Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Fún Àwọn Tọkọtaya

Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Fún Àwọn Tọkọtaya

Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Fún Àwọn Tọkọtaya

“Kí àwọn aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín.” —Éfésù 5:22, 25.

1. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ìgbéyàwó?

 ỌLỌ́RUN so ọkùnrin àti obìnrin pọ̀ “di ara kan,” èyí sì ni Jésù pè ní ìgbéyàwó. (Mátíù 19:5, 6) Ìyẹn ni àwọn méjì tí ìwà wọn yàtọ̀ síra àmọ́ tí wọ́n ní láti kọ́ bí wọ́n ṣe lè máa rí nǹkan bákan náà tí wọ́n á sì jọ máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú ohun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe. Àdéhùn láti jọ wà títí ayé ni ìgbéyàwó, kì í ṣe àdéhùn onígbà kúkúrú téèyàn kàn lè pa tì. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ó rọrùn fún ọkọ àti aya láti kọ ara wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, àmọ́ ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀ fáwọn Kristẹni, nítorí wọ́n mọ̀ pé ohun mímọ́ ni ìgbéyàwó. Àyàfi ohun pàtàkì kan ló lè fòpin sí i.—Mátíù 19:9.

2. (a) Ìrànlọ́wọ́ wo ló wà fún àwọn tọkọtaya? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká sapá kí ìgbéyàwó wa lè láyọ̀?

2 Obìnrin kan tó jẹ́ agbaninímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó sọ pé: “Kí ìgbéyàwó kan tó lè dára, ó gba pé kí tọkọtaya máa ṣe ìyípadà bí ọ̀ràn tuntun bá ṣe ń yọjú, kí wọ́n máa yanjú àwọn ìṣòro tó ń wáyé, kí wọ́n sì máa ṣàmúlò àwọn ohun tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ìgbésí ayé wọn.” Ní ti àwọn tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni, àwọn ohun tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ ni ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì, ìtìlẹ́yìn látọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni, àti àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà. Ìgbéyàwó aláyọ̀ máa ń borí ìṣòro, ó sì máa ń jẹ́ kí tọkọtaya láyọ̀ kí ọkàn wọn sì balẹ̀. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé ó máa ń mú ọlá bá Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 2:18, 21-24; 1 Kọ́ríńtì 10:31; Éfésù 3:15; 1 Tẹsalóníkà 5:17.

Fára Wé Jésù àti Ìjọ Rẹ̀

3. (a) Ṣàkópọ̀ ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn tọkọtaya? (b) Àpẹẹrẹ rere wo ni Jésù fi lélẹ̀?

3 Ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni ní ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n kan, ó sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìjọ ti wà ní ìtẹríba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn nínú ohun gbogbo. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Éfésù 5:24, 25) Ẹ ò rí i pé àfiwé yìí bá a mu gan-an! Ìjọ Kristẹni làwọn aya tó bá ń fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹrí bá fún ọkọ wọn ń fara wé. Irú àwọn aya bẹ́ẹ̀ mọ ohun tí ìlànà ipò orí jẹ́, wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún ìlànà náà. Àpẹẹrẹ Kristi làwọn ọkọ onígbàgbọ́ tó nífẹ̀ẹ́ aya wọn lọ́jọ́ dídùn àti lọ́jọ́ kíkorò ń tẹ̀ lé, nítorí pé Kristi nífẹ̀ẹ́ ìjọ ó sì ń ṣìkẹ́ rẹ̀.

4. Báwo làwọn ọkọ ṣe lè fara wé àpẹẹrẹ Jésù?

4 Àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni ni olórí ìdílé, àmọ́ àwọn náà ní orí tiwọn. Jésù ni orí náà. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ń tọ́jú ìjọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ káwọn ọkọ máa fìfẹ́ bójú tó ipò tẹ̀mí ìdílé wọn kí wọ́n sì tún máa bójú tó o nípa tara, àní bí èyí tilẹ̀ gba pé kí wọ́n yááfì àwọn nǹkan kan. Ó yẹ kí wọ́n máa fi ohun tó máa ṣe ìdílé wọn láǹfààní ṣáájú ohun tó wù wọ́n. Jésù sọ pé: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Inú ìgbéyàwó ni ìlànà yẹn ti wúlò jù lọ. Pọ́ọ̀lù fèyí hàn nígbà tó sọ pé: “Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. . . . Kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀.” (Éfésù 5:28, 29) Ọkùnrin kan ní láti máa bọ́ aya rẹ̀ kó sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀ lọ́nà tí òun gan-an ń gbà bọ́ ara rẹ̀ tó sì ń ṣìkẹ́ ara rẹ̀.

5. Báwo làwọn aya ṣe lè fara wé ìjọ Kristẹni?

5 Àwọn aya tó bẹ̀rù Ọlọ́run máa ń wo àpẹẹrẹ ìjọ Kristẹni. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, tinútinú làwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ fi pa iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀ tì, tí wọ́n sì tẹ̀ lé e. Lẹ́yìn ikú rẹ̀, wọ́n ń bá a lọ láti máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu, ó sì ti ń lọ sí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún báyìí tí ìjọ Kristẹni tòótọ́ ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì ti ń tẹ̀ lé Jésù nínú ohun gbogbo. Lọ́nà kan náà, àwọn aya tó jẹ́ Kristẹni kì í fojú àbùkù wo ọkọ wọn tàbí kí wọ́n máa fojú kéré ipò orí tí Ìwé Mímọ́ là kalẹ̀ nínú ìgbéyàwó. Dípò bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń ran àwọn ọkọ wọn lọ́wọ́ tí wọ́n sì máa ń tẹrí bá fún wọn, wọ́n máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kórí àwọn ọkọ wọn yá. Nígbà tí ọkọ àti aya bá ń fìfẹ́ hùwà sí ara wọn lọ́nà yìí, ìgbéyàwó wọn yóò tòrò minimini, àwọn méjèèjì yóò sì rí ayọ̀ nínú ìgbéyàwó wọn.

Máa Bá Wọn Gbé

6. Ìmọ̀ràn wo ni Pétérù fún àwọn ọkọ, kí sì nìdí tí ìmọ̀ràn ọ̀hún fi ṣe pàtàkì?

6 Àpọ́sítélì Pétérù tún gba àwọn tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni nímọ̀ràn, ọ̀rọ̀ tó sì bá àwọn ọkọ sọ ṣe ṣàkó. Ó sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní bíbá [àwọn aya yín] gbé lọ́nà kan náà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀, kí ẹ máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo, níwọ̀n bí ẹ tún ti jẹ́ ajogún ojú rere ìyè tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí pẹ̀lú wọn, kí àdúrà yín má bàa ní ìdènà.” (1 Pétérù 3:7) Ọ̀rọ̀ tó kẹ́yìn ẹsẹ yẹn jẹ́ ká rí i bí ìmọ̀ràn Pétérù yẹn ti ṣe pàtàkì tó. Bí ọkọ kan ò bá bọlá fún aya rẹ̀, yóò ṣàkóbá fún àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Àdúrà rẹ̀ yóò ní ìdènà.

7. Báwo ló ṣe yẹ kí ọkọ máa bọlá fún aya rẹ̀?

7 Wàyí o, báwo làwọn ọkọ ṣe lè máa bọlá fún aya wọn? Bíbọlá fún aya ẹni túmọ̀ sí híhùwà sí i tìfẹ́tìfẹ́, fífi ọ̀wọ̀ àti ẹ̀yẹ bá a lò. Híhùwà sí aya ẹni lọ́nà yìí lè dà bí ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lójú ọ̀pọ̀ èèyàn. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì kan sọ pé: “Lábẹ́ òfin àwọn ará Róòmù, obìnrin kò ní ẹ̀tọ́ kankan. Lábẹ́ òfin yìí, obìnrin ò yàtọ̀ sí ọmọdé rárá. . . . Ọkọ rẹ̀ ló ń darí rẹ̀, ohunkóhun tó bá wu ọkọ rẹ̀ ló lè fi ṣe.” Èyí mà kúkú yàtọ̀ gan-an sí ẹ̀kọ́ àwọn Kristẹni o! Ọkọ tó jẹ́ Kristẹni máa ń bọlá fún aya rẹ̀. Ìlànà Kristẹni ló fi ń bá a lò, kì í ṣe ohunkóhun tó bá kàn ti wù ú ṣáá. Ìyẹn nìkan kọ́, ó máa ń gba ti aya rẹ̀ rò, nítorí ó mọ̀ pé kò lágbára tó ọkùnrin.

Ọ̀nà Wo Ló Gbà Jẹ́ “Ohun Èlò Tí Ó Túbọ̀ Jẹ́ Aláìlera”?

8, 9. Ọ̀nà wo làwọn obìnrin gbà bá àwọn ọkùnrin dọ́gba?

8 Nígbà tí Pétérù sọ pé obìnrin jẹ́ “ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera,” kò ní in lọ́kàn pé àwọn obìnrin jẹ́ aláìlera ju ọkùnrin tó bá kan níní ọgbọ́n àti jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí. Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ ọkùnrin máa ń ní àǹfààní nínú ìjọ èyí táwọn obìnrin kò ní, bákan náà ló jẹ́ pé nínú ìdílé, abẹ́ ọkọ wọn làwọn obìnrin wà. (1 Kọ́ríńtì 14:35; 1 Tímótì 2:12) Síbẹ̀síbẹ̀, ìgbàgbọ́ kan náà, ìpamọ́ra kan náà àti ìlànà ìwà rere kan náà la béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin àtobìnrin. Gẹ́gẹ́ bí Pétérù ṣe sọ, àti ọkọ àti aya ló jẹ́ “ajogún ojú rere ìyè tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí.” Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàlà, ipò kan náà ni gbogbo wọn wà níwájú Jèhófà Ọlọ́run. (Gálátíà 3:28) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti ọ̀rúndún kìíní ni Pétérù kọ̀wé yìí sí. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ rẹ̀ rán àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni lákòókò náà létí pé bí wọ́n ti jẹ́ “ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi” làwọn aya wọn náà jẹ́, irú ìrètí kan náà ni wọ́n jọ ní lọ́run. (Róòmù 8:17) Lọ́jọ́ kan, àwọn méjèèjì yóò jọ máa ṣe àlùfáà àti ọba nínú Ìjọba Ọlọ́run ní ọrun!—Ìṣípayá 5:10.

9 Àwọn aya tó jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró kò rẹlẹ̀ sí àwọn ọkọ wọn tó jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró rárá. Ìlànà yìí sì kan àwọn tí wọ́n ní ìrètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn ọkùnrin àtobìnrin tó jẹ́ ara “ogunlọ́gọ̀ ńlá” fọ aṣọ wọn, wọ́n sì sọ ọ́ di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. Tọkùnrin tobìnrin ló ń lọ́wọ́ nínú pípolongo ìyìn Jèhófà “tọ̀sán tòru.” (Ìṣípayá 7:9, 10, 14, 15) Àtọkùnrin àtobìnrin ló ń fojú sọ́nà láti gbádùn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run,” nígbà tí wọ́n á máa gbádùn “ìyè tòótọ́.” (Róòmù 8:21; 1 Tímótì 6:19) Yálà ara àwọn ẹni àmì òróró ni wá tàbí ara àwọn àgùntàn mìíràn, gbogbo Kristẹni ló ń sin Jèhófà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí “agbo kan” lábẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan.” (John 10:16) Ẹ ò rí i pé ó yẹ kí èyí mú káwọn ọkọ àti aya tí wọ́n jẹ́ Kristẹni máa fi ọlá tó yẹ fún ara wọn!

10. Ọ̀nà wo làwọn obìnrin gbà jẹ́ ‘ohun èlò tó túbọ̀ jẹ́ aláìlera’?

10 Ọ̀nà wo wá làwọn obìnrin gbà jẹ́ “ohun èlò tó túbọ̀ jẹ́ aláìlera”? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí Pétérù ń sọ ni pé tá a bá wò ó káríkárí, àwọn obìnrin sábà máa ń kéré ní ìrísí, wọn ò sì lágbára tó àwọn ọkùnrin. Láfikún sí i, nínú ipò àìpé tá a wà yìí, ìnira kékeré kọ́ làwọn obìnrin ń fara dà nítorí àǹfààní pàtàkì tí wọ́n ní láti bímọ. Àwọn obìnrin tí wọ́n ṣì wà ní ọjọ́ orí ọmọ bíbí lè máa ní ìnira látìgbàdégbà. Wọ́n ń fẹ́ àbójútó pàtàkì àti ìgbatẹnirò nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìnira ọ̀hún tàbí nígbà tí wọ́n bá ń jẹ̀rora tó ń bá oyún níní àti ìbímọ rìn. Ọkọ tó ń bọlá fún aya rẹ̀ tó sì mọ̀ pé ó yẹ kí òun ràn án lọ́wọ́, yóò mú kí ìgbéyàwó wọn láyọ̀ gan-an.

Nínú Ìdílé Tí Wọn Ò Ti Ṣe Ẹ̀sìn Kan Náà

11. Ọ̀nà wo ni tọkọtaya tí wọn ò ṣe ẹ̀sìn kan náà fi lè láyọ̀ nínú ìgbéyàwó wọn?

11 Ká ní ọkọ àti aya kò ṣe ẹ̀sìn kan náà nítorí pé ọ̀kan lára wọn gba ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ṣègbéyàwó tí èkejì rẹ̀ kò sì gbà á ńkọ́? Ǹjẹ́ ayọ̀ lè wà nínú irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀? Ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ ti fi hàn pé bẹ́ẹ̀ ni. Tọkọtaya tí wọn ò ṣe ẹ̀sìn kan náà lè máa fayọ̀ gbé kí wọ́n sì jọ wà títí lọ. Yàtọ̀ síyẹn, ìgbéyàwó náà ṣì fìdí múlẹ̀ lójú Jèhófà: “ara kan” ṣì ni wọ́n. Nítorí náà, Bíbélì gba ọkọ tàbí aya tó jẹ́ Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n má ṣe kúrò lọ́dọ̀ ẹnì kejì wọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ bí onítọ̀hún bá gbà láti máa bá a gbé. Bí wọ́n bá bímọ, àwọn ọmọ náà yóò jàǹfààní nínú bí òbí tó jẹ́ Kristẹni náà ṣe dúró ṣinṣin.—1 Kọ́ríńtì 7:12-14.

12, 13. Nípa títẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pétérù, báwo làwọn aya tó jẹ́ Kristẹni ṣe lè ran ọkọ wọn aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́?

12 Pétérù fún àwọn obìnrin tó jẹ́ Kristẹni ní ìmọ̀ràn rere kan, ìyẹn àwọn tó ń gbé nínú ilé tí ẹnì kejì wọn ti ń ṣe ẹ̀sìn tó yàtọ̀. Àwọn Kristẹni ọkùnrin tó wà nírú ipò kan náà sì lè lo ìlànà tó wà nínú ìmọ̀ràn náà. Pétérù sọ pé: “Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”—1 Pétérù 3:1, 2.

13 Ó dára tí aya kan bá lè fọgbọ́n ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ fún ọkọ rẹ̀. Àmọ́, ká ní ọkọ náà ò fẹ́ gbọ́ ńkọ́? Bó ṣe wu ọkọ náà nìyẹn. Síbẹ̀ náà, ìrètí ṣì wà, nítorí híhu ìwà tó yẹ Kristẹni máa ń wàásù lọ́nà tó lágbára. Ọ̀pọ̀ àwọn ọkọ tí wọn kò nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí aya wọn gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀ tàbí tí wọ́n ti ń ta kò wọ́n rí, ti wá “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” lẹ́yìn tí wọ́n rí ìwà rere àwọn aya wọn. (Ìṣe 13:48) Àní bí ọkọ kan ò bá tiẹ̀ fara mọ́ ohun táwọn Kristẹni tòótọ́ fi ń kọ́ni, ìwà ìyàwó rẹ̀ lè wú u lórí tí èyí á sì mú kí ìdè ìgbéyàwó wọn lágbára sí i. Ọkọ kan tí ìyàwó rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé òun ò lè tẹ̀ lé ìlànà wọn. Síbẹ̀, ó pe ara rẹ̀ ní “ọkọ tó láyọ̀ nítorí tí ó ní aya rere” ó sì yin aya rẹ̀ àtàwọn Ẹlẹ́rìí yòókù nínú lẹ́tà tó kọ sí iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn kan.

14. Ọ̀nà wo làwọn ọkọ lè gbà ran aya wọn aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́?

14 Àwọn ọkọ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni tí wọ́n fi ìlànà tó wà nínú ọ̀rọ̀ Pétérù sílò ti fi ìwà wọn jèrè aya wọn bákan náà. Àwọn aláìgbàgbọ́ aya náà ti rí i pé ọkọ wọn ti dẹni tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́, wọn kò náwó dà nù sórí sìgá mímú, ọtí mímú, àti tẹ́tẹ́ títa mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkọ wọn kò sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí wọn mọ́. Àwọn kan lára àwọn aláìgbàgbọ́ aya wọ̀nyí ti dojúlùmọ̀ àwọn kan nínú ìjọ Kristẹni. Ìfẹ́ táwọn Kristẹni ní síra wọn mú orí wọn wú, ohun tí wọ́n sì rí láàárín àwọn Kristẹni lọ́kùnrin lóbìnrin ti mú kí wọ́n sún mọ́ Jèhófà.—Jòhánù 13:34, 35.

“Ẹni Ìkọ̀kọ̀ ti Ọkàn-Àyà”

15, 16. Irú ìwà wo ni obìnrin tó jẹ́ Kristẹni lè fi jèrè ọkọ rẹ̀ aláìgbàgbọ́?

15 Irú ìwà wo ló lè jèrè ọkọ? Ká sòótọ́, ìwà tó yẹ àwọn obìnrin tó jẹ́ Kristẹni ni. Pétérù sọ pé: “Kí ọ̀ṣọ́ yín má sì jẹ́ ti irun dídì lóde ara àti ti fífi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà sára tàbí ti wíwọ àwọn ẹ̀wù àwọ̀lékè, ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù, èyí tí ó níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run. Nítorí, nígbà yẹn lọ́hùn-ún, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn obìnrin mímọ́ tí wọ́n ní ìrètí nínú Ọlọ́run máa ń ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, ní fífi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ tiwọn, gẹ́gẹ́ bí Sárà ti máa ń ṣègbọràn sí Ábúráhámù, ní pípè é ní ‘olúwa.’ Ẹ sì ti di ọmọ rẹ̀, kìkì bí ẹ bá ń bá a nìṣó ní ṣíṣe rere, tí ẹ kò sì bẹ̀rù okùnfà èyíkéyìí fún ìpayà.”—1 Pétérù 3:3-6.

16 Pétérù gba àwọn obìnrin tó jẹ́ Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n má ṣe gbára lé ẹwà wọn. Dípò ìyẹn, ńṣe ló yẹ kí aya jẹ́ kí ọkọ òun máa rí i bí ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe ń tún ìwà òun ṣe. Ó yẹ kó jẹ́ kí ọkọ rẹ̀ máa rí i pé ìwà òun ti yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ọkọ náà wá rí i pé ìyàwó òun kò hu àwọn ìwà tó ti ń hù nígbà kan rí mọ́. (Éfésù 4: 22-24) Ó dájú pé “ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́” àti “ìwà tútù” rẹ̀ yóò wu ọkùnrin náà yóò sì tù ú lára. Kì í ṣe pé irú ìwà yìí yóò tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ ìwà tó “níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run.”—Kólósè 3:12.

17. Báwo ni Sárà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún àwọn aya tó jẹ́ Kristẹni?

17 A máa ń tọ́ka sí Sárà pé ó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, ó sì yẹ káwọn aya tó jẹ́ Kristẹni tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, yálà ọkọ wọn jẹ́ onígbàgbọ́ tàbí aláìgbàgbọ́. Láìsí tàbí ṣùgbọ́n, Sárà gbà pé Ábúráhámù ni orí òun. Àní nínú ọkàn rẹ̀ pàápàá, ó pè é ní “olúwa” òun. (Jẹ́nẹ́sísì 18:12) Síbẹ̀ ìyẹn ò bu iyì Sárà kù. Ó dájú pé obìnrin tẹ̀mí gidi ni Sárà, nítorí pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Jèhófà dúró ṣinṣin. Àní, Sárà wà lára “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí” tí àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn yẹ kó mú wa máa “sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa.” (Hébérù 11:11; 12:1) Bí aya kan tó jẹ́ Kristẹni bá fara wé Sára, èyí kò ní bu iyì rẹ̀ kù.

18. Ìlànà wo la ní láti máa lò nínú ìdílé tí ọkọ àti aya ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀?

18 Nínú ilé tó jẹ́ pé ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ọkọ àti aya ń ṣe, ọkọ ṣì ni olórí ìdílé. Tó bá jẹ́ ọkọ ni Kristẹni tòótọ́, yóò máa gba ti ìgbàgbọ́ aya rẹ̀ rò bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní pa ìgbàgbọ́ tirẹ̀ tì. Bó bá sì jẹ́ pé aya ni Kristẹni tòótọ́, òun náà ò ní pa ìgbàgbọ́ tirẹ̀ tì. (Ìṣe 5:29) Síbẹ̀, kò ní máa bá ọkọ rẹ̀ du ipò orí. Yóò bọlá fún ipò ọkọ rẹ̀ yóò sì wà lábẹ́ “òfin ọkọ rẹ̀.”—Róòmù 7:2.

Ìmọ̀ràn Rere Tí Bíbélì Fúnni

19. Àwọn ohun wo ló ń fa ìṣòro nínú ìgbéyàwó, àmọ́ báwo la ṣe lè dènà àwọn ìṣòro náà?

19 Lónìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń fa ìṣòro nínú ìgbéyàwó. Àwọn ọkọ kan kì í ṣe ojúṣe wọn. Àwọn aya kan kò sì gbà pé ọkọ wọn ni orí wọn. Nínú àwọn ìgbéyàwó kan sì rèé, ọkọ tàbí ìyàwó máa ń fojú ẹnì kejì wọn rí màbo. Àwọn ohun tó máa ń dán ìdúróṣinṣin àwọn Kristẹni wò ni àìrówóná, àìpé ẹ̀dá àti ẹ̀mí ayé, títí kan ìṣekúṣe tó kúnnú ayé àti káwọn èèyàn máa ka ohun tí kò dára sí ohun tó dára. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni lọ́kùnrin lóbìnrin tí wọ́n ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì nínú ipòkípò tí wọn ì báà wà ti rí ìbùkún Jèhófà gbà. Àní ká tiẹ̀ ní ẹnì kan lára àwọn tó fẹ́ ara wọn ló ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, ìyẹn ṣì dára ju káwọn méjèèjì má fi sílò lọ. Síwájú sí i, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró ti ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wọn, kódà bí wọ́n bá tiẹ̀ wà nínú ipò tó lé koko pàápàá, ó máa ń tì wọ́n lẹ́yìn. Kì í gbàgbé ìdúróṣinṣin wọn.—Sáàmù 18:25; Hébérù 6:10; 1 Pétérù 3:12.

20. Ìmọ̀ràn wo ni Pétérù fún gbogbo àwa Kristẹni?

20 Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù ti fún àwọn lọ́kọláya nímọ̀ràn, ó wá fi ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí parí rẹ̀ pé: “Lákòótán, gbogbo yín ẹ jẹ́ onínú kan náà, kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ni ará, kí ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú, kí ẹ má ṣe máa fi ìṣeniléṣe san ìṣeniléṣe tàbí ìkẹ́gàn san ìkẹ́gàn, ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, kí ẹ máa súre, nítorí tí a pè yín sí ipa ọ̀nà yìí, kí ẹ lè jogún ìbùkún.” (1 Pétérù 3:8, 9) Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n mà lèyí jẹ́ fún gbogbo wa o, pàápàá jù lọ fún àwọn lọ́kọláya!

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Ọ̀nà wo làwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni gbà ń fara wé Jésù?

• Báwo làwọn aya tó jẹ́ Kristẹni ṣe ń fara wé ìjọ?

• Ọ̀nà wo làwọn ọkọ lè gbà bọlá fún aya wọn?

• Ohun tó dara jù lọ wo ni Kristẹni aya tó ní ọkọ aláìgbàgbọ́ lè ṣe?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ọkọ tó jẹ́ Kristẹni máa ń nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ ó sì máa ń tọ́jú rẹ̀

Aya tó jẹ́ Kristẹni máa ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ó sì máa ń bọlá fun un

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ẹ̀kọ́ Kristẹni yàtọ̀ sí òfin Róòmù, ó sọ pé kí ọkọ máa bọlá fún aya rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àtọkùnrin àtobìnrin tó jẹ́ ara “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ló ń retí láti wàláàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Sárà ka Ábúráhámù sí olúwa rẹ̀