Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ bí Dáfídì àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ṣe jẹ búrẹ́dì àfihàn túmọ̀ sí pé èèyàn lè rú òfin Ọlọ́run nígbà tí nǹkan ò bá rọrùn kéèyàn sì lọ láìjìyà?—1 Sámúẹ́lì 21:1-6.

Ìwé Léfítíkù 24:5-9 jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn àlùfáà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ búrẹ́dì àfihàn tí wọ́n máa ń fi òmíràn rọ́pò ní gbogbo ọjọ́ Sábáàtì. Ìlànà tó mú kó jẹ́ pé àwọn àlùfáà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ búrẹ́dì yìí ni pé ohun mímọ́ ni búrẹ́dì náà jẹ́, àwọn ọkùnrin tó ń ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run ló sì lè jẹ ẹ́, ìyẹn àwọn àlùfáà. Nítorí náà, ohun tó lòdì pátápátá ló máa jẹ́ tí wọ́n bá fún àwọn tó kàn jẹ́ òṣìṣẹ́ lásán tàbí téèyàn bá kàn jẹ ẹ́ bí oúnjẹ lásán. Síbẹ̀, Áhímélékì àlùfáà kò dẹ́ṣẹ̀ kankan nígbà tó fún Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀ ní búrẹ́dì àfihàn náà.

Dáfídì ṣe bíi pé Sọ́ọ̀lù Ọba rán òun ní àkànṣe iṣẹ́ kan lákòókò náà. Ebi sì ń pa òun àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí Áhímélékì ti rí i pé wọn kì í ṣe aláìmọ́, ó fún wọn ní búrẹ́dì àfihàn náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé jíjẹ tí wọ́n jẹ ẹ́ kò bá òfin mu rárá tá a bá ní ká wò ó dáadáa, síbẹ̀ èyí ṣì bá ìdí pàtàkì tí wọ́n fi pèsè búrẹ́dì náà mu. Ìdí nìyẹn tí Áhímélékì ò ṣe rin kinkin mọ́ ìlànà tó ti wà nílẹ̀. Àní, Jésù Kristi fúnra rẹ̀ mẹ́nu kan ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé báwọn Farisí ṣe máa ń wonkoko mọ́ òfin Sábáàtì kò bójú mu rárá.—Mátíù 12:1-8.

Àmọ́ ṣá o, ìtàn tá a gbé yẹ̀ wò yìí kò sọ pé a lè rú òfin Ọlọ́run nígbà tí nǹkan ò bá rọrùn. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tó dà bíi pé nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ fáwọn jagunjagun Ísírẹ́lì bí wọ́n ṣe ń bá àwọn Filísínì jà. Sọ́ọ̀lù Ọba ti sọ ṣáájú pé: “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó bá jẹ oúnjẹ kí ó tó di alẹ́ àti títí èmi yóò fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi!” Bíbélì sọ pé: “Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣá àwọn Filísínì balẹ̀.” Ogun táwọn jagunjagun náà jà mú kó rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu, ebi sì ń pa wọ́n gan-an, ‘àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí pa ẹran sórí ilẹ̀, wọ́n sì ń jẹ ẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.’ (1 Sámúẹ́lì 14:24, 31-33) Wọ́n rú òfin tí Jèhófà ṣe nípa ẹ̀jẹ̀, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí i. Ohun tí wọ́n ṣe yìí lòdì sí ọ̀nà kan ṣoṣo tí Ọlọ́run sọ pé kéèyàn máa gbà lo ẹ̀jẹ̀, ìyẹn ni ‘láti fi ṣe ètùtù’ ẹ̀ṣẹ̀. (Léfítíkù 17:10-12; Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4) Àmọ́ Jèhófà ṣíjú àánú wò wọ́n, ó gba ẹbọ àkànṣe tí wọ́n rú nítorí àwọn tó dẹ́ṣẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 14:34, 35.

Dájúdájú, Jèhófà fẹ́ ká máa pa òfin òun mọ́ ní gbogbo ìgbà àti lábẹ́ ipòkípò. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.”—1 Jòhánù 5:3.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Gbogbo ọjọ́ Sábáàtì ni wọ́n máa ń gbé búrẹ́dì àfihàn tuntun sínú àgọ́ ìjọsìn