Ìwà Tó Dára Máa Ń ‘Ṣe Ẹ̀kọ́ Ọlọ́run Lọ́ṣọ̀ọ́’
Ìwà Tó Dára Máa Ń ‘Ṣe Ẹ̀kọ́ Ọlọ́run Lọ́ṣọ̀ọ́’
Ọ̀DỌ́MỌBÌNRIN kan tó ń jẹ́ Maria tó ń gbé ní ìlú Kransnoyarsk, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, jẹ́ ẹni tó mọ orin kọ gan-an. Èyí ló mú kí olùkọ́ rẹ̀ fi sára àwọn tó ń kọrin níléèwé. Àmọ́ Maria lọ bá ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ rẹ̀ láìpẹ́ lẹ́yìn náà ó sì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé fún un pé òun ò ní lè kọ àwọn orin kan. Kí nìdí? Nítorí pé, kíkọ àwọn orin ìsìn kò bá ohun tó kọ́ nínú Bíbélì tó sì gbà gbọ́ mu. Ọ̀rọ̀ yìí ya olùkọ́ rẹ̀ lẹ́nu gan-an, ó sì sọ pé, ‘Kí ló burú nínú kéèyàn fi orin yin Ọlọ́run lógo?’
Maria sọ ìdí tòun ò fi ní lè kọ orin tó ń fi hàn pé Mẹ́talọ́kan ni Ọlọ́run. Ó ṣí Bíbélì rẹ̀, ó sì ṣàlàyé pé Ọlọ́run àti Jésù Kristi kì í ṣe ẹnì kan ṣoṣo, àtipé agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run ni ẹ̀mí mímọ́. (Mátíù 26:39; Jòhánù 14:28; Ìṣe 4:31) Maria sọ pé: “Àárín èmi àti olùkọ́ náà kò dàrú rárá. Àwọn olùkọ́ tá a ní níléèwé wa dára gan-an. Wọn ò fẹ́ ká máa bẹ̀rù àwọn.”
Títí tọ́dún yẹn fi jálẹ̀ làwọn olùkọ́ Maria àtàwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ ń buyì fún un. Maria sọ pé: “Àwọn ìlànà inú Bíbélì ń ràn mí lọ́wọ́ gan-an nígbèésí ayé mi. Lópin ọdún yẹn, mo gba ẹ̀bùn ọmọ tó jẹ́ olóòótọ́ jù lọ àti ọmọ tó wà létòlétò jù lọ. Wọ́n tún fún àwọn òbí mi ní lẹ́ta ìgbóríyìn nítorí pé wọ́n tọ́ ọmọ wọn dáadáa.”
Ọjọ́ kejìdínlógún oṣù August ọdún 2001 ni Maria ṣèrìbọmi. Ó sọ pé: “Inú mi dùn gan-an pé mò ń sin Jèhófà, Ọlọ́run àgbàyanu ni!” Kárí ayé, àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń mú ọ̀rọ̀ inú ìwé Títù 2:10 ṣẹ, èyí to sọ pé ká “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́ nínú ohun gbogbo.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Lẹ́tà ìmọrírì àti ìwé ẹ̀rí ìgbóríyìnfúnni
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Maria àtàwọn òbí rẹ̀ lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi