Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí a Ò Ṣe Ní Wà Láàyè Fún Ara Wa Mọ́

Bí a Ò Ṣe Ní Wà Láàyè Fún Ara Wa Mọ́

Bí a Ò Ṣe Ní Wà Láàyè Fún Ara Wa Mọ́

“[Kristi] kú fún gbogbo wọn kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 5:15.

1, 2. Àṣẹ Ìwé Mímọ́ wo ló mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní borí ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan?

 NÍ ALẸ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́. Wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn tó sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ló sì fi ẹ̀mí rẹ̀ lé lẹ̀ fún gbogbo àwọn tó máa lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Lára ohun tó sọ fún wọn ni pé, wọ́n gbọ́dọ̀ ní ànímọ́ pàtàkì kan tá a máa fi dá àwọn tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ̀. Ó ní: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:34, 35.

2 Àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ lo ara wọn gan-an fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. Wọ́n ní láti máa fi ohun tí yóò ṣe àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn láǹfààní ṣáájú ọ̀ràn ti ara wọn. Kódà, kò yẹ kí wọ́n lọ́ tìkọ̀ láti ‘fi ọkàn wọn lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ wọn.’ (Jòhánù 15:13) Ǹjẹ́ àwọn Kristẹni ìjímìjí tẹ̀ lé àṣẹ tuntun náà? Nínú ìwé kan tó lókìkí tí Tertullian, òǹkọ̀wé kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì kọ, èyí tó pè ní Apology, ó sọ ohun táwọn èèyàn sọ nípa àwọn Kristẹni pé: ‘Wọ́n mà nífẹ̀ẹ́ ara wọn o; kódà wọn ò kọ̀ láti kú fún ara wọn.’

3, 4. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fàyè gba ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Àwa náà gbọ́dọ̀ ‘máa bá a lọ láti máa ru ẹrù ìnira ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, kí a sì tipa báyìí mú òfin Kristi ṣẹ.’ (Gálátíà 6:2) Àmọ́, ọ̀kan lára olórí ìṣòro tí kì í jẹ́ kó rọrùn fún wa láti pa àṣẹ Kristi yìí mọ́ ni ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan. Òun náà ni kò jẹ́ kó rọrùn fún wa láti ‘nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run wa pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú wa ká sì tún nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa gẹ́gẹ́ bí ara wa.’ (Mátíù 22:37-39) Nítorí pé aláìpé ni wá, tára wa nìkan la máa ń gbájú mọ́. A tún máa ń dojú kọ wàhálà lójoojúmọ́, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ìwà bó o bá a, o pá, bó ò ba, o bù ú lẹ́sẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ níléèwé àti níbi iṣẹ́, títí kan wàhálà àtijẹ-àtimu. Ńṣe làwọn nǹkan wọ̀nyí túbọ̀ máa ń mú kí ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tá a ti jogún lágbára sí i. Àmọ́ ìwà yìí ń burú sí i ni o. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún wa pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, . . . àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn.”—2 Tímótì 3:1, 2.

4 Bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé ti ń lọ sópin, ó sọ àwọn ohun mẹ́ta kan tó lè ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ láti borí ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan. Kí làwọn ohun náà, ọ̀nà wo làwọn ìtọ́ni tó fún wọn sì lè gbà ràn wá lọ́wọ́?

Ohun Tó Máa Lé Ẹ̀mí Ìmọtara-Ẹni-Nìkan Dà Nù!

5. Nígbà tí Jésù ń wàásù ní àríwá Gálílì, kí ló sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kí nìdí tí ọ̀rọ̀ náà sì fi bà wọ́n lọ́kàn jẹ́ gan-an?

5 Jésù wà ní àgbègbè Kesaréà ti Fílípì lápá àríwá Gálílì, ó ń wàásù. Àgbègbè yìí tòrò minimini ó sì fani mọ́ra gan-an. Kò jọ ibi téèyàn ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìjìyà, kàkà bẹ́ẹ̀, ibi téèyàn ti ń gbádùn ara rẹ̀ ló jọ. Àmọ́ bí Jésù ṣe wà níbẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé “òun gbọ́dọ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí òun sì jìyà ohun púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin, kí wọ́n sì pa òun, kí a sì gbé òun dìde ní ọjọ́ kẹta.” (Mátíù 16:21) Ìbànújẹ́ gbáà lọ̀rọ̀ yìí jẹ́ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù o! Nítorí kó tó dìgbà yẹn, gbogbo èrò ọkàn wọn ni pé Ọ̀gá àwọn máa gbé Ìjọba tirẹ̀ kalẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé!—Lúùkù 19:11; Ìṣe 1:6.

6. Kí nìdí tí Jésù fi bá Pétérù wí gan-an?

6 Kíákíá ni Pétérù “mú [Jésù] lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí lọ́nà mímúná, pé: ‘Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; ìwọ kì yóò ní ìpín yìí rárá.’” Kí ni Jésù ṣe? Ó “yí ẹ̀yìn rẹ̀ padà, ó wí fún Pétérù pé: ‘Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì! Ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi, nítorí kì í ṣe àwọn ìrònú Ọlọ́run ni ìwọ ń rò, bí kò ṣe ti ènìyàn. ‘” Ẹ ò rí i pé ojú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ gbáà làwọn méjèèjì fi wo ọ̀rọ̀ náà! Tinútinú ni Jésù fi gbà láti gbé ìgbésí ayé tí Ọlọ́run là kalẹ̀ fún un, ìyẹn láti yọ̀ọ̀da ara rẹ̀ pátápátá, èyí tó máa wá yọrí sí ikú rẹ̀ lórí òpó igi òró lóṣù díẹ̀ sí i. Àmọ́ ìgbésí ayé jẹ̀lẹ́ńkẹ́ ni Pétérù dámọ̀ràn ní tiẹ̀. Ó sọ fún Jésù pé: “Ṣàánú ara rẹ.” Kò sí àní-àní pé èrò rere ni Pétérù rò pé òun ní. Síbẹ̀, Jésù bá Pétérù wí gan-an, torí pé lákòókò yẹn, ó ti gbà kí Sátánì lo òun. Pétérù kò ní ‘ìrònú Ọlọ́run lọ́kàn, ìrònú èèyàn ló ní.’—Mátíù 16:22, 23.

7. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Mátíù 16:24, kí ni Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ṣe?

7 Lónìí, a máa ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó jọ ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ fún Jésù yẹn. Ìmọ̀ràn tí aráyé sábà máa ń gbani ni pé ‘jayé orí ẹ’ tàbí kí wọ́n sọ pé ‘má fayé ni ara rẹ lára.’ Àmọ́ èrò tí Jésù dámọ̀ràn pé ká ní yàtọ̀ pátápátá sí èyí. Ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Mátíù 16:24) Ìwé tó ń jẹ́ The New Interpreter’s Bible sọ pé: “Kì í ṣe àwọn tí kò tíì di ọmọ ẹ̀yìn ni ọ̀rọ̀ Jésù yìí ń bá wí o. Ńṣe ni gbólóhùn yìí ń rọ àwọn tó tiẹ̀ ti ń tẹ̀ lé Kristi pé kí wọ́n ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn túmọ̀ sí.” Àwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ ní láti ṣe ohun mẹ́ta tí Jésù là lẹ́sẹẹsẹ nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn. Ẹ jẹ́ ká gbé wọn yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.

8. Ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí láti sẹ́ ara rẹ.

8 Lákọ̀ọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ sẹ́ ara wa. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “kí èèyàn sẹ́ ara rẹ̀” túmọ̀ sí pé kéèyàn múra tán láti pa àwọn ìfẹ́ ọ̀kan rẹ̀ tì tàbí kó kọ ìgbésí ayé ìdẹ̀ra sílẹ̀. Sísẹ́ra wa kì í kàn án ṣe ọ̀rọ̀ ká máa pa àwọn ìgbádùn kan tì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, bẹ́ẹ̀ ni kò túmọ̀ sí pé ká kúkú wá di ọ̀tá ìgbádùn pátápátá tàbí ká máa ṣẹ́ra wa níṣẹ̀ẹ́. A ‘kì í ṣe ti ara wa’ mọ́ ní ti pé, a fi gbogbo ọkàn wa yọ̀ọ̀da ìgbésí ayé wa fún Jèhófà pátápátá. (1 Kọ́ríńtì 6:19, 20) Dípò ká gbájú mọ́ ìfẹ́ ọkàn wa, ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló máa wà lórí ẹ̀mí wa. Sísẹ́ ara wa túmọ̀ sí pé ká pinnu pé ìfẹ́ Ọlọ́run la máa ṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè ta ko ohun tí ẹran ara wa aláìpé ń fẹ́. Nígbà tá a bá ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run tá a sì ṣe ìrìbọmi, ńṣe là ń fi hàn pé a fi ara wa fún un pátápátá. Lẹ́yìn náà, a óò wá máa sapá láti rí i pé gbogbo ohun tá à ń ṣe nígbèésí ayé wa bá ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa mu.

9. (a) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, kí ni òpó igi oró dúró fún? (b) Ọ̀nà wo la ń gbà gbé òpó igi oró wa?

9 Ohun kejì ni pé, a gbọ́dọ̀ gbé òpó igi oró wa. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, òpó igi oró dúró fún ìyà, ìtìjú àti ikú. Àwọn ọ̀daràn ni wọ́n sábà máa ń pa lórí òpó igi oró tàbí kí wọ́n gbé wọn kọ́ sórí rẹ̀. Àmọ́ lílò tí Jésù lo gbólóhùn yìí ń fi hàn pé ẹnikẹ́ni tó bá di Kristẹni gbọ́dọ̀ mọ̀ pé òun ní láti rí inúnibíni tàbí ẹ̀gàn àti pé wọ́n tiẹ̀ lè pa òun, nítorí kì í ṣe apá kan ayé. (Jòhánù 15:18-20) Àwọn ìlànà tí àwa Kristẹni ń tẹ̀ lé mú ká yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé, èyí sì lè mú kí wọ́n máa ‘sọ̀rọ̀ wa tèébútèébú.’ (1 Pétérù 4:4) Èyí lè ṣẹlẹ̀ ní iléèwé, níbi iṣẹ́, kódà ó lè ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé pàápàá. (Lúùkù 9:23) Ṣùgbọ́n, nítorí pé a ò wà láàyè fún ara wa mọ́, a ṣe tán láti fara da ẹ̀gàn látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn ayé. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi. Ẹ yọ̀, kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú, níwọ̀n bí èrè yín ti pọ̀ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:11, 12) Ká sòótọ́, kò sóhun tó ṣe pàtàkì bíi rírí ojú rere Ọlọ́run.

10. Kí ló túmọ̀ sí láti máa tọ Jésù lẹ́yìn nígbà gbogbo?

10 Ẹ̀kẹta, Jésù Kristi sọ pé a gbọ́dọ̀ máa tọ òun lẹ́yìn nígbà gbogbo. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tó ń jẹ́ An Expository Dictionary of New Testament Words látọwọ́ W. E. Vine ṣe sọ, láti tẹ̀ lé ẹnì kan túmọ̀ sí láti máa bá ẹni náà rìn, ìyẹn ni pé “kí wọ́n jọ máa lọ sí ibi kan náà.” Jòhánù kìíní orí kejì ẹsẹ kẹfà sọ pé: “Ẹni tí ó bá sọ pé òun dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú [Ọlọ́run] wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe pẹ̀lú láti máa bá a lọ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí ẹni yẹn [Kristi] ti rìn.” Báwo ni Jésù ṣe rìn? Nítorí pé Jésù nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ ọ̀run àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kò fàyè gba ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: ‘Kristi kò ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀.’ (Róòmù 15:3) Kódà, nígbà tó rẹ Jésù àti nígbà tí ebi ń pà á, ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíràn ló fi ṣáájú tirẹ̀. (Máàkù 6:31-34) Jésù tún lo ara rẹ̀ gan-an nínú wíwàásù àti kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Ǹjẹ́ kò yẹ káwa náà fara wé e bá a ti ń fìtara ṣe iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́, ìyẹn iṣẹ́ ‘sísọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ká máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tó pa láṣẹ mọ́’? (Mátíù 28:19, 20) Nínú ìwà àti ìṣe, Kristi fi àpẹẹrẹ tó yẹ ká tẹ̀ lé lélẹ̀ fún wa, a sì gbọ́dọ̀ “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.”—1 Pétérù 2:21.

11. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká sẹ́ ara wa, ká gbé òpó igi oró wa, ká sì máa tọ Jésù Kristi lẹ́yìn nígbà gbogbo?

11 Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká sẹ́ ara wa, ká gbé òpó igi oró wa, ká sì máa tọ Jésù Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa lẹ́yìn nígbà gbogbo. Èyí ni yóò jẹ́ ká lè borí ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tí kì í jẹ́ kéèyàn fẹ́ láti lo ara rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. Kò tán síbẹ̀ o, Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là yóò pàdánù rẹ̀; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá pàdánù ọkàn rẹ̀ nítorí mi yóò rí i. Nítorí àǹfààní wo ni yóò jẹ́ fún ènìyàn kan bí ó bá jèrè gbogbo ayé ṣùgbọ́n tí ó pàdánù ọkàn rẹ̀? tàbí kí ni ènìyàn kan yóò fi fúnni ní pàṣípààrọ̀ fún ọkàn rẹ̀?”—Mátíù 16:25, 26.

A Ò Lè Sin Ọ̀gá Méjì

12, 13. (a) Kí ló jẹ ọ̀dọ́ alákòóso tó wá béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Jésù lógún? (b) Ìmọ̀ràn wo ni Jésù gbà á, kí sì nídìí tó fi gbà á nírú ìmọ̀ràn yẹn?

12 Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí Jésù ti sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé ó pọn dandan kí wọ́n sẹ́ ara wọn, ọ̀dọ́ ọlọ́rọ̀ kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì sọ fún un pé: “Olùkọ́, ohun rere wo ni mo gbọ́dọ̀ ṣe láti rí ìyè àìnípẹ̀kun?” Jésù sọ fún un pé kó “máa pa àwọn àṣẹ mọ́ nígbà gbogbo” ó sì mẹ́nu ba díẹ̀ lára àwọn àṣẹ náà. Ọkùnrin náà wá sọ fún Jésù pé: “Mo ti pa gbogbo ìwọ̀nyí mọ́.” Ó hàn gbangba pé òótọ́ inú lọkùnrin yìí fi sọ̀rọ̀, àti pé ó ti ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti pa Òfin náà mọ́. Ó wá béèrè pé: “Kí ni mo ṣaláìní síbẹ̀?” Jésù sọ fún ọkùnrin náà pé kó lọ ṣe ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó ní: “Bí ìwọ bá fẹ́ jẹ́ pípé [“ṣe àṣepé” gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ ti Bíbélì New American Standard Bible], lọ ta àwọn nǹkan ìní rẹ, kí o sì fi fún àwọn òtòṣì, ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá di ọmọlẹ́yìn mi.”—Mátíù 19:16-21.

13 Jésù mọ̀ pé kí ọkùnrin yìí tó lè fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mú ohun ńlá kan tó ń pín ọkàn rẹ̀ níyà kúrò, ìyẹn ni ọrọ̀ rẹ̀. Ẹni tó bá jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi lóòótọ́ kò lè sin ọ̀gá méjì. “Kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” (Mátíù 6:24) Ojú rẹ̀ gbọ́dọ̀ mú ọ̀nà kan, ìyẹn ni pé kó gbájú mọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí. (Mátíù 6:22) Ìfẹ́ láti yọ̀ọ̀da ara ẹni pátápátá ló máa jẹ́ kéèyàn lè palẹ̀ gbogbo ohun tó ní mọ́ kó sì kó wọn fún àwọn tálákà. Àǹfààní kan tí kò lẹ́gbẹ́ ni Jésù wá sọ pé òun máa fi rọ́pò rẹ̀ fún ọkùnrin náà tó ba ṣe ohun tóun ní kó ṣe. Yóò ní ọrọ̀ rẹpẹtẹ ní ọ̀run, tó túmọ̀ sí pé yóò ní ìyè ayérayé, èyí tó máa mú kó dẹni tó ń ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lọ́run níkẹyìn. Àmọ́ ọ̀dọ́ ọlọ́rọ̀ yìí kò ṣe tán láti sẹ́ ara rẹ̀ o. Ó “lọ kúrò pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn, nítorí ó ní ohun ìní púpọ̀.” (Mátíù 19:22) Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù yòókù kò ṣe bẹ́ẹ̀.

14. Kí làwọn apẹja mẹ́rin kan ṣe nígbà tí Jésù pè wọ́n pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé òun lẹ́yìn?

14 Ní nǹkan bí ọdún méjì ṣáájú ìgbà yẹn, bí Jésù ṣe pe ọkùnrin yìí ló ṣe pe àwọn apẹja mẹ́rin kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Pétérù, Áńdérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù. Méjì lára wọn ń pẹja lọ́wọ́ lákòókò náà, ọwọ́ àwọn méjì yòókù sì dí níbi tí wọ́n ti ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn, ṣe ni èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin fi iṣẹ́ ẹja pípa tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín wọ́n sì ń tẹ̀ lé Jésù ní gbogbo ìyókù ayé wọn.—Mátíù 4:18-22.

15. Kí ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan lóde òní yááfì kó bàa lè tẹ̀ lé Jésù?

15 Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni lónìí ló ti ṣe bíi tàwọn apẹja mẹ́rin yẹn, wọn ò ṣe bíi ti ọ̀dọ́ ọlọ́rọ̀ yẹn. Wọ́n mójú wọn kúrò nínú ọrọ̀ àtàwọn àǹfààní tí ì bá sọ wọ́n di èèyàn ńlá nínú ayé nítorí kí wọ́n lè sin Jèhófà. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Deborah sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlélógún, ìpinnu ńlá kan wà tí mo ní láti ṣe.” Ó ṣàlàyé pé: “Mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún nǹkan bí oṣù mẹ́fà nígbà yẹn, mo sì fẹ́ fi ìgbésí ayé mi sin Jèhófà, àmọ́ ìdílé mi kò fara mọ́ ìpinnu yìí rárá. Wọ́n lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n sì ronú pé bí mo bá lọ di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí, ohun ìtìjú ló máa jẹ́ fáwọn láwùjọ. Wọ́n fún mi lọ́jọ́ kan péré kí n fi lọ ro ohun tí màá ṣe, bóyá ọrọ̀ ni màá mú tàbí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Bí mi ò bá dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn Ẹlẹ́rìí, a jẹ́ pé mi ò ní ìpín kankan nínú ohun tí ìdílé mi ní nìyẹn. Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu ó sì tún fún mi lágbára láti dúró lórí ìpinnu náà. Ó ti di ọdún méjìlélógójì báyìí tí mo ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún, mi ò sì kábàámọ̀ kankan. Nítorí pé mo kọ ìgbésí ayé onímọtara-ẹni-nìkan àti ìgbádùn jíjẹ sílẹ̀, Jèhófà ti yọ mí nínú ìgbésí ayé òfo táwọn kan lára ìdílé mi ń gbé. Ó lé ní ọgọ́rùn-ún èèyàn tí èmi àti ọkọ mi ti ràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àwọn ọmọ wa nípa tẹ̀mí yìí ṣe pàtàkì lójú mi ju ọrọ̀ tara èyíkéyìí lọ.” Irú èrò arábìnrin yìí náà ni ẹgbàágbèje àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní. Ìwọ ńkọ́?

16. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ò wà láàyè fún ara wa mọ́?

16 Nítorí pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fẹ́ láti wà láàyè fún ara wọn mọ́ ló mú kí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà tàbí iṣẹ́ pípolongo Ìjọba Ọlọ́run nígbà gbogbo. Àwọn tí ipò wọn ò jẹ́ kí wọ́n lè máa lo àkókò púpọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ní irú ẹ̀mí táwọn aṣáájú ọ̀nà ní, wọ́n ń kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà lẹ́yìn débi tí wọ́n lè ṣe é dé. Báwọn òbí ti ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní àwọn ìlànà tẹ̀mí, tí wọ́n sì ń mojú kúrò nínú àwọn ohun kan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, ńṣe ni wọ́n ń fi hàn pé àwọn náà ní irú ẹ̀mí táwọn aṣáájú ọ̀nà ní. Gbogbo wa la lè fi hàn lọ́nà kan tàbí òmíràn pé àwọn ìgbòkègbodò tó dá lórí Ìjọba Ọlọ́run ló gbapò iwájú ní ìgbésí ayé wa.— Mátíù 6:33.

Ìfẹ́ Ta Ló Mú Kó Di Ọ̀ranyàn fún Wa?

17. Kí ló ń sún wa láti ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ?

17 Kò rọrùn rárá láti ní ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ. Àmọ́, ronú nípa ohun tó ń sún wa láti ní irú ìfẹ́ yìí. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nítorí ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa, nítorí èyí ni ohun tí àwa ti ṣèdájọ́, pé ọkùnrin kan kú fún gbogbo ènìyàn . . . Ó sì kú fún gbogbo wọn kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.” (2 Kọ́ríńtì 5:14, 15) Ìfẹ́ Kristi tá a ní ló mú kó di ọ̀ranyàn fún wa láti má ṣe wà láàyè fún ara wa mọ́. Ẹ ò rí i pé ohun ńlá ló mú ká ṣe bẹ́ẹ̀! Níwọ̀n bí Kristi ti kú fún wa, ǹjẹ́ a ò rí ìdí tó fi yẹ káwa náà wà láàyè fún un? Ó ṣe tán, torí pé a mọyì ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Ọlọ́run àti Kristi fi hàn sí wa ló mú ká ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run tá a sì di ọmọ ẹ̀yìn Kristi.—Jòhánù 3:16; 1 Jòhánù 4:10, 11.

18. Kí nìdí tí ṣíṣàìwà láàyè fún ara wa mọ́ fi lérè nínú?

18 Ǹjẹ́ èrè tiẹ̀ wà nínú ṣíṣàìwà láàyè fún ara wa mọ́? Lẹ́yìn tí ọ̀dọ́ ọlọ́rọ̀ tó jẹ́ alákòóso yẹn ti kọ̀ láti ṣe ohun tí Jésù sọ pé kó ṣe tó sì ti bá tirẹ̀ lọ, Pétérù wá sọ fún Jésù pé: “Wò ó! Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; kí ni yóò wà fún wa ní ti gidi?” (Mátíù 19:27) Òótọ́ ni, Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù ti sẹ́ ara wọn tọkàntọkàn. Kí ni yóò jẹ́ èrè wọn? Jésù kọ́kọ́ sọ nípa àǹfààní kan tí wọ́n máa ní, ìyẹn àǹfààní láti ṣàkóso pẹ̀lú òun ní ọ̀run. (Mátíù 19:28) Lákòókò yẹn náà ló tún sọ àwọn ìbùkún tí gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yóò rí gbà. Ó sọ pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó fi ilé sílẹ̀ tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí ìyá tàbí baba tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn pápá nítorí mi àti nítorí ìhìn rere tí kì yóò gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún nísinsìnyí ní sáà àkókò yìí . . . àti nínú ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀, ìyè àìnípẹ̀kun.” (Máàkù 10:29, 30) Ohun tá à ń rí gbà pọ̀ gan-an ju ohun tá a yááfì lọ. Ǹjẹ́ àwọn bàbá wa, ìyá wa, àwọn arákùnrin àti arábìnrin, àtàwọn ọmọ wa nípa tẹ̀mí kò ṣeyebíye gan-an ju ohunkóhun tá a ti yááfì nítorí Ìjọba náà? Nínú Pétérù àti ọ̀dọ́ ọlọ́rọ̀ tó jẹ́ alákòóso yẹn, ta ni ayé rẹ̀ dára jù lọ?

19. (a) Kí ló ń fúnni ní ojúlówó ayọ̀? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?

19 Jésù fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀ pé kéèyàn máa ṣe nǹkan fáwọn ẹlòmíràn ń fúnni láyọ̀, kì í ṣe mímọ tara ẹni nìkan. (Mátíù 20:28; Ìṣe 20:35) Nígbà tá ò bá wà láàyè fúnra wa mọ́ ṣùgbọ́n tí à ń tẹ̀ lé Kristi nígbà gbogbo, a óò rí ayọ̀ rẹpẹtẹ nínú ìgbésí ayé wa ìsinsìnyí a ó sì tún ní ìrètí àtiwà láàyè títí láé lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́, nígbà tá a bá sẹ́ ara wa, a di ti Jèhófà nìyẹn. Èyí mú ká di ẹrú Ọlọ́run. Kí ló mú kí irú ìsìnrú bẹ́ẹ̀ lérè nínú? Báwo lèyí sì ṣe kan àwọn ìpinnu tá à ń ṣe nígbèésí ayé wa? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò bójú tó àwọn ìbéèrè yìí.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fàyè gba ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan?

• Kí ló túmọ̀ sí pé ká sẹ́ ara wa, ká gbé òpó igi oró wa, ka sì máa tọ Jésù lẹ́yìn nígbà gbogbo?

• Kí ló ń sún wa láti má ṣe wà láàyè fún ara wa mọ́?

• Kí nìdí tí ṣíṣàìwà láàyè fún ara wa mọ́ fi lérè nínú?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

“Ṣàánú ara rẹ, Olúwa”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Kí ni kò jẹ́ kí ọ̀dọ́ alákòóso yẹn tẹ̀ lé Jésù?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ìfẹ́ ló mú kó di ọ̀ranyàn fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti máa fi ìtara polongo Ìjọba náà