Ìṣẹ̀lẹ̀ Tó Yẹ Ká Ṣe Ìrántí Rẹ̀
Ìṣẹ̀lẹ̀ Tó Yẹ Ká Ṣe Ìrántí Rẹ̀
KÍ NI ìṣẹ̀lẹ̀ náà? Ikú ọkùnrin kan tó kú ní nǹkan bí ẹgbẹ̀wá [2,000] ọdún sẹ́yìn ni. Ọkùnrin náà sọ pé: “Mo fi ọkàn mi lélẹ̀, kí n lè tún rí i gbà. Kò sí ènìyàn kankan tí ó gbà á kúrò lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n mo fi í lélẹ̀ ní ìdánúṣe ti ara mi.” (Jòhánù 10:17, 18) Jésù Kristi ni ọkùnrin náà.
Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣe Ìrántí ikú tí òun kú láti fi ṣe ìrúbọ. Orúkọ mìíràn tí a tún ń pe ìrántí yìí ni “oúnjẹ alẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 11:20) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ọ̀rẹ́ wa yóò ṣe Ìrántí yìí, tí Jésù fi lọ́lẹ̀ ní ìrántí ikú rẹ̀, ní Thursday, March 24, 2005, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀.
Lọ́jọ́ náà, a óò sọ àsọyé kan tá a mú látinú Bíbélì tí yóò jẹ́ ká mọ ohun tí búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì pupa tá a máa lò níbẹ̀ túmọ̀ sí. (Mátíù 26:26-28) Àsọyé náà yóò tún jẹ́ ká rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bíi: Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn Kristẹni máa ṣe ìrántí ikú Jésù lemọ́lemọ́ tó? Àwọn wo ló yẹ kó jẹ búrẹ́dì àti wáìnì ìṣàpẹẹrẹ náà? Àwọn wo ló lè jàǹfààní nínú ikú Jésù? Ìrántí pàtàkì yìí yóò jẹ́ kí gbogbo wa mọ ìdí tí Jésù fi wá sáyé àti ìdí tó fi kú.
Inú wa yóò dùn gan-an láti rí ọ níbi Ìrántí ikú Jésù. Jọ̀wọ́, béèrè ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ ti máa ṣe Ìrántí yìí àti àkókò tí wọ́n máa ṣe é.