Ṣé Òótọ́ Ni Iṣẹ́ Ìyanu Ń Ṣẹlẹ̀?
Ṣé Òótọ́ Ni Iṣẹ́ Ìyanu Ń Ṣẹlẹ̀?
ỌKÙNRIN kan tajú kán rí àkọlé kan tí wọ́n lẹ̀ mọ́ ẹ̀yìn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan tó ń kọjá lọ. Ohun tí àkọlé náà sọ ni pé: “Iṣẹ́ Ìyanu Ń Ṣẹlẹ̀, Ìwọ Sáà Ti Béèrè Lọ́wọ́ Àwọn Áńgẹ́lì.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́sìn ni ọkùnrin yìí fúnra rẹ̀, kò mọ ohun tí gbólóhùn náà túmọ̀ sí. Ṣé ohun tí àkọlé náà túmọ̀ sí ni pé awakọ̀ náà gbà pé iṣẹ́ ìyanu wà? Àbí ńṣe ló ń fi ṣàwàdà pé kò sí iṣẹ́ ìyanu kò sì sí áńgẹ́lì?
Gbọ́ ohun tí òǹṣèwé ọmọ ilẹ̀ Jámánì kan, Manfred Barthel, sọ nípa iṣẹ́ ìyanu. Ó sọ pé: “Báwọn èèyàn bá ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, iṣẹ́ ìyanu, kíá ló máa ń pín wọn sí ẹgbẹ́ méjì, èrò wọn kì í sì bára mu rárá.” Àwọn tó nígbàgbọ́ nínú iṣẹ́ ìyanu gbà pé ó máa ń ṣẹlẹ̀, wọ́n tiẹ̀ sọ pé ó máa ń ṣẹlẹ̀ léraléra. a Bí àpẹẹrẹ, a gbọ́ pé lẹ́nu ọdún àìpẹ́ yìí nílẹ̀ Gíríìsì, àwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ níbẹ̀ sọ pé iṣẹ́ ìyanu máa ń ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ẹ̀ẹ̀kan lóṣù. Èyí ló mú kí bíṣọ́ọ̀bù Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì kan sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n ṣọ́ ohun tí wọ́n á máa sọ, ó ní: “Àwọn onígbàgbọ́ máa ń wo Ọlọ́run, Màríà, àtàwọn ẹni mímọ́ bíi pé èèyàn ni wọ́n. Kò yẹ káwọn onígbàgbọ́ ti àṣejù bọ ọ̀rọ̀ yìí.”
Àwọn orílẹ̀-èdè kan wà tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ nígbàgbọ́ nínú iṣẹ́ ìyanu. Àjọ aṣèwádìí kan tó ń jẹ́ Allensbach lórílẹ̀-èdè Jámánì fọ̀rọ̀ wá àwọn èèyàn lẹ́nu wò, wọ́n sì tẹ àbọ̀ ìwádìí wọn jáde lọ́dún 2002. Ìwádìí yìí fi hàn pé ìdá mọ́kànléláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-un àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè náà ni kò gbà pé iṣẹ́ ìyanu wà. Àwọn obìnrin mẹ́ta kan wà lára àwọn nǹkan bíi ìdá kan nínú mẹ́tà tó gbà gbọ́ pé iṣẹ́ ìyanu ń ṣẹlẹ̀. Àwọn obìnrin náà sọ pé Màríà Wúńdíá bá àwọn sọ̀rọ̀. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Jámánì kan tó ń jẹ́ Westfalenpost sọ nǹkan kan ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn táwọn obìnrin náà sọ pé àwọn rí Màríà Wúndíá tòun tàwọn áńgẹ́lì àti ẹyẹ àdàbà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó sọ pé: “Látìgbà náà làwọn arìnrìn-àjò ẹ̀sìn tó ń wá ìwòsàn tí wọ́n tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta àtàwọn olójúmìító èèyàn ti ń wá ọ̀nà láti rí ohun táwọn obìnrin náà sọ pé àwọ́n rí.” Ó ṣeé ṣe kí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá èèyàn tún ṣì rọ́ lọ sí abúlé náà láti lè rí Màríà nígbà tó bá tún fara hàn. Bákan náà làwọn kan tún sọ pé Màríà Wúńdíá fara hàn láwọn ìlú bíi Lourdes nílẹ̀ Faransé lọ́dún 1858 àti ní ìlú Fátima, lórílẹ̀ èdè Portugal lọ́dún 1917.
Ǹjẹ́ Àwọn Tí Kì Í Ṣe Ẹlẹ́sìn Kristi Náà Gbà Pé Iṣẹ́ Ìyanu Wà?
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹ̀sìn kan tí kò gbà pé iṣẹ́ ìyanu wà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tó ń jẹ́ The Encyclopedia of Religion ṣàlàyé pé èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn tó dá ẹ̀sìn Búdà, ẹ̀sìn Kristẹni àti ẹ̀sìn Ìsìláàmù sílẹ̀ ní nípa iṣẹ́ ìyanu. Àmọ́, ìwé náà sọ pé: “Ìtàn àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ẹ̀sìn wọ̀nyí fi hàn gbangba pé aráyé ka ìgbàgbọ́ nínú iṣẹ́ ìyanu àtàwọn ìròyìn nípa iṣẹ́ ìyanu sí pàtàkì nínú ìsìn wọn.” Ìwé yìí kan náà sọ pé, “Búdà fúnra rẹ̀ máa ń ṣe iṣẹ́ ìyanu nígbà míì.” Nígbà tó sì yá tí “wọ́n mú ẹ̀sìn Búdà
lọ sílẹ̀ Ṣáínà, àwọn míṣọ́nnárì tó mú ẹ̀sìn náà lọ sábà máa ń fi hàn pé àwọn lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu.”Lẹ́yìn tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ yìí ti mẹ́nu ba díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ ìyanu tí wọ́n sọ pé ó ṣẹlẹ̀, ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Èèyàn lè má gba gbogbo iṣẹ́ ìyanu táwọn òpìtàn tí ẹ̀sìn ti wọ̀ lára yìí sọ gbọ́. Àmọ́ ó dájú pé ìdí tí wọ́n fi sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí ni láti fògo fún Búdà, ẹni tí wọ́n gbà pé ó lè fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó bá nítara ní irú agbára tó fi ń ṣe iṣẹ́ ìyanu.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ yìí tún sọ nípa ẹ̀sìn Ìsìláàmù, ó ní: “Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ẹlẹ́sìn Ìsìláàmù ló ṣì ń retí pé iṣẹ́ ìyanu máa ṣẹlẹ̀. Ìwé ìtàn ẹ̀sìn Ìsìláàmù tá a mọ̀ sí (hadīths) sọ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni Mùhámádù ṣe iṣẹ́ ìyanu fáwọn èèyàn. . . . Àwọn mùsùlùmí sì nígbàgbọ́ pé lẹ́yìn táwọn ẹni mímọ́ bá ti kú pàápàá, wọ́n ṣì ń ṣe iṣẹ́ ìyanú níbi sàárè wọn fáwọn tó bá nígbàgbọ́, àwọn èèyàn sì máa ń bẹ àwọn ẹni mímọ́ wọ̀nyí pé kí wọ́n ran àwọn lọ́wọ́.”
Iṣẹ́ Ìyanu Táwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Sọ Pé Ó Ń Ṣẹlẹ̀ ŃKọ́?
Èrò ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn Kristi ò ṣọ̀kan nípa iṣẹ́ ìyanu. Àwọn kan gbà gbọ́ pé òótọ́ làwọn iṣẹ́ ìyanu tí Bíbélì sọ pé Jésù Kristi ṣe àtèyí táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wà kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé ṣe. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ tún fara mọ́ èrò Martin Luther tó jẹ́ alátùn-únṣe ìsìn. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tó ń jẹ́ The Encyclopedia of Religion sọ nípa ọkùnrin yìí pé: “Luther àti Calvin kọ̀wé pé àsìkò tí iṣẹ́ ìyanu ń ṣẹlẹ̀ ti kọjá àti pé kò yẹ káwọn èèyàn máa retí pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ á tún ṣẹlẹ̀.” Ìwé gbédègbẹ́yò yìí sọ pé Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ṣì gbà gbọ́ gan-an pé iṣẹ́ ìyanu ń ṣẹlẹ̀, “ó kàn jẹ́ pé kò sọ bó ṣe ń ṣẹlẹ̀ ni.” Àmọ́ “àwọn tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé nínú àwọn ìsìn tí kì í ṣe ìsìn Kátólíìkì gbà pé ohun tí ẹ̀sìn Kristẹni dá lé kò ju kéèyàn máa hùwà rere. Àti pé ohun tó ń lọ nígbèésí ayé ẹ̀dá èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ kan Ọlọ́run àtàwọn tó wà lókè ọ̀run.”
Àwọn mìíràn tó pera wọn ní Kristẹni, títí kan àwọn àlùfáà kan, kò gbà pé lóòótọ́ làwọn iṣẹ́ ìyanu Ẹ́kísódù 3:1-5 nípa igi kan tó ń jó. Ìwé kan tó ń jẹ́ What the Bible Really Says (Ohun Tí Bíbélì Dìídì Sọ) ṣàlàyé pé, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan lórílẹ̀-èdè Jámánì kò gbà pé iṣẹ́ ìyanu tó dìídì ṣẹlẹ̀ ni àkọsílẹ̀ yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ní ohun tó túmọ̀ sí ni pé “ọkàn Mósè ò lélẹ̀ nítorí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ń dà á láàmú.” Ìwé náà sọ síwájú pé: “Iná náà tún lè dúró fáwọn òdòdó tó ṣàdédé rú yọ nínú oòrùn tó ń ṣàpẹẹrẹ wíwà níbẹ̀ Ọlọ́run.”
tí Bíbélì sọ ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wo àkọsílẹ̀ tó wà nínú Bíbélì níÀlàyé yìí lè má tẹ́ ọ lọ́rùn. Kí ló wá yẹ kó o gbà gbọ́? Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu ká gbà pé iṣẹ́ ìyanu ṣẹlẹ̀ rí? Àwọn iṣẹ́ ìyanu táwọn èèyàn sọ pé ó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní ńkọ́? Níwọ̀n bá ò ti lè béèrè lọ́wọ́ àwọn áńgẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n lẹ̀ mọ́ ara ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tá a mẹ́nu bà lókè yẹn ṣe sọ, tá la lè béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?
Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Iṣẹ́ Ìyanu
Kò sẹ́ni tó lè sọ pé Bíbélì kò sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe dá sí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn kan láyé àtijọ́ tó sì ṣe àwọn ohun tí ẹ̀dá èèyàn ò lè ṣe. A kà nípa Ọlọ́run pé: “Ìwọ sì tẹ̀ síwájú láti mú àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì jáde wá láti ilẹ̀ Íjíbítì, pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ àmì àti pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ìyanu àti pẹ̀lú ọwọ́ líle àti pẹ̀lú apá nínà jáde àti pẹ̀lú ẹ̀rù ńláǹlà.” (Jeremáyà 32:21) Rò ó wò ná, Ọlọ́run fàbùkù kan orílẹ̀-èdè tó lágbára jù lọ láyé Mósè nípa mímú ìyọnu mẹ́wàá wá sórí wọn, lára rẹ̀ sì ni pé gbogbo àwọn tó jẹ́ àkọ́bí ọmọ ní orílẹ̀ èdè náà ló kú. Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ìyanu gbáà làwọn ìyọnu wọ̀nyí!—Ẹ́kísódù, orí 7 sí orí 14.
Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn tí èyí ṣẹlẹ̀, àwọn mẹ́rin tó kọ ìwé Ìhìn Rere tún sọ nípa iṣẹ́ ìyanu bíi márùndínlógójì tí Jésù ṣe. Ká sòótọ́, àkọsílẹ̀ wọn fi hàn pé iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe pọ̀ jùyẹn lọ dáadáa. Ǹjẹ́ òótọ́ làwọn ohun tí wọ́n sọ yìí àbí ìtàn àròsọ lásán ni wọ́n? b—Mátíù 9:35; Lúùkù 9:11.
Bí Bíbélì bá jẹ́ ohun tá a mọ̀ ọ́n sí, ìyẹn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ òtítọ́, ó yẹ kí èyí mú ọ gba àwọn iṣẹ́ ìyanu tó sọ pé ó ṣẹlẹ̀ gbọ́. Bíbélì sọ lọ́nà tó yeni kedere pé iṣẹ́ ìyanu ṣẹlẹ̀ nígbà àtijọ. Ó sọ pé ìwòsàn, àjínde, àtàwọn nǹkan mìíràn ṣẹlẹ̀ lọ́nà ìyanu. Àmọ́, ó tún fi yé wa kedere pé irú àwọn iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ mọ́ lásìkò yìí. (Wo àpótí tó sọ pé “Ìdí Tí Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Kan Ò Fi Ṣẹlẹ̀ Mọ́,” lójú ìwé 4) Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé àwọn tó gba Bíbélì gbọ́ kò gbà pé iṣẹ́ ìyanu ń ṣẹlẹ̀ lónìí ni? Jẹ́ kí àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí dáhùn ìbéèrè yìí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì ṣe túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà “iṣẹ́ ìyanu” la ṣe lò ó nínú àpilẹ̀kọ yìí. Ó túmọ̀ rẹ̀ sí: “Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé tó kọjá agbára ẹ̀dá èèyàn tàbí agbára àwọn ìṣẹ̀dá mìíràn, tá a sì máa ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ pé agbára àwámáàrídìí kan ló wà lẹ́yìn irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀.”
b O lè ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé a lè gba Bíbélì gbọ́. Irú àwọn ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ wà nínú ìwé The Bible—God’s Word or Man’s? tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
ÌDÍ TÍ ÀWỌN IṢẸ́ ÌYANU KAN Ò FI ṢẸLẸ̀ MỌ́
Bíbélì sọ nípa onírúurú iṣẹ́ ìyanu tó ṣẹlẹ̀. (Ẹ́kísódù 7:19-21; 1 Àwọn Ọba 17:1-7; 18:22-38; 2 Àwọn Ọba 5:1-14 Mátíù 8:24-27; Lúùkù 17:11-19; Jòhánù 2:1-11; 9:1-7) Ọ̀pọ̀ lára àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà, wọ́n sì tún jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ọlọ́run ló ń ti Jésù lẹ́yìn. Àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu, irú bíi fífi èdè fọ̀ àti lílóye àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí. (Ìṣe 2:5-12; 1 Kọ́ríńtì 12:28-31) Àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí sì wúlò gan-an nígbà tí ìjọ Kristẹni kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀. Lọ́nà wo?
Lákòókò yẹn, ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ tó wà kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Àwọn ọlọ́rọ̀ ló sábà máa ń ní àwọn àkájọ ìwé tàbí ìwé èyíkéyìí lọ́wọ́. Àwọn èèyàn tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ̀sìn Kristẹni ò tíì dé nígbà yẹn kò mọ ohun tó ń jẹ́ Bíbélì bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì mọ nǹkan kan nípa ẹni tó ni Bíbélì, ìyẹn Jèhófà. Ẹnu làwọn onígbàgbọ́ fi ń sọ ẹ̀kọ́ Kristi fáwọn èèyàn. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé Ọlọ́run ń lo ìjọ Kristẹni.
Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí máa wá sópin nígbà tí wọn ò bá wúlò mọ́. Ó sọ pé: “Yálà àwọn ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ wà, a óò mú wọn wá sí òpin; yálà àwọn ahọ́n àjèjì wà, wọn yóò ṣíwọ́; yálà ìmọ̀ wà, a óò mú un wá sí òpin. Nítorí àwa ní ìmọ̀ lápá kan, a sì ń sọ tẹ́lẹ̀ lápá kan; ṣùgbọ́n nígbà tí èyíinì tí ó pé pérépéré bá dé, èyíinì tí ó jẹ́ ti apá kan ni a óò mú wá sí òpin.”—1 Kọ́ríńtì 13:8-10.
Lónìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ní Bíbélì lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún láwọn atọ́ka Bíbélì àtàwọn ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Àwọn Kristẹni tá a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa tí wọ́n lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà sì tún ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa Ọlọ́run látinú Bíbélì. Nípa bẹ́ẹ̀, a ò nílò àwọn iṣẹ́ ìyanu mọ́ láti fi ṣe ẹ̀rí pé Jésù Kristi lẹni tí Ọlọ́run yàn gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà tàbí láti fi hàn pé Jèhófà ń ti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn.