Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀mí Èèyàn Ǹjẹ́ Ó Ṣeyebíye àbí Kò Já Mọ́ Nǹkan Kan?

Ẹ̀mí Èèyàn Ǹjẹ́ Ó Ṣeyebíye àbí Kò Já Mọ́ Nǹkan Kan?

Ẹ̀mí Èèyàn Ǹjẹ́ Ó Ṣeyebíye àbí Kò Já Mọ́ Nǹkan Kan?

“Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti dá èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀, tẹ́nì kan bá gbẹ̀mí èèyàn, á jẹ́ pé ohun tó ṣeyebíye jù lọ tó sì lọ́wọ̀ jù lọ lonítọ̀hún bà jẹ́ yẹn.”—Ìwé The Plain Man’s Guide to Ethics látọwọ́ William Barclay.

ÒǸKỌ̀WÉ yìí sọ pé ẹ̀mí èèyàn ‘lohun tó ṣeyebíye jù lọ láyé.’ Ṣé ojú tí ìwọ náà fi ń wo ẹ̀mí èèyàn nìyẹn? Ìwà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń hù fi hàn gbangba pé wọn ò fara mọ́ ohun tí òǹkọ̀wé yìí sọ. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn làwọn aláìláàánú ẹ̀dá ń pa nítorí kọ́wọ́ wọn lè tẹ nǹkan tí wọ́n ń lé láìgba tọmọnìkejì wọn rò.—Oníwàásù 8:9.

Wọ́n Ò Ka Ẹ̀mí Èèyàn Sí

Àpẹẹrẹ kan ni ti ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Òpìtàn kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ A.J.P. Taylor sọ pé nígbà ogun àjàkú akátá yẹn, “ńṣe ni wọ́n kàn ń pa àwọn èèyàn nípakúpa láìnídìí.” Káwọn ọ̀gá sójà lè gbayì lójú àwọn èèyàn káwọn èèyàn sì lè máa kan sáárá sí wọn, wọ́n wá ń lo àwọn sójà nílòkulò bíi pé wọn kò já mọ́ nǹkan kan. Ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méje èèyàn tó kú nínú ogun tí wọ́n jà ní ìlú Verdun lórílẹ̀-èdè Faransé. Òpìtàn Taylor sọ pé: “Kò sẹ́ni tógun ọ̀hún gbè nínú ìhà méjèèjì tó jagun náà o, kí wọ́n sá ti pààyàn káwọn èèyàn sì máa kan sáárá sí wọn ni wọ́n mọ̀.”—Ìwé The First World War.

Títí di bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, kárí ayé ni ẹ̀mí èèyàn kò ti já mọ́ nǹkan kan lójú àwọn èèyàn. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kevin Bales sọ pé lẹ́nu àìpẹ́ yìí, “bí iye èèyàn ṣe ń pọ̀ sí i láyé ti mú kí àwọn akúùṣẹ́ àtàwọn tí kò ní alábàárò

tó ń wáṣẹ́ pọ̀ jaburata.” Gbogbo ọjọ́ ayé wọn ni wọ́n fi ń forí ṣe fọrùn ṣe kí wọ́n lè rọ́nà gbé e gbà nínú ètò ọrọ̀ ajé tí ò fara rọ, èyí “tó ń sọ ìgbésí ayé di ohun tí kò já mọ́ nǹkan kan.” Bales sọ síwájú sí i pé ńṣe làwọn tó ń lo àwọn akúùṣẹ́ ń lò wọ́n nílò ẹrú; “nítorí àtilówó, wọ́n á lò wọ́n nílòkulò, wọ́n á wá dà wọ́n nù bí omi ìṣanwọ́.”—Ìwé Disposable People.

“Lílépa Ẹ̀fúùfù”

Ọ̀pọ̀ nǹkan míì ló wà tó ti mú kí ẹgbàágbèje èèyàn sọ̀rètínù tó sì mú kí wọ́n máa rò pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan. Lédè mìíràn, wọ́n ń rò pé kò sẹ́nì kankan tó bìkítà nípa àwọn, bóyá àwọn tiẹ̀ ti kú ni tàbí àwọn ṣì wà láàyè. Yàtọ̀ sí ogun àti ìwà ìrẹ́jẹ, lára àwọn ohun tó ń pọ́n aráyé lójú ni ọ̀dá, ìyàn, àrùn àti ikú èèyàn ẹni. Gbogbo èyí mú káwọn èèyàn máa ṣe kàyéfì pé bóyá ló tiẹ̀ yẹ kéèyàn máa gbé ayé yìí rárá.—Oníwàásù 1:8, 14.

Kò sí àní-àní pé gbogbo èèyàn kọ́ ló ń rí ìnira tó gàgaàrá àti ìpọ́njú tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀. Àmọ́ gbogbo ìgbà làwọn tí kì í fi bẹ́ẹ̀ rí ìnira máa ń béèrè ìbéèrè tí Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ayé àtijọ́ béèrè, pé: “Kí ni ènìyàn wá ní nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ àti nítorí ìlàkàkà ọkàn-àyà rẹ̀ èyí tí ó fi ń ṣiṣẹ́ kárakára lábẹ́ oòrùn?” Lẹ́yìn táwọn èèyàn bá ronú nípa ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n ti gbé ṣe, wọ́n máa ń kíyè sí pé “asán . . . àti lílépa ẹ̀fúùfù” ni.—Oníwàásù 2:22, 26.

Nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá wo ìgbésí ayé tí wọ́n ti gbé kọjá, ìbéèrè tí wọ́n máa ń béèrè ni pé: “Ṣé ìgbésí ayé kò jù báyìí náà lọ?” Òótọ́ ni, àbí ó dẹni mélòó tó gbó tó tọ́ bíi ti Ábúráhámù baba ńlá? (Jẹ́nẹ́sísì 25:8) Ńṣe ló ń ṣe ọ̀pọ̀ bíi pé asán ni ìgbésí ayé wọn já sí. Ṣùgbọ́n kò yẹ kí ìgbésí ayé ẹni já sásán. Ohun iyebíye ni Ọlọ́run ka ẹ̀mí olúkúlùkù èèyàn sí, ó sì fẹ́ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan gbádùn ìgbésí ayé tó lárinrin. Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ṣe ìyẹn? Wo ohun tí àpilẹ̀kọ tó kàn sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí.