Ayé Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Bá Ń Fìyìn fún Jèhófà Máa Ń Dára
“Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ni Ìrànlọ́wọ́ Mi Ti Wá”
Ayé Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Bá Ń Fìyìn fún Jèhófà Máa Ń Dára
“ÀWỌN nǹkan tó dáa jù lọ ni mo fẹ́ ní láyé mi!” Ohun tí ọ̀dọ́mọkùnrin kan sọ nìyẹn nípa àwọn nǹkan tó ń fẹ́ nígbèésí ayé. Àmọ́, báwo lọwọ́ àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè tẹ ohun tó dára jù lọ nígbèésí ayé? Bíbélì dáhùn ìbéèrè yẹn lọ́nà tó ṣe tààrà, ó ní: “Ranti ẹlẹda rẹ nisisiyi li ọjọ ewe rẹ!”—Oníwàásù 12:1, Bíbélì Mímọ́.
Kì í ṣe àwọn tó ti dàgbà nìkan ló yẹ kó máa fi ìyìn fún Jèhófà, kí wọ́n sì máa sìn ín o. Ọ̀dọ́ ni Sámúẹ́lì ọmọ Ẹlikénà àti Hánà nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà nínú àgọ́ ìjọsìn. (1 Sámúẹ́lì 1:19, 20, 24; 2:11) Ọ̀dọ́mọbìnrin Hébérù kan fi hàn pé òun nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà nígbà tó sọ pé tí Náámánì, olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Síríà tó lárùn ẹ̀tẹ̀ bá lọ sọ́dọ̀ wòlíì Èlíṣà, yóò rí ìwòsàn. (2 Àwọn Ọba 5:2, 3) Nínú Sáàmù 148:7, 12, Bíbélì sọ fáwọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin pé kí wọ́n fìyìn fún Jèhófà. a Ọmọ ọdún méjìlá péré ni Jésù nígbà tó ti fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ Baba rẹ̀. (Lúùkù 2:41-49) Nígbà táwọn ọmọdékùnrin kan rí Jésù, ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti kọ́ látinú Ìwé Mímọ́ mú kí wọ́n kígbe pé: “Gba Ọmọkùnrin Dáfídì là, ni àwa bẹ̀bẹ̀!”—Mátíù 21:15, 16.
Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ń Fìyìn fún Jèhófà Lóde Òní
Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni kì í tijú láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́, wọ́n sì ń fi ìgboyà wàásù fáwọn ọmọ ilé ìwé wọn àtàwọn ẹlòmíì. Wo àpẹẹrẹ ọ̀dọ́ méjì yìí.
Ọ̀dọ́bìnrin kan wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Stephanie. Ọmọ ọdún méjìdínlógún ni. Lọ́jọ́ kan, òun àtàwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ jọ ń fèrò wérò lórí ọ̀rọ̀ ìṣẹ́yún àtàwọn ọ̀rọ̀ mìíràn tó jẹ mọ́ ìwà rere. Olùkọ́ rẹ̀ wá sọ fún gbogbo àwọn ọmọ kíláàsì pé ibi gbogbo làwọn èèyàn ti ń ṣẹ́yún láyé ìsinsìnyí, àti pé òun ò rídìí tí ọmọbìnrin kan á fi sọ pé òun ò ní ṣẹ́yún. Nígbà tí Stephanie rí i pé gbogbo àwọn ọmọ kíláàsì fara mọ́ ohun tí olùkọ́ wọn sọ yìí, ó rí i pé ó yẹ kóun sọ ohun tóun rí nínú Bíbélì tóun ò fi lè ṣẹ́yún. Stephanie láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí olùkọ́ rẹ̀ sọ pé kó sọ èrò rẹ̀ nípa ìṣẹ́yún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù kọ́kọ́ ń bà á, síbẹ̀ ó lo àǹfààní yẹn láti jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa rẹ̀. Ó sọ kókó tó wà nínú Ẹ́kísódù 21:22-24, ó wá ṣàlàyé pé tó bá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣèpalára fún oyún inú, mélòómélòó ni kéèyàn wá ṣẹ́ oyún ọ̀hún. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìṣẹ́yún lòdì sófin Ọlọ́run.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àlùfáà ni olùkọ́ Stephanie, kò tíì ka àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí rí. Ìgboyà tí Stephanie fi wàásù mú kó láǹfààní láti bá ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí onírúurú ẹ̀kọ́. Ní báyìí, ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ kíláàsì rẹ̀ ti ń gba Ilé Ìṣọ́ àti Jí! déédéé. Méjì lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ sì lọ sí àpéjọ àgbègbè àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti lọ wo ìrìbọmi Stephanie, èyí tó jẹ́ àmì pé ó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run.
Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti ọmọ ọdún mẹ́fà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Vareta tó ń gbé orílẹ̀-èdè Suriname tó wà ní Gúúsù Amẹ́ríkà. Ọ̀dọ́mọbìnrin yìí lo àǹfààní kan tó ní láti fìyìn fún Ọlọ́run nígbà tí olùkọ́ rẹ̀ ń wá ẹni tó máa fi Bíbélì tu òun nínú. Ó ṣẹlẹ̀ pé olùkọ́ yìí ò wá sílé ìwé fún ọjọ́ mẹ́ta. Nígbà tó wá padà sílé ìwé lẹ́yìn ọjọ́ kẹta, ó bi àwọn ọmọ tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bóyá wọ́n mọ ohun tó fà á tóun ò fi wá
sílé ìwé. Àwọn ọmọ náà sọ pé, “Ó dà bíi pé ó rẹ̀ yín díẹ̀ ni.” Olùkọ́ wọn sọ pé: “Rárá, kì í ṣe pé ara mi ò yá. Àǹtí mi ló ṣaláìsí, inú ìbànújẹ́ ni mo sì wà báyìí. Torí náà, mi ò fẹ́ ariwo kankan lọ́wọ́ tí mo wà yìí.”Lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn kan náà, nígbà tí Mọ́mì Vareta ń sùn lọ́wọ́, Vareta kó àwọn ìwé ìròyìn tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ jọ, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í yẹ àkọlé wọn wò níkọ̀ọ̀kan. Vareta rí Ilé Ìṣọ́ July 15, 2001 tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Ṣé Èèyàn Máa Ń Wà Láàyè Lẹ́yìn Ikú?” Inú rẹ̀ dùn gan-an, ló bá lọ jí mọ́mì ẹ̀, ó ní: “Mọ́mì, Mọ́mì, ẹ wo nǹkan! Mo ti rí ìwé ìròyìn tí màá fún tíṣà mi! Ó sọ̀rọ̀ nípa ikú.” Vareta fi ìwé ìròyìn náà àti lẹ́tà tó kọ mọ́ ọn ránṣẹ́ sí olùkọ́ rẹ̀. Ó kọ ọ́ sínú lẹ́tà náà pé: “Ẹ̀yin ni mo dìídì fi ìwé ìròyìn yìí ránṣẹ́ sí. Nínú Párádísè, ẹ óò padà rí ẹ̀gbọ́n yín torí pé Jèhófà kì í purọ́. Jèhófà ti ṣèlérí pé ayé yìí lòun máa sọ di Párádísè kì í ṣe ọ̀run.” Olùkọ́ rẹ̀ dúpẹ́-dúpẹ́ fún ọ̀rọ̀ ìtùnú látinú Bíbélì tó wà nínú ìwé ìròyìn náà.
Múra Sílẹ̀ fún Ọjọ́ Ọ̀la
Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀,” ó sì fẹ́ káwọn ọ̀dọ́ náà máa láyọ̀. (1 Tímótì 1:11) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Gbádùn ìgbà èwe rẹ. Máa yọ̀ nígbà tó o ṣì wà léwe.” (Oníwàásù 11:9, Bíbélì Today’s English Version) Kì í ṣe pé Jèhófà rí àwọn ohun táwọn èèyàn bá ń ṣe nísinsìnyí nìkan ni, ó tún mọ ohun tí yóò jẹ́ àbájáde ìwà rere tàbí búburú tí wọ́n bá hù. Ìdí nìyí tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi gba àwọn ọ̀dọ́ níyànjú pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin, kí àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù tó bẹ̀rẹ̀ sí dé, tàbí tí àwọn ọdún náà yóò dé nígbà tí ìwọ yóò wí pé: ‘Èmi kò ní inú dídùn sí wọn.’”—Oníwàásù 12:1.
Kò sí àní-àní pé Jèhófà fẹ́ káwọn ọ̀dọ́ gbádùn ẹ̀bùn ìwàláàyè wọn tó ṣe iyebíye lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Táwọn ọ̀dọ́ bá ń rántí Ọlọ́run tí wọ́n sì ń fìyìn fún un, ayé wọn á nítumọ̀ á sì dára. Kódà, bí wọ́n tiẹ̀ níṣòro, wọ́n á lè fi ìdánilójú sọ pé: “Ọ̀dọ́ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá.”—Sáàmù 121:2.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo oṣù March àti April nínú kàlẹ́ńdà 2005 Calendar of Jehovah’s Witnesses.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]
“Ẹ yin Jèhófà láti ilẹ̀ ayé, . . . ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin àti ẹ̀yin wúńdíá pẹ̀lú.”—SÁÀMÙ 148:7, 12.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
JÈHÓFÀ Ń RAN ÀWỌN Ọ̀DỌ́ LỌ́WỌ́
“Ìwọ ni ìrètí mi, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìgbọ́kànlé mi láti ìgbà èwe mi wá.”—Sáàmù 71:5.
“[Ọlọ́run] ń fi ohun rere tẹ́ ọ lọ́rùn ní ìgbà ayé rẹ; ìgbà èwe rẹ ń sọ ara rẹ̀ dọ̀tun gẹ́gẹ́ bí ti idì.” —Sáàmù 103:5.