Agbára Jèhófà Mú Kí Sámúsìnì Borí!
Agbára Jèhófà Mú Kí Sámúsìnì Borí!
ÀWỌN ọ̀tá tó mú Sámúsìnì lẹ́rú yọ ojú rẹ̀ méjèèjì, wọ́n sì tún ní kó máa ṣiṣẹ́ àṣekára nítorí wọ́n fẹ́ gbẹ̀san ohun tó ti fojú wọn rí. Lọ́jọ́ kan, wọ́n mú un jáde látinú ẹ̀wọ̀n tó wà kó lè dá wọn lárayá nínú ilé òrìṣà wọn. Wọ́n mú un wá síwájú ẹgbàágbèje èèyàn tó ń wòran, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ṣẹ̀sín. Sámúsìnì kì í ṣe ọ̀daràn bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe olórí ogun àwọn ọ̀tá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, olùjọsìn Jèhófà ni, ó sì ti fi nǹkan bí ogún ọdún ṣèdájọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì ṣáájú àsìkò yìì.
Báwo ni Sámúsìnì tó jẹ́ ọkùnrin tó lágbára jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn ṣe dẹni tí wọ́n fi ń ṣe irú ẹ̀sín yìí? Ǹjẹ́ agbára àrà ọ̀tọ̀ tó ní lè gbà á sílẹ̀? Kí ni àṣírí agbára Sámúsìnì? Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tá a lè rí kọ́ nínú ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀?
“Yóò Mú Ipò Iwájú Nínú Gbígba Ísírẹ́lì Là”
Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti yà kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n “tún kó wọnú ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, . . . Jèhófà fi wọ́n lé àwọn Filísínì lọ́wọ́ fún ogójì ọdún.”—Àwọn Onídàájọ́ 13:1.
Bí ìtàn Sámúsìnì ṣe bẹ̀rẹ̀ ni pé áńgẹ́lì Jèhófà wá bá obìnrin àgàn kan, ìyẹn ìyàwó ọmọ Ísírẹ́lì kan tó ń jẹ́ Mánóà, ó sì sọ fún un pé ó máa bí ọmọ ọkùnrin. Áńgẹ́lì náà wá kìlọ̀ fún obìnrin ọ̀hún pé: “Kí abẹ fẹ́lẹ́ má . . . kan orí rẹ̀, nítorí pé Násírì Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò dà bí ó bá ti jáde láti inú ikùn wá; òun sì ni ẹni tí yóò mú ipò iwájú nínú gbígba Ísírẹ́lì là kúrò ní ọwọ́ àwọn Filísínì.” (Àwọn Onídàájọ́ 13:2-5) Kí wọ́n tó lóyún Sámúsìnì rárá ni Jèhófà ti pinnu pé òun yóò lò ó fún iṣẹ́ àkànṣe kan. Nípa bẹ́ẹ̀, àtìgbà tí wọ́n ti bí i ló ti jẹ́ Násírì, ìyẹn ẹni tí Ọlọ́run dìídì yàn láti ṣe iṣẹ́ pàtàkì kan.
Ó “Ṣe Wẹ́kú ní Ojú Mi”
Bí Sámúsìnì ṣe ń dàgbà sí i ni “Jèhófà . . . ń bá a lọ ní bíbùkún fún un.” (Àwọn Onídàájọ́ 13:24) Lọ́jọ́ kan, Sámúsìnì lọ bá bàbá àti ìyá rẹ̀ ó sì sọ pé: “Obìnrin kan wà tí mo rí ní Tímúnà, lára àwọn ọmọbìnrin àwọn Filísínì, wàyí o, ẹ fẹ́ ẹ fún mi kí n fi ṣe aya.” (Àwọn Onídàájọ́ 14:2) Kò sí àní-àní pé ìyàlẹ́nu gbáà ni èyí máa jẹ́ fún wọn. Ìdí ni pé dípò kí ọmọ wọn wá bó ṣe máa gba Ísírẹ́lì kúrò lọ́wọ́ àwọn aninilára, ńṣe ló fẹ́ lọ bá wọn dána. Ọmọ Ísírẹ́lì tó bá sì lọ fẹ́ abọ̀rìṣà ń rú Òfin Ọlọ́run ni. (Ẹ́kísódù 34:11-16) Èyí ló mú káwọn òbí rẹ̀ kọ̀ jálẹ̀ tí wọ́n fi sọ pé: “Kò ha sí obìnrin kankan láàárín àwọn ọmọbìnrin arákùnrin rẹ àti láàárín gbogbo àwọn ènìyàn mi ni, tí ó fi jẹ́ pé ìwọ yóò lọ fẹ́ aya láti inú àwọn Filísínì aláìdádọ̀dọ́?” Ṣùgbọ́n, ẹ̀yìn etí Sámúsìnì ni gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ń bọ́ sí torí pé ohun tó ṣáà ń tẹnu mọ́ ni pé: “Òun gan-an ni kí o fẹ́ fún mi, nítorí pé òun gan-an ló ṣe wẹ́kú ní ojú mi.”—Àwọn Onídàájọ́ 14:3.
Àmọ́, báwo ló ṣe jẹ́ pé obìnrin ilẹ̀ Filísínì yìí gan-an “ló ṣe wẹ́kú” lójú Sámúsìnì? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Cyclopedia, èyí tí McClintock àti Strong ṣe, sọ pé kì í ṣe nítorí pé obìnrin náà jẹ́ “arẹwà ló ṣe wu Sámúsìnì, bí kò ṣe pé [Sámúsìnì] yóò rí i lò kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ ohun kan tó ń lépa.” Kí lohun náà tí Sámúsìnì ń gbèrò láti ṣe? Àwọn Onídàájọ́ 14:4 sọ pé ńṣe ni Sámúsìnì “ń wá àyè lòdì sí àwọn Filísínì.” Ìdí tí Sámúsìnì fi nífẹ̀ẹ́ sí obìnrin náà nìyẹn. Bí Sámúsìnì ṣe ń dàgbà sí i ni “ẹ̀mí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí sún un ṣiṣẹ́.” (Àwọn Onídàájọ́ 13:25) Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí Jèhófà ló mú kí Sámúsìnì sọ pé òun máa fẹ́ obìnrin àjèjì yìí, ẹ̀mí yìí kan náà ló sì tún ń ṣiṣẹ́ lára rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tó fi jẹ́ onídàájọ́ lórí Ísírẹ́lì. Ǹjẹ́ ohun tí Sámúsìnì ń wá tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́? Ká tó dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ lórí ọ̀nà tí Jèhófà fi mú kó dá a lójú pé òun ń tì í lẹ́yìn.
Lọ́jọ́ kan tí Sámúsìnì ń lọ sí Tímúnà, ìyẹn ìlú tó ti fẹ́ fẹ́yàwó, ohun kan ṣẹlẹ̀. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Nígbà tí ó lọ títí dé àwọn ọgbà àjàrà Tímúnà, họ́wù, wò ó! ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ kan ń ké ramúramù nígbà tí ó pàdé rẹ̀. Nígbà náà ni ẹ̀mí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára rẹ̀, tí ó fi ya á sí méjì.” Sámúsìnì nìkan ló wà níbẹ̀ nígbà tí agbára tó kàmàmà yìí gùn ún. Kò sí ẹnì kankan tó rí ohun tó ṣẹlẹ̀. Ṣé ọ̀nà yìí ni Jèhófà fi fẹ́ mú kó dá Sámúsìnì lójú ni, pé níwọ̀n bó ti jẹ́ Násírì, yóò lè ṣe iṣẹ́ tí òun bá yàn fún un? Bíbélì ò sọ, àmọ́ láìsí àní-àní, Sámúsìnì mọ̀ pé agbára àrà ọ̀tọ̀ náà kì í ṣe tòun. Ó ní láti jẹ́ pé Ọlọ́run ló fún òun lágbára. Èyí fi í lọ́kàn balẹ̀ pé tí òun bá gbára lé Jèhófà, yóò ran òun lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tí ń bẹ níwájú. Nítorí pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fún Sámúsìnì lókun gan-an, ó “ń bá ọ̀nà rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá obìnrin náà sọ̀rọ̀; ó sì ṣe wẹ́kú síbẹ̀ ní ojú [rẹ̀].”—Àwọn Onídàájọ́ 14:5-7.
Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, bí Sámúsìnì ṣe ń padà lọ sọ́dọ̀ àwọn àna rẹ̀ kó lè mú obìnrin náà wálé, “ó yà láti bojú wo òkú kìnnìún náà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ kòkòrò oyin sì ń bẹ níbẹ̀ nínú òkú kìnnìún náà, àti oyin.” Sámúsìnì rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ó sì lò ó láti fi pa àlọ́ kan fún ọgbọ̀n ọkùnrin Filísínì tó fi ṣe ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó lọ́jọ́ ìgbéyàwó rẹ̀. Àlọ́ tó pa fún wọn ni pé: “Láti inú olùjẹ nǹkan ni nǹkan jíjẹ ti jáde wá, láti inú alágbára sì ni nǹkan dídùn ti jáde wá.” Sámúsìnì sọ pé tí wọ́n bá lè já àlọ́ náà, òun yóò fún wọn ní ọgbọ̀n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti ọgbọ̀n aṣọ wíwọ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn ni yóò fún òun ní nǹkan wọ̀nyí. Àwọn ọkùnrin Filísínì náà kò lè já àlọ́ náà fún odindi ọjọ́ mẹ́ta. Ṣùgbọ́n nígbà tó di ọjọ́ kẹrin, wọ́n lọ halẹ̀ mọ́ ìyàwó Sámúsìnì, wọ́n ní: “Tan ọkọ rẹ kí ó lè já àlọ́ náà fún wa. Bí Àwọn Onídàájọ́ 14:8-15.
bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò fi iná sun ìwọ àti ilé baba rẹ.” Òṣìkà paraku mà làwọn ará ibí yìí o! Bí àwọn Filísínì bá lè hu irú ìwà ìkà yìí sáwọn èèyàn wọn, ẹ ò rí i pé inú ewu ńlá gan-an làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ń ni lára wà!—Jìnnìjìnnì bo obìnrin yìí ló bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ Sámúsìnì títí ó fi pin ín lẹ́mìí, tí Sámúsìnì sì sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún un. Níwọ̀n bí kò sì ti nífẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ̀ dénú, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló ti lọ tú àṣírí yìí fún àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó náà. Wọ́n já àlọ́ náà lóòótọ́, àmọ́ Sámúsìnì mọ ọgbọ́n tí wọ́n ta. Ó sọ fún wọn pé: “Ká ní ẹ kò fi ẹgbọrọ abo màlúù mi túlẹ̀ ni, ẹ kì bá ti rí ojútùú àlọ́ mi.” Àǹfààní tí Sámúsìnì ti ń wá tipẹ́ wá yọjú wàyí. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára rẹ̀, tí ó fi sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Áṣíkẹ́lónì, ó sì ṣá ọgbọ̀n ọkùnrin balẹ̀ lára wọn, ó sì kó ohun tí ó bọ́ kúrò lára wọn, ó sì fi àwọn aṣọ wíwọ̀ náà fún àwọn tí ó já àlọ́ náà.”—Àwọn Onídàájọ́ 14:18, 19.
Ṣé torí kí Sámúsìnì lè gbẹ̀san ló ṣe lọ fikú pa wọ́n ní Áṣíkẹ́lónì ni? Rárá o. Ọlọ́run ló dìídì lo Sámúsìnì, ẹni tó fẹ́ kó dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè, láti pa àwọn èèyàn wọ̀nyí run. Jèhófà lo Sámúsìnì láti bẹ̀rẹ̀ ogun tó fẹ́ bá àwọn òǹrorò ẹ̀dá tí ń fi ayé ni àwọn èèyàn rẹ̀ lára jà. Ogun yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni o. Àǹfààní mìíràn tún yọjú nígbà tí Sámúsìnì lọ sọ́dọ̀ aya rẹ̀.
Sámúsìnì Lọ Dá Jagun
Nígbà tí Sámúsìnì padà sí Tímúnà, ó rí i pé bàbá ìyàwó òun ti fi ìyàwó òun fún ẹlòmíràn nítorí ó rò pé Sámúsìnì ò fẹ́ràn rẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí bí Sámúsìnì nínú gan-an ni. Ohun tó wá ṣe ni pé, ó lọ mú ọ̀ọ́dúnrún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, ó sì so wọ́n pọ̀ ní méjì-méjì níbi ìrù. Lẹ́yìn náà, ó so ògùṣọ̀ mọ́ ìrù àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà, ó sì fi iná sí àwọn ògùṣọ̀ náà. Nígbà tó tú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà sílẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tanná ran àwọn pápá ọkà, àwọn ọgbà àjàrà àtàwọn oko ólífì àwọn Filísínì. Bí irè oko mẹ́ta pàtàkì tí wọ́n gbójú lé lọ́dún náà ṣe jóná ráúráú nìyẹn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ káwọn Filísínì onínú burúkú náà lọ hùwà ìkà bíburú jáì kan. Wọ́n wò ó pé ìyàwó Sámúsìnì àti bàbá rẹ̀ ló jẹ́ kí ohun burúkú yìí ṣẹlẹ̀, wọ́n sì dáná sun àti bàbá àtọmọ. Ìwà ọ̀dájú tí wọ́n hù yìí tún fún Sámúsìnì láǹfààní láti túbọ̀ pa lára wọn. Bó ṣe lọ dojúùjà kọ wọ́n nìyẹn tó sì pa wọ́n ní ìpakúpa.—Àwọn Onídàájọ́ 15:1-8.
Ǹjẹ́ ó yé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé Jèhófà Ọlọ́run ló ń ti Sámúsìnì lẹ́yìn, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ bá a fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí wọ́n bàa lè jọ rẹ́yìn àwọn Filísínì tó ń jẹ gàba lé wọn lórí? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, nítorí pé wọn ò fẹ́ wàhálà, ńṣe làwọn ọkùnrin Júdà ran ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọkùnrin pé kí wọ́n wá gbé aṣáájú tí Ọlọ́run yàn yìí, wọ́n sì fà á lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́. Àmọ́, ìwà ọ̀dàlẹ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì hù yìí tún jẹ́ kí àyè ṣí sílẹ̀ fún Sámúsìnì láti túbọ̀ fojú àwọn ọ̀tá rí màbo. Bí wọ́n ṣe fà á lé àwọn Filísínì lọ́wọ́, “ẹ̀mí Jèhófà . . . bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára rẹ̀, àwọn ìjàrá tí ó wà ní apá rẹ̀ sì wá dà bí àwọn fọ́nrán òwú ọ̀gbọ̀ tí iná ti jó gbẹ, tí àwọn ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ rẹ̀ fi yọ́ kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.” Lẹ́yìn náà, ó mú egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tó rí nílẹ̀, ó sì fi ṣá ẹgbẹ̀rún èèyàn balẹ̀ lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.—Àwọn Onídàájọ́ 15:10-15.
Sámúsìnì wá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà, ó ní: “Ìwọ ni ó fi ìgbàlà ńláǹlà yìí lé ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ, àti nísinsìnyí, èmi yóò ha kú nítorí òùngbẹ kí n sì ṣubú sí ọwọ́ àwọn aláìdádọ̀dọ́?” Jèhófà tẹ́tí sí àdúrà Sámúsìnì, ó sì dá a lóhùn. Ìwé Mímọ́ sọ pé: ‘Ọlọ́run pín ibi kótópó onírìísí odó kan níyà, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá láti inú rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mumi, lẹ́yìn èyí tí ẹ̀mí rẹ̀ padà, ó sì sọ jí.’—Àwọn Onídàájọ́ 15:18, 19.
Sámúsìnì ò jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn òun níyà rárá, ogun tó ń bá àwọn Filísínì jà ló wà lọ́kàn rẹ̀. Nítorí kó lè ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Ọlọ́run, ó lọ sun ilé obìnrin kárùwà kan ní Gásà. Kì í ṣe torí àtiṣe ìṣekúṣe ni Sámúsìnì fi lọ síbẹ̀ o. Ńṣe ló ń wá ibi tó lè sùn mọ́jú nílùú àwọn ọ̀tá, ilé obìnrin kárùwà ló sì lè sùn sí. Ọ̀gànjọ́ òru ló kúrò nílé obìnrin náà, ó sì lọ fa àwọn ilẹ̀kùn ẹnubodè ìlú ńlá náà àtàwọn arópòódògiri ẹ̀gbẹ́ méjèèjì yọ, ó sì gbé wọn gòkè lọ sí orí òkè ńlá kan nítòsí Hébúrónì, èyí tó jìnnà tó nǹkan bí ọgọ́ta kìlómítà sí ìlú Gásà. Ọlọ́run fọwọ́ sí ohun tí Sámúsìnì ṣe yìí, ó sì fún un lókun kó lè ṣe é láṣeyọrí.—Àwọn Onídàájọ́ 16:1-3.
Ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ gbáà ni ẹ̀mí mímọ́ gbà ṣiṣẹ́ lára Lúùkù 11:13.
Sámúsìnì nítorí pé àwọn ohun tí Ọlọ́run lò ó láti ṣe ṣàjèjì pátápátá. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run òde òní náà lè gbára lé ẹ̀mí mímọ́ láti fún wọn lókun. Jésù jẹ́ kó dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú pé Jèhófà yóò “fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”—Kí Nìdí Tí Jèhófà Fi ‘Lọ Kúrò Lọ́dọ̀ Sámúsìnì’?
Bí àkókò ti ń lọ, ìfẹ́ obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dèlílà kó sí Sámúsìnì lórí. Àwọn alákòóso márùn-ún tó wà nílẹ̀ Filísínì tí wọ́n jọ lẹ̀dí àpò pọ̀ fẹ́ yanjú Sámúsìnì pátápátá, ọ̀ràn yìí sì ká wọn lára débi pé wọ́n lọ bá Dèlílà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sọ fún un pé: “Tàn án kí o sì rí inú ohun tí agbára ńlá rẹ̀ wà àti ohun tí a lè fi borí rẹ̀.” Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn alákòóso márààrún yìí sì sọ pé àwọn máa fún un ní “ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ẹyọ fàdákà” tó bá lè ṣe ohun táwọn sọ.—Àwọn Onídàájọ́ 16:4, 5.
Bí ẹyọ fàdákà yìí bá jẹ́ ṣékélì, á jẹ́ pé owó tabua ni ẹgbẹ̀rún márùn-ún àbọ̀ ṣékélì [5,500] tí wọ́n sọ pé àwọn máa fún un gẹ́gẹ́ bí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yìí. Irínwó ṣékélì ni Ábúráhámù san nígbà tó fẹ́ ra ilẹ̀ tó máa sin òkú aya rẹ̀ sí, ọgbọ̀n ṣékélì péré ni wọ́n sì ń ta ẹrú láyé ìgbà yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 23:14-20; Ẹ́kísódù 21:32) Àfàìmọ̀ ni ò ní jẹ́ pé ọmọ Ísírẹ́lì ni Dèlílà. Ìdí ni pé ńṣe làwọn ọkùnrin tó ń ṣàkóso ìlú márùn-ún nílẹ̀ Filísínì náà fún un lówó ẹ̀yìn kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́, dípò kí wọ́n kàn lọ bá a pé kó bá àwọn lẹ̀dí àpò pọ̀ nítorí pé ohun tí wọ́n ń gbèrò láti ṣe yóò ṣe orílẹ̀-èdè àwọn láǹfààní. Lọ́rọ̀ kan ṣá, Dèlílà gba owó ẹ̀yìn tí wọ́n fún un.
Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Sámúsìnì tan Dèlílà nígbà tó ń yọ ọ́ lẹ́nu pé kó dáhùn ìbéèrè òun, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta sì ni obìnrin náà gbìyànjú láti fi ọkọ rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́. Àmọ́, “ó . . . ṣẹlẹ̀ pé, nítorí pé ó ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ pin ín lẹ́mìí ní gbogbo ìgbà, tí ó sì ń rọ̀ ọ́ ṣáá, ọkàn rẹ̀ kò lélẹ̀ títí dé ojú àtikú.” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Sámúsìnì sọ àṣírí agbára àrà ọ̀tọ̀ tó ní fún un, ìyẹn ni pé wọn ò gé irun orí òun rí. Ó sọ pé bí wọ́n bá fá irun orí òun, òun ò ní lágbára bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, pé ńṣe lòun máa dà bíi gbogbo àwọn ọkùnrin tó kù.—Àwọn Onídàájọ́ 16:6-17.
Ohun tí Sámúsìnì sọ yìí gan-an ló kó bá a. Dèlílà ta ọgbọ́n kan fún un kí wọ́n lè ráyè fá irun rẹ̀. Àmọ́ o, kì í ṣe pé inú irun orí Sámúsìnì ni agbára rẹ̀ wà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni irun rẹ̀ kàn fi hàn pé ó ní àjọṣe pàtàkì pẹ̀lú Ọlọ́run, pé ó jẹ́ Násírì. Nígbà tí Sámúsìnì sì ti gba àwọn kan láyè kí wọ́n ṣe ohun tó ba ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Násírì jẹ́ bí wọ́n ṣe fá irun rẹ̀, ‘Jèhófà lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.’ Ìyẹn ló jẹ́ káwọn Filísínì lè kápá Sámúsìnì, tí wọ́n fọ́ ọ lójú, tí wọ́n sì sọ ọ́ sẹ́wọ̀n.—Àwọn Onídàájọ́ 16:18-21.
Ẹ̀kọ́ ńlá lèyí kọ́ wa! Ǹjẹ́ kò yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà? Bí a bá ṣe ohun tó lè ba ìyàsímímọ́ wa jẹ́ lọ́nàkọnà, báwo la ṣe lè retí pé kí Ọlọ́run máa bù kún wa?
“Jẹ́ Kí Ọkàn Mi Kú Pẹ̀lú Àwọn Filísínì”
Inú àwọn Filísínì dùn gan-an nígbà tí wọ́n rí Sámúsìnì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dúpẹ́ lọ́wọ́ Dágónì ọlọ́run wọn pé òun ló fi ọ̀tá àwọn lé wọn lọ́wọ́. Wọ́n wá mú Sámúsìnì lọ sí ilé Dágónì òrìṣà wọn láti lọ ṣàjọyọ̀. Àmọ́, Sámúsìnì mọ ohun tó kó bá òun. Ó mọ ìdí tí Jèhófà fi lọ kúrò lọ́dọ̀ òun, ó sì ronú pìwà dà lórí àṣìṣe tó ṣe. Irun orí Sámúsìnì bẹ̀rẹ̀ sí hù gan-an ní gbogbo àsìkò tó fi wà lẹ́wọ̀n. Ní báyìí tó ti wá bára rẹ̀ níwájú ẹgbàágbèje àwọn Filísínì, èwo wá ni kó ṣe o?
Sámúsìnì gbàdúrà pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, rántí mi, jọ̀wọ́, kí o sì fún mi lókun, jọ̀wọ́, lẹ́ẹ̀kan yìí péré, ìwọ Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì jẹ́ kí n gbẹ̀san ara mi lára àwọn Filísínì nípa gbígbẹ̀san ọ̀kan nínú ojú mi méjèèjì.” Lẹ́yìn náà, ó fara ti ọwọ̀n méjèèjì tó wà ní àárín ilé náà, “ó [sì] tẹ̀ tagbára-tagbára.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀? “Ilé náà sì bẹ̀rẹ̀ sí wó lé àwọn olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀ lórí àti lé gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀ lórí, tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí ó kú, tí ó fi ikú pa nígbà ikú tirẹ̀, wá pọ̀ ju àwọn tí ó fi ikú pa nígbà ayé rẹ̀.”—Àwọn Onídàájọ́ 16:22-30.
Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó lágbára, kò sí ẹlẹ́gbẹ́ Sámúsìnì. Agbára rẹ̀ kàmàmà, ohun ribiribi ló sì fi ṣe. Àmọ́ ju gbogbo rẹ̀ lọ, Bíbélì sọ pé Sámúsìnì wà lára àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn lágbára.—Hébérù 11:32-34.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Kí ni àṣírí agbára Sámúsìnì?