Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀mí Rẹ Ṣeyebíye

Ẹ̀mí Rẹ Ṣeyebíye

Ẹ̀mí Rẹ Ṣeyebíye

BÁWỌN kan ṣe ń gbẹ̀mí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ní Yúróòpù nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, bẹ́ẹ̀ lẹnì kan ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti gba ẹ̀mí àwọn èèyàn kan là nílẹ̀ Antarctic. Onítọ̀hún ni olùṣàwárí kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Orúkọ rẹ̀ ni Ernest Shackleton. Ọkọ̀ òkun tí wọ́n pè ní Endurance tí òun àtàwọn tó ń bá a rìnrìn àjò wọ̀ forí sọ yìnyín ràbàtà tó léfòó sójú omi, ló bá rì. Àmọ́ Shackleton sapá láti yọ wọ́n nínú ewu náà, ó sì fi ọkọ̀ ojú omi kékeré gbé wọn lọ sí erékùṣù kan tó ń jẹ́ Elephant Island ní Gúúsù Òkun Àtìláńtíìkì. Àmọ́, ewu ńlá ṣì wà níbi tí wọ́n lọ yẹn.

Shackleton rí i pé ohun kan ṣoṣo tó kù táwọn fi lè yè é ni pé kóun ránṣẹ́ sí àwọn tó wà níbì kan tí wọ́n ti ń pa ẹja àbùùbùtán ní erékùṣù South Georgia pé kí wọ́n wá ran àwọn lọ́wọ́. Ibẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún kìlómítà síbi tí wọ́n wà, ọkọ̀ ojú omi kan ṣoṣo tí Shackleton gbé jáde látinú ọkọ̀ òkun Enduranceọkọ̀ náà tó rì ló sì wà. Nítorí náà, kò dájú pé wọ́n lè yè é.

Shackleton àti mélòó kan lára àwọn tí wọ́n wà nínú ọkọ̀ náà forí lé erékùṣù South Georgia, wọ́n sì débẹ̀ ní May 10, 1916 lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyà lọ́nà fún ọjọ́ mẹ́tàdínlógún. Àmọ́ ibi tí wọ́n ń lọ gan-an ní erékùṣù yẹn kọ́ ni wọ́n gúnlẹ̀ sí nítorí pé omi òkun tó ń ru gùdù darí wọn gba ibòmíràn. Ni wọ́n bá tún fẹsẹ̀ rin ìrìn ọgbọ̀n kìlómítà gba àwọn òkè tí yìnyín bò kí wọ́n tó lè dé ibi tí wọ́n ń lọ gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, ibi tí wọ́n wà yẹn tutù ju yìnyín lọ, wọn kò sì ní ohun tí wọ́n fi máa ń gun òkè. Ṣùgbọ́n Shackleton àtàwọn tó kù dé ibi tí wọ́n ń lọ láyọ̀. Ó wá gbé ọkọ̀ ojú omi láti ibẹ̀ lọ sí erékùṣù Elephant Island láti fi gbé àwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò tó ṣì há síbẹ̀. Bó ṣe gba ẹ̀mí gbogbo wọn là nìyẹn. Kí nìdí tí Shackleton fi ṣe gbogbo wàhálà yẹn? Roland Huntford tó máa ń kọ ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn sọ pé: “Ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni kó lè gba ẹ̀mí gbogbo àwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò là.”

“Kò Sí Ìkankan Nínú Wọn Tí Ó Dàwáàrí”

Erékùṣù táwọn tó ń bá Shackleton rìnrìn àjò ti ń dúró dè é “fẹ̀ tó ọgbọ̀n kìlómítà, ibẹ̀ tutù gan-an, ilẹ̀ àpáta àti yìnyín ni.” Ńṣe ni wọ́n ń ká ṣíóṣíó nítorí òtútù. Àmọ́ kí ló fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ tí wọn kò fi sọ̀rètínù? Wọn kò sọ̀rètínù nítorí ó dá wọn lójú pé Shackleton tó jẹ́ aṣáájú wọn yóò wá gbé wọn kúrò níbẹ̀ bó ṣe ṣèlérí fún wọn.

Àwọn tó há sí erékùṣù náà ò fi bẹ́ẹ̀ nírètí pé àwọn lè yè é. Lónìí, irú ipò tí aráyé wà nìyẹn. Ipò táwọn míì wà burú jáì, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ wọn débi pé agbára káká ni wọ́n fi ń róúnjẹ jẹ. Síbẹ̀, ó dájú hán-únhán-ún pé Ọlọ́run yóò “gba ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́” lọ́wọ́ ìnira àti ìpọ́njú. (Jóòbù 36:15) Mọ̀ dájú pé Ọlọ́run ka ẹ̀mí gbogbo wa pátá sí iyebíye. Jèhófà Ọlọ́run, tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa sọ pé: “Pè mí ní ọjọ́ wàhálà. Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀.”—Sáàmù 50:15.

Ǹjẹ́ ó ṣòro fún ọ láti gbà pé Ẹlẹ́dàá kà ọ́ sí iyebíye, ìwọ tó jẹ́ pé o wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí ń bẹ láyé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ronú nípa ohun tí wòlíì Aísáyà sọ nípa ọ̀kẹ́ àìmọye ìràwọ̀ tí ń bẹ nínú òbítíbitì ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run. Ó kà pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí? Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye, àwọn tí ó jẹ́ pé àní orúkọ ni ó fi ń pe gbogbo wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga, àti ní ti pé òun ní okun inú nínú agbára, kò sí ìkankan nínú wọn tí ó dàwáàrí.”—Aísáyà 40:26.

Ǹjẹ́ ohun tí ẹsẹ Bíbélì yẹn ń sọ yé ọ? Ṣé o rí i, ó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000,000,000] ìràwọ̀ tó wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ onírìísí wàrà (Milky Way galaxy). Kó o sì wá wò ó, ńṣe ni àpapọ̀ oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yípo rẹ̀ wulẹ̀ jẹ́ ara ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ yìí. Yàtọ̀ síyẹn, ó tó ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ mélòó tó tún wà? Kò sẹ́ni tó lè sọ iye wọn ní pàtó, àmọ́ àwọn kan fojú bù ú pé àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó tún wà tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùndínláàádóje [125,000,000,000]. Iye ìràwọ̀ tó wà mà pọ jaburata o, ohun ìyanu ni! Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé mọ orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìràwọ̀ yìí.

‘Gbogbo Irun Orí Yín Ni A Ti Kà’

Àmọ́, ẹnì kan lè sọ pé: ‘Bí Ọlọ́run tiẹ̀ mọ orúkọ ọ̀kẹ́ àìmọye ìràwọ̀ àti ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ó ń bìkítà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn.’ A mọ̀ pé a lè forúkọ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn pa mọ́ sórí kọ̀ǹpútà, ṣùgbọ́n kò sẹ́ni tó máa jẹ́ sọ pé kọ̀ǹpútà bìkítà nípa àwọn tá a forúkọ wọn pa mọ́ sórí rẹ̀. Àmọ́ Bíbélì sọ pé yàtọ̀ sí pé Jèhófà Ọlọ́run mọ orúkọ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn, ó tún ń bìkítà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: ‘Ẹ kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.’—1 Pétérù 5:7.

Jésù Kristi sọ pé: “Kì í ha ṣe ológoṣẹ́ méjì ni a ń tà ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré? Síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” (Mátíù 10:29-31) Kíyè sí i pé Jésù ò wulẹ̀ sọ pé Ọlọ́run ń kíyè sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ológoṣẹ́ àti èèyàn, àmọ́ ó tún sọ pé: “Ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” Kí lohun tó mú kó o níye lórí ju ológoṣẹ́ lọ? Ohun náà ni pé “àwòrán Ọlọ́run” ni Ọlọ́run dá ọ, èyí tó fún ọ láǹfààní láti ní àwọn ànímọ́ pàtàkì tí Ọlọ́run ní, irú bí ìwà rere àti ọgbọ́n.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27.

“Iṣẹ́ Ọwọ́ Ẹnì Kan Tó Ní Làákàyè”

Má ṣe gbọ́ tàwọn tó ń sọ pé kò sí Ẹlẹ́dàá o. Ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ni pé èèyàn kàn ṣàdédé wà ni. Wọ́n sọ pé kì í ṣe ní “àwòrán Ọlọ́run” ni a dá èèyàn, wọ́n sì ní èèyàn kò yàtọ̀ sí ẹranko àti ẹyẹ, títí kan ẹyẹ ológoṣẹ́.

Lójú rẹ, ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn sọ pé ńṣe làwọn ohun ẹlẹ́mìí ṣèèṣì wà? Michael J. Behe tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè sọ pé, “ọ̀nà ìyanu tí àwọn kẹ́míkà tó wà nínú ohun alààyè gbà ń ṣiṣẹ́” fi hàn pé, kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn sọ pé ńṣe làwọn ohun alààyè ṣèèṣì wà. Ó sọ síwájú sí i pé bí kẹ́míkà ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú ara jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé “àwọn ohun tín-tìn-tín tí ń bẹ nínú àwọn ohun alààyè tó wà lórí ilẹ̀ ayé . . . jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ẹnì kan tó ní làákàyè.”—Ìwé Darwin’s Black Box—The Biochemical Challenge to Evolution.

Bíbélì sọ fún wa pé ẹnì kan tó ní làákàyè ló dá gbogbo ohun alààyè tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Ó sì sọ pé Ẹni tó fi làákàyè dá gbogbo ohun wọ̀nyí ni Jèhófà Ọlọ́run, tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá ayé òun ọ̀run.—Sáàmù 36:9; Ìṣípayá 4:11.

Má ṣe tìtorí pé ìnira àti ìyà wà nínú ayé yìí, kó o wá sọ pé o ò ní gbà gbọ́ pé Ẹnì kan wà tó jẹ́ Oníṣẹ́ Ọnà tó dá ayé yìí àti gbogbo ohun alààyè tí ń bẹ nínú rẹ̀. Fi ohun pàtàkì méjì kan sọ́kàn. Àkọ́kọ́ ni pé Ọlọ́run kọ́ ló fa gbogbo nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. Èkejì ni pé ó nídìí tí Ẹlẹ́dàá fi fàyè gba àwọn nǹkan burúkú náà fúngbà díẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn tó o mú lọ́wọ́ yìí ṣe máa ń ṣàlàyé, ìdí tí Jèhófà Ọlọ́run fi fàyè gba ìnira fúngbà díẹ̀ ni pé kó lè yanjú ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀ lákòókò táwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ kọ Jèhófà ní ọba aláṣẹ. aJẹ́nẹ́sísì 3:1-7; Diutarónómì 32:4, 5; Oníwàásù 7:29; 2 Pétérù 3:8, 9.

“Òun Yóò Dá Òtòṣì Tí Ń Kígbe fún Ìrànlọ́wọ́ Nídè”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn lojú ń pọ́n lónìí, ó dájú pé ẹ̀bùn iyebíye ni ìwàláàyè ṣì jẹ́. Gbogbo ohun tá a bá sì mọ̀ là ń ṣe kí ẹ̀bùn ọ̀hún má bàa bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. Ayé tí Ọlọ́run ṣèlérí fún wa kì í ṣe èyí tí a ó ti máa làkàkà ká tó lè jẹun gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹmẹ̀wà Shackleton ṣe làkàkà kí wọ́n tó lè yè é ní erékùṣù Elephant Island. Ọlọ́run pinnu pé òun á gbà wá nínú ìnira àti ìmúlẹ̀mófo ká lè “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí,” ìyẹn ìyè tí Ọlọ́run fẹ́ kéèyàn ní nígbà tó dá èèyàn àkọ́kọ́.—1 Tímótì 6:19.

Ọlọ́run yóò ṣe gbogbo èyí nítorí pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló ṣeyebíye lójú rẹ̀. Ó ṣètò pé kí Jésù, Ọmọ rẹ̀, pèsè ìràpadà tá a nílò ká tó lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, àìpé àti ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà. (Mátíù 20:28) Jésù Kristi sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ . . . lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.

Kí wá ni Ọlọ́run máa ṣe fún àwọn tí ìnira àti ìyà ń pọ́n lójú nísinsìnyí? Nínú Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, ó sọ fún wa nípa Ọmọ rẹ̀ pé: “Òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.” Kí nìdí tó fi máa ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ‘ẹ̀jẹ̀ wọn [tàbí ẹ̀mí wọn] yóò ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.’Sáàmù 72:12-14.

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ni ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ti fi pọ́n ẹ̀dá èèyàn lójú, àfi bíi pé ẹ̀dá èèyàn ń ‘kérora’ nítorí ìyà àti ìnira tó pọ̀ gan-an. Ọlọ́run fàyè gba ìyẹn nítorí ó mọ̀ pé òun á mú ohun tó bá jẹ́ àbájáde rẹ̀ kúrò. (Róòmù 8:18-22) Láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, Ọlọ́run yóò lo Ìjọba rẹ̀ tí Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ yóò ṣàkóso láti ‘mú ohun gbogbo bọ̀ sípò.’—Ìṣe 3:21; Mátíù 6:9, 10.

Ìyẹn kan àjíǹde àwọn èèyàn tí ìyà jẹ tí wọ́n ti kú. Ọlọ́run ò lè gbàgbé wọn. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Láìpẹ́, wọn yóò ní ìyè “lọ́pọ̀ yanturu,” ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé, níbi tí wọ́n á ti di ẹni pípé tí wọn ò sì ní rí ìnira àti ìyà mọ́. (Jòhánù 10:10; Ìṣípayá 21:3-5) Olúkúlùkù àwọn tó bá wà láyé nígbà yẹn yóò gbádùn ìgbésí ayé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, wọn yóò sì láǹfààní láti ní àwọn ànímọ́ rere tó máa fi hàn pé “àwòrán Ọlọ́run” ni Ọlọ́run dá èèyàn. Wọ́n á tún lè gbé ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe.

Ṣé wàá wà níbẹ̀ láti gbádùn ìyè tí Jèhófà ṣèlérí? Ọwọ́ rẹ nìyẹn kù sí o. A rọ̀ ọ́ pé kó o jàǹfààní àwọn ètò tí Ọlọ́run ti ṣe láti mú gbogbo ìbùkún wọ̀nyí wá. Inú àwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe bẹ́ẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kó o lè rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ọ̀rọ̀ yìí, wo ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, orí 8 tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Èéṣe Tí Ọlọrun Fi Fàyègba Ìjìyà?” Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ ìwé yìí jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Ó dá àwọn ọkùnrin tó há sí erékùṣù Elephant Island lójú pé Shackleton yóò wá gbé wọn kúrò níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣèlérí fún wọn

[Credit Line]

© CORBIS

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

“Ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ”