“Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà”
“Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà”
LÁYÉ ọjọ́un, àwọn aṣọ́bodè ló máa ń ṣọ́ ibodè ìlú àti ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì. Wọ́n tún máa ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé nígbà míì. Wọ́n máa ń rí i dájú pé àwọn ti ilẹ̀kùn ibodè ìlú nígbà tílẹ̀ bá ṣú. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún máa ń ṣọ́ ìlú lóru. Iṣẹ́ yìí ṣe pàtàkì gan-an o, nítorí pé wọ́n ní láti ké tantan sáwọn ará ìlú láti kìlọ̀ fún wọn tí wọ́n bá rí i pé ewu ń bọ̀.
Jésù mọ ojúṣe àwọn aṣọ́bodè, tí wọ́n tún máa ń pè ní olùṣọ́nà nígbà yẹn. Nígbà kan, Jésù fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wé olùṣọ́nà, ó sì gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa ṣọ́nà nítorí ètò àwọn nǹkan Júù tó fẹ́ pa run. Ó sọ pé: “Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́. Ó dà bí ọkùnrin kan tí ó ń rin ìrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀, tí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì . . . pàṣẹ fún olùṣọ́nà láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà. Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí ọ̀gá ilé náà ń bọ̀.”—Máàkù 13:33-35.
Bákan náà, ó ti lé ní ọdún márùndínláàádóje [125] báyìí tí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tó o mú dání yìí, ti ń kéde ọ̀rọ̀ ìyànjú Jésù pé, “ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” Báwo ni Ilé Ìṣọ́ ṣe ń ṣe ìkéde yìí? Gẹ́gẹ́ bó ti wà ní ojú ìwé kejì, bó ṣe ń ṣe é ni pé “ó ń wo bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé ṣe ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ. Ó ń fi ìhìn rere náà tu gbogbo ènìyàn nínú pé Ìjọba Ọlọ́run yóò pa àwọn tí ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn níṣẹ̀ẹ́ run, tí yóò sì sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè láìpẹ́.” Iye Ilé Ìṣọ́ tá à ń pín kiri jákèjádò ayé ju mílíọ̀nù mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26,000,000], ní àádọ́jọ èdè. Nípa bẹ́ẹ̀, òun ni ìwé ìròyìn ìsìn tá à ń pín kiri jù lọ lágbàáyé. Báwọn aṣọ́bodè ṣe máa ń ké tantan sáwọn èèyàn láyé ọjọ́un, bẹ́ẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lo Ilé Ìṣọ́ láti máa fi ké tantan sáwọn èèyàn níbi gbogbo pé kí wọ́n “wà lójúfò” nípa tẹ̀mí. Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé Jésù Kristi tó jẹ́ Ọ̀gá náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé láti mú ìdájọ́ bá ètò àwọn nǹkan yìí.—Máàkù 13:26, 37.