, 24) Ṣé gbólóhùn yẹn túmọ̀ sí pé àpọ́sítélì Jòhánù máa pẹ́ láyé ju àwọn àpọ́sítélì yòókù lọ? Ó dá bí ẹni pé bẹ́ẹ̀ gan-an lọ́rọ̀ rí, nítorí pé Jòhánù ṣì fi òtítọ́ ọkàn sin Jèhófà fún nǹkan bí àádọ́rin ọdún lẹ́yìn náà. Àmọ́, ohun tí ọ̀rọ̀ Jésù túmọ̀ sí jùyẹn lọ.

15 Gbólóhùn náà “títí èmi yóò fi dé” mú ká rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé “Ọmọ ènìyàn . . . ń bọ̀ nínú ìjọba rẹ̀.” (Mátíù 16:28) Jòhánù wà láyé títí Jésù fi dé ní ti pé, nígbà tó yá Jésù fi ìran alásọtẹ́lẹ̀ mìíràn hàn án nínú èyí tó ti ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba náà. Nígbà tó ku díẹ̀ kí Jòhánù kú, ìyẹn nígbà tó ṣì wà ní erékùṣù Pátímọ́sì, ó rí Ìran àgbàyanu nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní “ọjọ́ Olúwa.” Ìràn àrà ọ̀tọ̀ tí Jòhánù rí yìí wú u lórí débi pé, nígbà tí Jésù sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni; mo ń bọ̀ kíákíá,” Jòhánù fi ìtara sọ pé: “Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.”—Ìṣípayá 1:1, 10; 22:20.

16. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fún ìgbàgbọ́ wa lókun sí i?

16 Àwọn tó lọ́kàn tó dáa ní ọ̀rúndún kìíní gbà pé Jésù ni Mèsáyà, wọ́n sì nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ó yẹ káwọn tó di onígbàgbọ́ wọ̀nyí túbọ̀ mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára sí i. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó wà lágbègbè wọn ni kò nígbàgbọ́ nínú Jésù, iṣẹ́ sì ńbẹ níwájú wọn, àdánwò sì tún ń dúró dè wọ́n lọ́jọ́ iwájú. Jésù ti fún wọn ní ẹ̀rí tó pọ̀ tó láti fi hàn pé òun ní Mèsáyà náà, ó sì ti fi ìran tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ hàn wọ́n láti lè fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó jẹ́ adúróṣinṣin níṣìírí. Lónìí, a ti wọ “ọjọ́ Olúwa” náà jìnnà. Láìpẹ́, Kristi yóò pa ètò nǹkan búburú ti Sátánì run, yóò sì gba àwọn èèyàn Ọlọ́run là. Nítorí náà, ó yẹ káwa náà fún ìgbàgbọ́ wa lókun nípa lílo gbogbo àwọn nǹkan tí Jèhófà ń pèsè fún àǹfààní wa nípa tẹ̀mí.

A Gbà Wọ́n Lọ́wọ́ Òkùnkùn àti Ìpọ́njú

17, 18. Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ wo ló wà láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní àtàwọn tí wọ́n ń ta ko ète Ọlọ́run, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí ẹgbẹ́ méjèèjì?

17 Lẹ́yìn ikú Jésù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi ìgboyà ṣe iṣẹ́ tó pá láṣẹ pé kí wọ́n ṣe. Iṣẹ́ náà ni pé kí wọ́n jẹ́rìí nípa òun “ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ṣe inúnibíni sí ìjọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ náà, Jèhófà fi òye tẹ̀mí jíǹkí wọn, ó sì mú kí ọ̀pọ̀ ọmọ ẹ̀yìn tuntun dara pọ̀ mọ́ wọn.—Ìṣe 2:47; 4:1-31; 8:1-8.

18 Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ńṣe ni ipò tí àwọn tó ń ta ko ìhìn rere náà wà túbọ̀ ń burú sí i. Òwe 4:19 sọ pé: “Ọ̀nà àwọn ẹni burúkú dà bí ìṣúdùdù; wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń kọsẹ̀ lára rẹ̀ ṣáá.” Ipò táwọn alátakò náà wà túbọ̀ burú sí i nígbà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù fẹ́ wá pa Jerúsálẹ́mù run ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa. Àmọ́ láìsí ìdí kan tó ṣe gúnmọ́, àwọn ọmọ ogun náà kàn ṣàdédé padà sílùú wọn. Nígbà tó di ọdún 70 Sànmánì Tiwa, wọ́n tún padà wá, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ńṣe ni wọ́n pa ìlú náà run ráúráú. Òpìtàn ọmọ Júù nì tó ń jẹ́ Josephus sọ pé àwọn Júù tó ṣègbé lé ní mílíọ̀nù kan. Àmọ́ ṣá o, àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ elétí ọmọ yè bọ́. Kí ló mú kí wọ́n yè bọ́? Ohun náà ni pé nígbà táwọn ọmọ ogun Róòmù kọ́kọ́ kógun dé, àwọn Kristẹni náà ṣe ohun tí Jésù ní kí wọ́n ṣe, ìyẹn ni pé kí wọ́n sá lọ fún ẹ̀mí wọn.—Lúùkù 21:20-22.

19, 20. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ káwọn èèyàn Ọlọ́run máa bẹ̀rù bí òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti ń sún mọ́lé? (b) Òye tó pabanbarì wo ni Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀ láwọn ọdún tó ṣáájú ọdún 1914?

19 Ipò táwa náà wà lónìí fara jọ tiwọn. Ìpọ́njú ńlá tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ ni yóò fòpin sí ètò àwọn nǹkan búburú ti Sátánì. Àmọ́ kò sídìí fáwọn èèyàn Ọlọ́run láti máa bẹ̀rù nítorí Jésù ṣèlérí fún wọn pé: “Wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 28:20) Kí Jésù lè mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ìjímìjí lágbára sí i kó sì tún múra wọn sílẹ̀ fáwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ló ṣe fi ìran kan hàn wọ́n nípa ògo tó máa ní nígbà tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà Ọba. Òde òní wá ńkọ́? Nígbà tó di ọdún 1914, ìran tí Jésù fi hàn wọ́n yẹn ṣẹlẹ̀ ní ti gidi. Èyí sì ti fún ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run lókun gan-an! Ó mú kí wọ́n máa retí ọjọ́ ọ̀la kan tó mìrìngìndìn, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà sì ti ń rí ìlàlóye ní ṣísẹ̀-ń-tẹ̀lé nípa Ìjọba náà tí Mèsáyà yóò ṣàkóso. Nínú ayé tó ṣú dùdù tí nǹkan ti ń burú sí i yìí, “ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, títí di ọ̀sán gangan.”—Òwe 4:18.

20 Ká tiẹ̀ tó wọ ọdún 1914 làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í lóye òtítọ́ pàtàkì nípa ìpadàbọ̀ Olúwa. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n mọ̀ pé a ò ní fojú rí i nígbà tó bá padà wá, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe lóye rẹ̀ látinú ọ̀rọ̀ àwọn áńgẹ́lì méjì tó fara han sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa nígbà tí Jésù fi ń gòkè re ọ̀run. Nígbà tí ìkùukùu àwọsánmà bo Jésù táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ò sì rí i mọ́, áńgẹ́lì náà sọ fún wọn pé “Jésù yìí tí a gbà sókè kúrò lọ́dọ̀ yín sínú sánmà yóò wá bẹ́ẹ̀ ní irú ọ̀nà kan náà bí ẹ ti rí i tí ó ń lọ sínú sánmà.”—Ìṣe 1:9-11.

21. Kí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

21 Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin nìkan ló rí Jésù nígbà tó ń gòkè re ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí nípa ìran ìyípadà ológo yẹn; àwọn èèyàn ò tiẹ̀ mọ̀ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wáyé. Bó ṣe rí nìyẹn nígbà tí Kristi padà wá tòun ti agbára Ìjọba. (Jòhánù 14:19) Àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró nìkan ló róye pé ó ti dé gẹ́gẹ́ bí Ọba. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a óò rí bí òye yìí ṣe ní ipa kíkàmàmà lórí wọn, èyí tó yọrí sí kíkó ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí yóò di ọmọ abẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé jọ.—Ìṣípayá 7:9, 14.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó jọ pé Jòhánù nìkan ló gbọ́ ohùn Ọlọ́run nígbà ìrìbọmi Jésù. Àwọn Júù tí Jésù bá sọ̀rọ̀ “kò tíì gbọ́ ohùn [Ọlọ́run] nígbà kankan rí, bẹ́ẹ̀ ni [wọn] kò tíì rí ìrísí rẹ̀.”—Jòhánù 5:37.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Nígbà táwọn èèyàn fẹ̀sùn kan Jésù pé ó rú òfin Sábáàtì, tí wọ́n tún sọ pé ó sọ̀rọ̀ òdì, ẹ̀rí wo ló fi hàn wọ́n láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ní Mèsáyà náà?

• Báwo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ìjímìjí ṣe jàǹfààní látinú ìran ìyípadà ológo náà?

• Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé Jòhánù máa wà títí òun á fi dé?

• Ìran alásọtẹ́lẹ̀ wo ló nímùúṣẹ lọ́dún 1914?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Jésù jẹ́ káwọn èèyàn rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé òun ní Mèsáyà náà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ìran ìyípadà ológo náà fún ìgbàgbọ́ lókun

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Jòhánù ò kú títí Jésù fi “dé”