Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ló Máa Bọ́ Gbogbo Ayé?

Ta Ló Máa Bọ́ Gbogbo Ayé?

Ta Ló Máa Bọ́ Gbogbo Ayé?

ÀWỌN ìṣirò tó wá láti ọ̀dọ̀ Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Oúnjẹ Lágbàáyé, èyí tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè dá sílẹ̀ kí oúnjẹ bàa lè wà fún mùtúmùwà, fi hàn pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rin mílíọ̀nù èèyàn ní kì í róúnjẹ jẹ. Àwọn ọmọdé ló sì pọ̀ jù nínú wọn. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni Àjọ yẹn sọ pé àwọn ohun àmúṣọrọ̀ àti àkókó tó yẹ kí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà fi bójú tó ìṣòro yìí ni wọ́n fi ń gbọ́ tàwọn ìṣòro míì, irú bí ọ̀ràn àwọn apániláyà. Èyí tó tiẹ̀ tún wá mú kí ìṣòro ọ̀hún túbọ̀ lékenkà ni àwọn àrùn tó máa ń ranni tó ń gbilẹ̀ sí i. Ìwé kan tí àjọ náà ń tẹ̀ jáde, tí wọ́n ń pè ní Global School Feeding Report, sọ nípa àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà ti àrùn éèdì tí gbilẹ̀, pé: “Gbogbo àwọn òbí ọlọ́mọ ni àrùn éèdì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa tán ní rèwerèwe. Àwọn ọmọ tí wọ́n fi sílẹ̀ ló ń fúnra wọn wá àtijẹ àtimu kiri. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn ni kò mọ iṣẹ́ àgbẹ̀, wọn ò sì mọ iṣẹ́ ilé kankan tọ́mọ máa ń kọ́ lọ́dọ̀ àwọn òbí.”

Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Oúnjẹ Lágbàáyé ti ṣe ètò kan. Ohun tí ètò náà sì wà fún ni láti máa fún àwọn ọmọ ilé ìwé ní oúnjẹ, ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan lóòjọ́. Yàtọ̀ sí pé wọ́n ń lo ètò náà láti dín ebi kù, wọ́n tún ń tipasẹ̀ ètò náà kọ́ àwọn èwe bí wọ́n ṣe lè dènà àrùn éèdì àti kòkòrò tó ń fa àrùn náà.

Àwọn ọmọdé ti ń rí oúnjẹ jẹ láwọn ibi tí wọ́n ti ń tẹ̀ lé ètò tá à ń wí yìí. Kódà wọ́n ti kọ́ wọn ní ìmọ́tótó ara, wọ́n tún ṣe àwọn ìrànwọ́ míì fún wọn pẹ̀lú. Wọ́n tún wá rí i pé àrùn éèdì àti kòkòrò tó ń fa àrùn náà ti dín kù làwọn ibi táwọn èèyàn ti kiwọ́ ìwà pálapàla bọlẹ̀.

Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé kò sí báwọn èèyàn ṣe lè sapá tó tí wọ́n lè yanjú gbogbo ìṣòro náà. Ṣùgbọ́n Bíbélì ṣèlérí tó fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ebi máa kásẹ̀ nílẹ̀ títí láé. Sáàmù 72:16, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀.” Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé, àwọn èèyàn yóò lè sọ nípa Jèhófà Ọlọ́run pé: “Ìwọ ti yí àfiyèsí rẹ sí ilẹ̀ ayé, kí o lè fún un ní ọ̀pọ̀ yanturu . . . Ìwọ ti pèsè ọkà wọn sílẹ̀, nítorí pé bí ìwọ ṣe pèsè ilẹ̀ ayé sílẹ̀ nìyẹn.”—Sáàmù 65:9.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

WFP/Y. Yuge