Àǹfààní Tó Wà Nínú Yíyanjú Aáwọ̀
Àǹfààní Tó Wà Nínú Yíyanjú Aáwọ̀
EDWARD wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn, Bill sì ń bínú sí i. Ìdí tí Bill fi ń bínú sí Edward ni pé, ní nǹkan bí ogún ọdún ṣáájú àkókò náà, ohun kan tí Edward ṣe ló mú kí Bill pàdánù iṣẹ́ rẹ̀, èyí ló sì fà á tí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn méjì yìí fi pín gaàrí. Orí ìdùbúlẹ̀ àìsàn yìí ni Edward ti wá ń bẹ Bill pé kó forí ji òun kí òun lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀rí ọkàn tó ń dá òun lẹ́bi kóun tó kú. Àmọ́, Bill sọ pé láéláé, òun ò ní dárí jì í.
Ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tó kù díẹ̀ kí Bill fúnra rẹ̀ kú, ó wá sọ ìdí tí òun kò fi dárí ji Edward. Ó ní: “Kò yẹ kí Edward ṣe ohun tó ṣe yẹn sí èmi tí mo jẹ́ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ̀. Mo mọ̀ọ́mọ̀ máà fẹ́ bá a ṣọ̀rẹ́ mọ́ lẹ́yìn ogún ọdún tá a ti pínyà ni. . . . Ó ṣeé ṣe kí ohun tí mo ṣe yẹn máà dára o, àmọ́ bọ́ràn náà ṣe rí lára mi ni mo ṣe hùwà yẹn.” a
Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni èdèkòyédè máa ń yọrí sí ohun tó burú tó báyìí, àmọ́ ó sábà máa ń dun àwọn èèyàn wọra ó sì máa ń múnú bí wọn gan-an. Ìwọ ronú nípa ẹnì kan tó ní irú ẹ̀mí tí Edward ní yìí. Tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá mọ̀ pé nǹkan tóun ṣe ti ba nǹkan jẹ́ fẹ́nì kejì, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í dá a lẹ́bi, ó sì lè máa dùn ún pé òun ti pàdánù ọ̀rẹ́ kòríkòsùn òun. Síbẹ̀, á ṣì máa dùn ún nígbà tó bá ro bí ẹni tí òun ṣẹ̀ náà ṣe da òun nù bí omi ìṣanwọ́ tí kò sì bá òun ṣọ̀rẹ́ mọ́.
Àmọ́, ẹni kan tó ní irú ẹ̀mí tí Bill ní yóò máa rò ó pé òun ò jẹ̀bi rárá, inú sì lè máa bí i burúkú-burúkú. Lójú rẹ̀, ńṣe ló máa dà bí pé ọ̀rẹ́ rẹ̀ mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun burúkú tó ṣe sí i yẹn ni. Tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín ẹni méjì, àwọn méjèèjì ló sábà máa ń rò pé ẹnì kejì ló jẹ̀bi. Ohun tó máa ń jẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn méjì dà bí ẹní ń bára wọn jagun nìyẹn.
Ohun ìjà téèyàn ò lè gbúròó rẹ̀ ni wọ́n fi máa ń bára wọn jà, bíi kẹ́nì kan rí i pé ẹnì kejì ń bọ̀, kó yà bàrá síbòmíràn. Bí wọ́n bá sì jọ wà nínú àwùjọ kan, wọn ò ní fọhùn síra wọn. Bí wọ́n bá ríra wọn lókèèrè, wọ́n á fojú para wọn rẹ́ tàbí kí wọ́n fojú kó ara wọn mọ́lẹ̀, kí wọ́n sì wọ́ òṣé ṣààràṣà. Bí wọ́n bá sì bára wọn sọ̀rọ̀, kòbákùngbé ọ̀rọ̀ ni yóò jẹ́, ọ̀rọ̀ tó máa ń dunni wọra bí ìgbà téèyàn bá fẹsẹ̀ gún ìṣó.
Àmọ́ o, bó ṣe dà bí ẹni pé wọ́n ta ko ara wọn pátápátá tó yẹn, àwọn nǹkan kan ṣì wà tí wọ́n á jọ gbà. Àwọn méjèèjì lè mọ̀ pé ìṣòro tó le gan-an làwọn jọ ní, wọ́n sì lè mọ̀ pé kò dára báwọn ò ṣe bára àwọn ṣọ̀rẹ́ mọ́. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ náà máa dun àwọn méjèèjì gan-an, kí wọ́n sì mọ̀ pé ó yẹ káwọn wá nǹkan ṣe sí i káwọn lè padà rẹ́. Àmọ́ ta ló wá máa kọ́kọ́ ṣe nǹkan kan tó máa mú kí àjọṣe wọn padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ kí aáwọ̀ àárín wọn sì yanjú? Kò sẹ́ni tó ṣe tán láti ṣe nǹkan kan nínú àwọn méjèèjì.
Ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, àwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi máa ń bára wọn ṣàríyànjiyàn nígbà míì débi pé wọ́n á bínú síra wọn. (Máàkù 10:35-41; Lúùkù 9:46; 22:24) Lẹ́yìn tí wọ́n ti bára wọn ṣe irú àríyànjiyàn kan bẹ́ẹ̀, Jésù bi wọ́n pé: “Kí ni ẹ ń jiyàn lé lórí lójú ọ̀nà?” Ojú tì wọ́n débi pé ńṣe lẹnu wọn wọhò, kò sẹ́ni tó lè dáhùn nínú wọn. (Máàkù 9:33, 34) Ohun tí Jésù fi kọ́ wọn ló jẹ́ kí wọ́n rẹ́ padà. Títí dòní olónìí, ìmọ̀ràn Jésù àtèyí táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kan fúnni ṣì ń ranni lọ́wọ́ láti parí aáwọ̀ ká sì so ìdè ọ̀rẹ́ tó ti já padà. Jẹ́ ká wo bíyẹn ṣe máa ń ṣẹlẹ̀.
Làkàkà Láti Jẹ́ Kí Aáwọ̀ Yanjú
“Mi ò fẹ́ bá lágbájá sọ̀rọ̀ mọ́. Mí ò tiẹ̀ fẹ́ rí i mọ́ rárá.” Tí irú ọ̀rọ̀ yìí bá ń ti ẹnu rẹ jáde, àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà nísàlẹ̀ yìí fi hàn pé o gbọ́dọ̀ wá nǹkan ṣe sí i.
Jésù kọ́ni pé: “Nígbà náà, bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ.” (Mátíù 5:23, 24) Jésù tún sọ pé: “Bí arákùnrin rẹ bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, lọ fi àléébù rẹ̀ hàn án láàárín ìwọ àti òun nìkan.” (Mátíù 18:15) Yálà ìwọ lo ṣẹ ẹnì kan tàbí ẹnì kan ló ṣẹ̀ ọ́, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí fi hàn pé ó yẹ kí o lọ bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní kánmọ́. “Ẹ̀mí ìwà tútù” ni kó o fi bá a sọ̀rọ̀ náà. (Gálátíà 6:1) O gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé, nígbà tó o bá lọ bá a sọ̀rọ̀, kì í ṣe pé kó o máa lọ wí àwíjàre nípa àṣìṣe tìẹ tàbí kó o máa dọ́gbọ́n sọ fún onítọ̀hún pé kó tọrọ àforíjì, dípò ìyẹn, ńṣe ni kó o jẹ́ kó mọ̀ pé nítorí kí aáwọ̀ tó wà láàárín ẹ̀yin méjèèjì lè yanjú lo ṣe wá. Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn Bíbélì yìí máa ń ṣiṣẹ́?
Ernest jẹ́ ọ̀gá kan ní ilé iṣẹ́ ńlá tó ti ń ṣiṣẹ́. b Nítorí irú iṣẹ́ tó ń ṣe, ọ̀pọ̀ ọdún ló ti fi mójú tó ọ̀rọ̀ tó kan onírúurú èèyàn, àwọn ọ̀rọ̀ náà sì gba ọgbọ́n. Síbẹ̀, àárín òun àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ kò bà jẹ́ rí. Ernest ti rí i pé wẹ́rẹ́ báyìí ni èdèkòyédè máa ń bẹ̀rẹ̀. Ó sọ pé: “Àwọn ìgbà kan wà tí èmi àtàwọn ẹlòmíì ti ṣàìgbọ́ra wa yé. Àmọ́, ńṣe ni mo máa ń lọ bá onítọ̀hún, tí àá sì jọ jókòó sọ̀rọ̀ náà. Tíwọ àtẹnì kan ò bá gbọ́ra yín yé, lọ bá onítọ̀hún fúnra rẹ. Bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà tí àlàáfíà fi tún máa padà wà láàárín yín. Irú ọgbọ́n yìí ò bà á tì rí.”
Alicia ní ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́, onírúurú ibi ni wọ́n sì ti wá. Ó sọ pé: “Nígbà míì tí mo bá sọ ohun kan, tí mo sì wá kíyè sí i pé ó ṣeé ṣe kí n ti ṣẹ ẹnì kan, ṣe ni mo máa ń tọ onítọ̀hún lọ tí màá sì tọrọ àforíjì. Ó ṣeé ṣe kí n ti máa tọrọ àforíjì jù, nítorí pé bí inú ò tiẹ̀ bí ẹni náà, ó ṣì máa ń tẹ́ mi lọ́rùn kí n tọrọ àforíjì. Ìgbà tí mo bá tọrọ àforíjì ló máa tó dá mi lójú pé kò sí ìjà láàárín wa.”
Bó O Ṣe Lè Borí Àwọn Ohun Tó Lè Fa Ìdíwọ́
Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn nǹkan kan lè fa ìdíwọ́ tí kò fi ni ṣeé ṣe láti yanjú èdèkòyédè. Ǹjẹ́ o ti sọ rí pé: “Ṣé èmi ló wá yẹ kí n kọ́kọ́ lọ bá onítọ̀hún láti parí ìjà ni? Òun ló ṣáà dá ìjà ọ̀hún sílẹ̀.” Àbí o ti lọ bá ẹnì kan rí kẹ́ ẹ lè jọ yanjú aáwọ̀ kan, tó sì jẹ́ pé ohun tó jáde lẹ́nu ẹni náà ni pé: “Mi ò ní nǹkan kan bá ẹ sọ”? Ìdí táwọn kan fi máa ń fọ irú èsì bẹ́ẹ̀ ni pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ti dùn wọ́n jù. Òwe 18:19 sọ pé: “Arákùnrin tí a hùwà ìrélànàkọjá sí, ó ju ìlú tí ó lágbára; asọ̀ sì wà tí ó dà bí ọ̀pá ìdábùú ilé gogoro ibùgbé.” Nítorí náà, ro ti bi ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára onítọ̀hún. Tí kò bá dá ẹ lóhùn nígbà tó o lọ bá a, fi sílẹ̀, kó o sì tún gbìyànjú rẹ̀ tó bá ṣe sàà. Ó ṣeé ṣe kí “ìlú tí ó lágbára” ti wà ní ṣíṣí sílẹ̀ nígbà tó o bá tún padà lọ bá a. “Ọ̀pá ìdábùú” tí kò jẹ́ kẹ́ ẹ lè padà rẹ́ sì ti lè kúrò lójú ọ̀nà.
Ohun mìíràn tó tún lè fa ìdíwọ́ ni kéèyàn máa ka títọrọ àforíjì sí ìfara-ẹni-wọ́lẹ̀. Àwọn kan rò pé táwọn bá lọ ń tọrọ àforíjì tàbí táwọn bá ń bá ẹni táwọn jọ ń jà sọ̀rọ̀, àwọn ń fi ara àwọn wọ́lẹ̀ nìyẹn. Lóòótọ́, kò yẹ kéèyàn fi ara rẹ̀ wọ́lẹ̀, àmọ́ tẹ́nì kan bá kọ̀ láti parí ìjà pẹ̀lú ẹlòmíì, ṣé ìyẹn yóò wá fi kún iyì rẹ̀ ni àbí yóò bù ú kù? Àbí ó lè jẹ́ pé ẹ̀mí ìgbéraga ló fà á tó fi ń rò pé ìfara-ẹni wọ́lẹ̀ ni kéèyàn máa tọrọ àforíjì?
Jákọ́bù tó wà lára àwọn tó kọ Bíbélì fi hàn pé ọmọ ìyá ni ẹ̀mí asọ̀ àti ìgbéraga. Lẹ́yìn tó fi hàn pé “ogun” àti “ìjà” ń lọ láàárín àwọn Kristẹni, ó sọ pé: “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” (Jákọ́bù 4:1-3, 6) Báwo ni ìrera tàbí ìgbéraga ṣe máa ń jẹ́ kó ṣòro féèyàn láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ẹlòmíràn?
Ńṣe ni ìgbéraga máa ń tanni jẹ, ó máa ń mú kéèyàn máa rò pé òun sàn ju àwọn ẹlòmíì lọ. Àwọn agbéraga máa ń rò pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣèdájọ́ ọmọnìkejì àwọn. Lọ́nà wo? Tí àwọn àtẹnì kan bá ní èdèkòyédè, wọ́n á ro onítọ̀hún pin pé kò lè tún ìwà rẹ̀ ṣe mọ́. Ìgbéraga máa ń mú káwọn kan máa rò pé kò yẹ káwọn ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ẹni táwọn pẹ̀lú ẹ̀ jọ ní èdèkòyédè, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti pé káwọn ní kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ forí ji àwọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn tí ìgbéraga bá ń yọ lẹ́nu kì í jẹ́ kí ìjà tán nílẹ̀.
Bí igi tí wọ́n gbé sáàárín títì márosẹ̀ ṣe máa ń dí ọkọ̀ lọ́wọ́ eré sísá bẹ́ẹ̀ ni ìgbéraga ṣe máa ń dí ìsapá tẹ́nì kan ń ṣe láti parí ìjà lọ́wọ́. Nítorí náà, tó o bá rí i pé o kò jẹ́ kí ìsapá tẹ́nì kan ń ṣe kí àlàáfíà bàa lè padà wà láàárín òun àti ìwọ kẹ́sẹ járí, ó lè jẹ́ pé ìgbéraga ló fà á. Báwo lo ṣe lè bọ́ ẹ̀wù ìgbéraga sílẹ̀? Bó o ṣe lè ṣe é ni pé kó o jẹ́ kí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ jọba lọ́kàn rẹ.
Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Borí
Bíbélì sọ pé ó yẹ kéèyàn ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀. Ó sọ pé: “Ìyọrísí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.” (Òwe 22:4) Sáàmù 138:6 sọ irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn onírẹ̀lẹ̀ àti àwọn agbéraga, ó ní: “Jèhófà ga, síbẹ̀síbẹ̀, ó ń rí onírẹ̀lẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbé ara rẹ̀ ga fíofío ni òun mọ̀ kìkì láti òkèèrè.”
Àwọn kan sọ pé àbùkù ni téèyàn bá níwà ìrẹ̀lẹ̀. Ó jọ pé èrò yẹn náà làwọn tó ń ṣèjọba ní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ará ìlú ló ń ṣe ohun tí wọ́n bá pa láṣẹ, àwọn alákòóso òṣèlú kì í gbà pé àwọn jẹ̀bi tí wọ́n bá ṣe ohun tí kò dára. Tí alákòóso kan bá fi lè sọ pé “ẹ jọ̀wọ́, ẹ máà bínú,” bóyá ni kò ní jáde nínú ìròyìn. Nígbà tí ẹnì kan tó jẹ́ aláṣẹ ìjọba tẹ́lẹ̀ tọrọ àforíjì lẹ́nu àìpẹ́ yìí nítorí àṣìṣe rẹ̀ nínú àjálù kan tó ṣẹlẹ̀, gàdàgbà-gadagba ni wọ́n gbé ohun tó sọ jáde nínú ìwé ìròyìn.
Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ni kéèyàn rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ tàbí kó má ṣe máa ro ara rẹ ju bó ṣe yẹ lọ. Ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ ìdàkejì ìgbéraga tàbí ìrera. Kéèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kì í ṣe àbùkù, ojú tẹ́nì kan fi ń wo ara rẹ̀ ni, kì í ṣe èrò táwọn Òwe 18:12.
ẹlòmíràn ní nípa rẹ̀. Tẹ́nì kan bá fi ìrẹ̀lẹ̀ gbà pé lóòótọ́ lòun ṣàṣìṣe tó sì tọrọ àforíjì, ìyẹn ò bu ẹni náà kù, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa fi kún iyì rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ṣáájú ìfọ́yángá, ọkàn-àyà ènìyàn a ga fíofío, ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ògo.”—Ohun tí ẹnì kan sọ nípa àwọn olóṣèlú tí kì í tọrọ àforíjì ni pé: “Bóyá ohun tí wọ́n máa ń rò ni pé àwọn èèyàn á ka àwọn sí dọ̀bọ̀sìyẹsà táwọn bá gbà pé àwọn jẹ̀bi. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn tó jẹ́ dọ̀bọ̀sìyẹsà gan-an ló máa ń bẹ̀rù láti sọ pé, ‘Jọ̀wọ́, forí jì mí.’ Àwọn tí wọ́n bá ń gba tẹni rò tí wọ́n sì jẹ́ onígboyà mọ̀ pé àwọn ò lè dẹni ẹ̀tẹ́ táwọn bá gbà pé, ‘àṣìṣe làwọn ṣe.’” Bó ṣe rí fún àwọn tí kì í ṣe olóṣèlú náà nìyẹn o. Tó o bá sapá láti fi ìrẹ̀lẹ̀ rọ́pò ìgbéraga, kò ní ṣòro fún ọ láti parí ìjà tó wà láàárín ìwọ àtẹlòmíì. Kíyè sí bí ìdílé kan ṣe rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.
Àìgbọ́ra-ẹni-yé dá wàhálà sílẹ̀ láàárín Julie àti William àbúrò rẹ̀. Èyí ló mú kí William bẹ̀rẹ̀ sí í bínú sí Julie àti Joseph ọkọ rẹ̀ débi pé kò báwọn da nǹkan pọ̀ mọ́ rárá. Kódà ó dá gbogbo ẹ̀bùn tí Julie àti Joseph ti fún un padà. Nígbà tó yá, ìbínú tó lékenkà wá rọ́pò ìbárẹ́ tó wà láàárín tẹ̀gbọ́n tàbúrò yìí tẹ́lẹ̀.
Ṣùgbọ́n Joseph, ọkọ Julie, pinnu láti lo ìmọ̀ràn tó wà nínú Mátíù 5:23, 24. Ó gbìyànjú láti fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kọ lẹ́tà láti fi tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àbúrò ìyàwó rẹ̀. Joseph tún ní kí ìyàwó òun forí ji William àbúrò rẹ̀. Nígbà tó yá, William rí i pé tọkàntọkàn ni Julie àti Joseph fi fẹ́ kí ìjà náà parí, inú tó ń bí i sì rọlẹ̀. William àti aya rẹ̀ lọ ba Julie àti Joseph, gbogbo wọn sì tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ara wọn, wọ́n dì mọ́ ara wọn, wọ́n sì dọ̀rẹ́ padà.
Tó bá wù ọ́ kí ìjà tó wà láàárín ìwọ àtẹnì kan parí, fi sùúrù fi ohun tí Bíbélì sọ sílò kó o sì gbìyànjú láti yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín ìwọ àtẹni náà. Jèhófà yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. Ohun tí Ọlọ́run sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láyé ọjọ́un yóò wá ṣẹ sí ọ lára, pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò.”—Aísáyà 48:18.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A fa ọ̀rọ̀ yìí yọ látinú Ìwé The Murrow Boys—Pioneers on the Front Lines of Broadcast Journalism, látọwọ́ Stanley Cloud àti Lynne Olson.
b A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Títọrọ àforíjì sábà máa ń jẹ́ káwọn tó ń bára wọn jà padà rẹ́