Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ipa Wo Ni Jésù Kristi Ń Ní Lórí Rẹ?

Ipa Wo Ni Jésù Kristi Ń Ní Lórí Rẹ?

Ipa Wo Ni Jésù Kristi Ń Ní Lórí Rẹ?

LÁTÀRÍ ohun tá a gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè sọ pé ibì kan wà láyé yìí táwọn èèyàn ò ti mọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ Jésù? Síbẹ̀, ìbéèrè pàtàkì tó yẹ kí kálukú bi ara rẹ̀ ni pé, “Ipa wo làwọn ẹ̀kọ́ Jésù ń ní lórí mi?”

Onírúurú nǹkan làwọn ẹ̀kọ́ Jésù dá lé lórí. Àwọn ohun tá a sì rí kọ́ nínú àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí lè nípa lórí gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí ohun tí Jésù fi kọ́ni nípa bá a ṣe lè mọ àwọn ohun tó yẹ ká fi ṣáájú nígbèésí ayé, bá a ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, bá a ṣe lè máa fi àlàáfíà bá àwọn ẹlòmíì lò, bá a ṣe lè yanjú ìṣòro, àti bá a ṣe lè yẹra fún ìwà ipá.

Mọ Ohun Tó Yẹ Kó O Fi Ṣáájú

Kòókòó jàn-ánjàn-án inú ayé lónìí máa ń gba àkókò wa, ó sì lè mú kó rẹ̀ wá tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tá ò fi ní lè ráyè fáwọn nǹkan tẹ̀mí. Wo àpẹẹrẹ ọmọkùnrin kan tó ti lé lógún ọdún tá a pe orúkọ rẹ̀ ní Jerry nínú àpilẹ̀kọ yìí. Jerry jẹ́ ẹnì kan tó máa ń fẹ́ kóun àtàwọn ẹlòmíràn máa jíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí, ó sì mọyì àwọn ẹ̀kọ́ tó ń rí kọ́ látinú ìjíròrò náà. Àmọ́, nǹkan kan wà tó máa ń dùn ún. Ó sọ pé: “Mi ò kì í sábà ráyè sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí. Ọjọ́ mẹ́fà ni mo fi ń ṣiṣẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀. Ọjọ́ Sunday nìkan ni mi kì í lọ síbi iṣẹ́. Nígbà tí mo bá sì fi máa parí àwọn iṣẹ́ tó yẹ kí n ṣe nílé, á ti rẹ̀ mí gan-an.” Tó bá jẹ́ pé ìwọ náà kì í ráyè fáwọn nǹkan tẹ̀mí bíi ti Jerry, o lè rí ohun tó máa ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan tí Jésù fi kọ́ni nínú ìwàásù rẹ̀ lórí òkè.

Jésù sọ fáwọn tó pé jọ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn nípa ọkàn yín, ní ti ohun tí ẹ ó jẹ tàbí ohun tí ẹ ó mu, tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ ó wọ̀. Ọkàn kò ha ṣe pàtàkì ju oúnjẹ àti ara ju aṣọ lọ? Ẹ fi tọkàntara ṣàkíyèsí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí wọn kì í fún irúgbìn tàbí ká irúgbìn tàbí kó jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́; síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí? . . . Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ Nítorí gbogbo ìwọ̀nyí ni nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:25-33) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ohun tí Jésù sọ yìí?

Jésù ò sọ pé ká máà gbọ́ bùkátà ara wa àti ti ìdílé wa o. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé: “Bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 5:8) Àmọ́, Jésù ṣèlérí pé tá a bá fi àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣáájú nígbèésí ayé wa, Ọlọ́run yóò rí sí i pé ọwọ́ wa tẹ àwọn nǹkan yòókù tá a nílò. Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ látinú ohun tí Jésù sọ yìí ni pé, a ní láti mọ àwọn ohun tó yẹ ká fi ṣáájú. Tá a bá sì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, a óò láyọ̀, nítorí pé “aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”—Mátíù 5:3.

Gbìyànjú Láti Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run

Àwọn tí nǹkan tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn mọ̀ pé ó pọn dandan káwọn ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Tá a bá fẹ́ bá ẹnì kan dọ́rẹ̀ẹ́, ibo la ti máa bẹ̀rẹ̀? Ǹjẹ́ kì í ṣe pé a máa kọ́kọ́ gbìyànjú láti mọ onítọ̀hún dáadáa? A óò wọ́nà láti mọ èrò onítọ̀hún nípa àwọn nǹkan, a ó mọ ìwà rẹ̀, àwọn ohun tó lè ṣe, àwọn ohun tó ti ṣe, àwọn ohun tó fẹ́ àtàwọn ohun tí kò fẹ́. Ohun tá a máa ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn tá a bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ó pọn dandan pé ká ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run. Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà sí Ọlọ́run nítorí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Bẹ́ẹ̀ ni, ká tó lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, a ní láti kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. Inú Bíbélì, ìyẹn Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, nìkan la sì ti lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. (2 Tímótì 3:16) Torí náà, a ní láti ya àkókò sọ́tọ̀ tá a ó fi máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú Ìwé Mímọ́.

Àmọ́ ṣá o, ìmọ̀ nìkan ò tó. Nínú àdúrà yìí kan náà tí Jésù gbà, ó sọ pé: “Wọ́n [ìyẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun] sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.” (Jòhánù 17:6) Yàtọ̀ sí pé ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, a tún gbọ́dọ̀ máa fi àwọn ohun tá à ń kọ́ ṣèwà hù. Àbí báwo lèèyàn ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tí ò bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run kó sì máa fi àwọn ohun tó ń kọ́ ṣèwà hù? Ǹjẹ́ a lè retí pé kí okùn ọ̀rẹ́ tó so àwa àti ẹnì kan pọ̀ máa lágbára sí i tá a bá mọ̀ọ́mọ̀ ń ṣe nǹkan tónítọ̀hún ò fẹ́? Ìdí nìyẹn tó fi yẹ kóhun tí Ọlọ́run fẹ́ àtàwọn ìlànà rẹ̀ jẹ́ atọ́nà wa nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Ẹ jẹ́ ká wo bí méjì lára àwọn ìlànà Ọlọ́run ṣe kan àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.

Máa Fi Àlàáfíà Bá Àwọn Ẹlòmíràn Lò

Lọ́jọ́ kan, Jésù sọ ìtàn kúkúrú kan láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa bá ara wọn lò. Ó sọ̀rọ̀ nípa ọba kan tó ní káwọn ìránṣẹ́ òun wá ṣèṣirò owó tí ń bẹ lọ́wọ́ wọn. Àmọ́, ọkàn lára àwọn ìránṣẹ́ náà jẹ ọba yìí ní gbèsè tabua kan, kò sì rówó ọ̀hún san. Ọba náà wá pàṣẹ pé kí wọ́n ta ìránṣẹ́ yìí tòun ti aya rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ kí wọ́n sì fi san gbèsè náà. Ni ìránṣẹ́ náà bá kúnlẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ ọba náà, ó ní: “Mú sùúrù fún mi, dájúdájú, èmi yóò sì san ohun gbogbo padà fún ọ.” Àánú ẹ̀ ṣe ọ̀gá rẹ̀, ó sì fagi lé gbèsè náà. Àmọ́, nígbà tí ẹrú yìí kúrò lọ́dọ̀ ọba, tó rí ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan tó jẹ ẹ́ lówó táṣẹ́rẹ́ kan, ó bu ẹrú náà so, ó ní kó bá òun gbówó òun. Ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yìí bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣàánú òun, àmọ́ ẹrú náà ò gbẹ̀bẹ̀, ó ní kí wọ́n ju ẹrú kejì náà sẹ́wọ̀n títí dìgbà tó fi máa sanwó òun. Nígbà tí ọba náà gbọ́rọ̀ yìí, inú bí i. Ó sọ fún ẹrú àkọ́kọ́ náà pé: “Kò ha yẹ kí ìwọ . . . ṣàánú fún ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú ti ṣàánú fún ọ?” Ó pàṣẹ pé kí wọ́n sọ ẹrú aláìláàánú yìí sẹ́wọ̀n títí dìgbà tó fi máa san gbogbo owó tó jẹ. Jésù sọ ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìtàn yìí, ó ní: “Ọ̀nà kan náà ni Baba mi ọ̀run yóò gbà bá yín lò pẹ̀lú bí olúkúlùkù yín kò bá dárí ji arákùnrin rẹ̀ láti inú ọkàn-àyà yín wá.”—Mátíù 18:23-35.

Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń ṣàṣìṣe nítorí pé aláìpé ni wá. Kò sí bá a ṣe lè san gbèsè tabua tá a jẹ Ọlọ́run nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tá à ń ṣẹ̀ ẹ́. Ohun kan ṣoṣo tá a lè ṣe ni pé ká máa tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Jèhófà Ọlọ́run sì ṣe tán láti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá bí àwa náà bá ń dárí ji àwọn arákùnrin wa tó bá ṣẹ̀ wá. Ẹ̀kọ́ ńlá mà lèyí o! Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé: “Dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa.”—Mátíù 6:12.

Ohun Tó Ń Pilẹ̀ Ìṣòro Ni Kó O Gbógun Tì

Kò sóhun tí Jésù ò mọ̀ nípa ẹ̀dá èèyàn. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ohun tó ń fa ìṣòro wa gan-an ni Jésù kọ́ wa bá a ṣe lè yanjú. Wo àpẹẹrẹ méjì yìí.

Jésù sọ pé: “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá ṣìkà pànìyàn yóò jíhìn fún kóòtù ìgbẹ́jọ́.’ Bí ó ti wù kí ó rí, mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ń bá a lọ ní kíkún fún ìrunú sí arákùnrin rẹ̀ yóò jíhìn fún kóòtù ìgbẹ́jọ́.” (Mátíù 5:21, 22) Ohun tí Jésù ń fi yé wa nínú ẹsẹ yìí ni pé kì í ṣe pípa tẹ́nìkan pànìyàn ni ibi tí ìṣòro ti bẹ̀rẹ̀. Ẹ̀mí búburú tẹ́ni tó pààyàn gbà kó jọba nínú ọkàn rẹ̀ ni olórí ìṣòro. Táwọn èèyàn ò bá gba ẹ̀mí ìkórìíra àti ìbínú láyè kó gbilẹ̀ nínú ọkàn wọn, kò sóhun tó máa mú wọn ronú àtiṣe ẹlòmíràn níbi. Ẹ ò rí i pé kì bá máà sí ìpànìyàn rárá ká ní pé àwọn èèyàn ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Jésù!

Kíyè sí ohun tí Jésù sọ pé ó ń pilẹ̀ ìṣòro kan tó lè kó ẹ̀dùn ọkàn báni. Ó sọ fáwọn tó pé jọ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.’ Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀. Wàyí o, bí ojú ọ̀tún rẹ yẹn bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” (Mátíù 5:27-29) Ohun tí Jésù fi ń kọ́ni níbí yìí ni pé èèyàn ò kàn lè ṣàdédé lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe. Ibi èròkérò ló ti máa ń bẹ̀rẹ̀. Tẹ́nì kan ò bá gba èròkérò láyè, ṣùgbọ́n tó ‘yọ wọ́n jáde’ kúrò nínú ọkàn rẹ̀, kò sóhun tó máa mú onítọ̀hún lọ ṣèṣekúṣe.

“Dá Idà Rẹ Padà sí Àyè Rẹ̀”

Lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n fi Jésù lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fa idà rẹ̀ yọ nítorí pé ó fẹ́ gbèjà Jésù. Ṣùgbọ́n, Jésù sọ fún un pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:52) Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, Jésù sọ fún Pọ́ńtíù Pílátù pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí. Bí ìjọba mi bá jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ẹmẹ̀wà mi ì bá ti jà kí a má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, ìjọba mi kì í ṣe láti orísun yìí.” (Jòhánù 18:36) Ǹjẹ́ a lè sọ pé ẹ̀kọ́ yìí ò ṣàǹfààní?

Ọwọ́ wo làwọn Kristẹni ìjímìjí fi mú ohun tí Jésù kọ́ wọn pé kí wọ́n má ṣe hùwà ipá? Ìwé The Early Christian Attitude to War (Ojú Táwọn Kristẹni Ìjímìjí Fi Ń Wo Ogun) sọ pé: ‘Níwọ̀n bí àwọn ẹ̀kọ́ Jésù ti fi hàn pé ó lòdì láti máa hùwà ipá àti láti máa ṣe ohun tó máa ṣèpalára fáwọn ẹlòmíràn, èyí fi hàn pé ogun jíjà ò bójú mu rárá. Ohun tí Jésù sọ gẹ́lẹ́ làwọn Kristẹni ìjímìjí ń tẹ̀ lé, wọ́n mọ̀ pé ńṣe ni Jésù ń kọ́ àwọn pé káwọn jẹ́ èèyàn jẹ́jẹ́ káwọn má sì bá ẹnikẹ́ni jà. Wọ́n jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹ̀sìn àlàáfíà làwọn ń ṣe; wọn ò fọwọ́ sí ogun jíjà rárá nítorí ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n máa ń ta sílẹ̀ nígbà ogun.’ Ká ní àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ Jésù ni, kò sí àní-àní pé àwọn nǹkan burúkú tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ì bá má ti wáyé!

Gbogbo Ẹ̀kọ́ Jésù Ló Lè Ṣe Ọ́ Láǹfààní

Àwọn ẹ̀kọ́ Jésù tá a gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí wúlò gan-an, ó rọrùn láti lóye, ó sì wọni lọ́kàn gan-an ni. Àwa èèyàn lè jàǹfààní látinú àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ tá a bá ń yẹ̀ wọ́n wò déédéé tá a sì ń fi wọ́n ṣèwà hù. a

Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ bí wàá ṣe jàǹfààní látinú àwọn ẹ̀kọ́ tó mọ́gbọ́n dání jù lọ yìí. A rọ̀ ọ́ pé kó o kàn sí wọn tàbí kó o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó wà lójú ìwé 2 ìwé ìròyìn yìí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa gbogbo ẹ̀kọ́ Jésù ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀ lé, wo ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

“Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn ẹ̀kọ́ Jésù lè ṣe ọ́ làǹfààní tó pọ̀