Sísọ Òkò Ọ̀rọ̀ Síra Ẹni Èé Ṣe Tó Fi Máa Ń Dunni?
Sísọ Òkò Ọ̀rọ̀ Síra Ẹni Èé Ṣe Tó Fi Máa Ń Dunni?
“Láti orísun wo ni àwọn ogun ti wá, láti orísun wo sì ni àwọn ìjà ti wá láàárín yín?”—JÁKỌ́BÙ 4:1.
KÌ Í ṣe àwọn ọmọ ogun Róòmù tí wọ́n ń jagun àjàṣẹ́gun nígbà yẹn ni Jákọ́bù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì kọjú ìbéèrè yìí sí, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé ó ń béèrè ìdí táwọn Síkárì tá a tún mọ̀ sí àwọn ọkùnrin ọlọ́bẹ aṣóró fi ń jagun abẹ́lẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní. Ohun tó ń fa awuyewuye tó ń wáyé láàárín àwọn èèyàn tí kò ju méjì lọ ni Jákọ́bù ń béèrè. Kí nìdí? Ìdí ni pé bí ogun ṣe máa ń ba nǹkan jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni ìjà tó máa ń wáyé láàárín ẹni méjì ṣe máa ń ba nǹkan jẹ́. Gbé àwọn ìtàn Bíbélì tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.
Àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù tó jẹ́ baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kórìíra Jósẹ́fù àbúrò wọn débi tí wọ́n fi tà á lẹ́rú. (Jẹ́nẹ́sísì 37:4-28) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Sọ́ọ̀lù Ọba Ísírẹ́lì gbìyànjú àtipa Dáfídì. Nítorí kí ni? Nítorí pé ó ń ṣe ìlara Dáfídì ni. (1 Sámúẹ́lì 18:7-11; 23:14, 15) Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn Kristẹni obìnrin méjì tórúkọ wọn ń jẹ́ Yúódíà àti Síńtíkè bá ara wọn ṣe awuyewuye tó dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ.—Fílípì 4:2.
Láyé àtijọ́, ìbọn àti àdá làwọn méjì máa fi ń bá ara wọn jà. Ohun tó sábà máa ń jẹ́ àbájáde rẹ̀ ni pé kí ẹnì kan pa ẹnì kejì tàbí kó sọ ọ́ di aláàbọ̀ ara, èyí tí yóò máa rán jálẹ̀ ayé rẹ̀. Àmọ́ lóde òní, sísọ òkò ọ̀rọ̀ síra ẹni, ìyẹn ọ̀rọ̀ tó máa ń dunni wọra tó sì máa ń múnú bíni, lohun ìjà táwọn méjì tó ń bá ara wọn jà sábà máa ń lò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé sísọ òkò ọ̀rọ̀ síni kì í ṣe ohun tó lè ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ó máa ń dun ẹni tí wọ́n bá sọ ọ́ sí wọra ó sì lè ba orúkọ rere tẹ́ni náà ní jẹ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tí ọ̀rọ̀ ò kàn máa ń fara gbá nínú “ogun” yìí.
Ìwọ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn nígbà tí àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà kan fẹ̀sùn kan àlùfáà mìíràn pé ó ń ṣowó ìjọ báṣubàṣu. Nígbà tó yá, àwọn ọmọ ìjọ mọ̀ pé àwọn àlùfáà náà ń bára wọn jà, ìjọ sì pín sí méjì. Táwọn ọmọ ìjọ kan bá rí i pé àlùfáà táwọn ò gba tiẹ̀ ló fẹ́ darí ìsìn, wọn ò ní lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ́jọ́ náà. Inú tí àwọn ọmọ ìjọ ń bí síra wọn le débi tí wọ́n fi ń bá ara wọn yan odì nínú ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n bá wá jọ́sìn. Awuyewuye tá à
ń wí yìí tún wá le sí i nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn kan àlùfáà kejì pé òun náà ṣèṣekúṣe.Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ìlú Canterbury rọ àwọn àlùfáà méjèèjì náà pé kí wọ́n yé jà, ó pe ìjà tí wọ́n ń bára wọn jà náà ní “àrùn jẹjẹrẹ” ó sì sọ pé “ó ń tàbùkù sí orúkọ Olúwa Wa.” Ní ọdún 1997, ọ̀kan nínú àwọn àlùfáà náà gbà láti fẹ̀yìn tì. Èkejì wonkoko mọ́ ipò rẹ̀ títí tó fi dàgbà débi tó fi di dandan pé kó fiṣẹ́ àlùfáà sílẹ̀. Àmọ́, kò fiṣẹ́ àlùfáà sílẹ̀ títí dìgbà tó fi ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àádọ́rin ọdún ní ọjọ́ keje oṣù kẹjọ ọdún 2001. Ìwé ìròyìn kan tí wọ́n ń pè ní The Church of England Newspaper sọ pé ọjọ́ tí wọ́n máa ń ṣe ayẹyẹ Victricius “Mímọ́” ni àlùfáà yìí fẹ̀yìn tì. Ta ni wọ́n ń pè ní Victricius “Mímọ́”? Bíṣọ́ọ̀bù kan tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kẹrin ni wọ́n ń pè bẹ́ẹ̀. Bíṣọ́ọ̀bù yìí la gbọ́ pé wọ́n lù nítorí ó sọ pé òun ò lọ sógun. Ìwé ìròyìn náà wá sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìwà àlùfáà yìí àti ìwà Victricius “Mímọ́,” ó ní: “Àlùfáà [tó fẹ̀yìn tì yìí] kì í ṣe ẹni tó lè kọ̀ tí wọ́n bá fi ogun ẹ̀sìn lọ̀ ọ́ ní tiẹ̀.”
Ká sọ pé àwọn àlùfáà náà ti fi ohun tó wà nínú Róòmù 12:17, 18 sílò ni, wọn ì bá tí ṣe ohun tó máa dun ara wọn àtàwọn ẹlòmíràn tó bẹ́ẹ̀. Ẹsẹ Bíbélì náà sọ pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. Ẹ pèsè àwọn ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lójú gbogbo ènìyàn. Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”
Ìwọ náà ńkọ́? Tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn ẹ́, ṣe inú á bí ẹ débi tó o fi máa sọ òkò ọ̀rọ̀ sí onítọ̀hún? Àbí wàá yẹra fún sísọ ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí wàá sì máa wá bí àlàáfíà ṣe máa jọba? Tó o bá ṣẹ ẹnì kan, ṣé kì í ṣe pé ńṣe lo máa ń bá ẹni náà yan odì, tí wàá máa rò pé tó bá yá, á gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ tó o ṣẹ̀ ẹ́? Àbí ńṣe lo máa ń tọrọ àforíjì? Yálà o tọrọ àforíjì tàbí o dárí ji ẹlòmíràn, tó o bá gbìyànjú láti jẹ́ kí àlàáfíà jọba, wàá láyọ̀. Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí á ṣe fi hàn, ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú aáwọ̀ tó ti wà nílẹ̀ tipẹ́tipẹ́.