Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Tó O Ti Fojú Ara Rẹ Rí!

Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Tó O Ti Fojú Ara Rẹ Rí!

Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Tó O Ti Fojú Ara Rẹ Rí!

Ọ̀RỌ̀ náà “iṣẹ́ ìyanu” tún lè túmọ̀ sí “ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí àṣeyọrí kan tó kàmàmà tàbí ohun kan tó jọni lójú gan-an.” Gbogbo wa la ti rí irú iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ rí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò ti ọwọ́ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ wá.

Bí ẹ̀dá èèyàn ṣe túbọ̀ ń lóye àwọn òfin tó ń darí àwọn ohun tá a lè fojú rí, wọ́n ti ṣe àwọn nǹkan tó jẹ́ pé àwọn èèyàn ò lérò pé ó ṣeé ṣe láyé ìgbà kan. Bí àpẹẹrẹ, ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, bóyá lọ̀pọ̀ èèyàn lè gbà pé àwọn ohun tí à ń rí lóde òní lè ṣeé ṣe. Ìyẹn àwọn ohun tí kọ̀ǹpútà, tẹlifíṣọ̀n, ìmọ̀-ẹ̀rọ ojú sánmà, àtàwọn nǹkan ìgbàlódé mìíràn ń gbé ṣe.

Bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń rí i pé òye àwọn ò tíì kún tó nípa àgbàyanu ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí Ọlọ́run fi dá gbogbo àwọn ohun tó dá, àwọn kan nínú wọn ti sọ pé àwọn ò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé nǹkan kan ò ṣeé ṣe mọ́. Ohun tí wọ́n kàn ń sọ báyìí ni pé kò dájú. Nítorí náà, wọ́n gbà pé àwọn ohun tó dà bí iṣẹ́ ìyanu tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kò lè ṣe nísinsìnyí ṣì lè wá ṣeé ṣe lọ́jọ́ iwájú.

Ká tiẹ̀ ní ìtumọ̀ tó kọ́kọ́ máa ń wá sí wa lọ́kàn tá a bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “iṣẹ́ ìyanu” la fẹ́ tẹ̀ lé, ìyẹn àwọn ohun tá a gbà pé “Ọlọ́run Olódùmarè nìkan ló lè ṣe wọ́n,” a ṣì lè sọ pé gbogbo wa la ti rí iṣẹ́ ìyanu rí. Bí àpẹẹrẹ, à ń rí oòrùn, òṣùpá, àtàwọn ìràwọ̀, tí gbogbo wọn jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ “Ọlọ́run Olódùmarè,” ìyẹn Ẹlẹ́dàá fúnra rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ta ló lè ṣe ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyé nípa bí ara èèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́? bí ọpọlọ ṣe ń ṣiṣẹ́? tàbí bí ọmọ ṣe ń dàgbà nínú aboyún? Ìwé tó ń jẹ́ The Body Machine (Bí Ara Ẹ̀dá Èèyàn Ṣe Ń Ṣiṣẹ́) sọ pé: “Ọpọlọ ń bá iṣan ara ṣiṣẹ́ láti darí ètò ara. Irinṣẹ́ tó díjú gidigidi ni ara èèyàn jẹ́, ó ń jẹ́ ká mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ńṣe ló sì dà bí ẹ̀rọ tó ń fúnra rẹ̀ ṣiṣẹ́ láìsí pé ẹnì kankan ń darí rẹ̀, ọpọlọ èèyàn sì máa ń fúnra rẹ̀ sọ ara rẹ̀ dọ̀tun. Ohun àgbàyanu ni ara ẹ̀dá èèyàn, ó díjú kọjá ohun tá a lè ṣàlàyé rẹ̀.” Ká sòótọ́, iṣẹ́ ìyanu ńlá ni Ọlọ́run tó ṣètò ‘ẹ̀yà ara èèyàn’ ṣe, kò sì yéé jọ wá lójú. Àwọn nǹkan mìíràn tún wà tó jẹ́ iṣẹ́ ìyanu tó o ti fojú ara rẹ rí àmọ́ tó o lè má mọ̀ pé iṣẹ́ ìyanu ni wọ́n.

Ǹjẹ́ A Lè Sọ Pé Ìwé Kan Jẹ́ Iṣẹ́ Ìyanu?

Bíbélì ni ìwé táwọn èèyàn ní lọ́wọ́ jù lọ. Ǹjẹ́ o gbà pé iṣẹ́ ìyanu ni Bíbélì? Ǹjẹ́ a lè sọ pé àtọ̀dọ̀ “Ọlọ́run Olódùmarè” ló ti wá? Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn ló kọ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀, àmọ́ àwọn tó kọ ọ́ sọ pé èrò Ọlọ́run làwọ́n kọ, kì í ṣe èrò tara àwọn. (2 Sámúẹ́lì 23:1, 2; 2 Pétérù 1:20, 21) Gbé kókó yìí yẹ̀ wò ná. Nǹkan bí ogójì èèyàn ló kọ Bíbélì, àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n gbé láyé, àpapọ̀ àkókò náà sì lé ní ẹgbẹ̀jọ [1,600] ọdún. Onírúurú èèyàn ni wọ́n. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wà lára wọn, àwọn ológun, àwọn àpẹja, àwọn òṣìṣẹ́ ọba, àwọn dókítà, àwọn àlùfáà, àtàwọn ọba. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ wọn kò takora rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tí wọ́n kọ fúnni ní ìrètí, òtítọ́ pọ́nbélé ni, ó sì pé pérépéré.

Lẹ́yìn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa, wọ́n fara mọ́ ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, wọn ò gbà á “gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (1 Tẹsalóníkà 2:13) Àwọn ìwé wọn tí wọ́n ti ń tẹ̀ jáde láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ti ṣàlàyé bí àwọn ohun kan táwọn èèyàn kan kà sí ìtakora nínú Bíbélì ṣe bá kókó tí Bíbélì dá lé lórí mu. Bí Bíbélì ṣe bára mu látòkèdélẹ̀ yìí fi hàn pé àtọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá lóòótọ́. a

Kò sí ìwé mìíràn táwọn èèyàn ti gbìyànjú lójú méjèèjì láti pa run bíi Bíbélì. Síbẹ̀, ó ṣì wà títí dòní, ó kéré tán lápá kan, ní ohun tó ju ẹgbẹ̀rún méjì èdè lọ. Bó ṣe jẹ́ ìwé tí kò ṣeé parun yìí àti báwọn èèyàn ò ṣe lè yí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ padà fi hàn pé iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run ni Bíbélì. Ká sòótọ́, iṣẹ́ ìyanu ni Bíbélì!

Iṣẹ́ Ìyanu Tó “Ń Sa Agbára”

Àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣẹlẹ̀ nígbà àtijọ́, irú bí ìwòsàn àti jíjí òkú dìde, kò ṣẹlẹ̀ mọ́ lóde òní. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká fọkàn balẹ̀ pé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ń mú bọ̀ láìpẹ́, irú àwọn iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ yóò tún ṣẹlẹ̀, yóò sì ṣẹlẹ̀ kárí ayé ni. Àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí á fòpin sáwọn ìṣòro wa pátápátá, ohun tó sì máa ṣẹlẹ̀ lákòókò yẹn á ju ohunkóhun tá a lè máa fọkàn rò nísinsìnyí lọ.

Bíbélì tí Ọlọ́run fún wa lọ́nà ìyanu yìí tiẹ̀ tún lè ṣe àwọn ohun tá a lè pè ní iṣẹ́ ìyanu lónìí. Ó lè mú káwọn èèyàn yí ìwà wọn padà kí wọ́n sì máa ṣe dáadáa. (Wo àpẹẹrẹ kan nínú àpótí tó sọ pé “Agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ní,” lójú ìwé 8.) Ìwé Hébérù 4:12 sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” Bẹ́ẹ̀ ni o, Bíbélì ti yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà padà. Àwọn èèyàn yìí wà lápá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé. Ó ti jẹ́ káyé wọn rójú kí ìgbésí ayé wọn sì nítumọ̀. Ó tún jẹ́ kí wọ́n máa retí àwọn nǹkan àgbàyanu lọ́jọ́ iwájú.

Ìwọ náà ò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí Bíbélì lè ṣe ohun ìyanu nínú ìgbésí ayé rẹ?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó o bá fẹ́ túbọ̀ mọ̀ nípa àwọn ohun táwọn kan kà sí ìtakora nínú Bíbélì àti báwọn ohun náà ṣe bá apá tó kù nínú Bíbélì mu, o lè rí ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ní orí keje ìwé tó ń jẹ́ The Bible—God’s Word or Man’s? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

ṢÉ JÉSÙ TI KÚ NÍGBÀ YẸN ÀBÍ KÒ TÍÌ KÚ?

Jòhánù 19:33, 34 sọ pé Jésù ti kú nígbà tí “ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun náà fi ọ̀kọ̀ gún ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde.” Àmọ́ Mátíù 27:49, 50 sọ pé Jésù kò tíì kú nígbà tí wọ́n fi ọ̀kọ̀ gún ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Kì ló dé táwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ò fi bára mu nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan?

Òfin Mósè sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gbọ́dọ̀ fi òkú ọ̀daràn sílẹ̀ lórí òpó igi títí di ọjọ́ kejì. (Diutarónómì 21:22, 23) Nítorí náà, nígbà ayé Jésù, bí ọ̀daràn tí wọ́n kàn mọ́gi kò bá kú títí dìrọ̀lẹ́, ńṣe ni wọ́n á kán ẹsẹ̀ rẹ̀, kí ikú rẹ̀ lè yá kánkán. Èyí kò ní jẹ́ kó lè gbórí sókè mọ́ débi tó fi máa lè mí dáadáa. Níwọ̀n bí àwọn ọmọ ogun náà ò ti kán ẹsẹ̀ Jésù nígbà tí wọ́n kán ẹsẹ̀ àwọn ọ̀daràn méjì tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, èyí fi hàn pé wọ́n ronú pé Jésù ti kú. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí tí ọmọ ogun náà fi fi ọ̀kọ̀ gún Jésù lẹ́gbẹ̀ẹ́ ni pé, kó lè dá a lójú pé Jésù ti kú àti pé kó má bàa lọ ta jí tó bá yá káwọn èèyàn sì lọ máa parọ́ kiri pé ó ti jíǹde.

Ọ̀nà táwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan gbà to ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nínú ìwé Mátíù 27:49, 50 yàtọ̀. Ẹsẹ náà sọ pé: “Ọkùnrin mìíràn mú ọ̀kọ̀, ó sì fi gún ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde. Jésù tún fi ohùn rara ké jáde, ó sì jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.” Àmọ́ gbólóhùn tá a kọ ní lẹ́tà wínníwínní yìí kò fara hàn nínú ẹsẹ yìí nínú gbogbo Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fọwọ́ kọ. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ló sọ pé ńṣe làwọn kan lọ mú gbólóhùn yìí látinú ìwé Ìhìn Rere Jòhánù àmọ́ tó jẹ́ pé ibi tí kò yẹ kó wà ni wọ́n lọ fi sí. Nípa bẹ́ẹ̀, nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì, inú àkámọ́ ni wọ́n fi gbólóhùn yìí sí, àwọn ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn sì ṣe àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé lórí rẹ̀, nígbà táwọn kan kúkú yọ ọ́ kúrò pátápátá.

Nínú àkójọ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì tí Westcott àti Hort ṣe, èyí tó jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, inú àkámọ́ méjì báyìí [[ ]] ni wọ́n fi gbólóhùn náà sí. Àlàyé tí wọ́n ṣe lórí gbólóhùn náà ni pé, “ó ní láti jẹ́ pé àwọn akọ̀wé òfin ló fi gbólóhùn yìí kún ẹsẹ náà.”

Nítorí náà, ẹ̀rí tá a rí tó lágbára jù lọ ni pé ohun tó wà nínú Jòhánù 19:33, 34 jẹ́ òtítọ́ pọ́ńbélé, pé Jésù ti kú nígbà tí ọmọ ogun Róòmù náà fi ọ̀kọ̀ gún ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

AGBÁRA TÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN NÍ

Nígbà tí Detlef wà ní ọ̀dọ́, ìyá àti bàbá rẹ̀ kọra wọn sílẹ̀, ló bá dẹni tó ń lo oògùn olóró, ó ń mu ọtí, ó sì máa ń gbọ́ orin onílù dídún kíkankíkan. b Ó wọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta tí wọ́n ń pè ní afáríkodoro, kò sì pẹ́ tó fi bára rẹ̀ nínú akóló àwọn ọlọ́pàá nítorí ìwà ìpáǹle rẹ̀.

Lọ́dún 1992, ìjà ńlá kan ṣẹlẹ̀ láàárín ọgọ́ta àwọn ọmọ ìta nínú ẹgbẹ́ afáríkodoro àtàwọn ọmọ ìta bíi márùndínlógójì nínú ẹgbẹ́ olórin rọ́ọ̀kì nílé oúnjẹ kan tí wọ́n tún ti ń ta ọtí, ní àríwá ìlà oòrùn ilẹ̀ Jámánì. Wọ́n lu Thomas tó jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ olórin rọ́ọ̀kì nílùkulù débi pé ó ṣèṣe gan-an ó sì kú. Ni wọ́n bá ju Detlef àtàwọn bíi mélòó kan tó jẹ́ abẹnugan nínú ẹgbẹ́ náà sẹ́wọ̀n, gbogbo bí ẹjọ́ náà sì ṣe ń lọ ni àwọn oníròyìn ń gbé e jáde.

Kò pẹ́ tí wọ́n tú Detlef sílẹ̀ lẹ́wọ̀n tó fi pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì fún un ní ìwé pélébé kan. Àkọlé ìwé pélébé náà ni: “Èé Ṣe Tí Ìgbésí-Ayé Fi Kún fún Ìṣòro Tó Bẹ́ẹ̀?” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni Detlef ti rí i pé òtítọ́ lohun tó wa nínú ìwé pélébé náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èyí mú kó yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà pátápátá. Láti ọdún 1996 ló ti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó sì ń sin Jèhófà tọkàntara.

Siegfried náà ti wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta olórin rọ́ọ̀kì tẹ́lẹ̀ rí, ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ sì lòun àti Thomas, ọmọkùnrin tí wọ́n pa yẹn. Siegfried náà di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tó yá, ó sì ti di alàgbà nínú ìjọ báyìí. Nígbà tí Siegfried lọ sí ìjọ tí Detlef wà láti lọ sọ àsọyé Bíbélì, (Màmá Thomas náà máa ń wá sípàdé níbẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan) Detlef ní kí Siegfried wá sílé òun kó wá jẹun. Tó bá jẹ́ ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn ni wọ́n pàdé ara wọn ni, ìjà kékeré kọ́ ló máa ṣẹlẹ̀ láàárín wọn. Àmọ́ lónìí, ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn nítorí pé wọ́n jẹ́ Kristẹni hàn gbangba.

Detlef àti Siegfried ń retí láti rí Thomas nígbà tó bá jíǹde nínú Paradísè orí ilẹ̀ ayé. Detlef sọ pé: “Ńṣe lomi máa ń bọ́ lójú mi tí n bá ti ronú kan ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Ohun ti mo ṣe dùn mí gan-an.” Ohun tó wà lọ́kàn àwọn méjèèjì báyìí ni láti ran Thomas lọ́wọ́ nígbà tó bá jíǹde bí wọ́n ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lónìí láti mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́ àti láti máa yọ̀ nínú ìrètí tó wà nínú Bíbélì.

Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lágbára tó la rí yìí!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

b A ti yí àwọn orúkọ inú àpilẹ̀kọ yìí padà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ọ̀nà ìyanu gbáà ni Ọlọ́run gbà dá ara èèyàn

[Credit Line]

Anatomy Improved and Illustrated, London, 1723, Bernardino Genga