Kárí Ayé Làwọn Èèyàn Mọyì Jésù
Kárí Ayé Làwọn Èèyàn Mọyì Jésù
ATÚMỌ̀ Bíbélì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Edgar Goodspeed sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan ni Jésù fẹ́ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí àwọn ìwé ìhìn rere ròyìn pé Jésù sọ, kò ní gbà á ju wákàtí méjì lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba ẹ̀kọ́ díẹ̀ ni Jésù fi kọ́ni, síbẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ náà wọ àwọn èèyàn lọ́kàn gan-an débi tá a fi lè sọ pé kò sẹ́ni tó gbayì tó o láyé yìí.”
Ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa tí Jésù Kristi parí iṣẹ́ tó wáyé wá ṣe, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tó nǹkan bí ọgọ́fà ó kéré tán. (Ìṣe 1:15) Àmọ́ lónìí, àwọn tó sọ pé Kristẹni làwọn lé ní bílíọ̀nù méjì. Ẹgbàágbèje èèyàn ló sì tún gbà pé wòlíì ni Jésù. A lè wá rí i báyìí pé lóòótọ́ làwọn ẹ̀kọ́ Jésù wọ àwọn èèyàn lọ́kàn.
Kódà, àwọn aṣáájú nínú àwọn ẹ̀sìn tí kì í ṣe ẹ̀sìn Kristẹni pàápàá mọyì Jésù. Bí àpẹẹrẹ, rábì kan tó jẹ́ Júù, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hyman Enelow kọ̀wé pé: “Látìgbà táráyé ti ń ṣe ẹ̀sìn, Jésù lẹni tó gbajúmọ̀ jù lọ, òun làwọn èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ jù lọ, òun ló sì gbayì jù lọ.” Enelow tún sọ pé: “Ipa tí Jésù ń ní lórí aráyé kọjá sísọ. Ṣé ìfẹ́ tó ní sáwọn èèyàn ni ká sọ ni, àbí ìtùnú tó fáwọn èèyàn tàbí oore tó ṣe fáwọn èèyàn, títí kan ìrètí àti ayọ̀ tó mú káwọn èèyàn ní? Ká sòótọ́, kò sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Nínú gbogbo àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn àtàwọn ẹni rere tó ti ń gbé ayé, kò sí ìkankan nínú wọn tí òkìkí àti iyì wọn sún mọ́ ti Jésù. Òun làwọn èèyàn gba tiẹ̀ jù lọ láyé yìí.” Mohandas K.
Gandhi tó jẹ́ olórí ìsìn Híńdù sọ pé: “Mi ò tíì rẹ́ni tó ṣe nǹkan fún aráyé tó Jésù. Ká sòótọ́, kò sí nǹkan kan tó burú nípa ẹ̀sìn Kristẹni.” Ó wá sọ pé: “Àmọ́, ẹ̀yin Kristẹni gan-an lẹ níṣòro. Ẹ ò kì í fi àwọn ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ ṣèwà hù.”Ọjọ́ pẹ́ táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti ń kùnà láti fi àwọn ẹ̀kọ́ Jésù ṣèwà hù. Òpìtàn kan nípa ẹ̀sìn Kristẹni tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Cecil John Cadoux sọ pé: “Láti nǹkan bí ọdún 140 Sànmánì Tiwa làwọn aṣáájú nínú ẹ̀sìn Kristẹni ti ń gbìyànjú láti wá nǹkan ṣe sí ìwàkiwà tó fẹ́ máa yọ́ wọnú ẹ̀sìn Kristẹni.” Ó tún sọ pé: “Báwọn onísìn ṣe gbà kí ìwàkiwà wọnú ẹ̀sìn Kristẹni, tí wọn ò ṣe bíi tàwọn Kristẹni ìjímìjí, ló sọ wọ́n dẹni tó ń hùwà bíi tàwọn èèyàn ayé.”
Ipò yìí túbọ̀ wá burú sí i ní ọ̀rúndún kẹrin nígbà tí Kọnsitatáìnì, Olú Ọba Róòmù, di Kristẹni. Cadoux sọ nínú ìwé rẹ̀ pé: “Àwọn òpìtàn máa ń rí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, kódà àwọn míì lára wọn máa ń ta ko àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì torí pé wọ́n lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Kọnsitatáìnì.” Látìgbà yẹn títí di ìsinsìnyí làwọn tó sọ pé Kristẹni làwọn sì ti ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan búburú tó ń bu ọlá orúkọ Kristi kù.
Ìbéèrè tó wá yẹ ká wá ìdáhùn sí nìyí: Kí ni àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni gan-an? Ipa wo ló sì yẹ káwọn ẹ̀kọ́ náà ní lórí wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
“Mi ò tíì rẹ́ni tó ṣe nǹkan fún aráyé tó Jésù.”—Mohandas K. Gandhi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
“Kò sẹ́ni tó gbayì tó o láyé yìí.”—Edgar Goodspeed
[Credit Line]
Culver ló ya fọ́tò wọ̀nyí