Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ipò Wa Tó Ń Yí Padà Jẹ́ Ká Lè Wàásù Láwọn Ibi Jíjìnnà Réré

Ipò Wa Tó Ń Yí Padà Jẹ́ Ká Lè Wàásù Láwọn Ibi Jíjìnnà Réré

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Ipò Wa Tó Ń Yí Padà Jẹ́ Ká Lè Wàásù Láwọn Ibi Jíjìnnà Réré

GẸ́GẸ́ BÍ RICARDO MALICSI TI SỌ Ọ́

Nígbà tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ mi nítorí pé mo rọ̀ mọ́ ìlànà Kristẹni, èmi àti ìdílé mi bẹ Jèhófà pé kó kọ́ wa bá a ṣe máa ṣètò ayé wa. Nínú àdúrà wa, a sọ fún un pé ó wù wá láti kópa gan-an nínú iṣẹ́ ìwàásù. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà la bẹ̀rẹ̀ sí ṣí kiri. Ṣíṣí kiri yìí gbé wa dé odindi orílẹ̀-èdè mẹ́jọ ní àgbègbè méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láyé. Èyí jẹ́ ká lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láwọn ibi jíjìnnà réré.

ỌDÚN 1933 ni wọ́n bí mi ní ilẹ̀ Philippines. Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Philippines sì ni gbogbo àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rìnlá tá a wà nínú ìdílé wa ń lọ. Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún méjìlá, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí n mọ èwo gan-an ni ìsìn tòótọ́. Ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ mi forúkọ mi sílẹ̀ ní kíláàsì tí wọ́n ti ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìsìn, bí mo sì ṣe di Kátólíìkì gidi nìyẹn. Mi ò pa ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ọjọọjọ́ Sátidé jẹ rí, bẹ́ẹ̀ ni mi ò lè ṣe é kí n má lọ sí Máàsì ọjọọjọ́ Sunday. Àmọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì nípa ohun tí wọ́n ń kọ́ mi, nígbà tó sì yá, àwọn ẹ̀kọ́ náà ò tẹ́ mi lọ́rùn mọ́. Ìbéèrè nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bá kú, nípa iná ọ̀run àpáàdì àti nípa ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ò yéé jà gùdù lọ́kàn mi. Ìdáhùn táwọn olórí ìsìn sì ń fún mi kò nítumọ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò tẹ́ mi lọ́rùn.

Mo Rí Ìdáhùn Tó Tẹ́ Mi Lọ́rùn

Nígbà tí mo wà ní Kọ́lẹ́ẹ̀jì, mo wọ ẹgbẹ́ òkùnkùn kan tó sọ mí dẹni tó ń jà, mò ń ta tẹ́tẹ́, mò ń mu sìgá, mo sì ń lọ́wọ́ sáwọn ìwàkiwà mìíràn tí kò yẹ ọmọlúwàbí. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, mo pàdé màmá ọmọ kíláàsì mi kan. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni màmá ọmọ náà. Ni mo bá bi í láwọn ìbéèrè tí mo ti bi àwọn olùkọ́ tó ń kọ mi lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn. Gbogbo ìbéèrè ti mo bi obìnrin náà pátá ló dáhùn rẹ̀ fún mi látinú Bíbélì, ó sì dá mi lójú pé òótọ́ lohun tó sọ.

Mo ra Bíbélì kan mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí gbogbo ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì pé “ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́,” mo sì dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ọ̀rẹ́kọ́rẹ̀ẹ́ tí mò ń bá rìn. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Èyí jẹ́ kí n lè tẹ̀ síwájú gan-an nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì mi mo sì ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi lọ́dún 1951, mo ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn àwọn òjíṣẹ́ tó ń wàásù nígbà gbogbo fúngbà díẹ̀. Nígbà tó sì di oṣù December ọdún 1953, mo fẹ́ Aurea Mendoza Cruz, tó wá di ẹnì kejì mi nígbèésí ayé mi àti alájọṣiṣẹ́ mi tòótọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù.

Ọlọ́run Dáhùn Àdúrà Wa

Ó wù wá gan-an láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Síbẹ̀, bó ṣe wù wá tó pé ká fi gbogbo àkókò wa sin Jèhófà, ọ̀rọ̀ ò tètè rí bá a ṣe rò ó. Àmọ́ a ò dákẹ́ àdúrà pé kí Jèhófà fún wa láǹfààní láti kó ipa tó pọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Nǹkan ò rọrùn fún wa rárá. Síbẹ̀ náà, a ò gbàgbé ohun tí à ń lé nípa tẹ̀mí, nígbà tí mo sì pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, wọn fi mí ṣe ìránṣẹ́ ìjọ, ìyẹn alábòójútó olùṣalága nínú ọ̀kan lára ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Bí ìmọ̀ mi nínú Bíbélì ti ń jinlẹ̀ sí i tí mo sì túbọ̀ ń lóye àwọn ìlànà Jèhófà dáadáa, mo rí i pé iṣẹ́ tí mò ń ṣe kò bá jíjẹ́ ti mo jẹ́ Kristẹni mu. (Aísáyà 2:2-4) Mo pinnu láti fi iṣẹ́ náà sílẹ̀. Ìdánwò ìgbàgbọ́ ni ìpinnu yìí jẹ́ fún wa. Báwo ni mo ṣe máa rówó gbọ́ bùkátà ìdílé mi? A tún mú ọ̀rọ̀ yìí tọ Jèhófà Ọlọ́run lọ nínú àdúrà. (Sáàmù 65:2) A sọ ìṣòro wa fún un àti ìbẹ̀rù wa nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀, àmọ́ a tún sọ fún un pé ó wù wá láti sìn ní ibi tí kò ti sáwọn tó ń wàásù Ìjọba rẹ̀. (Fílípì 4:6, 7) A ò mọ̀ rárá nígbà yẹn pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní láti wàásù la máa wá ní!

Ìrìn Àjò Wa Bẹ̀rẹ̀

Ní April ọdún 1965, mo rí iṣẹ́ kan ní Pápákọ̀ Òfuurufú Ńlá ti ìlú Vientiane, lórílẹ̀-èdè Laos, a sì ṣí lọ síbẹ̀. Iṣẹ́ náà jẹ́ ṣíṣe olùdarí àwọn tó ń paná ọkọ̀ òfuurufú tó bá já lulẹ̀ tí wọ́n sì ń yọ àwọn tó bá wà nínú rẹ̀. Ẹlẹ́rìí mẹ́rìnlélógún ló wà ní ìlú Vientiane, a sì gbádùn wíwàásù pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì àti ìwọ̀nba àwọn ará tó wà níbẹ̀. Lẹ́yìn náà ni wọ́n gbé mi lọ sí Pápákọ̀ Òfuurufú ìlú Udon Thani, lórílẹ̀-èdè Thailand. Kò sí Ẹlẹ́rìí kankan ní ìlú yìí. Èmi àti ìdílé mi nìkan là ń dá ṣe gbogbo ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. À ń wàásù láti ilé dé ilé, à ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, a sì ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa “bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀” ló máa ń wá sí wa lọ́kàn. (Jòhánù 15:8) A pinnu pé a óò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn a sì ń polongo ìhìn rere náà nìṣó. Kò pẹ́ tá a fi bẹ̀rẹ̀ sí rí àbájáde rẹ̀. Ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Thailand gba òtítọ́ ó sì di arábìnrin wa nípa tẹ̀mí. Àwọn méjì kan tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè tó wà lápá Àríwá Amẹ́ríkà náà gba òtítọ́, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi di alàgbà nínú ìjọ. Ó lé lọ́dún mẹ́wàá tá a fi wàásù ìhìn rere náà lápá àríwá Thailand. Inú wa dùn gan-an nígbà tá a gbọ́ pé ìjọ kan ti wà ní ìlú Udon Thani báyìí! Díẹ̀ lára àwọn irúgbìn tá a gbìn ṣì ń sèso lọ.

Àmọ́, ó dùn wá pé a tún ní láti ṣí kúrò níbẹ̀, a sì gbàdúrà sí “Ọ̀gá ìkórè” pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa wàásù nìṣó. (Mátíù 9:38) Ìlú Tehran tó jẹ́ olú-ìlú orílẹ̀-èdè Iran ni wọ́n gbé wa lọ. Èyí jẹ́ nígbà ìṣàkóso Shah.

A Wàásù Láwọn Ìpínlẹ̀ Tí Kò Rọrùn

Bá a ti ń gúnlẹ̀ sí ìlú Tehran, àwọn arákùnrin wa la kọ́kọ́ wá rí. A dara pọ̀ mọ́ àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kékeré kan tó jẹ́ pé orílẹ̀-èdè mẹ́tàlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni gbogbo wọn ti wá. A ní láti yí ọ̀nà tá à ń gbà wàásù padà ní orílẹ̀-èdè Iran. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ibẹ̀ ò ta kò wá ní tààràtà, síbẹ̀ ó gba pé ká ṣọ́ra.

Nítorí bí àkókò iṣẹ́ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ṣe rí, a máa ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀gànjọ́ òru nígbà mìíràn tàbí ní fẹ̀ẹ̀rẹ̀ kílẹ̀ mọ́. Síbẹ̀, inú wa dùn gan-an nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í rí èrè iṣẹ́ àṣekára yẹn! Àwọn ìdílé kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Philippines àtàwọn ìdílé kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kòríà gba òtítọ́, wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà.

Ìlú Dhaka lórílẹ̀-èdè Bangladesh ni iṣẹ́ tún gbé mi lọ. Oṣù December ọdún 1977 la débẹ̀. Orílẹ̀-èdè yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tí iṣẹ́ ìwàásù wa kò ti rọrùn láti ṣe. Síbẹ̀, a máa ń fi sọ́kàn pé a ò gbọ́dọ̀ dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró. Pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí Jèhófà, a rí ọ̀pọ̀ ìdílé tí wọ́n sọ pé Kristẹni làwọn. Òùngbẹ omi òtítọ́ tó ń tuni lára tó wà nínú Ìwé Mímọ́ sì ti ń gbẹ àwọn kan lára wọn. (Aísáyà 55:1) Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì la bẹ̀rẹ̀.

A máa ń fi sọ́kàn pé ìfẹ́ Jèhófà ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là.” (1 Tímótì 2:4) Inú wa dùn pé kò sẹ́ni tó bá wa fàjọ̀gbọ̀n. Ká lè borí ẹ̀tanú èyíkéyìí, a máa ń yọ̀ mọ́ àwọn èèyàn dáadáa nígbà tá a bá lọ wàásù fún wọn. Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, a gbìyànjú láti “di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo.” (1 Kọ́ríńtì 9:22) Nígbà táwọn èèyàn bá sì bi wá pé kí la bá wá, a máa ń fẹ̀sọ̀ ṣàlàyé fún wọn, a sì rí i pé ọ̀pọ̀ jù lọ wọn lára wọn yá mọ́ni.

Ní ìlú Dhaka yìí, a rí obìnrin kan níbẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí a sì rọ̀ ọ́ pé kó máa wá sáwọn ìpàdé ìjọ tí à ń ṣe, lẹ́yìn náà a tún rọ̀ ọ́ pé kó máa bá wa lọ sí iṣẹ́ ìwàásù. Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí, ìyàwó mi kọ́ ìdílé kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa wá sáwọn ìpàdé wa. Nípa inú rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà, gbogbo ìdílé náà wá sínú òtítọ́. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ wọn obìnrin méjì ṣèrànwọ́ láti tú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí èdè Bengali, ọ̀pọ̀ nínú ẹbí wọn ló sì wá mọ Jèhófà. Ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn náà tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gba òtítọ́. Èyí tó pọ̀ jù lára wọn sì ti di alàgbà nínú ìjọ báyìí tàbí aṣáájú ọ̀nà.

Nítorí pé àwọn èèyàn pọ̀ gan-an ni ìlú Dhaka, a ránṣẹ́ sí díẹ̀ lára àwọn mọ̀lẹ́bí wa pé kí wọ́n wá kún wa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn bíi mélòó kan ṣe bẹ́ẹ̀ wọ́n sì wá bá wa ní orílẹ̀-èdè Bangladesh. Inú wa dùn gan-an pé a lè lọ́wọ́ nínú wíwàásù ìhìn rere ní orílẹ̀-èdè yìí, a sì dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà fún àǹfààní náà! Látorí ẹnì kan ṣoṣo tó kọ́kọ́ dára pọ̀ mọ́ wa, ìjọ méjì ló ti wà lórílẹ̀-èdè Bangladesh báyìí.

Ní oṣù July ọdún 1982, á tún ní láti kó ẹrù wa, ká sì kúrò lórílẹ̀-èdè Bangladesh. Ńṣe lomi ń bọ́ lójú wa bá a ti ń fi àwọn arákùnrin wa sílẹ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Pápákọ̀ Òfuurufú Ńlá ti Entebbe lórílẹ̀-èdè Uganda, níbi tá a ti lo ọdún mẹ́rin àti oṣù méje. Ìbéèrè tá a bi ara wa nígbà tá a débẹ̀ ni pé, kí la lè ṣe láti gbé orúkọ ńlá Jèhófà ga lórílẹ̀-èdè yìí?

A Wàásù Ní Ìla Oòrùn Áfíríkà

Bá a ti ń gúnlẹ̀ sí Pápákọ̀ Òfuurufú Ńlá ti Entebbe, awakọ̀ kan gbé èmi àti ìyàwó mi lọ sí ibi tí a óò máa gbé. Bá a ti gbéra ní pápákọ̀ náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí wàásù fún awakọ̀ náà nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ló bá bi mí pé: “Ṣé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni yín ni?” Nígbà tí mo dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, ó ní: “Ọ̀kan lára yín ń ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń darí ọkọ̀ òfuurufú.” Kíá, mo ní kó máa gbé mi lọ síbẹ̀. A rí arákùnrin náà, inú òun náà sì dùn gan-an láti rí wa, la bá ṣe ètò ìpàdé àti òde ẹ̀rí.

Lákòókò náà, àwọn akédé Ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ igba àti méjìdínlọ́gbọ̀n [228] péré ló wà lórílẹ̀-èdè Uganda. Àwa àtàwọn arákùnrin méjì kan ní ìlú Entebbe kọ́kọ́ fi ọdún kan àkọ́kọ́ tá a lò níbẹ̀ gbin irúgbìn òtítọ́. Níwọ̀n báwọn èèyàn ibẹ̀ ti fẹ́ràn láti máa kàwé, ọ̀pọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwé ìròyin la fún àwọn èèyàn. A sọ fáwọn arákùnrin tó wà ní ìlú Kampala tí í ṣe olú-ìlú orílẹ̀-èdè Uganda pé kí wọ́n wá ràn wá lọ́wọ́ láti wàásù ní Entebbe lópin ọ̀sẹ̀. Nígbà àsọyé tí mo kọ́kọ́ sọ níbẹ̀, èèyàn márùn-ún péré ló wà níbẹ̀, mo sì wà lára àwọn márùn-ún yìí.

Ní ọdún mẹ́ta tó tẹ̀ lé e, ohun kan tó múnú wa dùn jù lọ nígbèésí ayé wa ṣẹlẹ̀. A rí i báwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ń yára tẹ̀ síwájú. (3 Jòhánù 4) Nígbà ìpàdé àyíká kan, àwọn mẹ́fà lára àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ṣèrìbọmi lẹ́ẹ̀kan náà. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa ń gba àkókò, báwọn ṣe rí i tá à ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà fún àwọn níṣìírí láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn náà.

A ronú pé ibi iṣẹ́ oúnjẹ òójọ́ wa náà lè jẹ́ ìpínlẹ̀ tó ń méso jáde. Nígbà kan, mo bá òṣìṣẹ́ pánápáná kan ní pápákọ̀ òfuurufú sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tó wà nínú Bíbélì nípa ìgbésí ayé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Mo fi hàn án nínú Bíbélì rẹ̀ pé àwọn èèyàn tó bá ṣègbọràn yóò máa gbé ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan. Pé kò ní sí ìnira àti àìríjẹrímu mọ́. Àwọn èèyàn á rí ilé gbé, kò sì ní sí ogun, àìsàn, àti ikú mọ́. (Sáàmù 46:9; Aísáyà 33:24; 65:21, 22; Ìṣípayá 21:3, 4) Bó ṣe ka àwọn nǹkan wọ̀nyí nínú Bíbélì tirẹ̀ fúnra rẹ̀ mú kó fẹ́ láti mọ̀ sí i. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó bẹ̀rẹ̀ sí wá sí gbogbo ìpàdé. Kò sì pẹ́ tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà tó sì ṣèrìbọmi. Òun náà dára pọ̀ mọ́ wa nínú iṣẹ́ ìwáàsù alákòókò kíkún tí à ń ṣe.

Nígbà tá a wà ní orílẹ̀-èdè Uganda, ẹ̀ẹ̀mejì ni rògbòdìyàn ńlá bẹ́ sílẹ̀, àmọ́ èyí kò dá àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí wa dúró rárá. Wọ́n kó àwọn ẹ̀bí àwa tá à ń ṣiṣẹ́ fún àwọn àjọ tó ń ṣojú ilẹ̀ òkèèrè lọ sílùú Nairobi ní orílẹ̀-èdè Kenya, wọ́n sì gbé ibẹ̀ fún oṣù mẹ́fà. Àwa tá a kù ní Uganda sì ń ṣe àwọn ìpàdé ìjọ nìṣó, bẹ́ẹ̀ la sì ń bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọgbọ́n la fi ń ṣe é.

Ní oṣù April ọdún 1988, mo parí iṣẹ́ mi ní Uganda, a sì tún kúrò níbẹ̀. Ọkàn wa balẹ̀ gan-an bá a ti ń fi Ìjọ Entebbe sílẹ̀, nítorí pé ìjọ náà ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. A láǹfààní láti tún ṣèbẹ̀wò sí ìlú Entebbe lóṣù July ọdún 1997. Nígbà tá a débẹ̀, díẹ̀ lára àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti di alàgbà nínú ìjọ. Inú wa dùn gan-an nígbà tá a rí ọgọ́rùn-ún kan ó lé mẹ́fà èèyàn tí wọ́n wá gbọ́ àsọyé tó wà fún gbogbo èèyàn!

A Ṣí Lọ sí Ìpínlẹ̀ Tẹ́nì Kankan Kò Tíì Wàásù Rí

Ǹjẹ́ a ó ṣì tún láǹfààní láti wàásù láwọn ibòmíràn? Bẹ́ẹ̀ ni, Pápákọ̀ Ńlá ìlú Mogadishu, lórílẹ̀-èdè Somalia ni iṣẹ́ tún gbé mi lọ. A pinnu pé a ó lo àǹfààní tuntun tá a ní láti sìn ní ìpínlẹ̀ tẹ́nì kankan ò tíì wàásù rí yìí dáadáa.

Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ tó ń ṣojú ìjọba ilẹ̀ òkèèrè, àwọn òṣìṣẹ́ ọmọ ilẹ̀ Philipines, àtàwọn mìíràn tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè mìíràn nìkan la máa ń rí wàásù fún jù. Lọ́pọ̀ ìgbà, inú ọjà la ti máa ń bá wọn pàdé. A tún máa ń lọ sílé wọn láti lọ kí wọn bí ọ̀rẹ́. Nípa lílo ìdánúṣe, ọgbọ́n inú, òye àti nípa gbígbáralé Jèhófà pátápátá, ó ṣeé ṣe fún wa láti sọ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì fáwọn èèyàn, èyí sì méso jáde gan-an láàárín àwọn èèyàn tó wá láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. A kúrò ní Mogadishu lẹ́yìn tá a ti lo ọdún méjì níbẹ̀, kò pẹ́ rárá sígbà yẹn ni ogun bẹ́ sílẹ̀.

Ìlú Yangon lórílẹ̀-èdè Myanmar ni Àjọ Tó Ń Rí sí Ètò Ìrìnnà Ọkọ̀ Òfuurufú Lágbàáyé tún gbé mi lọ. Níbí yìí náà, a tún ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti ran àwọn èèyàn tó jẹ́ olóòótọ́ inú lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé. Lẹ́yìn tá a kúrò ní Myanmar, wọ́n gbé wa lọ sí ìlú Dar es Salaam, lórílẹ̀-èdè Tanzania. Ó rọrùn gan-an láti wàásù láti ilé dé ilé ní ìlú yìí nítorí pé àwọn èèyàn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì wà níbẹ̀.

Ní gbogbo orílẹ̀-èdè tá a ti lọ ṣiṣẹ́, a ò fi bẹ́ẹ̀ níṣòrò bá a ti ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ fàyè gba iṣẹ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ nítorí irú iṣẹ́ tí mò ń ṣe, èyí tó sábà máa ń jẹ mọ́ ṣíṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba tàbí àwọn àṣojú orílẹ̀-èdè mìíràn, àwọn èèyàn ò dí wa lọ́wọ́ ká má wàásù.

Iṣẹ́ oúnjẹ òójọ́ mi ló fà á tí èmi àti ìyàwó mi fi ń ṣí kiri fún odindi ọgbọ̀n ọdún. Àmọ́ àǹfààní la ka iṣẹ́ mi yìí sí, torí ó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti lépa ohun tó ṣe pàtàkì jù. Fífi Ìjọba Ọlọ́run ṣáájú lohun tó máa ń kọ́kọ́ wá sí wa lọ́kàn. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ò jẹ́ ká lè lo ipò wa yìí lọ́nà tó dára gan-an ó sì tún jẹ́ ká lè ní àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ yìí láti tan ìhìn rere kálẹ̀ láwọn ibi jíjìnnà réré.

A Padà Síbi Tá A Ti Bẹ̀rẹ̀

Nígbà ti mo dẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́ta, mo pinnu láti tètè fiṣẹ́ sílẹ̀ mo sì padà sí Philippines. Nígbà tá a padà sílé, a gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ ìṣísẹ̀ wa. A bẹ̀rẹ̀ sí í sìn ní ìjọ kan ní ìlú Trece Martires lágbègbè Cavite. Nígbà tá a kọ́kọ́ débẹ̀, àwọn mọ́kàndínlógún péré ló ń polongo Ìjọba Ọlọ́run níbẹ̀. A ṣètò pé kí iṣẹ́ ìwáàsù máa wáyé lójoojúmọ́, ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì la sì bẹ̀rẹ̀. Díẹ̀díẹ̀ ìjọ náà bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí ìyàwó mi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́kàndínlógún tí èmí sì ń ṣe mẹ́rìnlá.

Kò pẹ́ kò jìnnà, Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a ń lò kò gbà wá mọ́. A gbàdúrà sí Jèhófà nípa ìṣòro yìí. Arákùnrin wa kan àti ìyàwó rẹ̀ sọ pé àwọn á fún wa ní ilẹ̀, ẹ̀ka ọ́fíìsì sì yá wa lówó láti fi kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun. Gbọ̀ngàn tuntun yìí jẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ máa tẹ́tí sí ìwàásù wa gan-an, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ sì làwọn tó ń wá sípàdé ń pọ̀ sí i. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, a tún ń ran ìjọ mìíràn tó ní akéde mẹ́tàdínlógún lọ́wọ́. Láti dé ìjọ yìí àti láti padà, ó máa ń gbà wá ju wákàtí méjì lọ.

Èmi àtìyàwó mi mọyì àǹfààní tá a ní láti sìn ní onírúurú orílẹ̀-èdè. Tá a bá bojú wẹ̀yìn wo ìgbésí ayé wa, ìyẹn bí a ti ń ṣí kiri, inú wa máa ń dùn gan-an pé a lo àǹfààní náà lọ́nà tó dára gan-an, nítorí ó jẹ́ kà lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà!

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

TANZANIA

UGANDA

SOMALIA

IRAN

BANGLADESH

MYANMAR

LAOS

THAILAND

PHILIPPINES

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Èmi àti Aurea, aya mi