Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Bí Ẹnì Kan Bá Fipá Gbéṣẹ́ fún Ọ’

‘Bí Ẹnì Kan Bá Fipá Gbéṣẹ́ fún Ọ’

‘Bí Ẹnì Kan Bá Fipá Gbéṣẹ́ fún Ọ’

“ÌWỌ wá ń bí! Fi nǹkan tó ò ń ṣe yẹn sílẹ̀ kíá, kó o wá bá mi gbé kiní yìí.” Kí lo rò pé Júù kan tó ń ṣiṣẹ́ kan lọ́wọ́ máa ṣe bí ọmọ ogun Róòmù kan bá sọ irú ọ̀rọ̀ yẹn sí i ní ọ̀rúndún kìíní? Jésù sọ ohun tó yẹ kó ṣe nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè, ó ní: “Bí ẹnì kan tí ó wà ní ipò ọlá àṣẹ bá sì fi tipátipá gbéṣẹ́ fún ọ fún ibùsọ̀ kan, bá a dé ibùsọ̀ méjì.” (Mátíù 5:41) Báwo làwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù ṣe máa lóye ìmọ̀ràn yẹn? Kí ló sì yẹ kó túmọ̀ sí fún àwa náà lónìí?

Ká tó lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ bí wọ́n ṣe máa ń fipá gbéṣẹ́ fáwọn èèyàn láyé ìgbàanì. Àwọn tó ń gbé nílẹ̀ Ísírẹ́lì nígbà ayé Jésù mọ̀ nípa àṣà yìí dáadáa.

Iṣẹ́ Àfipáṣe

Ẹ̀rí fi hàn pé láti ọ̀rúndún kejìdínlógún ṣáájú Sànmánì Tiwa làwọn èèyàn ti máa ń ṣe iṣẹ́ àfipáṣe ní Ìtòsí Ìlà Oòrùn ayé. Àwọn ìwé ètò ìlú, tí wọ́n kó wá láti ìlú Alalakh tó jẹ́ ìlú àwọn ará Síríà ìgbàanì sọ nípa àwọn èèyàn kan tí wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ sin ìlú, tíjọba wá ń fipá mú ṣe iṣẹ́. Nílùú Ugarit tó wà ní etíkun Síríà, àwọn àgbẹ̀ tó ń yá ilẹ̀ dáko ni wọ́n máa ń fipá mú láti ṣe irú iṣẹ́ yìí, àyàfi ẹni tí ọba bá sọ pé kó má ṣiṣẹ́.

Ó dájú pé iṣẹ́ àṣekúdórógbó làwọn èèyàn máa ń gbé fáwọn tí wọ́n bá kó níkòógun tàbí àwọn tí wọ́n bá kó lẹ́rù. Ńṣe làwọn akóniṣiṣẹ́ ní Íjíbítì máa ń fipá mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sìn bí ẹrú tí wọ́n á ní kí wọ́n máa yọ bíríkì. Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà fipá mú àwọn ará Kénáánì tó ń gbé ní Ilẹ̀ Ìlérí ṣe iṣẹ́ àṣebólórí. Dáfídì àti Sólómọ́nì náà tún tẹ̀ lé àṣà kan náà yìí.—Ẹ́kísódù 1:13, 14; 2 Sámúẹ́lì 12:31; 1 Àwọn Ọba 9:20, 21.

Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé àwọn fẹ́ lọ́ba, Sámúẹ́lì ṣàlàyé ohun tí ọba náà máa fẹ́ kí wọ́n ṣe. Ọba náà yóò sọ pé kí àwọn kan lára wọn máa gun kẹ̀kẹ́ ogun, káwọn kan sì máa gun ẹṣin. Yóò ní káwọn kan máa túlẹ̀, káwọn kan sì máa kórè, káwọn mìíràn máa ṣe ohun ìjà ogun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (1 Sámúẹ́lì 8:4-17) Lákòókò tí wọ́n sì ń kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń lo àwọn àjèjì bí omi ojo, síbẹ̀ “kò . . . sí ìkankan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí Sólómọ́nì sọ di ẹrú; nítorí àwọn ni jagunjagun àti ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ọmọ aládé rẹ̀ àti àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lójú ogun àti olórí àwọn oníkẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ àti ti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.”—1 Àwọn Ọba 9:22.

Ìwé 1 Àwọn Ọba 5:13, 14 sọ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí Sólómọ́nì gbà síṣẹ́ ìkọ́lé náà pé: “Sólómọ́nì Ọba sì ń bá a nìṣó ní mímú àwọn tí a ń fi túláàsì mú sìn nínú òpò àfipámúniṣe gòkè wá láti inú gbogbo Ísírẹ́lì; àwọn tí a sì ń fi túláàsì mú sìn nínú òpò àfipámúniṣe jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ ọkùnrin. Òun a sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Lẹ́bánónì ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oṣù kan. Wọn a máa wà ní Lẹ́bánónì fún oṣù kan, wọn a sì máa wà ní ilé wọn fún oṣù méjì.” (1 Àwọn Ọba 5:13, 14) Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé: “Kò sí àní-àní pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn ọba Jùdíà kan máa ń lo àwọn tó ń siṣẹ́ sin ìlú fún iṣẹ́ ìkọ́lé wọn àti fún iṣẹ́ lórí ilẹ̀ tó jẹ́ ti ọba kí wọ́n má bàa sanwó iṣẹ́.”

Iṣẹ́ àṣekúdórógbó ni wọ́n ń ṣe lábẹ́ ìṣàkóso Sólómọ́nì. Iṣẹ́ náà pọ̀ gan-an débi pé nígbà tí Rèhóbóámù halẹ̀ pé òun máa fi kún un, ńṣe ni gbogbo Ísírẹ́lì kọ̀ jálẹ̀, wọ́n sì sọ ẹni tó jẹ́ ọ̀gá lórí àwọn tá à ń fipá mú ṣiṣẹ́ lókùúta pa. (1 Àwọn Ọba 12:12-18) Àmọ́, ètò ká máa fipá múni ṣiṣẹ́ kò kásẹ̀ nílẹ̀. Ọmọ ọmọ Rèhóbóámù tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ásà sọ fún gbogbo àwọn tó ń gbé ní Júdà pé kí wọ́n kọ́ ìlú Gébà àti Mísípà, kò sì “yọ ẹnì kankan sílẹ̀.”—1 Àwọn Ọba 15:22.

Iṣẹ́ Àfipáṣe Lábẹ́ Ìjọba Róòmù

Ìwàásù Jésù Lórí Òkè fi hàn pé ọ̀rọ̀ ká ‘máa fipá múni ṣiṣẹ́’ kò ṣàjèjì sáwọn Júù ọ̀rúndún kìíní. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí gbólóhùn náà ni ag·ga·reuʹo, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbòkègbodò àwọn òṣìṣẹ́ Páṣíà láyé ìgbà yẹn. Àwọn òṣìṣẹ́ náà ní àṣẹ láti fagbára mú àwọn èèyàn, ẹṣin, ọkọ̀ òkun, tàbí ohunkóhun mìíràn tó máa mú kí iṣẹ́ wọn yá.

Nígbà ayé Jésù, àwọn ará Róòmù ló kún ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ńṣe làwọn náà sì máa ń fipá múni ṣiṣẹ́. Ní Ìlà Oòrùn ayé, yàtọ̀ sí owó orí tí wọ́n máa ń gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn, wọ́n tún máa ń fipá mú wọn ṣiṣẹ́ ní gbogbo ìgbà tàbí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Inú àwọn èèyàn kì í dùn sí irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ pé kí wọ́n máa fipá gba àwọn ẹranko, àwọn awakọ̀, àtàwọn ọkọ̀ tí ẹran ń fà láti máa fi wọ́n kérò láàárín ìlú. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Michael Rostovtzeff ti wí, àwọn alábòójútó “gbìyànjú láti dẹwọ́ [àṣà náà], àmọ́ wọn ò kẹ́sẹ járí, nítorí pé níwọ̀n bí àṣà náà bá ṣì wà, kò sì bí akitiyan wọn ṣe lè so èso rere. Oríṣiríṣi òfin làwọn aláṣẹ ṣe, ìyẹn àwọn aláṣẹ tó jẹ́ pé tọkàntọkàn ni wọ́n fẹ́ fi fòpin sí báwọn kan ṣe ń ṣi agbára lò àti bí wọn ṣe ń fipá mú àwọn èèyàn ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó . . . Síbẹ̀ ńṣe ló túbọ̀ ń burú sí i.”

Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì sọ pé: “Ẹnikẹ́ni ni wọ́n lè fipá mú pé kó bá ọmọ ogun kan gbé ẹrù rẹ̀ dé ibì kan pàtó, ẹnikẹ́ni ni wọ́n sì lè fipá mú pé kó ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí ẹni tó pè é bá gbé fún un.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Símónì ará Kírénè nìyẹn. Ọkùnrin yìí láwọn sójà Róòmù “fi tipátipá gbéṣẹ́ fún” pé kó gbé òpó igi oró Jésù.—Mátíù 27:32.

Ìwé àwọn rábì pẹ̀lú sọ̀rọ̀ nípa àṣà búburú yìí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fipá mú rábì kan láti bá wọn kó ewébẹ̀ lọ sí ààfin kan. Wọ́n lè kó àwọn òṣìṣẹ́ kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá wọn, kí wọ́n gbéṣẹ́ mìíràn fún wọn, kí wọ́n sì sọ fún ọ̀gá àwọn òṣìṣẹ́ náà pé kó máa san owó oṣù wọn lọ. Wọ́n lè fipá gba màlúù tàbí àwọn ẹran tó máa ń kó ẹrù. Wọ́n sì lè máà dá wọn padà. Tí wọ́n bá tiẹ̀ dá wọn padà rárá, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti lo àwọn ẹran náà débi tí wọn ò fi ní lè ṣe iṣẹ́ mìíràn mọ́. O lè wá rídìí tí fífi ipá gba ohun tí ẹnì kan ní láti lò ó fúngbà díẹ̀ ò fi yàtọ̀ sí gbígba àwọn nǹkan ọ̀hún lọ́wọ́ rẹ̀ pátápátá. Abájọ tí òwe àwọn Júù kan fi sọ pé “Angareia [tó túmọ̀ sí fífi ipá múni ṣiṣẹ́] kò yàtọ̀ sí ikú.” Òpìtàn kan sọ pé: “Odindi abúlé kan lè run pátápátá táwọn èèyàn bá fipá gba àwọn màlúù tó máa ń túlẹ̀ tí wọ́n sì lò wọ́n fún iṣẹ́ tó yẹ kí àwọn ẹranko tó máa ń fa ẹrù ṣe.”

Ẹ ò rí i pé inú àwọn èèyàn ò dùn sí irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, àgàgà bí wọ́n ṣe máa ń fi ẹ̀mí ìgbéraga àti ìwà ìrẹ́nijẹ mú àwọn èèyàn ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Nítorí pé àwọn Júù kórìíra àwọn Kèfèrí tó ń ṣàkóso wọn, inú wọn kì í dùn rárá nítorí agbára tí wọ́n fi máa ń mú wọn ṣe irú iṣẹ́ àṣekúdórógbó bẹ́ẹ̀. Kò sí òfin kankan tó sọ fún wa nípa bí ibi tí wọ́n lè fipá mú ẹnì kan gbé ẹrù dé ṣe gbọ́dọ̀ jìnnà tó. Àmọ́, ó dà bíi pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í fẹ́ gbé ẹrù kọjá ibi ti òfin sọ pé wọ́n lè gbé e dé.

Àṣà yìí gan-an ni Jésù ń tọ́ka sí nígbà tó sọ pé: “Bí ẹnì kan tí ó wà ní ipò ọlá àṣẹ bá sì fi tipátipá gbéṣẹ́ fún ọ fún ibùsọ̀ kan, bá a dé ibùsọ̀ méjì.” (Mátíù 5:41) Ọ̀rọ̀ tí kò mọ́gbọ́n dání rárá ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ka ohun tó sọ yẹn sí. Àmọ́, kí ni Jésù ní lọ́kàn?

Ohun Tó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Ṣe

Ohun tí Jésù ń sọ fáwọn olùgbọ́ rẹ̀ ni pé tí ẹnì kan tó ní ọlá àṣẹ bá fipá mú wọn láti ṣe iṣẹ́ kan tí kò lòdì sófin, ó yẹ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ náà tinútinú, kí wọ́n má sì bínú rárá. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á máa san “àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì.” Àmọ́, wọn ò gbọ́dọ̀ gbàgbé ojúṣe wọn láti san “àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” aMáàkù 12:17.

Láfikún sí i, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga, nítorí kò sí ọlá àṣẹ kankan bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; àwọn ọlá àṣẹ tí ó wà ni a gbé dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹni tí ó bá tako ọlá àṣẹ ti mú ìdúró kan lòdì sí ìṣètò Ọlọ́run. . . . Bí ìwọ bá ń ṣe ohun tí ó burú, kí o máa bẹ̀rù: nítorí kì í ṣe láìsí ète ni ó gbé idà.”—Róòmù 13:1-4.

Ó túmọ̀ sí pé Jésù àti Pọ́ọ̀lù gbà pé ọba kan tàbí ìjọba kan lẹ́tọ̀ọ́ láti fìyà jẹ àwọn tí kò bá pa àṣẹ wọn mọ́. Àmọ́, irú ìyà wo ni wọ́n lè fi jẹ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀? Onímọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì nì, Epictetus, tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kìíní sí ìkejì Sànmánì Tiwa bá wa dáhùn ìbéèrè yẹn, ó ní: “Tí ohun àìròtẹ́lẹ̀ kan bá ṣẹlẹ̀, tí sójà kan sì gba ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, jẹ́ kó máa mú un lọ. Má ṣe bá a fàjàngbọ̀n o, má sì ṣàròyé, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, á fi lílù ba tiẹ̀ jẹ́, wàá sì tún pàdánù kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ.”

Àmọ́ ṣá o, àwọn àkókò kan wà táwọn Kristẹni ti rí i pé ẹ̀rí ọkàn àwọn ò lè jẹ́ káwọn ṣe ohun tíjọba sọ pé káwọn ṣe. Irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ láyé ìgbàanì, ó sì tún ń ṣẹlẹ̀ lákòókò tá a wà yìí pẹ̀lú. Ohun tó máa ń tẹ̀yìn rẹ̀ jáde sì máa ń burú gan-an nígbà míì. Wọ́n ti tìtorí bẹ́ẹ̀ dá ẹjọ́ ikú fáwọn Kristẹni kan. Àwọn mìíràn ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lọ́gbà ẹ̀wọ̀n nítorí pé wọ́n kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú ohun tí wọ́n gbà pé ó lè sọ àwọn di apá kan ayé. (Aísáyà 2:4; Jòhánù 17:16; 18:36) Àwọn àkókò mìíràn sì wà táwọn Kristẹni rí i pé àwọn lè ṣe ohun tíjọba sọ pé káwọn ṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni kan ti rí i pé ẹ̀rí ọkàn wọn lè gbà wọ́n láyè láti ṣe àwọn iṣẹ́ kan lábẹ́ ìjọba alágbádá, ìyẹn àwọn iṣẹ́ tó máa wúlò fún ìlú. Iṣẹ́ náà lè jẹ́ iṣẹ́ ṣíṣèrànwọ́ fáwọn àgbàlagbà tàbí àwọn aláàbọ̀ ara, ó lè jẹ́ iṣẹ́ panápaná, iṣẹ́ títún etíkun ṣe, ṣíṣe iṣẹ́ láwọn ọgbà ìṣeré, ṣíṣe iṣẹ́ nínú igbó, tàbí láwọn ilé ìkówèésí, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ohun kan tó dájú ni pé, bí nǹkan ṣe ń rí ní orílẹ̀-èdè kan yàtọ̀ sí ti orílẹ̀-èdè mìíràn. Nítorí náà, Kristẹni kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́ bá sọ, kó tó lè pinnu bóyá kóun ṣe iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fóun tàbí kóun má ṣe é.

Bá A Dé Ibùsọ̀ Méjì

Kì í ṣe ìgbà tí ìjọba bá ní ká ṣe ohun kan nìkan la lè tẹ̀ lé ìlànà tí Jésù fi kọ́ni pé ká fi tinútinú ṣe iṣẹ́ tí kò lòdì. A tún lè tẹ̀ lé ìlànà náà nínú gbogbo ohun tó bá da àwa àtàwọn ẹlòmíràn pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ẹnì kan tó láṣẹ lórí rẹ sọ fún ọ pé kó o ṣe iṣẹ́ kan tí kò wù ọ́ ṣe, àmọ́ tí iṣẹ́ ọ̀hún kò lòdì sófin Ọlọ́run, kí lò máa ṣe? O lè máa rò pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ fẹ́ gba àkókò rẹ, tàbí pé ó fẹ́ máa lò ẹ́ bí omi òjò, kó o wá tìtorí bẹ́ẹ̀ máa bínú. Ìyẹn sì lè sọ ẹ̀yìn méjèèjì dọ̀tá ara yín. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, tó o bá gbà láti ṣe iṣẹ́ náà, àmọ́ tó o wá ń fi ìbínú ṣe é, o lè di ẹni tí kò láyọ̀ mọ́. Kí wá ní ṣíṣe? Ohun tí Jésù sọ yẹn gan-an ni kó o ṣe. Bá a dé ibùsọ̀ méjì. Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ni pé, kì í ṣe pé kó o ṣe ohun tó ní kó o ṣe yẹn nìkan àmọ́ kó o tún ṣe kọjá ibi tó sọ pé kó o ṣe é dé pàápàá. Ṣe é tọkàntọkàn. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní máa ronú pé ńṣe ni onítọ̀hún ń yàn ọ́ jẹ, dípò ìyẹn, wàá rí i pé ohun tí inú rẹ dùn sí lò ń ṣe.

Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé kìkì ohun téèyàn bá fagbára mú wọn ṣe nìkan ni wọ́n máa ń ṣe láyé wọn. Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ò gbà pé àwọn ń gbádùn ayé rárá, gbogbo ìgbà ní nǹkan sì máa ń tojú sú wọn. Àwọn mìíràn sì wà tí wọ́n gbà láti ṣe kọjá ohun téèyàn bá ní kí wọ́n ṣe, tó jẹ́ pé tinútinú ni wọ́n fi máa ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.” Lẹ́nu kan, ọ̀pọ̀ ìgbà lèèyàn máa fúnra rẹ̀ pinnu bóyá kóun bá ẹnì kan dé ibùsọ̀ kan tàbí kóun bá a dé ibùsọ̀ méjì. Ní ti àwọn tí wọ́n máa ń fagbára mú ṣe nǹkan, wọ́n lè máà fẹ́ kí ẹnikẹ́ni yan àwọn jẹ. Ní ti àwọn tó sì máa ń fi ayọ̀ ṣe ohun téèyàn ní kí wọ́n ṣe, inú wọn á máa dùn. Irú èèyàn wo ni ọ́? Ayọ̀ rẹ lè pọ̀ sí i, ó sì lè kẹ́sẹ járí tó o bá fẹ́ràn láti máa ṣe ohun tó ò ń ṣe, tí kì í ṣe pé o kàn ń ṣe é torí pé o ò ríbi yẹ̀ ẹ́ sí tàbí nítorí pé ó wulẹ̀ di dandan fún ọ láti ṣe é.

Tó bá jẹ́ pé ìwọ lo láṣẹ lé àwọn ẹlòmíràn lórí ńkọ́? Ó ṣe kedere pé kì í ṣe ohun tó fi ìfẹ́ hàn bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ìwà Kristẹni pé kí ẹnì kan tó láṣẹ lé àwọn míì lórí máa fagbára mú àwọn èèyàn ṣe nǹkan. Jésù sọ pé: “Àwọn olùṣàkóso orílẹ̀-èdè a máa jẹ olúwa lé wọn lórí, àwọn ènìyàn ńlá a sì máa lo ọlá àṣẹ lórí wọn.” Àmọ́, bó ṣe yẹ káwọn Kristẹni máa hùwà kọ́ nìyẹn. (Mátíù 20:25, 26) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé fífi agbára múni ṣiṣẹ́ lè mú káwọn èèyàn ṣe iṣẹ́ ọ̀hún, àmọ́ tí ẹni tó bẹ èèyàn níṣẹ́ bá lo ohùn jẹ́jẹ́, tí ẹni tí wọ́n bẹ̀ níṣẹ́ náà sì fi ọ̀yàyà àti ọ̀wọ̀ ṣe iṣẹ́ náà, àjọṣe tó wà láàárín wọn á mà dára gan-an o! Dájúdájú, mímúratán láti lọ sí ibùsọ̀ méjì dípò ibùsọ̀ kan ṣoṣo lè mú kí ayé rẹ túbọ̀ dára.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láti rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ohun tó túmọ̀ sí fún Kristẹni kan láti “san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run,” wo Ilé Ìṣọ́nà, May 1, 1996, ojú ìwé 15 sí 20.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]

BÍ WỌ́N ṢE FIPÁ MÚ ÀWỌN ÈÈYÀN ṢIṢẸ́ LỌ́NÀ TÍ KÒ YẸ LÁYÉ ỌJỌ́UN

Òfin tí ìjọba ṣe pé kí wọ́n dáwọ́ àṣà lílo èèyàn nílòkulò dúró ló jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn kan máa ń fipá mú àwọn èèyàn ṣe iṣẹ́ tí kò bójú mu. Ní ọdún 118 ṣáájú Sànmánì Tiwa, Ptolemy Euergetes Kejì ti ilẹ̀ Íjíbítì ṣòfin pé àwọn òṣìṣẹ́ òun “kò gbọ́dọ̀ fipá mú ẹnikẹ́ni tó ń gbé orílẹ̀-èdè náà ṣe iṣẹ́ tó jẹ́ ti àdáni. Bẹ́ẹ̀ ni wọn ò gbọ́dọ̀ fipá gba màlúù wọn láti lò ó fún àǹfààní ti ara wọn.” Ó tún fi kún un pé: “Kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ gba . . . ọkọ̀ ojú omi ẹlòmíràn láti lò ó fún àǹfààní ti ara rẹ̀.” Wọ́n kọ ọ̀rọ̀ kan sára Tẹ́ńpìlì Oasis Ńlá, ní Íjíbítì lọ́dún 49 Sànmánì Tiwa. Ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé aláṣẹ Róòmù kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Vergilius Capito sọ pé àwọn sójà máa ń gba nǹkan lọ́wọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tí kò bófin mu. Ó sì sọ pé “kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ mú ohunkóhun tàbí gba . . . ohunkóhun lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, àyàfi tó bá gba ìwé àṣẹ lọ́dọ̀ mi.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Wọ́n fipá mú Símónì ará Kírénè ṣe iṣẹ́ kan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ló ti ṣẹ̀wọ̀n nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tó lòdì sí òfin Ọlọ́run