Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Sámúẹ́lì Kìíní

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Sámúẹ́lì Kìíní

Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Sámúẹ́lì Kìíní

ỌDÚN 1117 ṣáájú Sànmánì Tiwa ni ohun tá a fẹ́ dẹ́nu lé yìí ṣẹlẹ̀. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ọdún ti kọjá lẹ́yìn tí Jóṣúà gba Ilẹ̀ Ìlérí. Àwọn àgbà ọkùnrin ilẹ̀ Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ wòlíì Jèhófà, wọ́n sì sọ fún un pé àwọn ń fẹ́ ọba, ohun kan tí kò ṣẹlẹ̀ rí. Wòlíì náà gbàdúrà lórí ọ̀ràn náà, Jèhófà sì fún wọn ní ohun tí wọ́n ń fẹ́. Èyí fi hàn gbangba pé àkókò táwọn Onídàájọ́ ń ṣàkóso nílẹ̀ Ísírẹ́lì ti dópin, àwọn ọba tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn ni yóò sì máa ṣàkóso láti àkókò yìí lọ. Ìwé Sámúẹ́lì Kìíní sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ń tani jí, tó wáyé ní àkókò pàtàkì yẹn nínú ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì.

Sámúẹ́lì, Nátánì àti Gádì ló kọ ìwé Sámúẹ́lì Kìíní, ọdún méjìlélọ́gọ́rùn-ún ló sì gbà kí wọ́n tó kọ ọ́ tán, ìyẹn láti ọdún 1180 sí 1078 ṣáájú Sànmánì Tiwa. (1 Kíróníkà 29:29) Ìwé yìí sọ ìtàn àwọn aṣáájú mẹ́rin nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Méjì lára wọn jẹ́ onídàájọ́, nígbà tí méjì jẹ́ ọba; méjì ṣègbọràn sí Jèhófà, àmọ́ aláìgbọràn làwọn méjì yòókù. Ìwé yìí tún jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn obìnrin méjì tí wọ́n jẹ àwòkọ́ṣe, àti nípa jagunjagun onígboyà kan tó jẹ́ èèyàn jẹ́jẹ́. Àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì nípa irú àwọn ìwà tó yẹ ká máa hù àtèyí tí kò yẹ ká hù. Nítorí náà, àwọn ohun tó wà nínú ìwé Sámúẹ́lì Kìíní yóò túbọ̀ mú kí èrò ọkàn àti ìṣesí wa dára sí i.—Hébérù 4:12.

SÁMÚẸ́LÌ DI ONÍDÀÁJỌ́ LẸ́YÌN ÉLÌ

(1 Sámúẹ́lì 1:1–7:17)

Ìgbà Àjọyọ̀ Ìkórèwọlé ni. Inú obìnrin kan tó ń jẹ́ Hánà, ẹni tó ń gbé nílùú Rámà, ń dùn gan-an nítorí pé Jèhófà ti dáhùn àdúrà rẹ̀, ó ti bí ọmọkùnrin kan. a Kí Hánà lè mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ ṣẹ, ó mú ọmọ rẹ̀ Sámúẹ́lì wá sí “ilé Jèhófà” kó lè máa ṣiṣẹ́ sin Jèhófà níbẹ̀. Ọmọ náà sì di “òjíṣẹ́ Jèhófà níwájú Élì àlùfáà.” (1 Sámúẹ́lì 1:24; 2:11) Nígbà tí Sámúẹ́lì ṣì kéré gan-an, Jèhófà bá a sọ̀rọ̀, ó sọ fún un pé òun máa dá ilé Élì lẹ́jọ́. Bí Sámúẹ́lì ṣe ń dàgbà sí i, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá mọ̀ pé wòlíì Jèhófà ni.

Nígbà tó yá, àwọn Filísínì wá bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jagun. Wọ́n gba àpótí ẹ̀rí, wọ́n sì pa àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì. Nígbà tí ìròyìn yìí dé etígbọ̀ọ́ Élì tó ti di darúgbó, ojú ẹsẹ̀ ló kú, lẹ́yìn tó ti “ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì fún ogójì ọdún.” (1 Sámúẹ́lì 4:18) Àmọ́, àjálù ni gbígbà táwọn Filísínì gba àpótí náà já sí fún wọn, èyí ló sì mú kí wọ́n dá a padà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Sámúẹ́lì ni onídàájọ́ Ísírẹ́lì lákòókò tá à ń wí yìí, gbogbo ìlú ló sì tòrò minimini.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:

2:10—Kí nìdí tí Hánà fi gbàdúrà sí Jèhófà pé kó “fi okun fún ọba rẹ̀” nígbà tó jẹ́ pé kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó jẹ́ ọba ní Ísírẹ́lì? Ó ti wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin Mósè pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò fi èèyàn jẹ ọba wọn. (Diutarónómì 17:14-18) Nígbà tí Jákọ́bù sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ kó tó kù, ó sọ pé: “Ọ̀pá aládé [tó jẹ́ àmì ìṣàkóso] kì yóò yà kúrò lọ́dọ̀ Júdà.” (Jẹ́nẹ́sísì 49:10) Bákan náà, nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa Sárà, ìyá ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó ní: “Àwọn ọba àwọn ènìyàn yóò sì wá láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 17:16) Ọba tó máa jẹ lọ́jọ́ iwájú ni Hánà ń gbàdúrà nípa rẹ̀.

3:3—Ǹjẹ́ inú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ni Sámúẹ́lì ń sùn lóòótọ́? Rárá o. Ọmọ Léfì ni Sámúẹ́lì, àmọ́ ìdílé Kóhátì tí kì í ṣe ìdílé àlùfáà ló ti wá. (1 Kíróníkà 6:33-38) Nípa bẹ́ẹ̀, kò lẹ́tọ̀ọ́ láti “wọlé lọ wo àwọn ohun mímọ́.” (Númérì 4:17-20) Apá ibì kan ṣoṣo tí Sámúẹ́lì lè lò sí ni àgbàlá àgọ́ ìjọsìn. Ó ní láti jẹ́ pé ibẹ̀ ló ń sùn sí. Bákan náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ibì kan nínú àgbàlá náà ni Élì ń sùn sí. Nítorí náà, ó hàn gbangba pé àgbàlá àgọ́ ìjọsìn ni gbólóhùn yìí, “níbi tí àpótí Ọlọ́run wà” ń tọ́ka sí.

7:7-9, 17—Kí nìdí tí Sámúẹ́lì fi lọ rú ẹbọ sísun ní Mísípà, tó sì lọ mọ pẹpẹ ní Rámà, nígbà tó jẹ́ pé ibi tí Jèhófà yàn nìkan ló yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti máa rúbọ ní gbogbo ìgbà? (Diutarónómì 12:4-7, 13, 14; Jóṣúà 22:19) Lẹ́yìn táwọn ọ̀tá ti gbé àpótí ẹ̀rí kúrò ní àgọ́ ìjọsìn ní Ṣílò, kò sí ohunkóhun mọ́ níbẹ̀ tó fi hàn pé Jèhófà ṣì wà láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ìdí nìyẹn tí Sámúẹ́lì, aṣojú Ọlọ́run, fi rú ẹbọ sísun ní Mísípà tó sì tún mọ pẹpẹ ní Rámà. Ó dájú pé Jèhófà fọwọ́ sí àwọn ohun tí Sámúẹ́lì ṣe yìí.

Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:

1:11, 12, 21-23; 2:19. Hánà kì í fi àdúrà ṣeré, ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ẹ̀dá, ó mọrírì inú rere Jèhófà, ó sì fẹ́ràn ọmọ tó bí gidigidi. Ó yẹ kí gbogbo àwọn obìnrin olùbẹ̀rù Ọlọ́run tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.

1:8. Ẹlikénà jẹ́ ẹnì kan tó máa ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ gbé àwọn ẹlòmíràn ró. Á mà dára gan-an o tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀! (Jóòbù 16:5) Nígbà tí Ẹlikénà rí i pé ohun kan ń ba Hánà ìyàwó òun lọ́kàn jẹ́, ó fi ohùn pẹ̀lẹ́ béèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ rẹ̀, ó ní: ‘Èé ṣe tí ìbànújẹ́ fi dé bá ọkàn-àyà rẹ?’ Èyí mú kí Hánà tú kẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀. Lẹ́yìn náà ni Ẹlikénà fi í lọ́kàn balẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó ní: “Èmi kò ha sàn fún ọ ju ọmọkùnrin mẹ́wàá lọ bí?”

2:26; 3:5-8, 15, 19. Bí a bá ń sa gbogbo ipá wa nínú iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wa, tí à ń fi àwọn ẹ̀kọ́ tí ètò àjọ Ọlọ́run ń kọ́ wa sílò, tá a sì jẹ́ ọmọlúwàbí àti onírẹ̀lẹ̀ ẹ̀dá, a óò di ẹni tí Ọlọ́run àtàwọn èèyàn bíi tiwa ‘túbọ̀ fẹ́ràn.’

4:3, 4, 10. Àní àpótí májẹ̀mú tó jẹ́ ohun mímọ́ pàápàá kò ṣiṣẹ́ bí oògùn ààbò fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ “ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.”—1 Jòhánù 5:21.

ỌBA TÓ KỌ́KỌ́ JẸ NÍ ÍSÍRẸ́lÌ —ǸJẸ́ Ó ṢE OHUN TÍ ỌLỌ́RUN FẸ́?

(1 Sámúẹ́lÌ 8:1–15:35)

Sámúẹ́lì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, àmọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ kò ṣèfẹ́ Jèhófà. Nígbà táwọn àgbà ọkùnrin ilẹ̀ Ísírẹ́lì sọ pé àwọn fẹ́ ọba tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn, Jèhófà gbà kí wọ́n ní in. Sámúẹ́lì wá tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jèhófà, ó lọ fòróró yan Sọ́ọ̀lù, arẹwà ọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ìran Bẹ́ńjámínì. Sọ́ọ̀lù lọ ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámónì kó lè túbọ̀ fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.

Lọ́jọ́ kan, Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù ọba, tó jẹ́ akọni jagunjagun, lọ ṣá àwọn jagunjagun Filísínì balẹ̀ níbi tí wọ́n pabùdó sí. Nígbà táwọn ọmọ ogun Filísínì máa wá bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jagun, wọ́n pọ̀ bí eéṣú. Èyí dẹ́rù ba Sọ́ọ̀lù débi pé ó ṣàìgbọràn nípa rírú ẹbọ sísun fúnra rẹ̀. Onígboyà ni Jónátánì ní tirẹ̀. Ó mú ẹni tó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ nìkan ṣoṣo dání, àwọn méjèèjì sì lọ ṣe àwọn ọmọ ogun Filísínì lọ́ṣẹ́ níbòmíràn tí wọ́n kóra jọ sí. Ṣùgbọ́n, ìbúra tí Sọ́ọ̀lù fi ìwàǹwára ṣe kò jẹ́ kí wọ́n lè ráyè ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá tán pátápátá. Lẹ́yìn èyí, Sọ́ọ̀lù ń ‘bá gbogbo ọ̀tá rẹ̀ jagun yíká-yíká.’ (1 Sámúẹ́lì 14:47) Lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù ṣẹ́gun àwọn ará Ámálékì, ó tún ṣàìgbọràn sí Jèhófà nítorí pé kò run àwọn ohun tí Jèhófà “yà sọ́tọ̀ fún ìparun.” (Léfítíkù 27:28, 29) Ìyẹn ló mú kí Jèhófà kọ Sọ́ọ̀lù lọ́ba.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:

9:9—Kí lohun tó ṣe pàtàkì nínú gbólóhùn yìí, “wòlíì òde òní ni a ń pè ní aríran ní àwọn ìgbà àtijọ́”? Ó ṣeé ṣe kí gbólóhùn yìí túmọ̀ sí pé, bí àwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn wòlíì dáadáa nígbà ayé Sámúẹ́lì àti nígbà táwọn ọba ń ṣàkóso nílẹ̀ Ísírẹ́lì ló di pé wọ́n ń pe “aríran” ní “wòlíì.” Sámúẹ́lì sì lẹni tí wọ́n kọ́kọ́ kà sí wòlíì.—Ìṣe 3:24.

14:24-32, 44, 45—Ǹjẹ́ Ọlọ́run bínú sí Jónátánì nítorí pé ó lá oyin lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù ti búra pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ fi ohunkóhun sẹ́nu? Ó dà bíi pé ohun tí Jónátánì ṣe yìí kò bí Ọlọ́run nínú. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jónátánì kò mọ̀ pé bàbá òun ti búra. Síwájú sí i, ńṣe ni ìbúra náà kó àwọn èèyàn sí ìṣòro. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìtara òdì tí Sọ́ọ̀lù ní tàbí agbára tó ń gùn ún nítorí pé ó jẹ́ ọba ló mú kó ṣe ìbúra yìí. Báwo ni Ọlọ́run ṣe lè fọwọ́ sí irú ìbúra bẹ́ẹ̀? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jónátánì gbà pé òun fara mọ́ ohunkóhun tó bá tìdí lílá tí òun lá oyin náà yọ, síbẹ̀ wọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.

15:6—Kí nìdí tí Sọ́ọ̀lù fi fi inú rere àrà ọ̀tọ̀ hàn sí àwọn Kénì? Àwọn Kénì jẹ́ ọmọ bàbá ìyàwó Mósè. Wọ́n ṣèrànwọ́ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n kúrò ní Òkè Sínáì. (Númérì 10:29-32) Bákan náà, àwọn Kénì gbé àárín àwọn ọmọ Júdà fúngbà díẹ̀ nílẹ̀ Kénáánì. (Àwọn Onídàájọ́ 1:16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kénì lọ gbé àárín àwọn ọmọ Ámálékì àtàwọn èèyàn míì lẹ́yìn náà, ẹ̀mí àlàáfíà ni wọ́n fi ń bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò. Ìdí nìyẹn tí Sọ́ọ̀lù fi dá ẹ̀mí wọn sí.

Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:

9:21; 10:22, 27. Sọ́ọ̀lù mọ ìwọ̀n ara rẹ̀, ó sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ nígbà tó kọ́kọ́ di ọba, èyí ni kò jẹ́ kó ṣìwà hù nígbà tí “àwọn ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun” ò gbà pé kó jọba lé àwọn lórí. Dájúdájú, táwa náà bá nírú ìwà yìí, a ò ní ṣe àwọn ohun tí kò bọ́gbọ́n mu!

12:20, 21. Má ṣe jẹ́ kí àwọn ohun tó jẹ́ “òtúbáńtẹ́” mú kó o ṣíwọ́ sísin Jèhófà, ì báà jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé èèyàn, gbígbára lé ẹgbẹ́ ọmọ ogun orílẹ̀-èdè tàbí ìbọ̀rìṣà.

12:24. Ohun pàtàkì kan tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká bàa lè máa bẹ̀rù Jèhófà látọkànwá ká sì máa fi gbogbo ọkàn wa sìn ín ni pé ká máa ‘kíyè sí àwọn ohun ńlá tó ti ṣe’ fún àwọn èèyàn rẹ̀ láyé ọjọ́un àti láyé ìsinsìnyí.

13:10-14; 15:22-25, 30. Ṣọ́ra fún ìwà ìkùgbù, ì báà jẹ́ híhùwà àìgbọràn tàbí jíjẹ́ ẹlẹ́mìí ìgbéraga.—Òwe 11:2.

Ọ̀DỌ́MỌKÙNRIN OLÙṢỌ́ ÀGÙNTÀN KAN LẸNI TÍ WỌ́N FẸ́ FI JỌBA

(1 Sámúẹ́lì 16:1–31:13)

Sámúẹ́lì fòróró yan Dáfídì tó wá láti ẹ̀yà Júdà gẹ́gẹ́ bí ọba lọ́la. Kété lẹ́yìn èyí ni Dáfídì fi kànnàkànnà àti ẹyọ òkúta kan pa òmìrán ilẹ̀ Filísínì tó ń jẹ́ Gòláyátì. Dáfídì àti Jónátánì wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ lẹ́yìn èyí. Sọ́ọ̀lù fi Dáfídì ṣe olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Nígbà táwọn obìnrin Ísírẹ́lì sì rí bí Dáfídì ṣe ń jagun mólú ṣáá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọrin pé: “Sọ́ọ̀lù ti ṣá ẹgbẹẹgbẹ̀rún tirẹ̀ balẹ̀, àti Dáfídì ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá tirẹ̀.” (1 Sámúẹ́lì 18:7) Orin tí wọ́n kọ yìí mú kí Sọ́ọ̀lù máa jowú Dáfídì burúkú-burúkú débi pé ó bẹ̀rẹ̀ sí lépa ẹ̀mí Dáfídì. Nígbà tó ti gbìyànjú lẹ́ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ kò tẹ Dáfídì ni Dáfídì bá fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ, ó wá dẹni tó ń sá kiri.

Láwọn ọdún tí Dáfídì fi ń sá kiri, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Sọ́ọ̀lù kó sí i lọ́wọ́ àmọ́ ó dá ẹ̀mí rẹ̀ sí. Nígbà tó yá, ó pàdé arẹwà obìnrin kan tó ń jẹ́ Ábígẹ́lì, ó sì fi í ṣaya lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Nígbà táwọn Filísínì fẹ́ kógun wá bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Sọ́ọ̀lù lọ ṣèwádìí lọ́dọ̀ Jèhófà. Àmọ́ Jèhófà ti fi í sílẹ̀. Sámúẹ́lì sì ti kú. Nígbà tí gbogbo nǹkan tojú sú Sọ́ọ̀lù tí kò mọ ohun tí ì bá ṣe, ó gba ọ̀dọ̀ abẹ́mìílò lọ, abẹ́mìílò náà sì sọ fún un pé ó máa bá ogun lọ tó bá lọ bá àwọn Filísínì jà. Wọ́n ṣe Sọ́ọ̀lù léṣe gan-an nínú ogun yẹn, wọ́n sì pa àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Ìparí ìtàn yìí fi hàn pé títí di ọjọ́ ikú Sọ́ọ̀lù, kò ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Àmọ́, Dáfídì ní tirẹ̀ ṣì ń sá kiri.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:

16:14—Ẹ̀mí búburú wo ló ń yọ Sọ́ọ̀lù lẹ́nu? Ẹ̀mí búburú tí kò jẹ́ kí ọkàn Sọ́ọ̀lù lélẹ̀ ni èrò ibi tó wà nínú ọkàn rẹ̀ èyí tó ń tì í ṣe ohun tí kò dára. Nígbà tí Jèhófà mú ẹ̀mí rẹ̀ kúrò lára Sọ́ọ̀lù, kò rí ìtìlẹyìn ẹ̀mí mímọ́ mọ́, bí ẹ̀mí búburú ṣe gbà á lọ́kàn nìyẹn. Nítorí pé Ọlọ́run fàyè gba ẹ̀mí yìí láti rọ́pò ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ ni Bíbélì ṣe pè é ní “ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.”

17:55—Gẹ́gẹ́ bí 1 Sámúẹ́lì 16:17-23 ṣe sọ, kí nìdí tí Sọ́ọ̀lù fi ń béèrè ẹni tó jẹ́ bàbá Dáfídì? Kì í wulẹ̀ ṣe orúkọ bàbá Dáfídì ni Sọ́ọ̀lù fẹ́ mọ̀. Àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ńṣe ló fẹ́ mọ irú ẹni tó bí ọmọ tó ṣe bẹbẹ yẹn, tó lọ ṣá òmìrán balẹ̀.

Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:

16:6, 7. Dípò tí a ó fi máa fi ìrísí àwọn èèyàn kà wọ́n sí ẹni rere tàbí ẹni burúkú, irú ojú tí Jèhófà fi ń wò wọ́n ló yẹ ká máa fi wò wọ́n.

17:47-50. A lè fi ìgboyà dojú kọ àtakò tàbí inúnibíni táwọn ọ̀tá alágbára bíi Gòláyátì bá ń ṣe sí wa nítorí pé “ti Jèhófà ni ìjà ogun.”

18:1, 3; 20:41, 42. A lè rí àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ láàárín àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.

21:12, 13. Jèhófà fẹ́ ká lo làákàyè àti òye wa láti fi yanjú àwọn ìṣòro tá a bá ní. Ó ti fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí, èyí tó lè jẹ́ ká ní ìmọ̀, ọgbọ́n àti agbára láti ronú. (Òwe 1:4) Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn alàgbà tún wà nínú ìjọ tí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́.

24:6; 26:11. Dáfídì bọ̀wọ̀ fún ẹni àmì òróró Jèhófà gan-an! Àwa náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ dáradára rẹ̀.

25:23-33. Ábígẹ́lì jẹ́ ọlọgbọ́n obìnrin, àwa náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.

28:8-19. Kí àwọn ẹ̀mí burúkú lè ṣi àwọn èèyàn lọ́nà tàbí kí wọ́n lè ṣe ìpalára fún wọn, wọ́n máa ń díbọ́n bí ẹni pé àwọn ni ẹnì kan tó ti kú. A kò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tó bá jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò.—Diutarónómì 18:10-12.

30:23, 24. Ìpinnu tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, tó dá lórí ohun tó wà nínú Númérì 31:27, fi hàn pé Jèhófà fojú pàtàkì wo àwọn tó ń kọ́wọ́ ti àwọn alábòójútó lẹ́yìn nínú ìjọ. Nítorí náà, ohun yòówù ká máa ṣe, ẹ jẹ́ ká máa “fi tọkàntọkàn ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà, kì í sì í ṣe fún ènìyàn.”—Kólósè 3:23.

Kí Ló “Sàn Ju Ẹbọ” Rírú Lọ?

Ẹ̀kọ́ pàtàkì tó jẹ́ òtítọ́ pọ́ńbélé wo ni ìtàn Élì, Sámúẹ́lì, Sọ́ọ̀lù àti ti Dáfídì kọ́ wa? Òun ni pé: “Ṣíṣègbọràn sàn ju ẹbọ, fífetísílẹ̀ sàn ju ọ̀rá àwọn àgbò; nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀ jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ ìwoṣẹ́, fífi ìkùgbù ti ara ẹni síwájú sì jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú lílo agbára abàmì àti ère tẹ́ráfímù.”—1 Sámúẹ́lì 15:22, 23.

Dájúdájú, àǹfààní ńláǹlà ló jẹ́ fún wa pé a wà lára àwọn tó ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run tó sì ń sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn jákèjádò ayé! Bí a ṣe ń fi “ẹgbọrọ akọ màlúù ètè wa rúbọ” sí Jèhófà, a gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti rí i pé à ń ṣègbọràn sí ìtọ́sọ́nà tí Ọlọ́run ń tipasẹ̀ Bíbélì àti ètò àjọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé fún wa.—Hóséà 14:2; Hébérù 13:15.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ mọ àwọn àgbègbè tí ìwé Sámúẹ́lì Kìíní dárúkọ, wo ojú ìwé 18 àti 19 nínú ìwé pẹlẹbẹ Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà, èyí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Sọ́ọ̀lù mọ ìwọ̀n ara rẹ̀ ó sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ nígbà tó kọ́kọ́ di ọba, àmọ́ nígbà tó yá, ó di ọba agbéraga àti ẹni tó ń kọjá àyè rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Kí ló yẹ kó dá wa lójú nígbà táwọn ọ̀tá alágbára bíi ti Gòláyátì bá ń gbógun tì wá?