Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kó O Máa Fi Ara Ẹ Wé Àwọn Ẹlòmíì?
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kó O Máa Fi Ara Ẹ Wé Àwọn Ẹlòmíì?
TA LÓ lè sọ pé òun ò tíì rí ẹni kan tó lẹ́wà, tó gbajúmọ̀, tí nǹkan si tètè ń yé, tàbí tó ń gba máàkì nílé ìwé ju òun lọ rí? Ó ṣeé ṣe kára àwọn míì le ju tiwa lọ, tàbí kíṣẹ́ wọn dáa ju tiwa lọ, wọ́n sì lè máa mókè jù wá lọ nínú àwọn nnkan tí wọ́n ń dáwọ́ lé, tàbí kí wọ́n lọ́rẹ̀ẹ́ jù wa lọ. Wọ́n lè ní dúkìá tó pọ̀ ju tiwa, tàbí kí wọ́n lówó jù wa, tàbí kí mọ́tò wọn tuntun ju tiwa, tàbí kó dà bíi pé wọ́n láyọ̀ jù wa lọ. Tá a bá rí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, ṣé ó wá yẹ ká máa fi ara wa wé wọn? Ǹjẹ́ a tiẹ̀ lè ṣeé ká máà fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì? Kí nìdí tó fi yẹ kí Kristẹni yẹra fún irú nǹkan bẹ́ẹ̀? Àti pé báwo la ṣe lè nítẹ̀ẹ́lọ́rùn láìjẹ́ pé à ń fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì?
Ohun Tó Lè Mú Ká Fi Àwọn Ẹlòmíràn Wé Ara Wa àti Ìgbà Tá A Lè Ṣe Bẹ́ẹ̀
Ọ̀kan lára ohun tó lè mú káwọn èèyàn máa fi àwọn ẹlòmíràn wé ara wọn ni pé ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọyì ara wọn. Àwọn èèyàn sábà máa ń fẹ́ láti ṣe àṣeyọrí bíi ti ojúgbà wọn. Ìdí mìíràn tó lè mú ká máa fi ẹlòmíràn wé ara wa ni pé ìyẹn ò ní jẹ́ ká ro ara wa pin, á jẹ́ ká mọ àwọn ohun tá a lè ṣe àtàwọn ohun tágbára wa ò gbé. A kì í ṣaláìrí ohun táwọn ẹlòmíràn ti gbé ṣe. Tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá sì jẹ́ ojúgbà wa, tí wọ́n sì ti ṣe àwọn nǹkan kan táwa ò tíì ṣe, a lè bẹ̀rẹ̀ sí i ronú pé kò sí nǹkan tí wọ́n ṣe táwa náà ò lè ṣe.
Àwọn tó bá jẹ́ ojúgbà kan náà ló sábà máa ń fi ara wọn wéra, bíi ọkùnrin sọ́kùnrin tàbí obìnrin sóbìnrin, tàbí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹgbẹ́, tàbí àwọn tí wọ́n wà nípò kan náà láwùjọ tàbí àwọn tí wọ́n mọra wọn. A kì í sábà fi ara wa wé ẹni tá a mọ̀ pé ipò rẹ̀ ga ju tiwa lọ fíìfíì. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́bìnrin kan ò ní fẹ́ fi ara rẹ̀ wé arẹwà kan tí gbogbo ayé mọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè máa fi ara wé ojúgbà rẹ̀ nílé ìwé. Bákan náà, a ò lè rí arẹwà kan tó gbajúmọ̀ kó máa fi ara rẹ̀ wé ọ̀dọ́bìnrin kan.
Kí làwọn ohun táwọn kan lè ní tó lè mú kéèyàn máa fẹ́ fi ara wé wọn? Dúkìá tàbí ẹ̀bùn àbínibí èyíkéyìí táwọn èèyàn bá kà sí ohun pàtàkì láwùjọ ni, irú bíi làákàyè, ẹwà, ọlà, tàbí aṣọ. Àmọ́, ẹni tó bá ní nǹkan tá a nífẹ̀ẹ́ sí la lè fẹ́ láti máa fi ara wa wé. Bí àpẹẹrẹ, a lè máà fẹ́ fi
ara wa wé ẹni tó ní ọ̀pọ̀ fọ́tò jọ sílé tá ò bá nífẹ̀ẹ́ sí fọ́tò yíyà.Onírúurú nǹkan ló lè jẹ́ àbájáde kéèyàn máa fi ara rẹ̀ wé àwọn ẹlòmíì. Ó lè mú kéèyàn soríkọ́ dípò tí ì bá fi ní ìbàlẹ̀ ọkàn, ó sì lè mú kéèyàn kórìíra ẹnì kan tàbí kó máa bínú rẹ̀ dípò tí ì bá máa fi sapá láti dà bí onítọ̀hún. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò dáa rárá, kò tiẹ̀ yẹ Kristẹni.
Fifi Àwọn Ẹlòmíràn Wé Ara Wa Lọ́nà Tí Kò Tọ́
Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbìyànjú láti yọrí ọlá ju ẹni tí wọ́n ń fi ara wọn wé máa ń gbé ẹ̀mí ìdíje wọ̀ bí ẹ̀wù. Nítorí pé wọn ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni jù wọ́n lọ, wọn kì í nítẹ̀ẹ́lọ́rùn àfìgbà tí ọwọ́ wọn bá tẹ ohun tí wọ́n ń wá. Téèyàn bá ní irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́, èèyàn ò lè gbádùn wọn. Kò sì sí bí ẹni tó bá ń bá wọn ṣọ̀rẹ́ ò ṣe ní máa ní ìdààmú ọkàn. Yàtọ̀ sí pé àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wọn kì í tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì, èyí tó sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa, torí irú ìwà tí wọ́n ní yẹn lè mú káwọn ẹlòmíràn máa rò pé àwọn ò já mọ́ ohunkóhun.—Mátíù 18:1-5; Jòhánù 13:34, 35.
Ká sòótọ́, tá a bá ń mú káwọn èèyàn máa ronú pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan, ó lè bà wọ́n nínú jẹ́. Òǹkọ̀wé kan sọ pé, “ẹ̀dùn ọkàn wa túbọ̀ máa ń pọ̀ sí i tá a bá rí i pé àwọn tá a jọ wa nípò kan náà ti ní àwọn nǹkan tó ń wù wá láti ní.” Nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ẹ̀mí ìdíje máa ń jẹ́ kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèlara ẹni ẹlẹ́ni nítorí àwọn ohun ìní, aásìkí, ipò, iyì, àǹfààní àtàwọn ohun mìíràn tí onítọ̀hún ní. Níkẹyìn, a óò wá bẹ̀rẹ̀ sí í lé onítọ̀hún burúkú-burúkú, gbogbo ohun tó bá ní ni a óò fẹ́ láti ní. Bíbélì sì sọ pé kò dára láti máa ‘ru ìdíjé sókè.’—Gálátíà 5:26.
Ńṣe làwọn tó lẹ́mìí ìdíje máa ń bẹnu àtẹ́ lu àwọn tí wọ́n ń fi ara wọn wé, kí wọ́n lè gbayì láwùjọ. Èèyàn lè má ka irú ìwà bẹ́ẹ̀ sí nǹkan tó burú níbẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ẹni yẹn ò bá bá ara rẹ̀ wí, ó lè mú kó hùwà ìkà tó burú jáì. Ronú nípa àwọn àkọsílẹ̀ méjì yìí tó wà nínú Bíbélì, èyí tó dá lórí ìlara.
Dúkìá tí Ísákì ní pọ̀ gan-an nígbà tó ń gbé láàárín àwọn Filísínì, Ọlọ́run bù kún un, ó ní “àwọn agbo àgùntàn àti ọ̀wọ́ màlúù àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ìránṣẹ́, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Filísínì fi ń ṣe ìlara rẹ̀.” Ohun tí wọ́n ṣe ni pé wọ́n rọ́ yẹ̀pẹ̀ dí àwọn kànga tí Ábúráhámù bàbá Ísákì gbẹ́, ẹ̀yìn ìyẹn lọba wọn ní kí Ísákì fi àdúgbò àwọn sílẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 26:1-3, 12-16) Ìlara tí wọ́n ní tí wá sọ wọ́n di ìkà èèyàn. Ara wọn ò gbà á mọ́ bí wọ́n ṣe ń wo Ísákì láàárín wọn tó ń gbádùn aásìkí rẹ̀.
Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ìgbà náà ni Dáfídì fakọ yọ lójú ogun. Àwọn obìnrin Ísírẹ́lì sì ṣayẹyẹ ìjagunmólú rẹ̀ yìí, wọ́n kọrin pé: “Sọ́ọ̀lù ti ṣá ẹgbẹẹgbẹ̀rún tirẹ̀ balẹ̀, àti Dáfídì ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá tirẹ̀.” Bó ti lẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi apá kan nínú orin ọ̀hún yin Sọ́ọ̀lù, síbẹ̀ ìwọ̀sí gbáà ló ka bí wọ́n ṣe ń fi òun wé Dáfídì sí, èyí sì mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í jowú kíkorò nínú ọkàn rẹ̀. Ìgbà yẹn ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrò ìkà sí Dáfídì. Kò pẹ́ rárá sígbà yẹn tó fi gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ láti pa Dáfídì, ó sì tún sapá lónírúurú ọ̀nà láti pa á lẹ́yìn náà. Àbẹ́ ò rí i pé ìlara lè mú kéèyàn hùwà ìkà tó burú jáì!—1 Sámúẹ́lì 18:6-11.
Nítorí náà, tí fifi àwọn ẹlòmíràn wé ara wa bá ti ń mú ká máa ṣe ìlara wọn tàbí ká máa jowú àṣeyọrí àti àǹfààní tí wọ́n ní, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra! Irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ léwu torí pé kò bá èrò Ọlọ́run mu. Àmọ́ ká tó ṣàlàyé bá a ṣe lè yẹra fún àwọn ìwà wọ̀nyẹn, ẹ jẹ́ ká wó nǹkan míì tó lè mú ká máa fi ara wa wé àwọn ẹlòmíràn.
Yíyẹ Ara Wa Wò àti Níní Ìtẹ́lọ́rùn
Ó ṣọ̀wọ́n ká tó rí ẹnì kan tó máa dúró síwájú dígí kó sì máa bi ara rẹ̀ làwọn ìbéèrè bíi: ‘Ǹjẹ́ olóye èèyàn ni mí? Ǹjẹ́ mo lẹ́wà? Ǹjẹ́ mo jáfáfá? Ǹjẹ́ ara mi le? Ǹjẹ́ àwọn èèyàn máa ń bọ̀wọ̀ fún mi? Ǹjẹ́ àwọn èèyàn fẹ́ràn mi? Báwo ni mo sì ṣe ni àwọn ànímọ́ wọ̀nyí tó?’ Síbẹ̀, òǹkọ̀wé kan sọ pé, “ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ìbéèrè
báwọ̀nyí máa ń wá sí wa lọ́kàn tòun ti ìdáhùn, ó kàn jẹ́ pé ìdáhùn ọ̀hún lè máà fi bẹ́ẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn ni.” Ẹni tí ò dá ara rẹ̀ lójú pé òun lè ní àwọn nǹkan wọ̀nyẹn lè ronú nípa wọn síbẹ̀ kó máà ní ẹ̀mí ìlara kankan kí ọ̀rọ̀ owú jíjẹ má tiẹ̀ wá sọ́kàn rẹ̀ rárá. Ńṣe ló wulẹ̀ ń ronú nípa àwọn nǹkan tó ní. Kò sì sóhun tó burú nínú ìyẹn. Àmọ́, ọ̀nà tó yẹ ká gbà ṣe ìyẹn kì í ṣe láti máa fi ara wé àwọn ẹlòmíràn.Ẹ̀bùn tí olúkúlùkù wa ní yàtọ̀ síra, ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì fà á. Dandan ni ká rí àwọn kan tó mọ nǹkan ṣe jù wá lọ. Dípò tá a ó fi máa ṣe ìlara wọn, ńṣe ló yẹ ká fi ìlànà òdodo Ọlọ́run díwọ̀n ohun tá à ń ṣe. Ìlànà yìí ló sì máa tọ́ wa sọ́nà láti mọ ohun tó tọ́ tó sì dára. Ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa jẹ́ ló ṣe pàtàkì lójú Jèhófà. Kì í fi wá wé ẹnikẹ́ni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn.”—Gálátíà 6:4.
Bá A Ṣe Lè Gbógun Ti Ìlara
A gbọ́dọ̀ sapá gidi gan-an ká tó lè dènà ẹ̀mí ìlara nítorí pé aláìpé ni gbogbo wa. Òótọ́ la mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú,” àmọ́ kì í rọrùn láti ṣe é. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ dídá máa ń wá sí òun lọ́kàn ìyẹn ló fi ní láti ‘lu ara rẹ̀ kíkankíkan, tó sì darí rẹ̀ bí ẹrú.’ (Róòmù 12:10; 1 Kọ́ríńtì 9:27) Ní tiwa, ìyẹn lè gba pé ká kọ ìrònú tó bá jẹ́ ti ẹ̀mí ìbánidíje sílẹ̀ ká sì fi èyí tó ń gbéni ró rọ́pò rẹ̀. A ní láti gbàdúrà, ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ “láti má ṣe ro ara [wa] ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.”—Róòmù 12:3.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì àti ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tá a kọ́ tún lè ṣèrànwọ́. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa Párádísè tí Ọlọ́run ṣèlérí fún wa lọ́jọ́ iwájú. Ibẹ̀ ni gbogbo wa ti máa ní àlàáfíà, tí a óò ní ìlera tó dáa, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ, ilé tó tura, àti iṣẹ́ tó fini lọ́kàn balẹ̀. (Sáàmù 46:8, 9; 72:7, 8, 16; Aísáyà 65:21-23) Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tún máa ronú àtibá ẹlòmíràn díje? Rárá o. Kò ní sídìí kankan téèyàn fi ní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Òótọ́ ni pé Jèhófà ò tíì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nígbà yẹn, ṣùgbọ́n ó bọ́gbọ́n mu láti ronú pé olúkúlùkù yóò máa ṣe ohun tó bá nífẹ̀ẹ́ sí. Ẹnì kan lè sọ pé ẹ̀kọ́ nípa ìràwọ̀ lòun fẹ́ gbájú mó, kí ẹlòmíì sì sọ pé aṣọ lòun fẹ́ máa hun. Kí ló máa wá mú kẹ́nì kan máa ṣe ìlara ẹnì kejì? Ìṣírí ni ìgbòkègbodò ọmọnìkejì wa máa jẹ́ fún wa dípò kó máa mu wa bínú. Ẹ̀mí ìbánidíje á ti di ohun àtijọ́.
Tí irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ bá wù wá, ǹjẹ́ kò yẹ ká máa fi ànímọ́ yìí kọ́ra láti ìsinsìnyí? A ti ń gbádùn párádísè tẹ̀mí báyìí, níbi tí kò ti sí ìṣòro bí irú èyí tó wà nínú ayé tó yí wa ká. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé kò ní sí ẹ̀mí ìbánidíje nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run, ìsinsìnyí ló yẹ ká yẹra fún un pátápátá.
Àmọ́, ṣé ó burú ká máa fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì? Àbí àwọn ìgbà kan wà tó bójú mu láti ṣe bẹ́ẹ̀?
Àwọn Ẹni Tá À Lè Fi Ara Wa Wé
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti fi ara wọn wé àwọn ẹlòmíì tíyẹn sì wá sọ wọ́n dẹni tó ń bínú tàbí kí wọ́n sorí kọ́, tí kò sì yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Nítorí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ jẹ́ aláfarawé àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.” (Hébérù 6:12) Bí a bá sapá láti fìwà jọ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ìgbà láéláé, ìyẹn á ṣe wá láǹfààní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé fífi àwọn ẹlòmíràn wé ara ẹni nìyẹn náà, síbẹ̀ ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn àpẹẹrẹ tó yááyì tá a lè fara wé, ó sì lè jẹ́ ká mọ ibi tó yẹ ká ti ṣàtúnṣe.
Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ ti Jónátánì yẹ̀ wò. Tá a bá wò ó dáadáa, a óò rí i pé Jónátánì ò jayò pa tó bá ṣèlara. Jónátánì ni àrẹ̀mọ Sọ́ọ̀lù Ọba Ísírẹ́lì. Ó sì lè máa retí pé bí bàbá òun bá kú òun loyè kàn. Àmọ́, Dáfídì ni Jèhófà yan. Ọgbọ̀n ọdún sì ni Jónátánì fi ju Dáfídì lọ. Dípò tí Jónátánì ì bá fi di kùnrùngbùn, ohun tẹ́nì kan ò retí ló ṣe, ó di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn Dáfídì ó sì kọ́wọ́ tì í gẹ́gẹ́ bí ọba tí Jèhófà yàn. Lóòótọ́, ẹni tẹ̀mí ni Jónátánì. (1 Sámúẹ́lì 19:1-4) Jónátánì ò ṣe bíi ti bàbá rẹ̀ tó ka Dáfídì sí alábàádíje. Kò fi ojú kéré Dáfídì, kó wá máa sọ pé, “Ó ṣe ni láti jẹ́ Dáfídì ni Jèhófà yàn níbi témi wà?” Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló fara mọ́ ìṣètò náà nítorí ó mọ̀ pé bí Jèhófà ṣe fẹ́ kó rí nìyẹn.
Tí ẹnì kan tá a jọ jẹ́ Kristẹni bá mọ ohun kan ṣe jù wá lọ, kò yẹ ká máa bẹ̀rù bíi pé onítọ̀hún fẹ́ ta wá yọ tàbí pé ó fẹ́ gbapò wa. Ìlara ò yẹ ọmọlúàbí o. Ìfọwọ́sowọ́pọ̀, ìṣọ̀kan, àti ìfẹ́ la fi ń dá àwọn Kristẹni tó bá dàgbà dénú mọ̀ yàtọ̀, kì í ṣe ẹ̀mí ìdíje. Onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Francesco Alberoni sọ pé: “Ìfẹ́ àti ìlara kì í ṣe ọmọ ìyá. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan, bí ayé onítọ̀hún ṣe máa dáa la óò máa wá, tí nǹkan bá sì ṣẹnuure fún un, tó ń yọ̀, àwa náà á bá a yọ̀.” Nítorí náà, tí wọ́n bá fún ẹnì kan láǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ àwa Kristẹni, ohun tó máa fìfẹ́ hàn ni pé ká jẹ́ kó tẹ́ wa lọ́rùn. Ohun tí Jónátánì ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn. Bó ṣe yọrí sí ìbùkún fún Jónátánì, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò jẹ́ ìbùkún fún wa tá a bá kọ́wọ́ ti àwọn tó ń fi ìṣòtítọ́ sìn nípò tí ètò Jèhófà yàn wọ́n sí.
A lè máa tẹ̀ lé àwòkọ́ṣe àwọn Kristẹni bíi tiwa tí wọ́n ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Tá a bá ń fi ara wa wé wọn lọ́nà tó tọ́, ìyẹn á jẹ́ ká lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn. (Hébérù 13:7) Ṣùgbọ́n ó gba ìṣọ́ra kí fífi tá à ń fi ara wa wé wọn má lọ yí padà sí ìlara. Bó bá dà bíi pé ẹni tá à ń tẹ̀ lé àwòkọ́ṣe rẹ̀ ti fi wá sílẹ̀ sẹ́yìn, tá a wá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹnu àtẹ́ lù ú lẹ́yìn, a jẹ́ pé àfarawé ti di ìlara nìyẹn o.
Kò sí ẹ̀dá èèyàn aláìpé tó lè jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ pípé. Ìdí nìyẹn tí Ìwé Mímọ́ fi sọ pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” Bákan náà “Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (Éfésù 5:1, 2; 1 Pétérù 2:21) Àwọn ànímọ́ Jèhófà àti ti Jésù, bí ìfẹ́, ọ̀yàyà, ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò, àti ìrẹ̀lẹ̀ ló yẹ ká sapá láti fara wé. Àwọn ànímọ́ wọn, ìdí tí wọ́n fi ń ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe, àti ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà ṣe nǹkan ló yẹ ká máa fi wéra pẹ̀lú bá a ṣe jẹ́. Irú ìfiwéra bẹ́ẹ̀ ló máa jẹ́ kí ayé wa nítumọ̀, ká mọ ọ̀nà tó tọ́, ká dúró ṣinṣin, ká wà láìséwu ká sì lè di Kristẹni tó dàgbà dénú lọ́kùnrin àti lóbìnrin. (Éfésù 4:13) Bí a bá pọkàn pọ̀ sórí sísa gbogbo ipá wa láti fara wé àpẹẹrẹ pípé ti Jèhófà àti ti Jésù, ó dájú pé a ò ní máa fi bẹ́ẹ̀ fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28, 29]
Ọba Sọ́ọ̀lù ṣe ìlara Dáfídì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Jónátánì ò fìgbà kankan ka Dáfídì tó kéré sí i lọ́jọ́ orí sí ẹni tó ń bá òun dupò