Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Gun Òkè Lọ sí Abúlé Kan Tó Ń Jẹ́ The Bottom ní Erékùṣù Saba

A Gun Òkè Lọ sí Abúlé Kan Tó Ń Jẹ́ The Bottom ní Erékùṣù Saba

A Gun Òkè Lọ sí Abúlé Kan Tó Ń Jẹ́ The Bottom ní Erékùṣù Saba

SABA jẹ́ erékùṣù kan ní àgbègbè orílẹ̀-èdè Netherlands. Nígbà kan rí, ibẹ̀ làwọn jàgùdà tó máa ń dá àwọn ọkọ̀ tó ń gba Òkun Caribbean kọjá fi ṣelé. Ó jẹ́ erékùṣù kékeré kan tó wà ní igba ó lé ogójì kìlómítà sí orílẹ̀-èdè Puerto Rico. Ẹgbẹ̀jọ [1,600] èèyàn ló sì ń gbé níbẹ̀ lónìí. Márùn-ún lára wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, ohun táwọn Ẹlẹ́rìí tó nígboyà wọ̀nyí ń wá ṣeyebíye gan-an ju ẹrù táwọn gbéwiri yẹn máa ń jí kó lọ. Tọkàntara ni wọ́n fi ń wá àwọn èèyàn tó ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.”—Ìṣe 13:48.

Ọjọ́ kejìlélógún oṣù June ní ọdún 1952 ni ìhìn rere Ìjọba náà kọ́kọ́ dé erékùṣù yìí, nígbà tí ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n ń pè ní Sibia gúnlẹ̀ sí etíkun erékùṣù Saba. Ọkọ̀ ojú omi náà gùn tó mítà méjìdínlógún, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló sì ṣe atọ́kùn rẹ̀. (Mátíù 24:14) Àtibẹ̀ ni àwọn míṣọ́nnárì méjì tórúkọ wọ́n ń jẹ́ Gust Maki àti Stanley Carter ti gun àtẹ̀gùn kan lọ sí abúlé kan tí wọ́n ń pè ní The Bottom tó jẹ́ olú ìlú Saba. a Òkúta tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta tí wọ́n tò léra ni wọ́n fi ṣe àtẹ̀gùn náà. Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni ọ̀nà tóóró yìí fi jẹ́ kìkì ibi téèyàn lè gbà dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ń gbé ní erékùṣù náà.

Ìròyìn tá a kọ́kọ́ tẹ̀ jáde nípa iṣẹ́ ìjẹ́rìí táwọn Kristẹni ṣe ní Saba ni èyí tó wà nínú Ìwé Ọdọọdún Ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún1966. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìròyìn náà fi hàn, Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo tó ń ṣe déédéé ló wà ní erékùṣù náà nígbà yẹn. Nígbà tó yá, ìdílé kan láti orílẹ̀-èdè Kánádà wá lo ọdún bíi mélòó kan ní erékùṣù náà láti wàásù ìhìn rere níbẹ̀. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Russel àti Kathy tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ sí Saba láti lọ máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà níbẹ̀. Tọkọtaya ni wọ́n, wọ́n sì ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́. Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí wọ́n sọ.

A Lọ sí Saba

Ọkọ̀ òfuurufú lèmi àti ìyàwó mi wọ débẹ̀. Ronald, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo tó wà ní erékùṣù náà ní ọdún tó pọ̀ jù lọ láwọn ọdún 1990 ló gbà wá lálejò. Arákùnrin yìí dúró sí pápákọ̀ òfuurufú dè wá. Inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tá a kó àwọn ohun ọ̀gbìn tó kúnnú àpótí kékeré kan fún un, nítorí pé kò sí àwọn tó ń ta nǹkan ọ̀gbìn ní erékùṣù náà. A wá wọ ọkọ̀ akẹ́rù kékeré kan, a sì rọra ń gba ọ̀nà kọ́lọkọ̀lọ kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè ńlá kan lọ títí a fi dé orí òkè tó ti yọná-yèéfín nígbà kan rí.

A tẹsẹ̀ dúró ní abúlé kan tí wọ́n ń pè ní Hell’s Gate. Ronald sì sọ̀kalẹ̀ lọ yẹ pátákó ìsọfúnni tó wà níbẹ̀ wò láti mọ̀ bóyá ìwé tó fi pe àwọn èèyàn wá síbi àsọyé fún gbogbo ènìyàn tó máa wáyé ní ọjọ́ Sunday ṣì wà níbẹ̀. Inú wa dùn gan-an láti rí i pé ó ṣì wà níbẹ̀. Ó padà sínú ọkọ̀ náà, bá a tún ṣe ń gun òkè náà lọ nìyẹn títí a fi dé Windwardside, ìyẹn abúlé tó tóbi jù lọ ní erékùṣù náà. Orúkọ abúlé tó lẹ́wà yìí fi hàn pé ó wà ní apá ibi tí atẹ́gùn ti máa ń fẹ́ gan-an ní erékùṣù náà. Ibi tí abúlé náà wà sì fi nǹkan bí irínwó mítà ga sókè ju ìtẹ́jú òkun lọ. Bí ọkọ̀ náà ṣe gbé wa dé ilé Ronald la rí pátákó kan tó jojúnígbèsè níbi gọ̀bì ilé náà. Èyí ló fi hàn pé Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni.

Nígbà tá à ń jẹ oúnjẹ ọ̀sán lọ́wọ́ ni mo béèrè ìbéèrè tó mú ká wá sí erékùṣù náà. Mo bi Ronald pé, “Báwo lo ṣe dẹni tó ń pòkìkí Ìjọba náà ní Saba?”

Ronald sọ pé: “Nígbà tí iṣẹ́ ìkọ́lé parí ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Puerto Rico lọ́dún 1993, ó wu èmi àti ìyàwó mi láti máa ba iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ nílẹ̀ òkèèrè. Ṣáájú àkókò yẹn, àwa àti tọkọtaya kan ti wá sí Saba, a sì ti gbọ́ pé egbèje [1,400] èèyàn ló wà níbẹ̀. Àmọ́ kò sí Ẹlẹ́rìí kankan lára wọn. Bá a ṣe fi ọ̀rọ̀ náà lọ Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Puerto Rico nìyẹn, tá a sì sọ fún wọn pe a fẹ́ wá síbi.

“Gbogbo ètò tá a ṣe ló kẹ́sẹ járí, nígbà tó sì yá, a rí ìwé àṣẹ gbà pé ká máa bọ̀ níbi. Àmọ́, ọdún méjì lẹ́yìn tá a ti wá síbí ni àìsàn burúkú kan kọ lu ìyàwó mi. Bá a ṣe padà sí ìpínlẹ̀ California nìyẹn. Ìgbà tí ìyàwó mi kú ni mo wá padà sí Saba. Nǹkan tó wà níbẹ̀ ni pé, mi ò fẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ ohun kan kí n má sì parí rẹ̀.”

Ìwàásù Ilé-Dé-Ilé ní Saba

Pálọ̀ tí Ronald ń lò nínú ilé kan tí wọ́n ti kọ́ láti ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn ló tún ń lò fún Gbọ̀ngàn Ìjọba. b Bá a ṣe ń jẹ oúnjẹ àárọ̀ lọ́wọ́ tá à ń múra àtilọ sí òde ìwàásù, kùrukùru òjò ń wọ́ lọ wọ́ bọ̀, òjò sì bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀. Òjò náà rin ilé ìdáná wa tí kò ní òrùlé lórí gbingbin. Nígbà tá a máa fi jẹun tán, òjò ti dá, a sì lọ sí iṣẹ́ ìwàásù àtilé-dé-ilé lábúlé tó ń jẹ́ The Bottom. Bá a ṣe ń dé ilé kọ̀ọ̀kan ni Ronald ń kí àwọn onílé náà tó sì ń dárúkọ wọn. Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ lábúlé náà láìpẹ́ sí àkókò yẹn ni ìjíròrò wá dá lé lórí. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn náà ló mọ Ronald bí ẹní mowó, wọ́n sì mọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Tayọ̀tayọ̀ ni ọ̀pọ̀ sì gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Kò rọrùn rárá láti dá ilé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba náà mọ̀ téèyàn ò bá mọ àwọn ará abúlé náà dáadáa. Kí nìdí? Ronald sọ pé nítorí pé “òfin ní kí wọ́n kun gbogbo ilé tó wà níbẹ̀ ní àwọ̀ kan náà.” Òótọ́ lohun tó sọ yẹn, nítorí pé nígbà tí mo wò yíká, mo rí i pé ọ̀dà funfun ni wọ́n fi kun gbogbo ilé tó wà ní Saba, ọ̀dà pupa ni wọ́n sì fi kun òrùlé wọn.

Nígbà tá a bá bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ látinú Bíbélì tán, a ó wá sọ fún onítọ̀hún pé kó wá síbi àsọyé Bíbélì tá a fẹ́ sọ fún gbogbo èèyàn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ní ọjọ́ Sunday. Nígbà tí Ronald ò bá lọ síbi kankan, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ló máa ń sọ àsọyé ní erékùṣù náà. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́tàdínlógún làwọn ará ń darí ní Saba. Ogún èèyàn ló wá síbi Ìṣe Ìrántí Ikú Kristi ní ọdún 2004. Ó lè jọ pé iye yẹn kéré gan-an, àmọ́ iye yẹn jẹ́ ìdá kan nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èèyàn tó ń gbé ní Saba!

Láìsí àní-àní, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti sa gbogbo ipá wọn láti máa sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń fúnni ní ìgbàlà fún ọ̀pọ̀ èèyàn tó ṣeé ṣe fún wọn láti bá sọ̀rọ̀. Tọkàntọkàn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń ṣe iṣẹ́ tá a gbé lé wọn lọ́wọ́ pé kí wọ́n “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,” ì báà jẹ́ ní erékùṣù kékeré bíi Saba tàbí ní orílẹ̀-èdè ńlá.—Mátíù 28:19.

Iye ọjọ́ tá a fẹ́ lo níbẹ̀ ti pé wàyí, a sì fi ibẹ̀ sílẹ̀. Bá a ṣe wọnú ọkọ̀ òfuurufú tó fẹ́ gbé wa lọ, a kí wọn pé ó dìgbòóṣe. A ò ní gbàgbé wíwá tá a wá sí Saba láé, a ò sì ní gbàgbé àkókò tá a fi ń gun òkè tó lọ sí abúlé tó ń jẹ́ The Bottom!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó dà bíi pé àwọn jàgùdà ló pe erékùṣù yìí ní The Bottom nítorí pé wọ́n rò pé ìsàlẹ̀ ihò òkè ayọnáyèéfín kan ló wà.

b Ní September 28, 2003, àwọn kan tó yọ̀ǹda ara wọn láti ìpínlẹ̀ Florida, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ sí Saba, wọ́n sì tún ilé kan tó wà nítòsí kọ́. Ilé náà ni wọ́n wá fi ṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba báyìí.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 10]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

PUERTO RICO

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]

Òkè tá à ń wò yìí: www.sabatourism.com