‘Ó Dà Bí Òkúta Aláwọ̀ Pupa Tí Ó Ṣeyebíye’
‘Ó Dà Bí Òkúta Aláwọ̀ Pupa Tí Ó Ṣeyebíye’
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Jòhánù rí ìran ìtẹ́ ológo kan tó wà lọ́run. Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́ náà dà bí “òkúta jásípérì.” Ẹni náà tún dà bí “òkúta aláwọ̀ pupa tí ó ṣeyebíye.” (Ìṣípayá 4:2, 3) Kí làwọn òkúta wọ̀nyí?
Àwọn òkúta wọ̀nyí jẹ́ òkúta tó mọ́ kedere débi pé èèyàn lè rí ohun tó wà lódìkejì rẹ̀. Láyé ìgbàanì, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “jásípérì” jẹ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń lò fún àwọn òkúta aláwọ̀ oríṣiríṣi, lára wọn sì làwọn òkúta iyebíye tó mọ́ kedere wà. Nígbà tí A. T. Robertson ń sọ̀rọ̀ lórí “òkúta jásípérì” tí Ìṣípayá 4:3 mẹ́nu kàn, ohun tó sọ nínú ìwé Word Pictures in the New Testament ni pé: “Ó dájú pé òkúta yìí kì í ṣe irú òkúta jásípérì òde òní tí wọ́n ń tà lówó pọ́ọ́kú.” Síwájú sí i, nígbà tí Jòhánù ń ṣàpèjúwe ìlú Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run, ohun tó sọ nínú ìwé Ìṣípayá ni pé: “Ìtànyinrin rẹ̀ dà bí òkúta ṣíṣeyebíye jù lọ, bí òkúta jásípérì tí ń dán bí kírísítálì tí ó mọ́ kedere.” (Ìṣípayá 21:10, 11) Kò sí àní-àní pé àwọn òkúta tó mọ́ kedere làwọn òkúta tí Jòhánù ń tọ́ka sí.
Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó lógo jù lọ láyé àti ọ̀run ni Jòhánù rí tó jókòó sórí ìtẹ́ nínú ìran náà. Òun ni ẹni mímọ́ jù lọ. Èyí bá ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ mú nígbà tó kọ̀wé pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀, kò sì sí òkùnkùn kankan rárá ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” (1 Jòhánù 1:5) Ìdí nìyẹn tí Jòhánù fi rọ àwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ pé kí wọ́n ‘wẹ ara wọn mọ́ gaara gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti mọ́ gaara.’—1 Jòhánù 3:3.
Kí la ní láti ṣe kí Ọlọ́run lè kà wá sí ẹni mímọ́? Ó ṣe pàtàkì gidigidi pé ká ní ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ tí Kristi ta sílẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa. Bákan náà, a tún gbọ́dọ̀ máa “rìn nínú ìmọ́lẹ̀,” ìyẹn ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé ká sì máa fi ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣèwà hù.—1 Jòhánù 1:7.