“A Ti Rà Yín Ní Iye Kan”
“A Ti Rà Yín Ní Iye Kan”
“A ti rà yín ní iye kan. Láìkùnà, ẹ yin Ọlọ́run lógo.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 6:20.
1, 2. (a) Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Òfin Mósè, báwo ni wọ́n ṣe gbọ́dọ̀ máa ṣe sáwọn ẹrú tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì? (b) Ìpinnu wo ni ẹrú tó nífẹ̀ẹ́ ọ̀gá rẹ̀ lómìnira láti ṣe?
ÌWÉ atúmọ̀ èdè kan sọ pé: “Fífi èèyàn ṣe ẹrú jẹ́ àṣà tó wọ́pọ̀ gan-an láyé ọjọ́un.” Ó tún fi kún un pé: “Iṣẹ́ táwọn ẹrú ṣe ló mú kí ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè Íjíbítì, ilẹ̀ Gíríìsì, àti ti ilẹ̀ Róòmù dúró sán-ún. Nígbà ayé àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, èèyàn kan nínú mẹ́ta ló jẹ́ ẹrú ní ilẹ̀ Ítálì nígbà tí èèyàn kan nínú márùn-ún jẹ́ ẹrú láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.”—Holman Illustrated Bible Dictionary.
2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà ìfiniṣẹrú wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un, Òfin Mósè mú kí ààbò wà fáwọn Hébérù tó jẹ́ ẹrú. Bí àpẹẹrẹ, Òfin náà sọ pé ọmọ Ísírẹ́lì kan kò gbọ́dọ̀ ṣe ẹrú ju ọdún mẹ́fà lọ. Tó bá di ọdún keje, ó ní láti “jáde lọ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a dá sílẹ̀ láìsanwó.” Àwọn ìlànà tí wọ́n fi ń bá àwọn ẹrú lò lákòókò náà dára gan-an ó sì fi ìgbatẹnirò hàn. Òfin Mósè fàyè sílẹ̀ fún ètò kan, ó ní: “Bí ẹrú náà bá fi ìtẹpẹlẹmọ́ wí pé, ‘Mo nífẹ̀ẹ́ ọ̀gá mi, aya mi àti àwọn ọmọ mi ní ti gidi; èmi kò fẹ́ jáde lọ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a dá sílẹ̀ lómìnira,’ nígbà náà, kí ọ̀gá rẹ̀ mú un sún mọ́ Ọlọ́run tòótọ́, kí ó sì mú un wá síbi ilẹ̀kùn tàbí òpó ilẹ̀kùn; kí ọ̀gá rẹ̀ sì fi òòlu lu etí rẹ̀, kí ó sì jẹ́ ẹrú rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Ẹ́kísódù 21:2-6; Léfítíkù 25:42, 43; Diutarónómì 15:12-18.
3. (a) Irú ìsìnrú wo làwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní gbà láti ṣe? (b) Kí ló sún wa láti máa sin Ọlọ́run?
3 Ètò tó wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì pé ẹnì kan lè fínnúfíndọ̀ jẹ́ ẹrú ń ṣàpẹẹrẹ irú ìsìnrú táwọn Kristẹni wà lábẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lára àwọn tí wọ́n kọ Bíbélì, irú bíi Pọ́ọ̀lù, Jákọ́bù, Pétérù àti Júúdà, pe ara wọn ní ẹrú Ọlọ́run àti ti Kristi. (Títù 1:1; Jákọ́bù 1:1; 2 Pétérù 1:1; Júúdà 1) Pọ́ọ̀lù rán àwọn Kristẹni ìlú Tẹsalóníkà létí pé wọ́n ti “yí padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run kúrò nínú òrìṣà [wọn] láti sìnrú fún Ọlọ́run tòótọ́ àti alààyè.” (1 Tẹsalóníkà 1:9) Kí ló sún àwọn Kristẹni yẹn láti fínnúfíndọ̀ di ẹrú Ọlọ́run? Àní, kí ló lè mú kí ọmọ Ísírẹ́lì kan tó jẹ́ ẹrú sọ pé òun ò fẹ́ di òmìnira? Ǹjẹ́ kì í ṣe nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ ọ̀gá rẹ̀ ni? Ìfẹ́ táwọn Kristẹni ní fún Ọlọ́run ló mú kí wọ́n di ẹrú rẹ̀. Nígbà tá a bá mọ Ọlọ́run tòótọ́ àti àláàyè, tá a sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, èyí á sún wa láti fi “gbogbo ọkàn” wa sìn ín. (Diutarónómì 10:12, 13) Àmọ́, kí ló rọ̀ mọ́ dídi ẹrú Ọlọ́run àti ti Kristi? Báwo ló ṣe kan ọ̀nà tá à ń gbà gbé ìgbésí ayé wa lójoojúmọ́?
“Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọ́run”
4. Ọ̀nà wo la gbà di ẹrú Ọlọ́run àti ti Kristi?
4 Ìwé kan túmọ̀ ẹrú sí “ẹnì kan tó jẹ́ ohun ìní ẹlòmíràn tàbí ohun ìní àwọn èèyàn mìíràn tó sì di dandan fún un láti máa ṣègbọràn sí wọn délẹ̀délẹ̀.” Nígbà tá a bá ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Jèhófà tá a sì ṣèrìbọmi, a di ohun ìní rẹ̀ nìyẹn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ẹ kì í ṣe ti ara yín, nítorí a ti rà yín ní iye kan.” (1 Kọ́ríńtì 6:19, 20) Ó dájú pé ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ni iye tí a fi rà wá yẹn, nítorí pé ìràpadà yẹn ló jẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà wá láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, yálà Kristẹni ẹni àmì òróró ni wá tàbí alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó ń rètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé. (Éfésù 1:7; 2:13; Ìṣípayá 5:9) Nítorí náà, látìgbà tá a ti ṣèrìbọmi la ti “jẹ́ ti Jèhófà.” (Róòmù 14:8) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi tó ṣeyebíye ni Jèhófà fi rà wá, a tún di ẹrú Jésù náà, ó sì pọn dandan ká pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.—1 Pétérù 1:18, 19.
5. Níwọ̀n bá a ti jẹ́ ẹrú Jèhófà, ojúṣe pàtàkì wo la ní, ọ̀nà wo la sì lè gbà ṣe ojúṣe náà?
5 Ẹrú gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí ọ̀gá rẹ̀. Tinútinú la fi gbà láti sìnrú fún Ọ̀gá wa, ìfẹ́ tá a sì ní fún un ló sún wa ṣe bẹ́ẹ̀. Jòhánù kìíní orí karùn-ún ẹsẹ kẹta sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” Nítorí náà, tá a bá ń ṣègbọràn, ńṣe lèyí ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti pé a jọ̀wọ́ ara wa fún un pátápátá. Ìgbọràn yìí á máa hàn nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 10:31) Bá a ti ń gbé ìgbésí ayé wa lójoojúmọ́, a gbọ́dọ̀ máa fi hàn pé à ń “sìnrú fún Jèhófà,” kódà nínú àwọn ohun tí kò tó nǹkan pàápàá.—Róòmù 12:11.
6. Báwo ni jíjẹ́ tá a jẹ́ ẹrú Ọlọ́run ṣe kan àwọn ìpinnu tí à ń ṣe nígbèésí ayé wa? Fi àpẹẹrẹ kan ti èyí lẹ́yìn.
6 Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a ba ń ṣe ìpinnu, ó yẹ ká rí i dájú pé a ronú dáadáa nípa ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà, Ọ̀gá wa ọ̀run. (Málákì 1:6) Àwọn ìpinnu tí kò rọrùn láti ṣe lè dán wa wò bóyá à ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run lóòótọ́. Ǹjẹ́ a ó fiyè sí ìmọ̀ràn rẹ̀ nígbà tá a bá ń ṣe irú àwọn ìpinnu bẹ́ẹ̀ dípò ká tẹ̀ lé èrò ọkàn wa tó máa ń ṣe “àdàkàdekè” tó sì ń “gbékútà”? (Jeremáyà 17:9) Kò pẹ́ rárá lẹ́yìn tí Melisa tó jẹ́ sisí ṣèrìbọmi tí ọ̀dọ́kùnrin kan sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Lójú rẹ̀, ọkùnrin náà ṣèèyàn, ó sì ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lákòókò náà. Síbẹ̀, alàgbà kan bá Melisa sọ̀rọ̀ pé yóò dára kó tẹ̀ lé àṣẹ tí Jèhófà pa pé ká ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39; 2 Kọ́ríńtì 6:14) Melisa fẹnu ara ẹ̀ sọ pé: “Kò rọrùn fún mi rárá láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí. Àmọ́ mo pinnu pé, níwọ̀n ìgbà tí mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Ọlọ́run láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, màá ṣègbọràn sí ìtọ́ni rẹ̀ tó ṣe kedere yìí.” Nígbà tí Melisa ń sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà, ó ní: “Inú mi dùn gan-an pé mo tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn. Nígbà tó yá, ọkùnrin náà ò kẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Ká ní mo ti lọ gbà fún un ni, aláìgbàgbọ́ ni ì bá jẹ́ ọkọ mi nísinsìnyí.”
7, 8. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká jẹ́ kí ṣíṣe ohun tó wu àwọn èèyàn kó àníyàn bá wa ju bó ṣe yẹ lọ? (b) Sọ àpẹẹrẹ bí a ṣe lè borí ìbẹ̀rù èèyàn.
7 Níwọ̀n bá a ti jẹ́ ẹrú Ọlọ́run, a ò tún gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú èèyàn mọ́. (1 Kọ́ríńtì 7:23) Lóòótọ́, kò sẹ́nì kankan nínú wa tó fẹ́ káwọn èèyàn máa fojú pa òun rẹ́, àmọ́ a gbọ́dọ̀ máa rántí pé ìlànà àwa Kristẹni yàtọ̀ sí tàwọn èèyàn ayé. Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Mo ha ń wá ọ̀nà láti wu àwọn ènìyàn?” Èsì rẹ̀ ni pé: “Bí mo bá ṣì ń wu àwọn ènìyàn, èmi kì yóò jẹ́ ẹrú Kristi.” (Gálátíà 1:10) A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe borí wa ká sì wá dẹni tó ń ṣe ohun tó wu àwọn èèyàn. Nítorí náà, kí la lè ṣe nígbà tí ìṣòro yìí bá dojú kọ wá?
8 Wo àpẹẹrẹ ọ̀dọ́mọbìnrin Kristẹni kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elena lórílẹ̀-èdè Sípéènì. Àwọn kan lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ máa ń fi ẹ̀jẹ̀ wọn tọrẹ. Wọ́n mọ̀ pé nítorí pé Elena jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ní fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọrẹ bẹ́ẹ̀ ni kò ní gba ẹ̀jẹ̀ sára. Nígbà tí àǹfààní kan yọjú tí Elena fi lè ṣàlàyé kókó yìí fún gbogbo àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀, ó sọ fún wọn pé òun yóò fẹ́ láti bá wọn sọ̀rọ̀. Elena ní: “Kí n sòótọ́, ẹ̀rù bà mí gan-an nígbà tí mo fẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí. Àmọ́ mo ti múra sílẹ̀ dáadáa, àbájáde rẹ̀ sì yà mí lẹ́nu gan-an. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ kíláàsì mi ló wá ń fojú dáadáa wò mí, olùkọ́ wa sì sọ fún mi pé òun nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìwàásù tí mò ń ṣe. Paríparí rẹ̀ ni pé, inú mi dùn gan-an pé mo lè gbé orúkọ Jèhófà ga mo sì tún lè ṣàlàyé yékéyéké fún àwọn ọmọ kíláàsì mi nípa ìdí tí mo fi tẹ̀ lé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ.” (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4; Ìṣe 15:28, 29) Bí Elena ṣe sọ lọ̀rọ̀ rí, nítorí pé ẹrú Ọlọ́run àti ti Kristi ni wá, a yàtọ̀ pátápátá. Àmọ́ ṣá, bí a bá ti wà ní ìmúrasílẹ̀ láti ṣàlàyé ìgbàgbọ́ wa fáwọn èèyàn, tá a sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, a lè wá dẹni iyì lójú wọn.—1 Pétérù 3:15.
9. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ lára áńgẹ́lì tó bá àpọ́sítélì Jòhánù sọ̀rọ̀?
9 Rírántí pé ẹrú Ọlọ́run ni wá tún lè jẹ́ ká ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Nígbà kan, àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran àgbàyanu kan nípa Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run. Ìran yìí wú u lórí débi pé kò mọ̀gbà tó dojú bolẹ̀ níwájú áńgẹ́lì tó jẹ́ agbẹnusọ Ọlọ́run tó sì fẹ́ jọ́sìn rẹ̀. Àmọ́ áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Gbogbo ohun tí mo jẹ́ ni ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ àti ti àwọn arákùnrin rẹ tí wọ́n jẹ́ wòlíì àti ti àwọn tí ń pa àwọn ọ̀rọ̀ àkájọ ìwé yìí mọ́. Jọ́sìn Ọlọ́run.” (Ìṣípayá 22:8, 9) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ rere ni áńgẹ́lì yìí jẹ́ fún gbogbo àwa tá a jẹ́ ẹrú Ọlọ́run! Àwọn kan láàárín àwa Kristẹni lè ní ojúṣe pàtàkì tí wọ́n ń bójú tó nínú ìjọ. Síbẹ̀, Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín, ẹnì yòówù tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú yín.” (Mátíù 20:26, 27) Níwọ̀n bá a ti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ẹrú ni gbogbo wa.
“Ohun Tí Ó Yẹ Kí A Ṣe Ni A Ṣe”
10. Sọ àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé kì í fìgbà gbogbo rọrùn fáwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
10 Kì í sábà rọrùn fún àwa èèyàn aláìpé láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Nígbà tí Jèhófà sọ fún wòlíì Mósè pé kó lọ kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú ilẹ̀ Íjíbítì, ó kọ́kọ́ lọ́ tìkọ̀, kò fẹ́ lọ. (Ẹ́kísódù 3:10, 11; 4:1, 10) Nígbà tí Ọlọ́run rán Jónà pé kó lọ polongo ìdájọ́ òun fún àwọn èèyàn ìlú Nínéfè, ńṣe ni Jónà “dìde, [tó] sì fẹsẹ̀ fẹ lọ sí Táṣíṣì kúrò níwájú Jèhófà.” (Jónà 1:2, 3) Bárúkù tó jẹ́ akọ̀wé Jeremáyà náà ṣàròyé pé iṣẹ́ náà ti sú òun. (Jeremáyà 45:2, 3) Kí ló yẹ ká ṣe bí ohun tó wù wá kò bá bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu? Àpèjúwe kan tí Jésù sọ yóò dáhùn ìbéèrè yìí.
11, 12. (a) Ní ṣókí, sọ àpèjúwe Jésù tá a rí nínú Lúùkù 17:7-10. (b) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe yìí?
11 Jésù sọ nípa ẹrú kan tó ti ń tọ́jú agbo ẹran ọ̀gá rẹ̀ nínú pápá látàárọ̀. Nígbà tí ẹrú náà dé sílé lẹ́yìn tó ti ṣiṣẹ́ àṣekára fún nǹkan bíi wákàtí méjìlá tó sì ti rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu, ọ̀gá rẹ̀ kò sọ fún un pé kó jókòó kó sì jẹ oúnjẹ alẹ́ tó dọ́ṣọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ọ̀gá náà sọ fún un pé: “Pèsè ohun kan sílẹ̀ fún mi láti fi ṣe oúnjẹ alẹ́ mi, sì gbé épírọ́ọ̀nù kan wọ̀, kí o sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi títí èmi yóò fi parí jíjẹ àti mímu, àti lẹ́yìn náà ìwọ lè jẹ, kí o sì mu.” Lẹ́yìn tí ẹrú náà bá ti sin ọ̀gá rẹ̀ tán ló tó ó lè bójú tó ara rẹ̀. Jésù wá parí àpèjúwe náà nípa sísọ pé: “Bákan náà ni ẹ̀yin, pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá ti ṣe gbogbo ohun tí a yàn lé yín lọ́wọ́ tán, ẹ wí pé, ‘Àwa jẹ́ ẹrú tí kò dára fún ohunkóhun. Ohun tí ó yẹ kí a ṣe ni a ṣe.’”—Lúùkù 17:7-10.
12 Kì í ṣe ohun tí Jésù ń fi àpèjúwe yìí sọ ni pé Jèhófà kò mọrírì ohun tí à ń ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Bíbélì sọ ọ́ kedere pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 6:10) Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ tí Jésù fẹ́ ká kọ́ nínú àkàwé yìí ni pé, ẹrú kò lè máa ṣe bó ṣe wù ú tàbí kó gbájú mọ́ ìgbádùn ti ara rẹ̀. Nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run tá a sì sọ pé a ó di ẹrú rẹ̀, ńṣe la gbà láti máa fi ìfẹ́ rẹ̀ ṣáájú tiwa. Ìfẹ́ ti Ọlọ́run ló gbọ́dọ̀ máa borí ìfẹ́ tiwa.
13, 14. (a) Àwọn ìgbà wo ni kò yẹ ká gbà kí èrò ọkàn wa borí wa? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ kí ìfẹ́ Ọlọ́run máa borí ìfẹ́ tiwa?
13 Ó lè gba pé ká sapá gan-an ká tó lè máa kẹ́kọ̀ọ́ déédéé nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nínú àwọn ìwé tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń mú jáde. (Mátíù 24:45) Yóò túbọ̀ gba ìsapá gan-an tá a bá lọ jẹ́ ẹni tí ìwé kíkà ò rọ̀ lọ́rùn tàbí tó bá jẹ́ pé “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” ni ìwé tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ń ṣàlàyé rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 2:10) Àmọ́, ǹjẹ́ kò yẹ ká ṣètò àkókò kan tá a óò máa fi dá kẹ́kọ̀ọ́? Ó lè gba pé ká mú ara wa ní tipátipá láti jókòó ká sì lo àkókò tó pọ̀ tó láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tó wà nínú ìwé náà. Láìṣe bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe máa dẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí “oúnjẹ líle [tó] jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú”?—Hébérù 5:14.
14 Àwọn ìgbà tá a máa ti ibi iṣẹ́ dé tó sì ti máa rẹ̀ wá tẹnutẹnu ńkọ́? Ó lè gba pé ká sapá gidigidi láti lè lọ sáwọn ìpàdé ìjọ. Ó sì lè jẹ́ pé ó máa ń ṣòro fún wa láti wàásù fáwọn tá ò mọ̀ rí. Pọ́ọ̀lù alára gbà pé àwọn àkókò kan lè wà tí kò ní wù wá láti wàásù ìhìn rere náà síbẹ̀ tí yóò di dandan ká ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 9:17) Àmọ́, nítorí pé Ọ̀gá wa ọ̀run, Jèhófà, ẹni tá a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, sọ pé ká wàásù la ṣe ń wàásù. Lẹ́yìn tá a bá ti sapá, tá a kẹ́kọ̀ọ́, tá a lọ sípàdé, tá a sì wàásù, ǹjẹ́ inú wa kì í dùn, ǹjẹ́ ara kì í sì í tù wá?—Sáàmù 1:1, 2; 122:1; 145:10-13.
Má Ṣe Wo “Àwọn Ohun Tí Ń Bẹ Lẹ́yìn”
15. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa nípa bá a ṣe lè jọ̀wọ́ ara wa fún Ọlọ́run pátápátá?
15 Jésù Kristi fi hàn lọ́nà tó dara jù lọ pé òun jọ̀wọ́ ara òun fún Baba òun ọ̀run. Ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Èmi sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.” (Jòhánù 6:38) Nígbà tí Jésù wà nínú ìnira lílékenkà nínú ọgbà Gẹtisémánì, ó gbàdúrà pé: “Baba mi, bí ó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí ife yìí ré mi kọjá lọ. Síbẹ̀, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí èmi tí fẹ́, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fẹ́.” (Mátíù 26:39)
16, 17. (a) Ojú wo ló yẹ ká fi wo àwọn ohun tá a ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn? (b) Ṣàlàyé bó ṣe jẹ́ pé òótọ́ ọ̀rọ̀ ni Pọ́ọ̀lù sọ pé “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí” ni gbogbo ohun tọ́wọ́ òun ì bá tẹ̀ nínú ayé.
16 Jésù Kristi fẹ́ ká dúró ti ìpinnu tá a ṣe pé a óò jẹ́ ẹrú Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Kò sí ènìyàn tí ó ti fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun ìtúlẹ̀, tí ó sì ń wo àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn tí ó yẹ dáadáa fún ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 9:62) Bá a ti ń sìnrú fún Ọlọ́run, kò ní dára rárá ká tún máa ronú ṣáá nípa àwọn ohun tá a ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká mọyì àwọn ohun tá a ti jèrè nítorí pé a yàn láti jẹ́ ẹrú Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn ará Fílípì pé: “Ní tòótọ́ mo ka ohun gbogbo sí àdánù pẹ̀lú ní tìtorí ìníyelórí títayọ lọ́lá ti ìmọ̀ nípa Kristi Jésù Olúwa mi. Ní tìtorí rẹ̀, èmi ti gba àdánù ohun gbogbo, mo sì kà wọ́n sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí, kí n lè jèrè Kristi.”—Fílípì 3:8.
17 Ronú ná nípa gbogbo ohun tí Pọ́ọ̀lù kà sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí tó sì pa tì nítorí kọ́wọ́ rẹ̀ lè tẹ àwọn èrè tẹ̀mí tó wà fáwọn tó jẹ́ ẹrú Ọlọ́run. Kì í ṣe àwọn ìgbádùn inú ayé nìkan ló fi sílẹ̀ o, ó tún kẹ̀yìn sí àǹfààní tó ṣeé ṣe kó ní lọ́jọ́ kan láti di aṣáájú Ìsìn Àwọn Júù. Ká ní Pọ́ọ̀lù ṣì ń ṣe Ìsìn Àwọn Júù nìṣó ni, ó ṣeé ṣe kóun náà dé ipò tí Síméónì dé, ìyẹn ọmọ Gàmálíẹ́lì, ẹni tó kọ́ Pọ́ọ̀lù lẹ́kọ̀ọ́. (Ìṣe 22:3; Gálátíà 1:14) Síméónì di aṣáájú àwọn Farisí, ipa kékeré kọ́ ló sì kó nígbà táwọn Júù gbéjà ko ìjọba Róòmù lọ́dún 66 sí ọdún 70 Sànmánì Tiwa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ṣe náà kò fi bẹ́ẹ̀ tinú rẹ̀ wá. Inú rògbòdìyàn yìí ló kú sí, ó sì ṣeé kó jẹ́ pé àwọn Júù onítara òdì ló pà á tàbí àwọn ọmọ ogun Róòmù.
18. Sọ àpẹẹrẹ kan láti fi hàn bí àwọn ohun téèyàn gbé ṣe nípa tẹ̀mí ṣe máa ń mú èrè wá.
18 Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù. Jean sọ pé: “Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ tí mo kúrò ní iléèwé, mo ríṣẹ́ lọ́dọ̀ lọ́yà kan tó gbajúmọ̀ nílùú London ó sì fi mí ṣe ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ náà. Mò ń gbádùn iṣẹ́ mi gan-an, owó gọbọi ni mo sì ń rí níbẹ̀, àmọ́ nínú ọkàn mi lọ́hùn-ún, mo mọ̀ pé ohun tí mò ń ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kò tíì tó. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, mo kọ̀wé fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà pé mo gbé ìgbésẹ̀ yẹn ní nǹkan bí ogún ọdún sẹ́yìn! Iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún tí mò ń ṣe ti mú káyé mi dùn ju ohun tí mo lè rí nínú iṣẹ́ ọ́fíìsì èyíkéyìí lọ. Kò sóhun tó ń mú inú èèyàn dùn tó kéèyàn máa rí bí Ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe ń yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn padà. Àǹfààní tí mo ní láti kópa nínú irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kọjá ohun tí mo lè fẹnu sọ. Ohun tí à ń fún Jèhófà kò tó nǹkan kan tá a bá fi wé ohun tí à ń gbà lọ́wọ́ rẹ̀.”
19. Kí lo yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa, kí sì nìdí?
19 Bí àkókò ti ń lọ, ipò wa lè yí padà. Àmọ́ ìyàsímímọ́ wa sí Ọlọ́run kò yí padà. Ẹrú Jèhófà ṣì ni wá, ó sì fi wá sílẹ̀ ká fúnra wa pinnu ọ̀nà tó dára jù lọ láti lo àkókò wa, okun wa, àti ẹ̀bùn àbínibí wa, àtàwọn ohun mìíràn tá a ní tó ṣeyebíye. Nítorí náà, àwọn ìpinnu wa lórí bí a ṣe ń lo àwọn nǹkan wọ̀nyí lè fi bí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó hàn. Wọ́n tún lè fi hàn bóyá a múra tán láti yááfì àwọn nǹkan kan nítorí ìjọba rẹ̀. (Mátíù 6:33) Ipò yòówù ká wà, ǹjẹ́ kò yẹ ká pinnu láti máa fún Jèhófà ní ohun tó dára jù lọ? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ìmúratán bá kọ́kọ́ wà, ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní pàtàkì ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn ní, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn kò ní.”—2 Kọ́ríńtì 8:12.
“Ẹ Ń So Èso Yín”
20, 21. (a) Irú èso wo làwọn tó jẹ́ ẹrú Ọlọ́run ń so? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe ń san èrè fáwọn tó bá ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀?
20 Jíjẹ́ ẹrú Ọlọ́run kò mú ìnira lọ́wọ́ rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ ìsìnrú tó ń pani lára tó sì máa ń gba ayọ̀ wa. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nítorí pé a ti dá yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n tí ẹ ti di ẹrú fún Ọlọ́run, ẹ ń so èso yín lọ́nà ìjẹ́mímọ́, ìyè àìnípẹ̀kun sì ni òpin rẹ̀.” (Róòmù 6:22) Jíjẹ́ tá a jẹ́ ẹrú Ọlọ́run ń so èso lọ́nà ìjẹ́mímọ́ ní ti pé, à ń rí èrè ìwà mímọ́ tàbí ìwà rere wa. Ìyẹn nìkan kọ́, jíjẹ́ ẹrú Ọlọ́run á tún jẹ́ ká lè ní ìyè ayérayé lọ́jọ́ iwájú.
21 Jèhófà jẹ́ ọ̀làwọ́ gan-an sáwọn ẹrú rẹ̀. Nígbà tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, ó máa ń ṣí “ibodè ibú omi ọ̀run” ó sì máa ń tú ‘ìbùkún dà sórí wa títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’ (Málákì 3:10) Ẹ ò rí i pé ayọ̀ wa kò ní lópin tá a bá lè jẹ́ ẹrú Jèhófà títí láé!
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ló mú ká di ẹrú Ọlọ́run?
• Báwo la ṣe ń fi hàn pé a jọ̀wọ́ ara wa fún Ọlọ́run láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa múra tán láti fi ìfẹ́ Jèhófà ṣáájú ìfẹ́ tara wa?
• Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ ‘wo àwọn ohun tá a ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn’?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Ètò tó wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì pé ẹnì kan lè fínnúfíndọ̀ jẹ́ ẹrú ń ṣàpẹẹrẹ irú ìsìnrú táwọn Kristẹni wà lábẹ́ rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Nígbà tá a ṣèrìbọmi, a di ẹrú Ọlọ́run
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ìfẹ́ Ọlọ́run làwọn Kristẹni máa ń fi ṣáájú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Mósè lọ́ tìkọ̀ láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un