Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Òtítọ́ Ń So Èso Nínú Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́?

Ǹjẹ́ Òtítọ́ Ń So Èso Nínú Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́?

Ǹjẹ́ Òtítọ́ Ń So Èso Nínú Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́?

NÍGBÀ tí ọmọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Eric sọ pé òun ò ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, inú àwọn òbí rẹ̀ bà jẹ́ gan-an. Wọn ò fura rárá pé irú èrò bẹ́ẹ̀ wà lọ́kàn rẹ̀. Eric ṣáà máa ń wà níjòókòó nígbà tí ìdílé wọn bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀, ó ṣáà máa ń lọ sípàdé, ó sì máa ń bá ìjọ lọ ṣiṣẹ́ ìwàásù. Ní gbogbo ìgbà yẹn, ńṣe ló dà bí pé Eric wà nínú òtítọ́. Ìgbà tó kúrò nílé làwọn òbí rẹ̀ tó mọ̀ pé òtítọ́ ò fìdí múlẹ̀ lọ́kàn rẹ̀. Ìjákulẹ̀ àti ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wọn.

Àwọn mìíràn ti rí irú àdánù yẹn nígbà táwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ fún wọn láìròtẹ́lẹ̀ pé àwọn ò kẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Nígbà tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ìbéèrè táwọn tó ṣẹlẹ̀ sí máa ń bi ara wọn ní pé, ‘Báwo ni mi ò ṣe mọ̀ pé ẹni yìí ń gbèrò irú nǹkan yẹn lọ́kàn?’ Ó dára, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe ká mọ̀ bóyá òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń so èso nínú àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n tó ṣubú nípa tẹ̀mí? Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé òtítọ́ ń so èso nínú àwa fúnra wa àtàwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́? Nínú àkàwé kan tá a mọ̀ bí ẹní mowó, ìyẹn àkàwé afúnrúgbìn, Jésù sọ kókó pàtàkì kan tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

Òtítọ́ Gbọ́dọ̀ Dénú Ọkàn

Jésù sọ pé: “Irúgbìn náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ní ti èyíinì tí [a fún sórí] erùpẹ̀ àtàtà, ìwọ̀nyí ni àwọn tí ó jẹ́ pé, lẹ́yìn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ọkàn-àyà àtàtà àti rere, wọ́n dì í mú ṣinṣin, wọ́n sì so èso pẹ̀lú ìfaradà.” (Lúùkù 8:11, 15) Nítorí náà, kí òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run tó lè so èso nínú àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, ó gbọ́dọ̀ fìdí múlẹ̀ nínú ọkàn wọn. Jésù fi dá wa lójú pé bí òtítọ́ bá dénú ọkàn ẹnì kan bí irúgbìn tó bọ́ sórí ilẹ̀ rere, ojú ẹsẹ̀ ló máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọkàn onítọ̀hún, yóò sì so èso. Kí ló wá yẹ ká máa wá lára àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́?

A ní láti fòye mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, ká má kàn máa wo ohun tó ń ṣe nìkan. Bí ẹnì kan tiẹ̀ ń kópa nínú gbogbo ìgbòkègbodò ìjọsìn Jèhófà, ìyẹn ò ní ká mọ ohun tó wà lọ́kàn onítọ̀hún. (Jeremáyà 17:9, 10; Mátíù 15:7-9) A ní láti kíyè sí onítọ̀hún dáadáa. Ó yẹ kí ìyípadà wà nínú àwọn ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí, àti ohun tó ń mú un ṣe àwọn ohun tó ń ṣe, títí kan àwọn ohun tó fi ṣáájú. Ó yẹ kí ẹni náà máa ní àkópọ̀ ìwà tuntun, èyí tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. (Éfésù 4:20-24) Àpèjúwe kan rèé: Pọ́ọ̀lù sọ pé nígbà táwọn ará Tẹsalóníkà gbọ́ ìhìn rere, wọ́n gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni. Àmọ́ ìfaradà tí wọ́n ní nígbà tó yá, bí wọ́n ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, àti ìfẹ́ tí wọ́n ní ló jẹ́ kó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé, òtítọ́ ‘wà lẹ́nu iṣẹ́ nínú wọn.’—1 Tẹsalóníkà 2:13, 14; 3:6.

Kò sí àní-àní pé bópẹ́bóyá, ohun tí ń bẹ lọ́kàn ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ yóò hàn síta gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti Eric. (Máàkù 7:21, 22; Jákọ́bù 1:14, 15) Ohun tó dunni níbẹ̀ ni pé, ìgbà téèyàn bá máa fi mọ̀ pé ẹnì kan ní àwọn ìwà kan tí kò dára, ó lè ti pẹ́ jù. Nítorí náà, ó di dandan kéèyàn gbìyànjú láti mọ àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tẹ́nì kan ní káwọn kùdìẹ̀-kudiẹ náà tó ṣèpalára fún un nípa tẹ̀mí. Nípa bẹ́ẹ̀, a ní láti kọ́ bá a ṣe lè mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹnì kan. Àmọ́, báwo la ṣe lè ṣe é?

Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Jésù

Ká sòótọ́, Jésù lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn. (Mátíù 12:25) Kò sẹ́ni tó lè ṣe bẹ́ẹ̀ nínú wa. Àmọ́, Jésù fi hàn wá pé àwa náà lè fọgbọ́n mọ àwọn ohun tẹ́nì kan nífẹ̀ẹ́ sí, àti ohun tó ń mú un ṣe àwọn ohun tó ń ṣe, títí kan àwọn ohun tó fi ṣáájú. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni dókítà tó mọṣẹ́ dunjú máa ń gbà yẹ ohun tó fa àrùn ọkàn tó ń ṣe ẹnì kan wò. Bákan náà, Jésù máa ń lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti fa ‘ìrònú àti ìpètepèrò ọkàn’ àwọn èèyàn “jáde,” àti láti fi í hàn. Ó máa ń ṣe èyí kódà báwọn ohun tí ń bẹ lọ́kàn àwọn èèyàn náà ò bá tiẹ̀ tíì hàn fáyé rí.—Òwe 20:5; Hébérù 4:12.

Bí àpẹẹrẹ, lákòókò kan, Jésù ran Pétérù lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ó ní kùdìẹ̀-kudiẹ kan, èyí tó wá kó o sí wàhálà nígbà tó yá. Jésù mọ̀ pé Pétérù fẹ́ràn òun. Kódà, Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ fún un ní “àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba ọ̀run” ni. (Mátíù 16:13-19) Síbẹ̀ Jésù mọ̀ pé Sátánì ń dọdẹ àwọn àpọ́sítélì. Tó bá ya, wọ́n á fojú winá àwọn nǹkan tó lè mú kí wọ́n bọ́hùn. Jésù sì mọ̀ pé ìgbàgbọ́ àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára. Nítorí náà, ó tètè sọ ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe fún wọn. Wo bó ṣe dá ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀.

Mátíù 16:21 sọ pé: “Láti ìgbà yẹn lọ, Jésù Kristi bẹ̀rẹ̀ sí fi han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òun gbọ́dọ̀ . . . jìyà . . . kí wọ́n sì pa òun.” Ṣàkíyèsí pé Jésù ò kàn sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí òun fún wọn, ńṣe ló fi hàn wọ́n. Bóyá ni ò fi ní jẹ́ pé àwọn ẹsẹ Bíbélì tó fi hàn pé Mèsáyà yóò jìyà yóò sì kú ni Jésù lò, ìyẹn àwọn ẹsẹ Bíbélì bíi Sáàmù 22:14-18 tàbí Aísáyà 53:10-12. Èyí ó wù kó jẹ́, Jésù ka Ìwé Mímọ́ tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ló fa ọ̀rọ̀ yọ ní tààràtà látinú rẹ̀ láti mú kí Pétérù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù sọ ohun tó wà lọ́kàn. Báwo ni wọ́n ṣe máa ṣe tí wọ́n bá gbọ́ pé inúnibíni ń bọ̀?

Ó yani lẹ́nu pé bí Pétérù ṣe máa ń fi hàn pé òun jẹ́ onígboyà àti onítara tó, ìwàǹwára ló fi dáhùn ìbéèrè tí Jésù bi wọ́n. Ìdáhùn Pétérù sì fi hàn pé ìrònú rẹ̀ kù díẹ̀ káàtó. Ó sọ pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; ìwọ kì yóò ní ìpín yìí rárá.” Ìrònú Pétérù ò dáa, nítorí Jésù sọ pé “kì í ṣe àwọn ìrònú Ọlọ́run ni [Pétérù] ń rò, bí kò ṣe ti ènìyàn.” Àléébù tí Pétérù sì ní yìí kì í ṣe kékeré, nítorí pé ó léwu. Kí wá ni Jésù ṣe? Lẹ́yìn tó bá Pétérù wí, ó sọ fún òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” Jésù sọ ohun tó wà nínú Sáàmù 49:8 àti Sáàmù 62:12 fún wọn láti fi rán wọn létí pé èèyàn ò lè fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun tí wọ́n ń retí, nítorí èèyàn kò lè gbani là. Ó fi yé wọn pé Ọlọ́run ló máa fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Mátíù 16:22-28.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù ba Pétérù fúngbà díẹ̀, tí èyí sì mú kó sẹ́ Jésù lẹ́ẹ̀mẹ́ta, ó dájú pé ọ̀rọ̀ tí Jésù bá wọn sọ yẹn mú kó tètè kọ́fẹ padà nípa tẹ̀mí. (Jòhánù 21:15-19) Ní àádọ́ta ọjọ́ péré lẹ́yìn náà, Pétérù fìgboyà dúró níwájú ọ̀pọ̀ èèyàn ní Jerúsálẹ́mù láti jẹ́rìí sí i pé lóòótọ́ ni Jésu jíǹde. Ní àwọn ọ̀sẹ̀, oṣù àti ọdún tó tẹ̀ lé e, Pétérù ní ìgboyà bí wọ́n ṣe ń fàṣẹ ọba mú un léraléra, tí wọ́n ń lù ú tí wọ́n sì ń fi í sẹ́wọ̀n. Nípa bẹ́ẹ̀, ó fàpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nípa béèyàn ṣe lè fìgboyà ṣe ìfẹ́ Jèhófà láìyẹsẹ̀.—Ìṣe 2:14-36; 4:18-21; 5:29-32, 40-42; 12:3-5.

Kí lèyí kọ́ wa? Ǹjẹ́ o rí ohun tí Jésù ṣe kó bàa lè mọ ohun tó wà lọ́kàn Pétérù? Ohun àkọ́kọ́ ni pé, ó lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá a mu láti mú kí Pétérù pọkàn pọ̀ sórí ohun tó fẹ́ kó ṣiṣẹ́ lé lórí. Lẹ́yìn náà, ó jẹ́ kí Pétérù sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Paríparí rẹ̀, ó túbọ̀ fi Ìwé Mímọ́ gba Pétérù nímọ̀ràn pé kó má máa ronú bó ṣe ń ronú yẹn, kó sì máa kíyè bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára rẹ̀. Ṣùgbọ́n o lè máa rò pé kò sí bó o ṣe lè kọ́ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ bíi ti Jésù. Àmọ́, jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ẹni méjì kan tá á fi hàn pé tá a bá múra sílẹ̀ tá a sì gbọ́kàn lé Jèhófà, a ó lè ṣe bíi ti Jésù.

Mú Kí Wọ́n Sọ Ohun Tó Wà Lọ́kàn Wọn

Àwọn ọmọkùnrin méjì kan tí ọ̀kan wà ní ọdún àkọ́kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, tí èkejì sì wà lọ́dún kejì, mú midinmíìdìn lórí tábìlì olùkọ́ wọn. Nígbà tí bàbá wọn gbọ́, ó pè wọ́n jókòó, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ lórí ohun tí wọ́n ṣe náà. Bàbá wọn ò kàn rò pé ohun tí wọ́n ṣe yẹn kò burú, pé ọmọdé lásán ló ń ṣe wọ́n. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Mo gbìyànjú láti mú kí wọ́n sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn tó mú kí wọ́n hùwàkiwà yẹn.”

Bàbá yìí ní káwọn ọmọ náà rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ákánì, tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà nínú ìwé Jóṣúà orí 7. Ojú ẹsẹ̀ lohun tí bàbá wọn ń sọ ti yé wọn, wọ́n sì jẹ́wọ́. Ẹ̀rí ọkàn wọn tiẹ̀ ti ń nà wọ́n ní pàṣán tẹ́lẹ̀. Nítorí náà, bàbá wọn ní kí wọ́n ka Éfésù 4:28, tó sọ pé: “Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, . . . kí ó lè ní nǹkan láti pín fún ẹni tí ó wà nínú àìní.” Bàbá àwọn ọmọ náà ní kí wọ́n ra midinmíìdìn mìíràn kí wọ́n sì dá a padà fún olùkọ́ náà. Èyí túbọ̀ tẹ ìbáwí tó fún wọn látinú Ìwé Mímọ́ mọ́ wọn lọ́kàn.

Bàbá náà sọ pé: “Gbàrà tá a bá ti kíyè sí i pé ohun tí kò dára wà lọ́kàn àwọn ọmọ wa la ti máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà ká lè gba ohun náà kúrò lọ́kàn wọn; a óò wá fi ohun tó dára rọ́pò àwọn ohun tí kò dára tá a gbà kúrò lọkàn wọn.” Nítorí pé àwọn òbí yìí máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tí wọ́n bá ń kọ́ àwọn ọmọ wọn, àwọn ọmọ náà di ọmọ rere. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn ọmọkùnrin méjèèjì dẹni tó ń sìn ní orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Brooklyn, ó sì ti lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n báyìí tí ọ̀kan nínú wọn ti wà níbẹ̀.

Tún wo bí Kristẹni kan ṣe ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ lọ́wọ́. Akẹ́kọ̀ọ́ náà máa ń lọ sípàdé ó sì máa ń lọ wàásù, kódà ó tiẹ̀ ti sọ pé òun fẹ́ láti ṣèrìbọmi. Àmọ́, ó dà bí ẹni pé ó ti gbára lé ara rẹ̀ jù dípò kó gbára lé Jèhófà. Ẹlẹ́rìí náà rántí pé “akẹ́kọ̀ọ́ yìí, tí kò tíì lọ́kọ, kò mọ̀ pé òun ń ya ara òun láṣo. Ẹ̀rù bà mí kí ohun tó ń ṣe yẹn má lọ dá àìsàn sí i lára tàbí kó ṣèpalára fún un nípa tẹ̀mí.”

Nítorí náà, Ẹlẹ́rìí yìí bá akẹ́kọ̀ọ́ náà fèrò wérò lórí ohun tó wà nínú Mátíù 6:33, ó sì gbà á níyànjú pé kó ronú lórí àwọn ohun tó fi ṣáájú kó sì ṣàtúnṣe. Ó ní kó fi wíwá Ìjọba Ọlọ́run ṣáájú kó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á ṣe ohun tó dára. Ẹlẹ́rìí náà bi í láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ pé: “Ǹjẹ́ bó o ṣe máa ń dá wà máa ń jẹ́ kó ṣòro fún ẹ nígbà míì láti gbára lé àwọn ẹlòmíràn, títí kan Jèhófà?” Akẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ́wọ́ pé òun tiẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dáwọ́ àdúrà gbígbà dúró. Akéde náà wá gbà á níyànjú pé kó fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Sáàmù 55:22 sílò pé kí ó kó àwọn ohun tó jẹ́ ẹrù ìnira rẹ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́ nítorí pé, 1 Pétérù 5:7 fi dá wa lójú pé, ‘Jèhófà bìkítà fún wa.’ Ọ̀rọ̀ yìí wọ akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́kàn. Ẹlẹ́rìí náà sọ pé: “Mi ò fi bẹ́ẹ̀ rí i kó sunkún rí, àmọ́ ó sunkún lọ́jọ́ tá a jọ sọ̀rọ̀ yìí.”

Jẹ́ Kí Òtítọ́ Máa Ṣiṣẹ́ Lára Rẹ

Inú wa máa ń dùn gan-an tá a bá rí i pé àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ń tẹ̀ lé òtítọ́ inú Bíbélì. Àmọ́ o, kí ìrànlọ́wọ́ tá à ń ṣe fáwọn ẹlòmíràn tó lè ṣiṣẹ́, a gbọ́dọ̀ fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀. (Júúdà 22, 23) Gbogbo wa la gbọ́dọ̀ “máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà [wa] yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.” (Fílípì 2:12) Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣèyẹn ni pé ká jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ máa tàn sínú ọkàn wa, ká lè ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí àti bá a ṣe ń ronú, ká sì tún ṣàyẹ̀wò bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára wa, ká sì ṣàtúnṣe tó bá yẹ.—2 Pétérù 1:19.

Bí àpẹẹrẹ, ṣé kì í ṣe pé ìtara tó o ní tó o fi ń lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí ti dín kù lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló fà á? Ó lè jẹ́ nítorí pé o ti ń gbójú lé ara rẹ̀ jù. Báwo lo ṣe lè mọ̀ pé ohun tó fà á nìyẹn? Ka Hágáì 1:2-11, kó o sì ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí Jèhófà sọ fáwọn Júù tó padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn láti ìgbèkùn. Lẹ́yìn náà, bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ mi ò ti ń ṣàníyàn jù nípa bùkátà mi àti bí mo ṣe lè gbé ìgbésí ayé tó ṣe gbẹdẹmukẹ? Ǹjẹ́ mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé yóò pèsè fún ìdílé mi tí mo bá fi ohun tẹ̀mí ṣáájú? Àbí ńṣe ni mo máa ń rò pé tara mi ló yẹ kí n kọ́kọ́ gbọ́?’ Tó o bá rí i pé ó yẹ kó o ṣàtúnṣe sí ọ̀nà tó ò ń gbà ronú àti bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára rẹ, tètè ṣe é. Ìmọ̀ràn tó wà nínú Ìwé Mímọ́, irú èyí tá a rí nínú Mátíù 6:25-33; Lúùkù 12:13-21 àti 1 Tímótì 6:6-12, yóò jẹ́ kó o mọ irú èrò tó yẹ kó o ní nípa àwọn ohun ìní. Irú èrò tó tọ́ bẹ́ẹ̀ ni yóò mú kí Jèhófà máa bù kún èèyàn.—Málákì 3:10.

Kéèyàn dìídì yẹ ara rẹ̀ wò báyẹn gba ìrònújinlẹ̀ o. Ó lè máà bá èèyàn lára mu tí wọ́n bá sọ fún un pé ó ní àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan nípa tẹ̀mí. Àmọ́, tó o bá fi ìfẹ́ ran ọmọ rẹ àtẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́, tó o sì tún ran ara rẹ lọ́wọ́, ó lè jẹ́ ìyẹn ló máa mú kó o gba ẹ̀mí rẹ̀ tàbí ti ìwọ alára là. Ó sì yẹ kó o ṣe èyí yálà ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ tàbí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tó gba ọgbọ́n.—Gálátíà 6:1.

Àmọ́, bó o ṣe ń gbìyànjú tó, tó bá jẹ́ pé nǹkan ọ̀hún kò yí padà ńkọ́? Máà jẹ́ kó sú ọ. Ó gba ọgbọ́n láti ran èèyàn lọ́wọ́ kó lè ṣàtúnṣe sí ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, ó máa ń gba àkókò, ó sì lè súni nígbà míì. Ṣùgbọ́n èrè wà níbẹ̀.

Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, orí ọmọkùnrin tó ń jẹ́ Eric tá a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí wálé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í “rìn nínú òtítọ́” padà. (2 Jòhánù 4) Ó sọ pé: “Àfìgbà tí mo mọ̀ pé mo ti sọ nù kí n tó padà sọ́dọ̀ Jèhófà.” Nítorí pé àwọn òbí Eric ràn án lọ́wọ́, ó ti ń fi òtítọ́ sin Ọlọ́run báyìí. Nígbà táwọn òbí rẹ̀ kọ́kọ́ ń gbìyànjú léraléra láti ràn án lọ́wọ́ kó lè yẹ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ wò, ńṣe ló máa ń bínú. Àmọ́ ní báyìí, ó ti wá mọrírì ohun tí wọ́n ṣe nígbà yẹn. Ó sọ pé: “Òbí tó yááyì làwọn òbí mi. Wọn ò yéé nífẹ̀ẹ́ mi.”

Tá a bá ń tan ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí ọkàn àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, à ń fi ojúlówó inú rere hàn sí wọn nìyẹn. (Sáàmù 141:5) Máa yẹ ọkàn àwọn ọmọ rẹ àti ọkàn àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wò kó o lè mọ̀ bóyá àwọn ìwà tó yẹ kí Kristẹni máa hù wà lọ́kàn wọn tàbí kò sí. Jẹ́ kí òtítọ́ máa ṣiṣẹ́ lọ́kàn àwọn ẹlòmíràn àti lọ́kàn ìwọ fúnra rẹ nípa fífi “ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.”—2 Tímótì 2:15.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fi àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan tí Pétérù ní hàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Máa lo Bíbélì láti fi mú káwọn èèyàn sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn