Ìròyìn Iṣẹ́ Ìwàásù Wa ní Áfíríkà
Ìròyìn Iṣẹ́ Ìwàásù Wa ní Áfíríkà
Iye orílẹ̀-èdè: 56
Iye èèyàn: 770,301,093
Iye akéde: 983,057
Iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: 1,769,182
ǸJẸ́ o mọ̀ pé a ti ń wàásù ìhìn rere náà ní àwọn ilẹ̀ Sàhárà? Nafissatou tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ń gbé ìlú tí wọ́n ti ń wa kùsà ní àríwá orílẹ̀-èdè Niger. Lọ́jọ́ kan, àwọn kan lára àwọn ọmọ tí wọ́n jọ ń lọ sílé ìwé ń fọ̀rọ̀ jomi tooro ọ̀rọ̀. Bí àwọn ọmọ náà ṣe dẹ́nu lé ọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè báyìí ni Nafissatou rìn kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wá sá tẹ̀ lé e, ó sì béèrè ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Nafissatou wá dá a lóhùn pé òun kì í fẹ́ gbọ́ irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀. Ọmọbìnrin náà kọ́kọ́ fi Nafissatou ṣe yẹ̀yẹ́, ó ní kéèyàn kàn wo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè lásán ò lè ṣèèyàn ní jàǹbá kankan. Nafissatou fèsì pé ọ̀ràn náà lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ nítorí pé Ẹlẹ́dàá ò fẹ́ ká máa wo irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Ó wá yọ ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ jáde nínú àpò tó ń gbé wá sílé ìwé, ó sì fi ibi tó sọ̀rọ̀ nípa ewu tó wà nínú wíwo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè han ọmọbìnrin náà. Ó tún mú Bíbélì rẹ̀ jáde, ó sì ka 2 Kọ́ríńtì 7:1 fún ọmọbìnrin náà. Ọmọbìnrin náà wá jẹ́wọ́ pé nígbà tóun bá wo fídíò tó ń fi ìwà pálapàla hàn, ó máa ń ṣe ara òun bákan lọ́nà tó lágbára gan-an tóun ò lè ṣàlàyé. Ó wá sọ pé kí Nafissatou fún òun ní ẹ̀dà kan ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè náà. Nafissatou fún un ní ẹ̀dà kan ìwé náà, ó wá ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Nígbà ti mo máa padà rí ọmọbìnrin náà, òun nìkan ló dá jókòó, mo wá béèrè ibi táwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wà. Ó ní, ‘Ìwé yìí ni ọ̀rẹ́ mi.’ Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí i kọ ọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn, ó sì wá sí ibi tá a ti ṣe Ìrántí Ikú Jésù.”
Ní ohun tó lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn, obìnrin kan kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ arábìnrin kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè Tanzania. Arábìnrin náà darí ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí fún ọdún bíi mélòó kan. Àmọ́, obìnrin náà ń lọ́ tìkọ̀ láti wá sínú òtítọ́ nítorí àtakò tí ìdílé rẹ̀ ń ṣe, nígbà tó yá kò ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà mọ́. Àmọ́, àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjì ti máa ń dọ́gbọ́n tẹ́tí sílẹ̀ lákòókò tí màmá wọn ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí èyí tó dàgbà jù lára àwọn ọmọbìnrin náà wá kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ nígbà tó pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, kíá ló lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sì ní káwọn Ẹlẹ́rìí wá kọ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó tẹra mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ó sì ṣèrìbọmi. Àbúrò rẹ̀ náà ní kí wọ́n kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, òun náà sì ṣèrìbọmi. Nígbà tí ìyá wọn rí i pé àwọn ọmọ òun sapá gidigidi láti wá sínú òtítọ́ lóun náà bá pinnu láti padà bẹ̀rẹ̀ sí i kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́tẹ̀ yìí, ó ṣẹ́pá ìbẹ̀rù èèyàn tí kò jẹ́ kó tẹ̀ síwájú tẹ́lẹ̀, ó sì ṣe ìrìbọmi ní àpéjọ àyíká kan ní May 2004.
Bí ìjọ kan bá ṣègbọràn sí àṣẹ tó sọ pé ká “máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn,” ó dájú pé Jèhófà á bù kún irú ìjọ bẹ́ẹ̀. (Jákọ́bù 1:27) Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nínú ìjọ kan tó wà ní orílẹ̀-èdè Lesotho nìyẹn. Ọ̀kan lára àwọn tó ti ṣèrìbọmi nínú ìjọ náà ni Mapolo tó jẹ́ ìyá tó ń dá nìkan tọ́ àwọn ọmọkùnrin kéékèèké mẹ́rin. Mapolo mọ̀ pé àìsàn kan tí ò gbóògùn ń ṣe òun, ó sì tìtorí bẹ́ẹ̀ tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́nà tí wọ́n á fi lè dá gbọ́ bùkátà ara wọn. Ó kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó máa ń mú wọn lọ́ sáwọn ìpàdé, ó sì tún kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa ṣe ìgbálẹ̀, èyí tí wọ́n máa ń tà lẹ́bàá ọ̀nà. Nígbà tí Mapolo kú lọ́dún 1998, àwọn ọmọ rẹ̀ tó ti di ọmọ òrukàn báyìí wá lọ ń gbé lọ́dọ̀ ìyá wọn àgbà. Arábìnrin míṣọ́nnárì tó ran Mapolo lọ́wọ́ láti di Ẹlẹ́rìí tó ṣèrìbọmi wá lọ sọ́dọ̀ àjọ ìfẹ́dàáfẹ́re kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ òrukàn náà, wọ́n sì fún un lówó ilé ìwé wọn. Àwọn ará tún kó aṣọ fáwọn ọmọkùnrin náà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni ìyà wọn àgbà tún kú. Arákùnrin kan nínú ìjọ náà wá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó tún bá wọn sanwó ilé tí wọ́n ń gbé. Àwọn ọmọkùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ló ń wá sípàdé déédéé. Méjì nínú wọn ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi báyìí, Rantso tó jẹ́ àgbà wọn ti pé ọmọ ogún ọdún, ó sì ṣèrìbọmi ní àpéjọ àyíká kan ní March 2004. Ó bá Retselisitsoe tó jẹ́ ìbátan rẹ̀ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọjọ́ tí Rantso ṣèrìbọmi ni ìbátan rẹ̀ yìí ṣèrìbọmi. Rantso dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin gan-an nítorí ìfẹ́ tí wọ́n fi bójú tó òun àtàwọn àbúrò rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún.
Míṣọ́nnárì kan tó wà ní orílẹ̀-èdè Cameroon ròyìn pé: “Bí mo bá ti ń bá ọmọkùnrin kan ṣèkẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni mo máa ń gbọ́ tí ẹnì kan máa ń kọ orin àwọn onísìn nínú ilé náà. Mo wá béèrè lọ́wọ́ ẹni tí mo ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ náà pé, ‘Ta ni akọrin tí kì í yọjú síta yìí?’ Àṣé àbúrò rẹ̀ tó jẹ́ afọ́jú ni, Stephen ni orúkọ rẹ̀. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Stephen lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn. A sì ń fi kásẹ́ẹ̀tì àfetígbọ́ ti ìwé pẹlẹbẹ náà Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ohun tá a pinnu láti máa ṣe ni pé ká máa há ẹsẹ Bíbélì kan sórí ní gbogbo ìgbà tá a bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Stephen mọ béèyàn ṣe ń há nǹkan sórí gan-an, ó sì ti mọ ẹsẹ Bíbélì tó pọ̀. Ó tún máa ń wá sáwọn ìpàdé, ó sí máa ń dáhùn ìbéèrè nípàdé lọ́pọ̀ ìgbà. Ẹnu àìpẹ́ yìí ló ṣe iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Bíbélì kíkà ni iṣẹ́ tí Stephen ṣe náà, ó ní láti há gbogbo rẹ̀ sórí nítorí kò mọ ìwé àwọn afọ́jú kà. Ohun tí mò ń wọ̀nà fún báyìí ni bí mo ṣe máa di Stephen lọ́wọ́ mú tí èmi àtòun á sì jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí láìpẹ́. Ọ̀kan lára ẹsẹ Bíbélì tí Stephen fẹ́ràn jù lọ ni Aísáyà 35:5, tó kà pé: ‘Ojú àwọn afọ́jú yóò là.’ Inú Stephen ń dùn pé ojú tẹ̀mí òun ti là báyìí, ó sì ti ń kọrin ìyìn sí Jèhófà, ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ojú òun tó fọ́ yóò là lọ́jọ́ iwájú.”
Ní orílẹ̀-èdè Làìbéríà tí ogun ti bà jẹ́, obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nancy lọ ba Ẹlẹ́rìí kan, ó sì sọ fún un pé kó wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Nancy ti sọ fún un pé Ọlọ́run máa sọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sínú iná ọ̀run àpáàdì nítorí pé èké Kristẹni ni wọ́n. Àmọ́, ilé Nancy ò jìnnà sílé àwọn Ẹlẹ́rìí bíi mélòó kan. Ó sì ti kíyè sí i pé ìgbàkigbà tí wọn ò bá ti gbúròó ìbọn fúngbà díẹ̀ làwọn alàgbà ìjọ náà máa ń jáde tí wọn á lọ máa béèrè àlàáfíà àwọn arákùnrin wọn. Ó tún kíyè sí i pé gbogbo ìgbà tí ogun bá rọlẹ̀ díẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí máa ń lọ wàásù fáwọn èèyàn. Ó wú Nancy àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn lórí gan-an nígbà tí wọ́n rí i pé ọkọ̀ tó wá láti ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ló kọ́kọ́ sọdá sí òdì kejì ibi tí wọ́n ti ń jagun náà, tó sì kó àwọn nǹkan táwọn èèyàn nílò gan-an lákòókò yẹn wá. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní ilẹ̀ Faransé àti orílẹ̀-èdè Belgium ló kó àwọn nǹkan wọ̀nyí ránṣẹ́. Obìnrin náà sọ pé: “Mo gbà pé ẹ̀yin èèyàn wọ̀nyí ló ń ṣòótọ́.” Ó tẹ̀ síwájú gan-an nínú ẹ̀kọ́ tó ń kọ́.
Ọ̀dọ́kùnrin kan wá sí abúlé kan ní orílẹ̀-èdè Uganda. Iṣẹ́ bíríkìlà ló ń ṣe, ó wá tún ibì kan ṣe lára ilé táwa Ẹlẹ́rìí ti ń ṣèpàdé. Bí ọ̀kan lára àwọn aṣáájú ọ̀nà tó wà níbẹ̀ ṣe lo àǹfààní yẹn láti wàásù fún bíríkìlà yìí nìyẹn, inú rẹ̀ sì dùn sí ohun tó gbọ́. Àmọ́ láìpẹ́, ó ní láti padà sí abúlé rẹ̀ tó jìnnà gan-an tó wà lórí àwọn òkè ńlá. Níwọ̀n bí kò ti sí Ẹlẹ́rìí kankan níbi tí ọkùnrin náà ń gbé, aṣáájú ọ̀nà yìí wá júwe ibi tó ti lé rí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sún mọ́ ọn jù lọ. Ọ̀dọ́kùnrin náà gun kẹ́kẹ́ rẹ̀, ó sì fi kẹ̀kẹ́ náà rin nǹkan bí ọgbọ̀n kìlómítà lójú ọ̀nà tóóró tó jẹ́ eléruku, tó gba ìsàlẹ̀ òkè kan báyìí kọ já, kó lè wá àwọn Ẹlẹ́rìí kàn. Nígbà tó débẹ̀, kò rí arákùnrin kankan ní Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Ó wá kọ ìwé pélébé kan tó fi sábẹ́ ilẹ̀kùn Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Ohun tó kọ síbẹ̀ ni pé kí wọ́n wá kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí arákùnrin aṣáájú ọ̀nà kan wá ọkùnrin yìí lọ sí abúlé rẹ̀ níkẹyìn, ó yà á lẹ́nu láti bá nǹkan bí igba èèyàn níbẹ̀, tí wọ́n ń dúró dé e láti gbọ́ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì! Tọkàntọkàn ni ọ̀pọ̀ lára wọn sì fi gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n ti ń ṣèpàdé ní àgbègbè jíjìnnà réré yìí nísinsìnyí.
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan ńṣe làwọn bí ẹgbẹ̀ta èèyàn tó ń gbé abúlé kékeré kan ní gúúsù ìlà oòrùn Nàìjíríà ṣàdédé rí iná kan tó mọ́lẹ̀ yòò lójú òfuurufú. Inú odò tó wà níbẹ̀ ni wọ́n ti rí ìtànṣán iná náà. Ó dà bíi pé iná náà ń bọ́ lọ́dọ̀ wọn, bí àwọn ará abúlé náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wá ibi ààbò nìyẹn. Ọ̀pọ̀ lára wọn rò pé ìparun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù nípa rẹ̀ ni. Bí wọn ṣe sáré lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba nìyẹn, tí wọ́n ń sọ pé, “Amágẹ́dọ́nì ò ní pa ilé yìí run.” Níkẹyìn, ní nǹkan bí aago mẹ́wàá alẹ́, àwọn ará abúlé náà wá rí i pé ibi igbó ńlá kan tí wọ́n dáná sun ni iná náà ti ń jó. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí béèrè ìdí táwọn ará abúlé náà kò fi sá lọ sáwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó wà nítòsí, ọkùnrin kan lára wọn dáhùn pé: “Ìranù làwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó kù. Amágẹ́dọ́nì yín máa pa wọ́n run, àmọ́ kò ní pa Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí run.”