Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Wọ́n Rí Péálì Olówó Iyebíye’

‘Wọ́n Rí Péálì Olówó Iyebíye’

‘Wọ́n Rí Péálì Olówó Iyebíye’

“Ìjọba ọ̀run ni góńgó tí àwọn ènìyàn ń fi ìsapá lépa, àwọn tí ń fi ìsapá tẹ̀ síwájú sì ń gbá a mú.”—MÁTÍÙ 11:12.

1, 2. (a) Ohun tó ṣọ̀wọ́n wo ni Jésù mẹ́nu kàn nínú ọ̀kan lára àwọn àkàwé tó fi ṣàlàyé Ìjọba ọ̀run? (b) Kí ni Jésù sọ nínú àkàwé péálì olówó iyebíye?

 ǸJẸ́ ohun kan wà tó ṣeyebíye gan-an lójú rẹ débi pé o lè yááfì gbogbo ohun tó o ní kí nǹkan ọ̀hún ṣáà lè tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn máa ń sọ pé kò sóhun táwọn ò lè ṣe kí ọwọ́ àwọn lè tẹ nǹkan táwọn ń wá, ìyẹn nǹkan bí owó, òkìkí, agbára, tàbí ipò. Síbẹ̀ ó ṣọ̀wọ́n pé kí ẹnì kan rí ohun kan tó ṣeyebíye gan-an tá á fi wá yááfì gbogbo ohun tó ní kí nǹkan ọ̀hún lè tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. Jésù Kristi tọ́ka sí nǹkan àrà ọ̀tọ̀ tọ́kùnrin kan ṣe nínú ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ àkàwé amúnironújinlẹ̀ tó fi ṣàlàyé Ìjọba Ọlọ́run.

2 Àkàwé tàbí àpèjúwe náà ni èyí tí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà táwọn èèyàn mìíràn ò sí lọ́dọ̀ wọn. Òun sì làwọn kan máa ń pè ní àkàwé péálì olówó iyebíye. Ohun tí Jésù sọ rèé, ó ní: “Ìjọba ọ̀run tún dà bí olówò arìnrìn-àjò kan tí ń wá àwọn péálì àtàtà. Nígbà tí ó rí péálì kan tí ìníyelórí rẹ̀ ga, ó jáde lọ, ó sì ta gbogbo ohun tí ó ní ní kánmọ́kánmọ́, ó sì rà á.” (Mátíù 13:36, 45, 46) Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù fẹ́ káwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ kọ́ látinú àkàwé yìí? Báwo la sì ṣe lè jàǹfààní látinú àwọn ọ̀rọ̀ Jésù?

Bí Péálì Ṣe Níye Lórí Tó

3. Kí nìdí tí péálì àtàtà fi níye lórí gan-an láyé ìgbàanì?

3 Àtayébáyé ni péálì ti jẹ́ nǹkan ọ̀ṣọ́ tó níye lórí gan-an. Òǹkọ̀wé kan sọ ohun tí ọ̀mọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Róòmù nì, Pliny Àgbà, wí pé, péálì “ló níye lórí jù lọ nínú gbogbo àwọn nǹkan olówó iyebíye.” Ara àwọn ohun alààyè la ti ń rí péálì, kò dà bíi wúrà, fàdákà, tàbí àwọn òkúta iyebíye mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìṣáwùrú kan wà tí wọ́n máa ń pa àwọn ìdọ̀tí bíi yanrìn tó bá kó sínú wọn dà di péálì iyebíye. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é ni pé wọ́n á fi èròjà kan tó wà nínú ìkarawun wọn bo yanrìn náà. Bí èròjà yìí bá ṣe ń bo ara yanrìn náà sí i, bẹ́ẹ̀ ni yanrìn náà yóò máa dán sí i títí tí yóò fi di péálì iyebíye. Láyé ọjọ́un, inú Òkun Pupa, ibi tí òkun ti ya wọ ilẹ̀ Páṣíà, àti inú Òkun Íńdíà, tó jìnnà gan-an sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì làwọn èèyàn ti máa ń rí péálì tó dára jù lọ kó. Ó dájú pé ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ̀rọ̀ nípa “olówò arìnrìn-àjò kan tí ń wá àwọn péálì àtàtà.” Èèyàn ní láti sapá gan-an kó tó lè rí ojúlówó péálì tó ṣeyebíye.

4. Kí ni olórí ẹ̀kọ́ tó wà nínú àkàwé Jésù nípa oníṣòwò arìnrìn-àjò?

4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pẹ́ táwọn péálì àtàtà ti lówó lórí gan-an, síbẹ̀ ó dájú pé kì í ṣe bó ṣe lówó lórí ni olórí ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ àwọn èèyàn nínú àpèjúwe yẹn. Kì í ṣe pé Jésù wulẹ̀ ń fi Ìjọba Ọlọ́run wé péálì olówó iyebíye lásán nínú àkàwé yìí. Ọ̀rọ̀ nípa “olówò arìnrìn-àjò kan tí ń wá àwọn péálì àtàtà” ló ń sọ. Ó tún sọ nípa ohun tí oníṣòwò náà ṣe lẹ́yìn tó rí péálì kan. Oníṣòwò arìnrìn-àjò tó ń ta péálì kò dà bí àwọn oníṣòwò tó máa ń jókòó sílé ìtajà. Ọ̀jọ̀gbọ́n ló jẹ́ nínú iṣẹ́ náà, ó dá péálì mọ̀ dáadáa, ó sì mọ gbogbo bó ṣe yẹ kí péálì kan rí ká tó lè sọ pé péálì àtàtà ni. Ó mọ èyí tó jẹ́ ojúlówó gan-an nígbà tó bá rí i débi pé kò sẹ́ni tó lè fi èyí tí kò dára tó tàbí èyí tó jẹ́ ayédèrú tàn án jẹ.

5, 6. (a) Kí ni ohun tó mú kí ọ̀rọ̀ oníṣòwò inú àkàwé Jésù yìí ṣàrà ọ̀tọ̀? (b) Kí ni ohun tí àkàwé ìṣúra tí wọ́n fi pa mọ́ jẹ́ ká mọ̀ nípa oníṣòwò arìnrìn-àjò tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí?

5 Nǹkan mìíràn wà tó yẹ kéèyàn tún kíyè sí nípa oníṣòwò tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Oníṣòwò kan á fẹ́ kọ́kọ́ mọ iye tí wọ́n ń ta péálì lọ́jà kó lè mọ iye tóun máa rà á àti iye tóun máa fi pa, kó lè jèrè púpọ̀. Ó tún lè fẹ́ mọ̀ bóyá irú péálì táwọn èèyàn máa ń fẹ́ ra lọ́jà ni kó bàa lè tètè rí i tà kó sì rí èrè tirẹ̀ níbẹ̀. Lọ́rọ̀ kan, kì í ṣe bí péálì ṣe máa tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ nìkan ló máa ká a lára bí kò ṣe bóun á ṣe tètè rí péálì náà tà, tóun á sì jèrè lórí rẹ̀. Àmọ́ ọ̀rọ̀ oníṣòwò inú àkàwé Jésù ò rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ owó tàbí èrè gọbọi kọ́ ló jẹ ẹ́ lógún. Kódà, ó múra tán láti yááfì “gbogbo ohun tí ó ní,” ìyẹn gbogbo ohun ìní àti dúkìá rẹ̀ kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ ohun tó ti ń wá kiri tipẹ́ yìí.

6 Òmùgọ̀ ni oníṣòwò inú àpèjúwe Jésù yìí máa jẹ́ lójú ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn oníṣòwò. Oníṣòwò kan tó jẹ́ ọlọgbọ́n kò ní ronú lọ sórí ṣíṣe òwò tí kò mọ ibi tó máa já sí. Àmọ́, ohun tó jẹ oníṣòwò inú àkàwé Jésù lógún yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Èrè tó máa rí kì í ṣe ọ̀rọ̀ owó rárá bí kò ṣe ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn téèyàn máa ń ní nígbà tọ́wọ́ ẹni bá tẹ ohun kan tó ṣeyebíye gan-an. Àpèjúwe mìíràn tí Jésù sọ ló wá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ṣe kedere gan-an. Ó ní: “Ìjọba ọ̀run dà bí ìṣúra tí a fi pa mọ́ sínú pápá, èyí tí ọkùnrin kan rí, tí ó sì fi pa mọ́; àti nítorí ìdùnnú tí ó ní, ó lọ, ó sì ta àwọn ohun tí ó ní, ó sì ra pápá yẹn.” (Mátíù 13:44) Láìsí àní-àní, ayọ̀ téèyàn máa ń ní nígbà tó bá rí ìṣúra kan tí ìṣúra náà sì tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ ló mú kí ọkùnrin yìí lọ ta gbogbo ohun tó ní. Ǹjẹ́ a ráwọn èèyàn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí? Ǹjẹ́ a rí ìṣúra tó lè mú kéèyàn ta gbogbo ohun tó ní?

Àwọn Tó Mọyì Bí Ìjọba Náà Ti Ṣe Pàtàkì Tó

7. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun mọyì bí Ìjọba náà ti ṣe pàtàkì tó?

7 Ọ̀rọ̀ nípa “Ìjọba ọ̀run” ni Jésù ń sọ nínú àpèjúwe rẹ̀ yẹn. Ó dájú pé òun fúnra rẹ̀ mọ bí Ìjọba náà ti ṣe pàtàkì tó. Àwọn ìwé Ìhìn Rere sì jẹ́rìí tí kò ṣeé já ní koro sí òtítọ́ yìí. Lẹ́yìn tí  Jésù ṣèrìbọmi tán ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa, ó “bẹ̀rẹ̀ wíwàásù, ó sì ń wí pé: ‘Ẹ ronú pìwà dà, nítorí ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’” Odindi ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ ló fi ń fi ọ̀rọ̀ Ìjọba náà kọ́ àìmọye èèyàn. Kò síbi tí kò dé ní gbogbo orílẹ̀-èdè náà, ó ń “lọ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá àti láti abúlé dé abúlé, ó ń wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.”—Mátíù 4:17; Lúùkù 8:1.

8. Kí ni Jésù ṣe láti jẹ́ ká mọ ohun tí Ìjọba náà yóò ṣe?

8 Onírúurú iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jákèjádò orílẹ̀-èdè náà tún jẹ́ ká mọ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe. Ó mú àwọn aláìsàn lára dá, ó bọ́ àwọn tí ebi ń pa. Kódà, ó dáwọ́ ìjì dúró, ó tún jí òkú dìde pàápàá. (Mátíù 14:14-21; Máàkù 4:37-39; Lúùkù 7:11-17) Níkẹyìn, ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀, ó sì kú bí ajẹ́rìíkú lórí òpó igi oró, èyí ló fi ẹ̀rí hàn pé ó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run àti pé kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀ràn Ìjọba náà. Ohun tí oníṣòwò arìnrìn-àjò yẹn ṣe gẹ́lẹ́ ni Jésù ṣe. Oníṣòwò náà fínnúfíndọ̀ ta gbogbo ohun tó ní nítorí “péálì kan tí ìníyelórí rẹ̀ ga,” bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù ṣe nípa wíwá tó wá sí ayé, tó sì kú nítorí Ìjọba náà.—Jòhánù 18:37.

9. Ìtara tó ṣọ̀wọ́n wo ni àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi hàn?

9 Kì í ṣe pé Jésù fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ gbọ́ ti Ìjọba náà nìkan, àmọ́ ó tún kó àwọn ọmọ ẹ̀yìn bíi mélòó kan jọ. Àwọn tó kó jọ náà mọyì bí Ìjọba náà ti ṣe pàtàkì tó. Lára wọn ni Áńdérù, tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù Olùbatisí tẹ́lẹ̀. Gbàrà tí Jòhánù sọ pé Jésù ni “ọ̀dọ́ àgùntàn Ọlọ́run” ni Áńdérù àti ẹlòmíràn tóun náà jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jòhánù tẹ̀ lé Jésù, wọ́n sì di onígbàgbọ́. Ó ṣeé ṣe kí ẹnì kejì yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Sébédè. Jòhánù sì ni orúkọ tirẹ̀ náà. Àmọ́ ọ̀ràn náà ò tán síbẹ̀ ò. Ojú ẹsẹ̀ ni Áńdérù lọ sọ́dọ̀ Símónì arákùnrin rẹ̀ tó sì sọ fún un pé: “Àwa ti rí Mèsáyà náà.” Kò pẹ́ rárá sí àkókò yẹn tí Símónì (tá a wá mọ̀ sí Kéfà, tàbí Pétérù) títí kan Fílípì àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Nàtáníẹ́lì fi mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà. Kódà, Nàtáníẹ́lì ò mọ̀gbà tóun sọ fún Jésù pé: “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run, ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì.”—Jòhánù 1:35-49.

Ó Ta Wọ́n Jí

10. Kí làwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe nígbà tí Jésù wá pè wọ́n ní oṣù bíi mélòó kan lẹ́yìn ìgbà àkọ́kọ́ tó bá wọn pàdé?

10 Ìtara Áńdérù, Pétérù, Jòhánù, àtàwọn yòókù nígbà tí wọ́n rí Mèsáyà la lè fí wé ìtara oníṣòwò arìnrìn-àjò yẹn nígbà tó rí péálì olówó iyebíye. Kí ní wọ́n máa ṣe báyìí? Àwọn ìwé Ìhìn Rere ò sọ ohun tí wọ́n ṣe lẹ́yìn ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n bá Jésù pàdé. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni èyí tó pọ̀ jù lára wọn padà sẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn. Àmọ́, ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà sí ọdún kan lẹ́yìn ìyẹn, Jésù tún rí Áńdérù, Pétérù, Jòhánù, àti Jákọ́bù tó jẹ́ arákùnrin Jòhánù níbi iṣẹ́ apẹja tí wọ́n ń ṣe ní etí Òkun Gálílì. a Nígbà tí Jésù rí wọn, ó ní: “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn, ṣe ni èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” Kí ni wọ́n wá ṣe? Ohun tí àkọsílẹ̀ Mátíù sọ nípa Pétérù àti Áńdérù ni pé: “Kíá, ní pípa àwọn àwọ̀n náà tì, wọ́n tẹ̀ lé e.” Ohun tá a kà nípa Jákọ́bù àti Jòhánù ni pé: “Kíá, ní fífi ọkọ̀ ojú omi náà àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n tẹ̀ lé e.” Àkọsílẹ̀ Lúùkù fi kún un pé wọ́n “pa ohun gbogbo tì, wọ́n sì tẹ̀ lé e.”—Mátíù 4:18-22; Lúùkù 5:1-11.

11. Kí lo lè jẹ́ ìdí táwọn ọmọ ẹ̀yìn náà fi tẹ̀ lé Jésù ní kíákíá?

11 Ṣé àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà kàn ṣàdédé tẹ̀ lé Jésù ni? Rárá o! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n padà sídìí iṣẹ́ apẹja wọn lẹ́yìn ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n bá Jésù pàdé, síbẹ̀ kò sí iyèméjì pé ohun tí wọ́n rí àti ohun tí wọ́n gbọ́ nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n bá Jésù pàdé yẹn wọ̀ wọ́n lọ́kàn ṣinṣin. Nǹkan bí ọdún kan tó ti kọjá lẹ́yìn ìyẹn ti jẹ́ kí wọ́n ní àkókò tó pọ̀ tó láti ronú lórí ohun tí wọ́n gbọ́. Àkókò ti wá tó láti pinnu báyìí. Ṣé wọ́n á tẹ̀ lé àkàwé Jésù yẹn, kí wọ́n ṣe bí oníṣòwò arìnrìn-àjò tínú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tó rí péálì olówó iyebíye débi pé “ó jáde lọ . . . ní kánmọ́kánmọ́,” tó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ra péálì náà? Bẹ́ẹ̀ ni o. Ohun tí wọ́n ti gbọ́ àtèyí tí wọ́n rí wú wọn lórí gan-an. Wọ́n rí i pé àkókò tí wọ́n ní láti jí gìrì ti dé. Nípa bẹ́ẹ̀, wọn ò lọ́ tìkọ̀ rárá. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ náà ti sọ, wọ́n fi gbogbo ohun tí wọ́n ní sílẹ̀, wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn Jésù.

12, 13. (a) Kí ni ohun tí ọ̀pọ̀ lára àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù ṣe? (b) Kí ni Jésù sọ nípa àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kí sì làwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ túmọ̀ sí?

12 Àwọn olóòótọ́ wọ̀nyí má yàtọ̀ o, wọn ò dà bí àwọn mìíràn tí àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere mẹ́nu kàn níkẹyìn! Ọ̀pọ̀ èèyàn ni Jésù mú lára dá tàbí tó bọ́ ní àbọ́yó, àmọ́ tí wọn ò tẹ̀ lé e. (Lúùkù 17:17, 18; Jòhánù 6:26) Àwáwí làwọn kan tiẹ̀ ń ṣe nígbà tí Jésù pè wọ́n pé kí wọ́n wá di ọmọlẹ́yìn òun. (Lúùkù 9:59-62) Àwọn olóòótọ́ èèyàn yìí ò ṣe bíi tàwọn yẹn rárá. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn olóòótọ́ yẹn lẹ́yìn àkókò náà, ó ní: “Láti àwọn ọjọ́ Jòhánù Oníbatisí títí di ìsinsìnyí, ìjọba ọ̀run ni góńgó tí àwọn ènìyàn ń fi ìsapá lépa, àwọn tí ń fi ìsapá tẹ̀ síwájú sì ń gbá a mú.”—Mátíù 11:12.

13 Kí ni gbólóhùn náà “fi ìsapá lépa” àti “ń fi ìsapá tẹ̀ síwájú” túmọ̀ sí? Ohun tí ìwé atúmọ̀ èdè Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words sọ nípa ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Gíríìkì tá a ti mú gbólóhùn wọ̀nyẹn jáde ni pé: “Ọ̀rọ̀ ìṣe náà túmọ̀ sí pé kéèyàn fi gbogbo agbára sakun.” Ọ̀mọ̀wé Heinrich Meyer tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ sọ nípa ẹsẹ yìí pé: “Ọ̀rọ̀ ìṣe náà ṣàpèjúwe ìtara àti ìsapá téèyàn á fi gbárùkù ti ìjọba Mèsáyà tó ti sún mọ́lé . . . Ìfẹ́ téèyàn ní sí ìjọba náà wá ga gan-an (kì í ṣe kéèyàn máa fi sùúrù retí rẹ̀.)” Bíi ti oníṣòwò arìnrìn-àjò yẹn, àwọn èèyàn wọ̀nyí tètè mọ ohun tó níye lórí, wọ́n sì yááfì gbogbo ohun tí wọ́n ní tinútinú nítorí Ìjọba náà.—Mátíù 19:27, 28; Fílípì 3:8.

Àwọn Mìíràn Dara Pọ̀ Mọ́ Wọn

14. Báwo ni Jésù ṣe múra àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

14 Bí Jésù ṣe ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lọ, ó kọ́ àwọn ẹlòmíràn bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ náà ó sì tún ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ọmọ abẹ́ Ìjọba náà. Ó kọ́kọ́ yan méjìlá lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì pè wọ́n ní àpọ́sítélì, tàbí àwọn tí a rán jáde. Àwọn wọ̀nyẹn ni Jésù fún ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí wọ́n máa gbà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Ó tún sọ fún wọn nípa àwọn ìṣòro tí wọ́n máa ní àti ìyà tó máa jẹ wọ́n lọ́jọ́ iwájú. (Mátíù 10:1-42; Lúùkù 6:12-16) Nǹkan bí ọdún méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n fi ń tẹ̀ lé Jésù kiri bó ṣe ń wàásù jákèjádò orílẹ̀-èdè náà, wọ́n sì mọwọ́ ara wọn gan-an. Wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀, wọ́n rí àwọn iṣẹ́ àrà tó ṣe, wọ́n sì rí àpẹẹrẹ tí òun fúnra rẹ̀ fi lélẹ̀. (Mátíù 13:16, 17) Gbogbo èyí wú wọn lórí gan-an débi pé àwọn náà ṣe bíi ti oníṣòwò arìnrìn-àjò yẹn. Wọ́n nítara, wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn wá Ìjọba náà.

15. Kí ni Jésù sọ pé ó jẹ́ olórí ìdí tó fi yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa yọ̀?

15 Yàtọ̀ sí àwọn àpọ́sítélì méjìlá, Jésù tún “yan àwọn àádọ́rin mìíràn sọ́tọ̀, ó sì rán wọn jáde ní méjìméjì ṣáájú rẹ̀ sínú gbogbo ìlú ńlá àti ibi tí òun fúnra rẹ̀ yóò dé.” Ó tún sọ nípa àdánwò àti ìṣòro tí wọ́n máa rí lọ́jọ́ iwájú fún wọn, ó sì ní kí wọ́n máa sọ fún àwọn èèyàn pé: “Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́ tòsí yín.” (Lúùkù 10:1-12) Nígbà táwọn àádọ́rin náà padà dé, inú wọn dùn jọjọ, wọ́n sì ròyìn fún Jésù pé: “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá ni a mú tẹrí ba fún wa nípasẹ̀ lílo orúkọ rẹ.” Àmọ́, Jésù wá mẹ́nu kan ohun mìíràn tó ní láti jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wọn. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ayọ̀ tó ju ìyẹn lọ wà níwájú fún wọn nítorí ìtara tí wọ́n ní fún Ìjọba náà. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe yọ̀ lórí èyí, pé a mú àwọn ẹ̀mí tẹrí ba fún yín, ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ nítorí pé a ti ṣàkọọ́lẹ̀ orúkọ yín ní ọ̀run.”—Lúùkù 10:17, 20.

16, 17. (a) Kí ni Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ ní alẹ́ tó wà lọ́dọ̀ wọn kẹ́yìn? (b) Ayọ̀ àti ìdánilójú wo ni ọ̀rọ̀ Jésù fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀?

16 Ní alẹ́ tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jọ wà pa pọ̀ kẹ́yìn, ìyẹn ní Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ó dá ayẹyẹ kan tá a wá mọ̀ sí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀, ó sì pa á láṣẹ pé kí wọ́n máa ṣe ayẹyẹ náà. Ní alẹ́ yẹn, Jésù sọ fún àwọn mọ́kànlá tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni ẹ ti dúró tì mí gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò mi; èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan, kí ẹ lè máa jẹ, kí ẹ sì máa mu nídìí tábìlì mi nínú ìjọba mi, kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́ láti ṣèdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.”—Lúùkù 22:19, 20, 28-30.

17 Ẹ ò rí i pé inú àwọn àpọ́sítélì yẹn á dùn gan-an, ọkàn wọn á sì balẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn lẹ́nu Jésù! Jésù ti fi wọ́n sí ipò tó ga jù lọ, ó sì tún fún wọn ní àǹfààní tí èèyàn mìíràn ò ní. (Mátíù 7:13, 14; 1 Pétérù 2:9) Bíi ti oníṣòwò arìnrìn-àjò yẹn, àwọn náà ti yááfì ohun púpọ̀ gan-an kí wọ́n lè tẹ̀ lé Jésù láti wá Ìjọba náà. Ó ti wá dá wọn lójú báyìí pé gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe nítorí Ìjọba náà kò já sásán.

18. Yàtọ̀ sí àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá, àwọn mìíràn wo ló tún máa jàǹfààní nínú Ìjọba náà níkẹyìn?

18 Kì í ṣe àwọn àpọ́sítélì tó wà lọ́dọ̀ Jésù lálẹ́ ọjọ́ yẹn nìkan ló máa jàǹfààní látinú Ìjọba náà. Ìfẹ́ Jèhófà ni pé kí àwọn tó para pọ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì wà nínú májẹ̀mú Ìjọba náà kí wọ́n sì bá Jésù Kristi ṣàkóso nínú Ìjọba ológo ti ọ̀run. Yàtọ̀ sí àwọn yẹn, àpọ́sítélì Jòhánù tún rí “ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, . . . wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Wọ́n ń sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.” Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ abẹ́ Ìjọba náà lórí ilẹ̀ ayé. bÌṣípayá 7:9, 10; 14:1, 4.

19, 20. (a) Àǹfààní wo làwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè ní? (b) Ìbéèrè wo la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

19 Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù gòkè re ọ̀run, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́. Sì wò ó! Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 28:19, 20) Nítorí náà, àtinú gbogbo orílẹ̀-èdè làwọn èèyàn ti máa wá, tí wọ́n á sì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú yóò pọkàn pọ̀ sórí Ìjọba náà bí oníṣòwò arìnrìn-àjò yẹn ṣe pọkàn pọ̀ sórí péálì àtàtà tó rí. Wọ́n ń retí àtigba èrè ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé.

20 Ọ̀rọ̀ Jésù yẹn fi hàn pé iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn yóò máa bá a lọ láti ìgbà yẹn títí di “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Lákòókò tá a wà yìí, ǹjẹ́ a ṣì rí àwọn kan tó dà bí oníṣòwò arìnrìn-àjò yẹn, tí wọ́n múra tán láti yááfì gbogbo ohun tí wọ́n ní, kí wọ́n lè máa lépa Ìjọba Ọlọ́run? Ìbéèrè yìí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó ní láti jẹ́ pé Jòhánù ọmọ Sébédè tẹ̀ lé Jésù tó sì fojú ara rẹ̀ rí gbogbo ohun tó ṣe lẹ́yìn ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n jọ pàdé. Ìdí nìyẹn tó fi lè kọ gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ kínníkínní nínú ìwé Ìhìn Rere tó kọ. (Jòhánù, orí 2 sí 5) Síbẹ̀, ó padà sídìí iṣẹ́ apẹja rẹ̀ fúngbà díẹ̀ kó tó di pé Jésù wá pè é lẹ́ẹ̀kejì.

b Láti rí ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyé, wo orí kẹwàá ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣe ìwé náà jáde.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Kí ni olórí ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni nínú àpèjúwe oníṣòwò arìnrìn-àjò?

• Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun mọyì bí Ìjọba náà ti ṣe pàtàkì tó?

• Kí ló mú kí Áńdérù, Pétérù, Jòhánù, àtàwọn yòókù tẹ̀ lé Jésù kíá nígbà tó pè wọ́n?

• Àǹfààní ńláǹlà wo ló wà fún àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

‘Wọ́n fi gbogbo ohun tí wọ́n ní sílẹ̀, wọ́n sì tẹ̀ lé Jésù’

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, ó pà á láṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn