“Ìgbàgbọ́ Wọn Ò Yẹ̀ Lábẹ́ Àdánwò”
“Ìgbàgbọ́ Wọn Ò Yẹ̀ Lábẹ́ Àdánwò”
NÍ ÌBẸ̀RẸ̀ oṣù April ọdún 1951, ìjọba ilẹ̀ Soviet gbógun ti àwùjọ àwọn Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà lójijì láìṣẹ̀-láìrò ní ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Soviet. Ìjọba ilẹ̀ náà kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sínú ọkọ̀ ojú irin, títí kan àwọn ọmọdé, àwọn aláboyún àtàwọn àgbàlagbà, wọ́n sì wà wọ́n lọ sí Siberia. Ìrìn-àjò tí ń tánni lókun ni nítorí pé ogúnjọ́ gbáko ni wọ́n lò lójú ọ̀nà. Ìgbèkùn tí wọ́n á ti jìyà tí wọ́n á sì máa gbé nínú ìṣẹ́ òun òṣì ni wọ́n kó wọn lọ, ìjọba sì sọ pé wọn ò ní padà wálé mọ́.
Ní oṣù April ọdún 2001, ní ìlú Moscow lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, a ṣe ayẹyẹ àádọ́ta ọdún tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé. Nígbà ayẹyẹ náà, a gbé fídíò kan jáde tó dá lórí bí wọ́n ṣe fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún odidi àádọ́ta ọdún ní ilẹ̀ Soviet Union tẹ́lẹ̀. Nínú fídíò náà, àwọn òpìtàn àtàwọn tí ọ̀rọ̀ ṣojú wọn sọ bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe yè é tí wọ́n sì ń pọ̀ sí i pẹ̀lú bí ìpọ́njú náà ṣe pọ̀ tó.
Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ní Rọ́ṣíà àti láwọn ibòmíràn ló ti wo fídíò náà, àwọn èèyàn níbi gbogbo àtàwọn òpìtàn sì ń gbóṣùbà fún un. Fídíò náà la pè ní, Faithful Under Trials—Jehovah’s Witnesses in the Soviet Union. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà tí wọ́n sì ń gbé ní àgbègbè tí wọ́n kó ọ̀pọ̀ jù lọ ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí lọ ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà sọ ohun tó tẹ̀ lé e yìí:
“Mo gbádùn fídíò náà gan-an. Gbogbo ìgbà tí mo bá ti rí àwọn tó wà nínú ìsìn yín ni mo máa ń gba tiwọn, àmọ́ lẹ́yìn tí mo wo fídíò náà, mo túbọ̀ ní èrò tó dára nípa yín. Fídíò náà kì í ṣe fídíò kúẹ́kúẹ́, àgbà iṣẹ́ lẹ ṣe sínú ẹ̀! Mo gba ti bẹ́ ẹ ṣe gbé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó wà nínú fídíò náà jáde. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ni mò ń lọ tí mi ò sì ní in lọ́kàn láti ṣe ìsìn mìíràn, mo gba tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Màá fẹ́ kí ẹ̀ka ẹ̀kọ́ nípa ìtàn ní Yunifásítì tí mo ti ń ṣiṣẹ́ tọ́jú kásẹ́ẹ̀tì fídíò yìí kan. Kódà, èmi àtàwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ní Yunifásítì ti fi fídíò náà han àwọn akẹ́kọ̀ọ́ a sì fẹ́ fi kún ohun tá à ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́.”—Ọ̀jọ̀gbọ́n Sergei Nikolayevich Rubtsov, olùkọ́ àgbà ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ nípa ìtàn ní ilé ẹ̀kọ́ State Pedagogical University tó wà ní ìpínlẹ̀ Irkutsk, ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.
Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kejì sọ pé: “Ó dáa bí wọ́n ṣe gbé fídíò yìí jáde. Kì í rọrùn láti ṣe fídíò láìfi igbá kan bọ̀kan nínú, àgàgà tó bá jẹ́ pé ọ̀ràn nípa ìfìyàjẹni ni ìtàn téèyàn ń sọ dá lé lórí. Àmọ́ ẹ gbìyànjú gan-an, ẹ sì ṣe fídíò náà dáadáa. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ máa mú àwọn fídíò yín wá fún mi.”—Ọ̀jọ̀gbọ́n Sergei Ilyich Kuznetsov, olùkọ́ àgbà ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ nípa ìtàn ní ilé ẹ̀kọ́ Yunifásítì ìpínlẹ̀ Irkutsk, ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Serbia pẹ̀lú mọyì fídíò náà. Díẹ̀ lára ohun tí wọ́n sọ nígbà tí wọ́n wo fídíò náà ló wà nísàlẹ̀ yìí:
“Lákòókò tí àwọn ohun tí wọ́n fi hàn nínú fídíò náà ń ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ni wọ́n sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ fún nípa ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n wo fídíò náà, wọ́n wá rí i pé ètò
wa kì í ṣe ẹ̀ya ìsìn kan lásán, bí wọ́n ṣe rò tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Àwọn kan tí wọ́n di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé: ‘Ká sọ pé a ò wo fídíò náà ni, a kì bá tí mọ̀ pé àwọn Kristẹni tí wọ́n ti fara da ohun tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ yẹn là ń bá gbé tá a sì jọ ń ṣiṣẹ́!’ Lẹ́yìn tí Ẹlẹ́rìí kan wo fídíò náà, ó sọ pé òun á fẹ́ di aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún.”—Anna Vovchuk tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n kó nígbèkùn lọ sí Siberia.“Nígbà tí mo rí bí ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kan ṣe ń kanlẹ̀kùn ilé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan nínú fídíò náà, ńṣe ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n. Ó dà bí ìgbà tí ọlọ́pàá kan kanlẹ̀kùn ilé wa, mo sì rántí ohun tí màmá mi sọ, pé: ‘Bóyá iná ń jó níbì kan ni.’ Ṣùgbọ́n fídíò náà tún rán mi létí pé ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ni ìyà jẹ jù mí lọ. Gbogbo ohun tá a rí nínú fídíò yìí túbọ̀ fún wa lókun ó sì mú ká túbọ̀ máa fi ìtara sin Jèhófà.”—Stepan Vovchuk, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n kó nígbèkùn lọ sí Siberia.
“Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n kó lọ sígbèkùn ni bàbá àti ìyá mi. Ìyẹn ló kọ́kọ́ mú kí n rò pé ọ̀pọ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ lákòókò yẹn ni mo ti gbọ́. Àmọ́ lẹ́yìn tí mo wo fídíò yìí, mo rí i pé mì ò tíì gbọ́ nǹkan kan rárá. Ńṣe ni omijé lé ròrò lójú mi bí mo ṣe ń gbọ́ ọ̀rọ̀ táwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò nínú fídíò náà ń sọ. Mo ti wá rí i báyìí pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn kì í ṣe ìtàn lásán. Fídíò náà mú kí àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Ọlọ́run lágbára sí i, ó sì mú mi gbára dì láti fara da àwon ìṣòro tí mo bá ní lọ́jọ́ iwájú.”—Vladimir Kovash tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ Irkutsk, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.
“Lójú tèmi, kéèyàn wo fídíò yìí dáa ju kéèyàn kàn ka ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn nínú ìwé lọ. Nígbà tí mo wo bí wọ́n ṣe fọ̀rọ̀ wá àwọn tí wọ́n kó lọ sígbèkùn lẹ́nu wò tí mo sì gbọ́ ohun tí wọ́n sọ, lára mi, ńṣe lódà bíi pé a jọ jẹ gbogbo ìyà tí wọ́n jẹ nígbà yẹn ni. Àpẹẹrẹ bàbá tó ń ya àwòrán ránṣẹ́ sáwọn ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré nígbà tó wà lẹ́wọ̀n kọ́ mi pé kí èmi náà máa gbìyànjú láti gbin òtítọ́ Bíbélì sí ọkàn àwọn ọmọ mi. Ẹ ṣeun! Fídíò yìí ti mú kó túbọ̀ dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Rọ́ṣíà lójú pé ara ètò Jèhófà tó kárí ayé làwọn.”—Tatyana Kalina tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ Irkutsk.
“Gbólóhùn kan bá fídíò yìí mu, gbólóhùn náà sì ni pé: ‘Kéèyàn fojú ara rẹ̀ rí nǹkan kan sàn ju kéèyàn gbọ́ ọ láìmọye ìgbà lọ.’ Àfi bíi pé ohun tá a wò nínú rẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì kàn wá! Nígbà tí mo wò ó tán, ó pẹ́ díẹ̀ tí mo fi ń ronú nípa rẹ̀. Fídíò náà jẹ́ kí n lè fi ara mi sípò àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ko lọ sígbèkùn yẹn. Ní báyìí, tí mo bá fi ipò tí mo wà wé tiwọn, mo máa ń ní èrò tó tọ́ nípa ìṣòro tá à ń ní lóde-òní.”—Lidia Beda tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ Irkutsk.
Ní báyìí, a ti ṣe fídíò Faithful Under Trials jáde ní èdè mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, jákèjádò ayé làwọn èèyàn sì ń gba tiẹ̀. a Wọ́n ti fi fídíò náà hàn látòkèdélẹ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n ní ìlú St. Petersburg, ní ìlú Omsk àti láwọn ìlú ńlá mìíràn ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà, títí kan ìlú Vynnytsya, ìlú Kerch, ìlú Melitopol àti àgbègbè Lviv ní orílẹ̀-èdè Ukraine. Bákan náà, àjọ tó ń ṣàyẹ̀wò fídíò lágbàáyé ti fún fídíò yìí ní àmì ẹ̀yẹ.
Ohun tó mú kí ẹ̀kọ́ tó wà nínú fídíò yìí bùyààrì ni àpẹẹrẹ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tí wọ́n jẹ́ aláìpé tí wọ́n fi ìgboyà tó pabanbarì hàn tí wọ́n sì tún jẹ́ ẹni tó lágbára gan-an nípa tẹ̀mí ní gbogbo ọdún tí wọ́n fi ṣe inúnibíni sí wọn. Ní tòdodo, ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ilẹ̀ Soviet ò yẹ̀ lábẹ́ àdánwò. Tó o bá fẹ́ láti wo fídíò yìí, inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn lati jẹ́ kó tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́. Jọ̀wọ́, kàn sí ọ̀kan lára wọn ní àdúgbò rẹ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fídíò náà wà ní èdè Bulgarian, Cantonese, Czech, Danish, Dutch, Faransé, Finnish, German, Gẹ̀ẹ́sì, Gíríìkì, Hungarian, Indonesian, Italian, Japanese, Korean, Lithuanian, Mandarin, Norwegian, Polish, Romanian, Russian, Slovak, Slovenian, Spanish àti Swedish.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]
Stalin: U.S. Army photo
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]
Stalin: U.S. Army photo