Ohun Tó Ń Mú Kí Ọjọ́ Ogbó Jẹ́ “Adé Ẹwà”
“Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ni Ìrànlọ́wọ́ Mi Ti Wá”
Ohun Tó Ń Mú Kí Ọjọ́ Ogbó Jẹ́ “Adé Ẹwà”
NÍGBÀ tí obìnrin ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rùn-ún kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Muriel ń sọ nípa bó ṣe fi ìgbésí ayé rẹ̀ sin Jèhófà, ó ní: “Ìgbésí ayé tó dára jù lọ ni.” Theodoros, tó jẹ́ ẹni àádọ́rin ọdún náà sọ pé: “Àǹfààní tó ga lọ́lá ni!” Maria tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rin sọ pé: “Ọ̀nà tó dára jù lọ ni mo gbà lo ìgbésí ayé mi.” Gbogbo àwọn tá a dárúkọ yìí ló ti fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn sin Jèhófà Ọlọ́run.
Irú àwọn àgbàlagbà wọ̀nyí pọ̀ rẹpẹtẹ nínú àwọn tó ń fìtara sin Jèhófà kárí ayé. Láìka ọjọ́ ogbó, àìlera àti àwọn ipò mìíràn tí kò bára dé sí, wọ́n ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìfọkànsin Ọlọ́run, àpẹẹrẹ àtàtà làwọn àgbàlagbà olóòótọ́ wọ̀nyẹn jẹ́ nínú Ìjọ Kristẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó níbi tí agbára àwọn àgbàlagbà mọ, síbẹ̀ iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń ṣe ṣe pàtàkì gan-an lójú Jèhófà. a—2 Kọ́ríńtì 8: 12.
Ìwé Sáàmù sọ irú ìgbésí ayé tó dára táwọn àgbàlagbà tó jẹ́ olóòótọ́ lè máa retí àtigbé tí wọ́n bá darúgbó. Ó ní wọ́n á gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ wọ́n á sì tún máa sèso bí igi tó ti pẹ́ nígbó. Onísáàmù wá kọrin nípa wọn pé: “Wọn yóò ṣì máa gbèrú nígbà orí ewú, wọn yóò máa bá a lọ ní sísanra àti ní jíjàyọ̀yọ̀.”—Sáàmù 92:14.
Àwọn kan nínú wọn lè máa bẹ̀rù pé àwọn èèyàn ò ní ka àwọn sí mọ́ nígbà tí ọjọ́ ogbó bá ti sọ àwọn di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Ìdí nìyẹn tí Dáfídì fi bẹ Ọlọ́run pé: “Má ṣe gbé mi sọnù ní àkókò ọjọ́ ogbó; ní àkókò náà tí agbára mi ń kùnà, má ṣe fi mí sílẹ̀.” (Sáàmù 71:9) Tẹ́nì kan bá jẹ́ olódodo, yóò gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ lọ́jọ́ ogbó, tí kò bá jẹ́ olódodo, ńṣe ni yóò kùnà lọ́jọ́ ogbó. Abájọ tí onísáàmù fi kọrin pé: “Olódodo yóò yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pẹ.”—Sáàmù 92:12.
Àwọn tó fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn sábà máa ń sèso dọjọ́ ogbó wọn ni. Ní tòdodo, àwọn ohun tí wọ́n ti ṣe láti ran ara wọn lọ́wọ́ tàbí láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ń so èso rere. (Gálátíà 6:7-10; Kólósè 1:10) Àmọ́ àwọn èèyàn tó máa ń lo ìgbésí ayé wọn nílòkulò láti tẹ́ ìfẹ́ inú ara wọn lọ́rùn kì í rí nǹkan gidi tí wọ́n fi àárọ̀ ọjọ́ wọn ṣe.
Ìwé Òwe wá tẹnu mọ́ ọn pé òdodo ni ọ̀ṣọ́ ọjọ́ ogbó. Bó ṣe kà rèé: “Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.” (Òwe 16:31) Bó ṣe rí gan an nìyẹn o, iṣẹ́ òdodo ló ń fi ẹwà inú lọ́hùn-ún hàn. Ẹni tó bá hùwà òdodo jálẹ̀ ìgbésí ayé máa ń níyì. (Léfítíkù 19:32) Béèyàn bá léwú lórí tó sì tún ní ọgbọ́n àti ìwà ọmọlúàbí, àwọn èèyàn á máa bọ̀wọ̀ fún un.—Jóòbù 12:12.
Ojú pàtàkì ni Jèhófà fi ń wo ẹni tó bá fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ sìn ín. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Àní títí di ọjọ́ ogbó ènìyàn, ẹnì kan náà ni mí; àti títí di ìgbà orí ewú ènìyàn, èmi fúnra mi yóò máa rù ú. Dájúdájú, èmi yóò gbé ìgbésẹ̀, kí èmi fúnra mi lè gbé, kí èmi fúnra mi sì lè rù, kí n sì pèsè àsálà.” (Aísáyà 46:4) Mímọ̀ pé Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ṣèlérí pé òun á pèsè fáwọn ẹni ìdúróṣinṣin, òun á sì dúró tì wọ́n lọ́jọ́ ogbó wọn, mà ń fini lọ́kàn balẹ̀ o!—Sáàmù 48:14.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà fojú pàtàkì wo àwọn to fi gbogbo ìgbésí ayé wọn sìn ín, ǹjẹ́ kò yẹ káwa náà máa gbé wọn gẹ̀gẹ̀? Tá a bá fìwà jọ Ọlọ́run, a ó máa ṣìkẹ́ àwọn àgbàlagbà tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. (1 Tímótì 5:1, 2) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká wá ọ̀nà tó dára tá a lè gbà fi ìfẹ́ Kristẹni hàn sí wọn, ká máa bójú tó wọn.
Èèyàn Lè Rìn ní Ọ̀nà Òdodo Lọ́jọ́ Ogbó
Sólómọ́nì fi dá wa lójú pé: “Ìyè wà ní ipa ọ̀nà òdodo.” (Òwe 12:28) Kéèyàn darúgbó kùjọ́kùjọ́ kò sọ pé kéèyàn má rìn ní ọ̀nà òdodo. Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀ èdè Moldova, ọkùnrin ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún kan wà tó jẹ́ pé ìjọba Kọ́múníìsì ló fi gbogbo àárọ̀ ọjọ́ ayé rẹ̀ gbé lárugẹ. Kódà ọkùnrin yìí máa ń yangàn pé òun ti bá àwọn gbajúgbajà aṣáájú Kọ́múníìsì kan tàkúrọ̀ sọ, ìyẹn àwọn bíi V.I. Lenin. Àmọ́ nígbà tí ìjọba Kọ́múníìsì kógbá sílé, baba àgbàlagbà yìí ò mọ ibi tí ìgbésí ayé òun dorí kọ. Ṣùgbọ́n nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ kó mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa yanjú ìṣòro ẹ̀dá, ó fara mọ́ òtitọ́ Bíbélì ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i fi ìtara kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́. Ikú ni ò jẹ́ kó ṣèrìbọmi, kó sì di ìránṣẹ́ Jèhófà.
Nígbà tí obìnrin ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin kan ní orílẹ̀-èdè Hungary kẹ́kọ̀ọ́ nípa irú ìwà tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa hù, ó rí i pé ó yẹ kóun àti ọkùnrin táwọn ti jọ ń gbé pọ̀ láti ọ̀pọ̀ ọdún ṣègbéyàwó lọ́nà òfin. Obìnrin náà lo ìgboyà, ó sì ṣàlàyé òye tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ní látinú Bíbélì yìí fún ọkùnrin náà. Ó yà á lẹ́nu pé ọkùnrin náà gbà láti bá a ṣègbéyàwó lọ́nà òfin. Lẹ́yìn tí wọ́n fìdí ìgbéyàwó wọn mulẹ̀ lábẹ́ òfin tán, ó jára mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́. Kò ju oṣù mẹ́jọ lọ tó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó fi di akéde aláìṣèrìbọmi, kò sì pẹ́ sí àkókò yẹn tó fi ṣèrìbọmi. Àṣé òótọ́ ni pé ìwà òdodo ni ẹwà orí ewú!
Káwọn Kristẹni olóòótọ́ tó ti dàgbà jẹ́ kó dá wọn lójú pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wọn. Jèhófà ò ní pa àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i tì láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìlérí tó ṣe ni pé òun á dáàbò bò wọ́n, òun á dúró tì wọ́n, òun á sì bójú tó wọn àní títí dọjọ́ ogbó wọn pàápàá. Àwọn náà á sì lè jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ tí onísáàmù sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá.”—Sáàmù 121:2.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo oṣù January àti February nínú 2005 Calendar of Jehovah’s Witnesses.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]
“Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.”—ÒWE 16:31
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
JÈHÓFÀ Ń BÓJÚ TÓ ÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ RẸ̀ TÓ TI DÀGBÀ
“Kí o dìde dúró níwájú orí ewú, kí o sì fi ìgbatẹnirò hàn fún arúgbó.”—Léfítíkù 19:32.
“Àní títí di ọjọ́ ogbó ènìyàn, ẹni kan náà ni mí; àti títí di ìgbà orí ewú ènìyàn, èmi fúnra mi yóò máa rù ú.”—Aísáyà 46:4.