Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Dáàbò Bo Ogún Iyebíye Tẹ́ Ẹ Ní

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Dáàbò Bo Ogún Iyebíye Tẹ́ Ẹ Ní

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Dáàbò Bo Ogún Iyebíye Tẹ́ Ẹ Ní

“Ọgbọ́n jẹ́ fún ìdáàbòbò . . . [Ó] máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.”—ONÍWÀÁSÙ 7:12.

1. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn òbí ka àwọn ọmọ wọn sí ẹ̀bùn?

 IPASẸ̀ àwọn òbí ni ọmọ jòjòló fi ń wá sáyé. Ọmọ tuntun yìí á sì ní àwọn ànímọ́ àtàwọn ìwà tó jọ tiwọn. Bíbélì pe irú àwọn ọmọ kéékèèké bẹ́ẹ̀ ní “ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” (Sáàmù 127:3) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ni Olùfúnni-Ní-Ìyè, ńṣe ló fi ohun tó jẹ́ tiẹ̀ yìí síkàáwọ́ àwọn òbí. (Sáàmù 36:9) Ẹ̀yin òbí, ojú wo lẹ fi ń wo ẹ̀bùn iyebíye tẹ́ ẹ gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run yìí?

2. Kí ni Mánóà ṣe nígbà tó gbọ́ pé òun máa tó di bàbá ọmọ?

2 Láìsí àní-àní, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí ìmoore ló yẹ káwọn òbí fi gba irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀. Ohun tí ọmọ Ísírẹ́lì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mánóà ṣe ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta sẹ́yìn nìyẹn, nígbà tí áńgẹ́lì kan wá sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé yóò bí ọmọ kan. Bí Mánóà ṣe gbọ́ ìhìn rere yìí ló gbàdúrà pé: “Dákun, Jèhófà. Ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ rán wá, jọ̀wọ́, jẹ́ kí ó tún tọ̀ wá wá, kí ó sì fún wa ní ìtọ́ni ní ti ohun tí ó yẹ kí a ṣe sí ọmọ náà tí a óò bí.” (Àwọn Onídàájọ́ 13:8) Ẹ̀yin òbí, ẹ̀kọ́ wo lẹ lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Mánóà?

Ìdí Tá A Fi Nílò Ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run Lákòókò Yìí

3. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé òde òní gan-an la nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run ju ti tẹ́lẹ̀ rí lọ láti tọ́ àwọn ọmọ wa?

3 Àkókò tá a wà yìí gan-an làwọn òbí nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà ju ti tẹ́lẹ̀ rí lọ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn. Kí nìdí? A ti lé Sátánì Èṣù àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ kúrò ní ọ̀run wá sórí ilẹ̀ ayé. Bíbélì sì sọ pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé . . . , nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:7-9, 12) Bíbélì ṣàlàyé pé “bí kìnnìún tí ń ké ramúramù” ni Sátánì ṣe “ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pétérù 5:8) Ẹran tí kò bá lágbára làwọn kìnnìún máa ń rí mú, èyí sì sábà máa ń jẹ́ ọmọ ẹran. Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà káwọn Kristẹni tó jẹ́ òbí máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn. Báwo lo ṣe ń sapá tó láti ṣe èyí?

4. (a) Bí kìnnìún kan bá ń rìn kiri ládùúgbò, kí ló yẹ káwọn òbí ṣe? (b) Kí làwọn ọmọ nílò kí wọ́n tó lè rí ààbò?

4 Tó o bá gbọ́ pé kìnnìún kan ń rìn kiri ládùúgbò rẹ, ó dájú pé bó o ṣe máa dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ ló máa ká ọ lára jù. Apanijẹ ni Sátánì. Bó ṣe máa mú àwọn èèyàn Ọlọ́run dẹ́ṣẹ̀ ló ń wá kí wọ́n má bàa rí ojú rere Ọlọ́run. (Jóòbù 2:1-7; 1 Jòhánù 5:19) Àwọn ọmọdé ló sì dùn-ún mú jù. Káwọn ọmọdé má bàá kó sínú pańpẹ́ Èṣù, wọ́n ní láti mọ Jèhófà kí wọ́n sì ṣègbọràn sí i. Ìmọ̀ Bíbélì ṣe pàtàkì. Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Láfikún sí i, àwọn ọmọdé nílò ọgbọ́n, kí wọ́n lè lóye ohun tí wọ́n ń kọ́, kí wọ́n sì fi í sílò. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “ọgbọ́n máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè,” ẹ̀yin òbí ní láti gbin òtítọ́ sínú ọkàn àwọn ọmọ yín. (Oníwàásù 7:12) Báwo lẹ ṣe lè ṣe èyí?

5. (a) Báwo la ṣe lè gbin ọgbọ́n sọ́kàn ẹnì kan? (b) Báwo ni ìwé Òwe ṣe ṣàpèjúwe bí ọgbọ́n ti ṣeyebíye tó?

5 O gbọ́dọ̀ máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí àwọn ọmọ rẹ létí. Àmọ́, kó o kàn máa kàwé sí wọn létí nìkan kò tó bó o bá fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kí wọ́n sì máa ṣègbọràn sí àṣẹ rẹ̀. Ó gba pé kí àwọn fúnra wọn lóye ohun tí wọ́n gbọ́. Láti ṣàpèjúwe èyí: A lè sọ fún ọmọ kan pé kó máa wo ọ̀tún kó sì máa wo òsì kó tó sọdá lójú títì. Síbẹ̀, àwọn ọmọ kan kì í ṣe ohun tá a wí yìí. Kí nìdí? Ó lè jẹ́ pé àwọn òbí ò ṣàlàyé dáadáa fáwọn ọmọ náà nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí mọ́tò bá gbá èèyàn. Tàbí kẹ̀, kí wọ́n má ṣàlàyé náà lọ́nà tó máa jẹ́ kí ọmọ yìí mọ bó ṣe léwu tó, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ sá fún “ìwà òmùgọ̀” tó lè yọrí sí jàǹbá yìí. Ó máa ń gba àkókò àti sùúrù ká tó lè gbin ọgbọ́n sọ́kàn ẹnì kan. Àmọ́ ọgbọ́n ṣeyebíye gan-an o! Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àwọn ọ̀nà adùn, gbogbo òpópónà rẹ̀ sì jẹ́ àlàáfíà. Ó jẹ́ igi ìyè fún àwọn tí ó dì í mú, àwọn tí ó sì dì í mú ṣinṣin ni a ó pè ní aláyọ̀.”—Òwe 3:13-18; 22:15.

Ẹ̀kọ́ Tó Ń Fúnni Ní Ọgbọ́n

6. (a) Kí nìdí táwọn ọmọ fi sábà máa ń hùwà òmùgọ̀? (b) Ipá wo ni Èṣù ń sà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí?

6 Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọmọdé máa ń ṣe ohun tí kò tọ́. Kì í ṣe nítorí pé a ò kọ́ wọn láti ṣe ohun tó tọ́ o, àmọ́ nítorí pé ẹ̀kọ́ náà ò tíì dé inú ọkàn wọn ni, ìyẹn ni pé kò tíì wọ̀ wọ́n lọ́kàn ṣinṣin. Èṣù ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti jọba lọ́kàn àwọn ọmọdé. Ọgbọ́n tó ń dá ni pé, ó máa ń jẹ́ kí àwọn àṣà ayé yìí tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu wù wọ́n. Ó tún máa ń lo ìrònú ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti jogún, èyí tó máa ń wá sọ́kàn wọn láti ṣe ohun tí kò dára. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21; Sáàmù 51:5) Ó yẹ káwọn òbí mọ̀ pé Èṣù ń sapá gidigidi láti darí ọkàn àwọn ọmọ wọn sí ọ̀nà búburú.

7. Kí nìdí tí sísọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fáwọn ọmọ kò fi tó?

7 Àwọn òbí sábà máa ń sọ ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́ fáwọn ọmọ wọn, wọ́n rò pé nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní àwọn ìlànà rere nìyẹn, èyí tó yẹ kí wọ́n máa tẹ̀ lé. Wọ́n lè sọ fún ọmọ náà pé kò dáa kéèyàn máa purọ́, kò dáa kéèyàn jalè, kò sì dáa kéèyàn ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe ọkọ tàbí aya ẹni. Síbẹ̀, ó yẹ kí ọmọ náà túbọ̀ mọ ìdí pàtàkì tí kò fi yẹ kóun ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, kò yẹ kó jẹ́ nítorí pé àwọn òbí rẹ̀ sọ pé kó má ṣe é nìkan. Jèhófà ló ṣe àwọn òfin náà. Ọmọ náà gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ láti ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run.—Òwe 6:16-19; Hébérù 13:4.

8. Irú ẹ̀kọ́ wo ló lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti di ọlọgbọ́n?

8 Tá a bá sọ fún ọmọ kan nípa bí àwọn ohun tó wà láyé àtọ̀run ṣe pọ̀ gan-an àti báwọn nǹkan náà ṣe ṣòro láti lóye fún ọmọ aráyé, tá a tún sọ̀ nípa onírúurú ohun alààyè tó wà fún un, àti bí àwọn ìgbà ṣe ń yí padà, irú bí ìgbà òjò àti ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, gbogbo ìwọ̀nyí lè jẹ́ kí ọmọ kékeré náà gbà pé lóòótọ́ ni Ẹlẹ́dàá kan wà tó jẹ́ ọlọgbọ́n. (Róòmù 1:20; Hébérù 3:4) Láfikún sí i, a tún gbọ́dọ̀ sọ fún ọmọ náà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ti ṣètò láti fún un ní ìyè ayérayé nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Ọmọ Rẹ̀, àti pé òun náà lè mú inú Ọlọ́run dùn nípa ṣíṣègbọràn sí ohun tí Ọlọ́run sọ. Nípa bẹ́ẹ̀ ó ṣeé ṣe kí ọmọ náà fẹ́ sin Jèhófà láìfi gbogbo bí Èṣù ṣe ń sapá láti dí i lọ́wọ́ pè.—Òwe 22:6; 27:11; Jòhánù 3:16.

9. (a) Kí làwọn òbí ní láti ṣe kí wọ́n tó lè fún àwọn ọmọ wọn ní ẹ̀kọ́ tó ń gba ẹ̀mí là? (b) Kí la sọ pé kí àwọn bàbá ṣe, kí lèyí sì ń béèrè?

9 Ẹ̀kọ́ tó máa dáàbò bo ọmọ kan tó sì máa sún un láti ṣe ohun tó tọ́ yóò gba pé kó wá àyè fún ọmọ náà, kó máa tẹ́tí sí i, kó sì máa múra ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀ dáadáa. Ó gba pé káwọn òbí gba ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀yin, baba, . . . ẹ máa bá a lọ ní títọ́ [àwọn ọmọ yín] dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? “Ìlànà èrò orí” nínú èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ túmọ̀ sí “fífi nǹkan síni lọ́kàn.” Nítorí náà, a rọ àwọn bàbá láti fi èrò Jèhófà sí àwọn ọmọ wọn lọ́kàn. Ààbò gidi nìyẹn á mà jẹ́ fáwọn ọmọdé o! Bí àwọn ọmọ bá ní èrò Ọlọ́run lọ́kàn, tá a gbin ọ̀nà tó gbà ń ronú sí wọn lọ́kàn, ìyẹn ò ní jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí kò dáa.

Ìfẹ́ Ló Lè Mú Ọ Ṣàṣeyọrí

10. Kí ni ohun pàtàkì tó yẹ kó o mọ̀ kó o tó lè tọ́ ọmọ rẹ lọ́nà tó gbéṣẹ́?

10 Tó o bá fẹ́ tọ́ ọmọ rẹ dàgbà lọ́nà tó dára, ìfẹ́ ló gbọ́dọ̀ máa mú ọ ṣe gbogbo ohun tó o bá ń ṣe. Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ déédéé ṣe pàtàkì gan-an ni. Máa bi ọmọ rẹ bí nǹkan ṣe ń lọ sí kó o sì gbìyànjú láti mọ èrò rẹ̀. Nígbà tọ́wọ́ ẹ̀yin méjèèjì bá dilẹ̀, rọra fọgbọ́n mú kí ọmọ rẹ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ jáde. Ohun tó máa sọ nígbà mìíràn lè yà ọ́ lẹ́nu gan-an. Ṣọ́ra kó o máà jẹ́ kó mọ̀ pé ohun tí ó sọ yẹn yà ọ́ lẹ́nu púpọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, fetí sílẹ̀ lọ́nà tó máa fi mọ̀ pé ire òun jẹ ọ́ lọ́kàn.

11. Báwo ni òbí kan ṣe lè fi èrò Ọlọ́run sínú ọkàn ọmọ rẹ̀?

11 Lóòótọ́, o lè ti ka òfin Ọlọ́run tó ka ìwà pálapàla láàárín takọtabo léèwọ̀ sétígbọ̀ọ́ àwọn ọmọ rẹ látinú Bíbélì, kódà o ti lè kà á sétígbọ̀ọ́ wọn nígbà bíi mélòó kan pàápàá. (1 Kọ́ríńtì 6:18; Éfésù 5:5) Èyí ti lè jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ mọ ohun tí inú Jèhófà dùn sí àti ohun tí inú rẹ̀ ò dùn sí. Àmọ́, èèyàn ní láti ṣe ju ìyẹn lọ kó tó lè fi èrò Jèhófà sínú ọkàn ọmọ kan. Àwọn ọmọdé nílò ìrànlọ́wọ́ kí wọ́n tó lè ronú lórí ìjẹ́pàtàkì òfin Jèhófà. A ní láti mú un dá wọn lójú pé àwọn òfin Ọlọ́run tọ̀nà wọ́n sì dára àti pé pípa àwọn òfin náà mọ́ ni ohun tó yẹ kéèyàn máa ṣe, òun ló sì fi hàn pé èèyàn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Kìkì tó o bá ń bá àwọn ọmọ rẹ fèrò wérò látinú Ìwé Mímọ́, tí wọ́n sì fara mọ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan lo tó lè sọ pé o ti fi èrò Ọlọ́run sí wọn lọ́kàn.

12. Báwo ni òbí kan ṣe lè ran ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti mọ ojú tó yẹ kéèyàn máa fi wo ọ̀ràn ìbálòpọ̀ takọtabo?

12 Nígbà tó o bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀, o lè bi ọmọ náà pé, “Ǹjẹ́ o rò pé ṣíṣe ìgbọràn sí òfin Jèhófà tó sọ pé a ò gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó kò ní jẹ́ kéèyàn láyọ̀?” Gba ọmọ rẹ níyànjú láti dáhùn ìbéèrè yẹn kó sì sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Lẹ́yìn tó o bá ti ṣàlàyé ọ̀nà àgbàyanu tí Ọlọ́run ń gbà pèsè ọmọ, o lè béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ lè ṣe àwọn òfin tí kò ní jẹ́ ká gbádùn ayé? Tàbí, ǹjẹ́ o gbà pé tìtorí ká lè láyọ̀ ká má sì kó sínú ewu làwọn òfin rẹ̀ ṣe wà nínú Bíbélì?” (Sáàmù 119:1, 2; Aísáyà 48:17) Gbìyànjú láti mọ èrò ọmọ rẹ lórí ọ̀ràn yìí. Lẹ́yìn ìyẹn, o lè wá mẹ́nu kan àwọn àpẹẹrẹ bíi mélòó kan nípa bí ìwà pálapàla ti ṣe fa ìbànújẹ́ tó sì dá wàhálà sílẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 13:1-33) Tó o bá lè bá ọmọ rẹ fèrò wérò débi pé á lóye ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn nǹkan, á sì fara mọ́ ọn, á jẹ́ pé o ti fi èrò Ọlọ́run sínú ọkàn rẹ̀ dáadáa nìyẹn. Àmọ́ ṣá o, ohun kan tún wà tó o lè ṣe.

13. Kí ni ọmọ kan ní láti lóye kó tó lè ṣègbọràn sí Jèhófà?

13 Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé, o ò ní wulẹ̀ kọ́ ọmọ rẹ ní ohun tó máa jẹ́ àbájáde ṣíṣàìgbọràn sí Jèhófà nìkan, àmọ́ wàá tún jẹ́ kó mọ bí ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbésí ayé wa ṣe ń rí lára Jèhófà. Fi han ọmọ rẹ látinú Bíbélì pé a lè ba Jèhófà nínú jẹ́ tá ò bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Sáàmù 78:41) O lè béèrè pé, “Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o ba Jèhófà nínú jẹ́?” Kó o wá ṣàlàyé pé: “Sátánì tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run sọ pé nítorí ohun tá a máa rí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà la ṣe ń sìn ín kì í ṣe nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Lẹ́yìn ìyẹn, wá ṣàlàyé bí Jóòbù ṣe pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́, tó múnú Ọlọ́run dùn, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. (Jóòbù 1:9-11; 27:5) Jẹ́ kí ọmọ rẹ lóye ìyẹn, kó mọ̀ pé ìwà òun lè ba Jèhófà nínú jẹ́, ìwà òun sì lè múnú rẹ̀ dùn. (Òwe 27:11) Èyí àti ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì mìíràn la lè kọ́ àwọn ọmọdé nípa lílo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. a

Àwọn Àbájáde Tó Múnú Ẹni Dùn

14, 15. (a) Àwọn ẹ̀kọ́ wo ló ti wú àwọn ọmọdé lórí nínú ìwé Olùkọ́? (b) Àwọn àbájáde rere wo lo ti rí látinú lílo ìwé náà? (Tún wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 18 sí 19.)

14 Bàbá àgbà kan ní orílẹ̀-èdè Croatia tí òun àti ọmọ ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún méje jọ ń ka ìwé Olùkọ́ kọ̀wé pé ọmọkùnrin náà sọ fún òun pé: “Mọ́mì mi sọ pé kí n ṣe nǹkan kan, àmọ́ mi ò fẹ́ ṣe é. Mo wá rántí orí tó sọ pé ‘Ìgbọràn Ń Dáàbò Bò Ọ́,’ bí mo ṣe padà nìyẹn tí mo lọ sọ fún mọ́mì mi pé màá máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu.” Tọkọtaya kan láti ìpínlẹ̀ Florida lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ̀rọ̀ nípa orí tí a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Máa Purọ́.” Wọ́n sọ pé: “Àwọn ìbéèrè kan wà nínú orí náà tó mú kí àwọn ọmọ sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde kí wọ́n sì gba àṣìṣe wọn ní àṣìṣe, èyí tí ì bá máà rí bẹ́ẹ̀ tí kì í bá ṣe ohun tí ìwé yẹn sọ.”

15 Àwòrán tó wà nínú ìwé Olùkọ́ lé ní igba àti ọgbọ̀n [230], ó tún ní àwọn àkọlé tàbí àpèjúwe tó ṣàlàyé àwòrán kọ̀ọ̀kan tàbí àwọn àwòrán tó wà pa pọ̀. Ìyá kan tó mọrírì gan-an sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọmọ mi máa ń tẹjú mọ́ àwòrán kan tí kò sì ní fẹ́ ká ṣí ìwé náà síbòmíràn. Kì í ṣe pé àwọn àwòrán náà fani mọ́ra nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, ó kéré tán, wọ́n ń jẹ́ káwọn ọmọ béèrè ìbéèrè. Níbi àwòrán tí ọmọ kan ti ń wo tẹlifíṣọ̀n nínú yàrá tó ṣókùnkùn, ọmọ mi béèrè pé, ‘Mọ́mì, kí ni ọmọkùnrin yìí ń ṣe?’ Bó ṣe béèrè ìbéèrè náà fi hàn pé ó mọ̀ pé ohun tí ọmọ náà ń ṣe ò dáa.” Àkọlé tí wọ́n kọ síbi àwòrán náà kà pé: “Ta ni ó máa ń rí gbogbo ohun tí a bá ṣe?”

Ẹ̀kọ́ Tó Ṣe Pàtàkì Lóde Òní

16. Kí ni ohun pàtàkì tó yẹ ká kọ́ àwọn ọmọ lóde òní, kí sì nìdí?

16 Àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ mọ bó ṣe yẹ káwọn lo àwọn ẹ̀yà ara wọn tó wà níkọ̀kọ̀ àti bí kò ṣe yẹ káwọn lò ó. Àmọ́, kì í sábà rọrùn láti sọ̀rọ̀ nípa èyí. Obìnrin kan tó máa ń kọ ọ̀rọ̀ sínú ìwé ìròyìn kan sọ pé àkókò táwọn èèyàn ka sísọ ọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀yà ìbímọ sí ohun tí kò yẹ ni òun gbọ́njú sí. Nígbà tó ń sọ nípa bó ṣe máa tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, ó kọ̀wé pé: “Mo ní láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ tó ń tì mí lára láti sọ yìí.” Lóòótọ́, nígbà táwọn òbí bá tìtorí ìtìjú ń sá fún ọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀, ìyẹn lè fi ọmọ sínú ewu. Ọmọ tí ò dákan mọ̀ làwọn oníṣekúṣe sì máa ń rí mú. Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí lọ́nà tó gbámúṣé tó sì fi ọ̀wọ̀ hàn. Sísọ ohun tí ìbálòpọ̀ jẹ́ fún àwọn ọmọ kò ní mú kí wọ́n lajú sódì, àìsọ fún wọn gan-an ló lè jẹ́ kí wọ́n yàyàkuyà.

17. Báwo ni ìwé Olùkọ́ ṣe ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa ìbálòpọ̀?

17 Nínú orí kẹwàá ìwé náà tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì búburú tó wá sórí ilẹ̀ ayé tí wọ́n sì bí ọmọ, ìwé náà béèrè ìbéèrè kan pé: “Kí lo mọ̀ tó ń jẹ́ ìbálòpọ̀?” Ìwé náà dáhùn ìbéèrè náà lọ́nà tó rọrùn tó sì ṣeé gbọ́ sétí. Lẹ́yìn náà, orí kejìlélọ́gbọ̀n [32] wá ṣàlàyé bá a ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ lọ́wọ́ àwọn oníṣekúṣe ẹ̀dá. Ọ̀pọ̀ lẹ́tà tá a ti rí gbà sọ pé irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an. Ìyá kan kọ̀wé pé: “Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá, ọmọ mi tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Javan lọ rí dókítà tó ń tọ́jú àwọn ọmọdé. Obìnrin náà béèrè bóyá a ti sọ fún un nípa ọ̀nà tó yẹ kó máa gbà lo àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ tó wà níkọ̀kọ̀. Orí obìnrin náà wú gan-an láti gbọ́ pé a ti ṣe bẹ́ẹ̀ nípa lílo ìwé tuntun yìí.”

18. Báwo ni ìwé Olùkọ́ ṣe jíròrò ọ̀rọ̀ nípa bíbọlá fún àwọn ohun tó dúró fún orílẹ̀-èdè?

18 Orí mìíràn sọ̀rọ̀ nípa ìtàn tí Bíbélì sọ fún wa nípa àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta nì, ìyẹn Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò, tí wọ́n kọ̀ láti forí balẹ̀ fún ère tó ń ṣojú fún ìjọba àwọn ará Bábílónì. (Dáníẹ́lì 3:1-30) Àwọn kan lè máa rò pé kò sóhun tí bíbọlá fún àsíá fi bá fíforí balẹ̀ fún ère mu gẹ́gẹ́ bí ìwé Olùkọ́ ṣe sọ. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí Edward Gaffney tó jẹ́ òǹkọ̀wé sọ nínú ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò kan tí ìwé ìròyìn U.S Catholic gbé jáde. Ó ní nígbà tí ọmọ òun obìnrin dé láti ilé ìwé ní ọjọ́ tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé, ó sọ pé òun ti kọ́ “àdúrà tuntun kan nílé ìwé.” Gaffney wá sọ pé kó ka àdúrà náà fóun. Gaffney sọ pé: “Ọmọdébìnrin náà gbé ọwọ́ lé àyà rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á tayọ̀tayọ̀, ó ní, ‘Mo túúbá fún àsíá . . . ’” Gaffney ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Lójijì ni ohun kan ṣàdédé sọ sí mi lọ́kàn. Mo rí i pé òótọ́ lohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ. Ọ̀rọ̀ nípa ìjọsìn orílẹ̀-èdè wà nínú rẹ̀, àwọn ilé ẹ̀kọ́ wa sì ti ń gbé èyí lárugẹ látìbẹ̀rẹ̀, ìyẹn ni pé wọ́n ń gbé orílẹ̀-èdè ga ju bó ṣe yẹ lọ.”

Ìsapá Tó O Bá Ṣe Tó Bẹ́ẹ̀, Ó Jù Bẹ́ẹ̀ Lọ

19. Èrè wo léèyàn máa rí tó bá kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀?

19 Láìsí àní-àní, ó yẹ kó o sa gbogbo ipá rẹ láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ. Ńṣe lomi bẹ̀rẹ̀ sí dà lójú ìyá kan tó wà ní ìpínlẹ̀ Kansas lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nígbà tó gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ ọmọ rẹ̀. Ohun tí ọmọ náà kọ sínú lẹ́tà ọ̀hún ni pé: “Inú mi dùn gan-an pé ẹ tọ́ mi lọ́nà tó jẹ́ kí ìrònú mi já gaara tí ọkàn mi sì balẹ̀. Ní ti tòótọ́, ó yẹ ká gbóríyìn fún ẹ̀yin àti Dádì.” (Òwe 31:28) Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà ṣì lè ran ọ̀pọ̀ òbí lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ dáàbò bò ogún tó ṣeyebíye yìí.

20. Kí ló yẹ káwọn òbí máa rántí nígbà gbogbo, ipa wo ló sì yẹ kíyẹn ní lórí wọn?

20 Kò sí iye àkókò àti ìtọ́jú tá a bá fún àwọn ọmọ wa, tàbí ìsapá tá a bá ṣe lórí wọn, tó pọ̀ jù. Kíákíá ni àkókò ìgbà èwe wọn máa ń kọjá lọ. Nítorí náà, ẹ lo gbogbo àǹfààní tẹ́ ẹ bá ní láti fi wà pẹ̀lú wọn, kẹ́ ẹ máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Ẹ ò ní kábàámọ̀ láé pé ẹ ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n á sì padà wá fẹ́ràn yín gan-an. Ẹ máa rántí nígbà gbogbo pé ẹ̀bùn Ọlọ́run làwọn ọmọ yín jẹ́, ó fi wọ́n ta yín lọ́rẹ ni o. Ogún iyebíye ni wọ́n! (Sáàmù 127:3-5) Nítorí náà, ọwọ́ pé wọ́n jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni kẹ́ ẹ máa fi mú wọn, pé ẹ máa padà jíhìn fún Ọlọ́run nípa bí ẹ ṣe tọ́ wọn, ó sì dájú pé ẹ óò padà jíhìn fún un.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde. Wo orí 40, “Bí A Ṣe Lè Mú Inú Ọlọ́run Dùn.”

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àkókò tá a wà yìí gan-an ló yẹ káwọn òbí dáàbò bo àwọn ọmọ wọn ju ti tẹ́lẹ̀ rí lọ?

• Irú ẹ̀kọ́ wo ló ń gbin ọgbọ́n síni lọ́kàn?

• Kí làwọn ohun pàtàkì tó yẹ kó o jíròrò pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ lónìí?

• Báwo ni ìwé Olùkọ́ ṣe ran àwọn òbí kan lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]

Ìwé Tó Wà fún Gbogbo Èèyàn

Kí àwọn òbí àtàwọn àgbàlagbà mìíràn lè bá àwọn ọmọdé jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù Kristi fi kọ́ni la ṣe ṣe ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Síbẹ̀, àwọn àgbàlagbà tó ti kà á ti sọ báwọn ṣe mọrírì ohun táwọn rí kọ́ níbẹ̀ gan-an.

Ọkùnrin kan ní ìpínlẹ̀ Texas lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Bí ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà ṣe dùn-ún kà tó sì tètè ń yéni ló mú kó máa wu tọmọdé-tàgbà kà, títí kan èmi tí mo jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin pàápàá. Ẹ ṣé gan-an ni, lẹ́tà yìí wá látọ̀dọ̀ ẹnì kan tó ti ń sin Jèhófà látìgbà èwe rẹ̀.”

Ẹnì kan tó ka ìwé náà nílùú London nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Kò sí bí àwọn àwòrán mèremère inú rẹ̀ kò ṣe ní wọ àwọn òbí àtàwọn ọmọ lọ́kàn ṣinṣin. Àwọn ìbéèrè ibẹ̀ àti bí wọ́n ṣe tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ dára gan-an ni. Ohun tó tún wúni lórí níbẹ̀ ni bí wọ́n ṣe ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ tó gbẹgẹ́ bí irú èyí tó wà ní orí kejìlélọ́gbọ̀n ìwé náà, tí àkòrí rẹ̀ sọ pé ‘Bí Ọlọ́run Ṣe Dáàbò Bo Jésù.’” Ó wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n dìídì ṣe ìwé yìí fún, ó dá mi lójú pé inú àwọn olùkọ́ àtàwọn mìíràn á dùn gan-an tí wọ́n bá lè ní ìwé náà lọ́wọ́. Ara mi ti wà lọ́nà láti bẹ̀rẹ̀ sí i lò ó láìpẹ́ àti lọ́jọ́ iwájú pẹ̀lú.

Obìnrin kan láti ìpínlẹ̀ Massachusetts, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ̀rọ̀ nípa “àwọn àwòrán mèremère tí wọ́n fi ṣàpèjúwe àwọn ẹ̀kọ́ inú rẹ̀.” Ó kọ̀wé pé: “Mo kíyè sí i pé àwọn ọmọdé ni wọ́n ṣe ìwé náà fún, àmọ́ àwọn kókó tí wọ́n jíròrò níbẹ̀ tún lè ran àwa àgbà náà lọ́wọ́ láti ronú nípa àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà.”

Obìnrin kan láti ìpínlẹ̀ Maine lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Áà! Ìwé yìí mà kọyọyọ o! Àwọn ọmọdé lo wà fún o, àmọ́ ó tún wà fún àwa àgbà náà, nítorí pé ọmọ ni gbogbo wa jẹ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ó wọ̀ mí lákínyẹmí ara, ó mú orí mi yá gágá, ó tún ti jẹ́ kí ara mi wálẹ̀ pẹ̀sẹ̀ débi pé ọkàn mi ti wá balẹ̀ báyìí. Mo rí i pé mo ti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà gan-an, ó sì ti wá di Bàbá fún mi. Ó ti bá mi mú gbogbo ìrora ọkàn tí mo ti ń ní láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kúrò, ó sì ti jẹ́ kí n túbọ̀ lóye ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé.” Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Mò ń sọ fún gbogbo èèyàn pé, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ ka ìwé yìí.’”

Obìnrin kan láti ìlú Kyoto, lórílẹ̀-èdè Japan sọ pé nígbà tí òun ń kà á sétí àwọn ọmọ ọmọ òun, wọ́n béèrè àwọn ìbéèrè bíi “‘Kí ni ọmọdékùnrin yìí ń ṣe? Kí nìdí tí wọ́n fi ń bá ọmọbìnrin kékeré yìí wí? Kí ni ìyá yìí ń ṣe? Kìnnìún yìí náà ńkọ́?’ Ohun tá a fẹ́ mọ̀ gan-an ni ìwé náà kọ́ wa. Ìdí nìyẹn tí mo fi fẹ́ràn rẹ̀ ju ìwé èyíkéyìí tí mo lè rí níbi ìkówèésí lọ.”

Bàbá kan tó wà nílùú Calgary, lórílẹ̀-èdè Kánádà, sọ pé bóun ṣe ń gba ìwé náà lòun bẹ̀rẹ̀ sí i kà á fún ọmọ òun obìnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án. Ó sọ pé: “Bí wọ́n ṣe ṣe yà mí lẹ́nu gan-an. Àwọn ọmọ mi fetí sílẹ̀ dáadáa, wọ́n sì ń dáhùn àwọn ìbéèrè ibẹ̀ látọkàn wọn wá. Inú wọn dùn pé àwọn náà ń lóhùn sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ìyẹn sì fún wọn láǹfààní láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde. Ìwé náà ti ta wọ́n jí, ọmọ mi obìnrin sì sọ pé òun fẹ́ máa kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìwé tuntun náà lálaalẹ́.”

Lẹ́yìn tí wọ́n parí ìkẹ́kọ̀ọ́ tán lọ́jọ́ kan, bàbá náà sọ pé: “Ọ̀pọ̀ wákàtí lèmi àti ọmọ mi ọkùnrin fi sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé. Ó béèrè àwọn ìbéèrè tó pọ̀ gan-an nípa ohun tá a kà nínú ìwé náà. Ńṣe lomi ń bọ́ lójú mi nígbà tó kí mi pé ó dàárọ̀ tó sì wá béèrè pé: ‘Dádì, ṣé a tún lè jọ kàwé yìí ká sì sọ̀rọ̀ báyìí nígbà mìíràn? Àwọn ohun tí mo fẹ́ béèrè pọ̀ gan-an, mo fẹ́ mọ gbogbo nǹkan nípa Jèhófà.’”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ẹ̀yin òbí, ẹ̀kọ́ wo lẹ lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Mánóà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ̀kọ́ wo lẹ lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ àwọn Hébérù mẹ́ta nì?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn àwòrán tó wà nínú ìwé “Olùkọ́” àtàwọn àkọlé tá a fi ṣàlàyé wọn dùn ún kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ gan-an

Irọ́ wo ni Ananíà ń pa fún Pétérù?

Ta ni ó máa ń rí gbogbo ohun tí a bá ṣe?