Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ṣé lóòótọ́ ni Dáfídì, ọkùnrin tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run, dá àwọn tó mú lóǹdè lóró, gẹ́gẹ́ bí ohun táwọn kan sọ pé 2 Sámúẹ́lì 12:31 àti 1 Kíróníkà 20:3 túmọ̀ sí?
Rárá o. Iṣẹ́ àṣelàágùn lásán ni Dáfídì gbé fún àwọn ọmọ Ámónì tó mú lóǹdè. Bí àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan ṣe túmọ̀ àwọn ẹsẹ wọ̀nyí ló jẹ́ káwọn èèyàn lérò tí kò tọ́ nípa bí Dáfídì ṣe lo àwọn èèyàn náà.
Bí àwọn ìtumọ̀ Bíbélì wọ̀nyẹn ṣe ṣàpèjúwe ohun tí Dáfídì ṣe fáwọn ọmọ Ámónì fi Dáfídì hàn bí òǹrorò ẹ̀dá. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀nà tí Bíbélì King James Version gbà túmọ̀ 2 Sámúẹ́lì 12:31 rèé: “Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀ ni ó sì kó jáde, ó sì fi ayùn rẹ́ wọn, ó fi àwọn ohun èlò mímú tí a fi irin ṣe gé wọn, ó sì fi àáké tí a fi irin ṣe ṣá wọn, ó tún mú wọn la inú iná tí wọ́n fi ń sun bíríkì kọjá: bẹ́ẹ̀ sì ni ó ṣe sí gbogbo àwọn ìlú àwọn ọmọ Ámónì.” Ọ̀nà kan náà ni wọ́n sì gbà túmọ̀ 1 Kíróníkà 20:3.
Àmọ́, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Samuel Rolles Driver, sọ pé, ‘kò sóhun tó jọ mọ́ [ìwà ìkà] nínú gbogbo ohun tá a mọ̀ nípa Dáfídì.’ Ìdí rèé tí The Anchor Bible fi ṣàlàyé pé: “Ńṣe ni Dáfídì máa ń kó àwọn tó bá mú lóǹdè látinú àwọn ìlú tó bá ṣẹ́gun ṣiṣẹ́ kó lè rí èrè àwọn ìlú náà jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn ọba tó bá ṣẹ́gun.” Òye kan náà ni Adam Clarke ní tó fi sọ pé: “Ohun tí ẹsẹ Bíbélì yẹn túmọ̀ sí ni pé, [Dáfídì] sọ àwọn ènìyàn náà di ẹrú, ó sì fi wọ́n sídìí iṣẹ́ fífi ayùn rẹ́ nǹkan, ó tún fi wọ́n sídìí fífi irin ṣe ohun èlò mímú tàbí wíwakùsà, . . . ó sì ní kí wọ́n máa la igi kí wọ́n sì máa ṣe bíríkì. Fífi ayùn rẹ́ èèyàn, tàbí ṣíṣá èèyàn yánnayànna, tàbí gígé èèyàn kélekèle, tàbí fífi àáké ṣá èèyàn kò bá ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí wí mu, bẹ́ẹ̀ náà ni irú ìwà bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Dáfídì ṣe sáwọn ọmọ Ámónì.”
Òye tó túbọ̀ péye yìí ni onírúurú ìtumọ̀ Bíbélì òde òní gbé yọ, wọ́n túmọ̀ àwọn ẹsẹ náà lọ́nà tó fi hàn kedere pé Dáfídì kì í ṣe òkú òǹrorò. a Kíyè sí ìtumọ̀ Bíbélì New English Translation (2003), ó kà pé: “Ó kó àwọn èèyàn tó wà nínú rẹ̀ jáde, ó mú kí wọ́n fi ayùn, ohun èèlò ìkólẹ̀ onírin àti àáké onírin ṣiṣẹ́ àṣelàágùn, ó sì ní kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń sun bíríkì. Ìlànà yìí ni ó lò fún gbogbo ìlú àwọn ọmọ Ámónì.” (2 Sámúẹ́lì 12:31) “Ó kó àwọn ènìyàn tó wà nínú ìlú náà jáde, ó sì fi ayùn, àwọn ohun èlò ìkólẹ̀ àti àáké lé wọn lọ́wọ́ láti fi ṣiṣẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì ṣe sí gbogbo àwọn ìlú àwọn ọmọ Ámónì.” (1 Kíróníkà 20:3) Bí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe túmọ̀ àwọn ẹsẹ náà pàápàá fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú tàwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ òde òní. Ó kà pé: “Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀ ni ó sì kó jáde, kí ó lè fi wọ́n sídìí fífi ayùn rẹ́ òkúta àti sídìí àwọn ohun èlò mímú tí a fi irin ṣe àti sídìí àáké tí a fi irin ṣe, ó sì mú kí wọ́n sìn nídìí bíríkì ṣíṣe.” (2 Sámúẹ́lì 12:31) “Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀ ni ó sì kó jáde, ó sì fi wọ́n sí ẹnu iṣẹ́ nídìí fífi ayùn rẹ́ òkúta àti nídìí àwọn ohun èlò mímú tí a fi irin ṣe àti nídìí àáké; bẹ́ẹ̀ sì ni Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe sí gbogbo àwọn ìlú ńlá àwọn ọmọ Ámónì.”—1 Kíróníkà 20:3.
Ó hàn gbangba pé Dáfídì ò dá àwọn ọmọ Ámónì tí Dáfídì ṣẹ́gun lóró, bẹ́ẹ̀ sì ni kó pa wọn nípakúpa. Kò hùwà bíi tàwọn ajagunṣẹ́gun ọjọ́ ayé rẹ̀ tí wọ́n máa ń dá àwọn èèyàn lóró.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tí a bá yọ lẹ́tà kan kúrò nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn lédè Hébérù, ó lè kà pé “ó fi wọ́n sínú ayùn” tàbí “ó (fi ayùn) rẹ́ wọn sí wẹ́wẹ́.” Síwájú sí i, ọ̀rọ̀ náà tá a túmọ̀ sí “ibi tí wọ́n ti ń sun bíríkì” tún lè túmọ̀ sí “ohun tí wọ́n fi ń yọ bíríkì.” Àmọ́, inú ohun tí wọ́n fi ń yọ bíríkì kéré jù ibi téèyàn lè gba kọjá lọ.