Bíbélì Berleburg
Bíbélì Berleburg
ẸGBẸ́ Olùfọkànsìn jẹ́ ẹ̀ya ìsìn kan tó bẹ̀rẹ̀ nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Luther ti ilẹ̀ Jámánì ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún sí ìkejìdínlógún. Àwọn èèyàn fi àwọn kan nínú ẹgbẹ́ yìí ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ìgbàgbọ́ wọn, kódà wọ́n ṣe inúnibíni sí wọn. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀mọ̀wé inú Ẹgbẹ́ Olùfọkànsìn yìí fi sá lọ sílùú Berleburg tó wà ní nǹkan bí àádọ́jọ kìlómítà sí ìhà àríwá ìlú Frankfurt am Main. Ọ̀tọ̀kùlú ọmọ ìbílẹ̀ ibẹ̀ kan tí kò fi ọ̀ràn ẹ̀sìn ṣeré rárá ló gbà wọ́n sọ́dọ̀. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Count Casimir von Wittgenstein Berleburg. Bí àwọn oníwàásù àtàwọn ọ̀mọ̀wé wọ̀nyí ṣe wà ní ìlú Berleburg ló jẹ́ kí ìtumọ̀ Bíbélì tuntun kan yọjú. Bíbélì náà la wá mọ̀ sí Bíbélì Berleburg lóde òní. Báwo ni ìtumọ̀ Bíbélì náà ṣe bẹ̀rẹ̀?
Ọ̀kan lára àwọn tó sá lọ sílùú Berleburg ni Johanne Haug. Ó ní láti sá kúrò nílé rẹ̀ tó wà nílùú Strasbourg nítorí pé àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ibẹ̀ ò fẹ́ kó máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn. Ọ̀mọ̀wé gidi ni Haug, ó sì tún ní ẹ̀bùn sísọ èdè púpọ̀. Ó sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún àwọn ọ̀mọ̀wé bíi tirẹ̀ tí wọ́n jọ wà nílùú Berleburg. Ó sọ fún wọn pé òun “fẹ́ túmọ̀ Bíbélì kan tí kò ní àmúlùmálà kankan, kí òun lè ṣàtúnṣe Bíbélì tí Luther túmọ̀, kóun lè mú kí ìtumọ̀ náà bá ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ gẹ́lẹ́ mu, kó sì tún bá ohun tó túmọ̀ sí ní ti gidi mu.” (Die Geschichte der Berlenburger Bibel [Ìwé Ìtàn Bíbélì Berleburg]) Ohun tó ní lọ́kàn gan-an ni pé ó fẹ́ ṣe Bíbélì kan tó máa ní àwọn àlàyé kan nínú, tó sì máa yé àwọn gbáàtúù. Haug bẹ àwọn ọ̀mọ̀wé tó wà làwọn orílẹ̀ èdè mìíràn nílẹ̀ Yúróòpù pé kí wọ́n ràn òun lọ́wọ́. Ogún ọdún gbáko ni iṣẹ́ ìtumọ̀ náà sì gbà á. Ọdún 1726 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ Bíbélì Berleburg jáde. Ìdìpọ̀ mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Bíbélì náà wà nítorí pé àwọn àlàyé inú rẹ̀ pọ̀ gan-an.
Ó hàn gbangba pé àwọn kókó tó gbàfiyèsí wà nínú Bíbélì Berleburg yìí. Bí àpẹẹrẹ, Ẹ́kísódù 6:2, 3 kà pé: “Síwájú sí i, Ọlọ́run bá Mósè sọ̀rọ̀, ó sì sọ fún un pé: Èmi ni OLÚWA! Mo fara hàn Ábúráhámù, Ísákì, àti Jékọ́bù ní Ọlọ́run tó lágbára láti ṣe ohun gbogbo: àmọ́ orúkọ mi JÈHÓFÀ ni wọn kò fi mọ̀ mí.” Àlàyé kan tó wà nínú Bíbélì náà kà pé: “Orúkọ náà JÈHÓFÀ . . . . , jẹ́ orúkọ tá a yà sọ́tọ̀ tàbí orúkọ tá a polongo rẹ̀.” Orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gan-an yìí, ìyẹn Jèhófà, tún fara hàn nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ṣàlàyé Ẹ́kísódù 3:15 àti Ẹ́kísódù 34:6.
Bí Bíbélì Berleburg ṣe di ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Bíbélì ilẹ̀ Jámánì tó lo orúkọ náà Jèhófà nìyẹn. Yálà kí wọ́n lo orúkọ náà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tàbí nínú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tàbí nínú àwọn àlàyé mìíràn tó wà nínú rẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn ìtumọ̀ ti òde òní tó fún orúkọ Ọlọ́run ní ọ̀wọ̀ tó yẹ ẹ́ ni Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.