Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ ó yẹ kí Kristẹni fún òṣìṣẹ́ ìjọba kan lówó tàbí lẹ́bùn kẹ́ni náà lè ṣe iṣẹ́ tó yẹ kó ṣe, àbí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ la máa ka irú owó tàbí ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ sí?

Ní gbogbo ibi táwọn Kristẹni ń gbé, wọ́n máa ń fi ọgbọ́n bójú tó àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbègbè wọn, nítorí wọ́n mọ̀ pé ohun táwọn èèyàn fara mọ́ tó sì bófin mu lórílẹ̀-èdè kan lè máà rí bẹ́ẹ̀ rárá lórílẹ̀-èdè mìíràn. (Òwe 2:6-9) Àwọn Kristẹni ní láti máa fi sọ́kàn pé, ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ jẹ́ “àlejò nínú àgọ́” Jèhófà gbọ́dọ̀ yàgò fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.—Sáàmù 15:1, 5; Òwe 17:23.

Kí ló ń jẹ́ àbẹ̀tẹ́lẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tó ń jẹ́ The World Book Encyclopedia ṣe túmọ̀ rẹ̀, “àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ni kéèyàn fún ẹnì kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ọba ní . . . ohun kan tó níye lórí, tí ẹni náà yóò sì wá ṣe ohun tí kò yẹ kó ṣe tàbí ohun tí kò bófin mu lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ kó bàa lè ṣoore fún ẹni tó fún un lẹ́bùn náà?” Nítorí náà, ibi tó wù kéèyàn máa gbé, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ni kéèyàn fún adájọ́ tàbí ọlọ́pàá ní owó tàbí ẹ̀bùn kí wọ́n lè ṣe ohun kan tí kò bófin mu tàbí kéèyàn fún ẹnì kan tó jẹ́ olùbẹ̀wò lẹ́bùn kó lè mójú kúrò nínú àìdáa kan téèyàn ṣe. Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tún ni kéèyàn fún ẹnì kan lẹ́bùn kó lè ṣojúure síni, bíi kó forúkọ ẹni ṣáájú nínú ìwé tórúkọ ọ̀pọ̀ èèyàn wà tàbí kó dáni lóhùn ṣáájú àwọn mìíràn tá a jọ tò sórí ìlà. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ tún fi hàn pé èèyàn kò nífẹ̀ẹ́.—Mátíù 7:12; 22:39.

Àmọ́ ṣé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ni kéèyàn fún ẹnì kan lẹ́bùn, bí àpẹẹrẹ, kéèyàn fún òṣìṣẹ́ ọba kan lẹ́bùn kí ẹni náà lè báni ṣe ohun tó jẹ́ ẹ̀tọ́ ẹni tàbí kó má bàa jẹ́ kí ìyà tí kò tọ́ síni jẹni? Bí àpẹẹrẹ, àwọn orílẹ̀ èdè kan wà tó jẹ́ pé táwọn aláṣẹ ò bá kọ́kọ́ gba ẹ̀bùn, wọ́n lè máà fẹ́ gba àwọn ọmọ síléèwé, wọ́n lè máà fẹ́ gbani sílé ìwòsàn tàbí kí wọ́n báni fi òǹtẹ̀ lu ìwé àṣẹ téèyàn fi ń wọ orílẹ̀-èdè. Tàbí kẹ̀, kí wọ́n máa foní dóni fọ̀la dọ́la nígbà téèyàn bá ní kí wọ́n bá òun sọ ìwé àṣẹ kan di ọ̀tun.

Fífúnni ní irú ẹ̀bùn yìí àti ojú táwọn èèyàn fi ń wo àṣà yìí yàtọ̀ lórílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Níbi táwọn èèyàn ò bá ti ka àṣà fífúnni ní irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ sí ohun tó burú tàbí tí wọ́n tiẹ̀ retí pé kéèyàn fúnni lẹ́bùn náà pàápàá, àwọn Kristẹni kan lè wò ó pé níwọ̀n ìgbà tí òfin kò ti ta kò ó, àwọn ò ṣe ohun tí kò bá ìlànà Bíbélì mu báwọn bá fún òṣìṣẹ́ ọba kan lẹ́bùn kó lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn èèyàn tiẹ̀ lè máa wo irú owó bẹ́ẹ̀ bí ẹ̀bùn láti mú kí owó oṣù tí kò tó nǹkan tí òṣìṣẹ́ kan ń gbà gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Àmọ́ ó yẹ kéèyàn máa fi sọ́kàn pé ìyàtọ̀ wà nínú kéèyàn fún ẹnì kan lẹ́bùn láti báni ṣe ohun tó bófin mu àti kéèyàn fún ẹnì kan ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kó lè báni ṣe ohun tí kò bófin mu.

Síbẹ̀ náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan kì í fún olùbẹ̀wò, òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn lẹ́bùn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ kírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá wọn ṣe iṣẹ́ tó bófin mu pàápàá. Kódà wọn kì í fúnni lẹ́bùn yìí láwọn ibi tí àṣà yìí tiẹ̀ ti wọ́pọ̀. Nítorí pé àwọn èèyàn àgbègbè náà sì ti mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí ibẹ̀ ò jẹ́ ṣe ohun tó ta ko ẹ̀rí ọkàn wọn yìí, tí wọ́n sì tún mọ̀ wọ́n sí olóòótọ́ èèyàn, wọ́n máa ń rí ẹ̀tọ́ wọn gbà nígbà mìíràn níbi tó jẹ́ pé bí àwọn èèyàn mìíràn ò bá fowó sílẹ̀, wọn ò lè rí irú ẹ̀tọ́ bẹ́ẹ̀ gbà.—Òwe 10:9; Mátíù 5:16.

Lákòótán, ẹnì kọ̀ọ̀kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ló máa fúnra rẹ̀ pinnu bóyá òun yóò fún àwọn kan lẹ́bùn kí wọ́n lè bá òun ṣe iṣẹ́ tó bófin mu tàbí kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ìyà tí kò tọ́ sí òun jẹ òun. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé, ohun tí kò ní ba ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ jẹ́, tí kò ní kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà, tí kò sì ní mú àwọn mìíràn kọsẹ̀ ló yẹ kó ṣe.—Mátíù 6:9; 1 Kọ́ríńtì 10:31-33; 2 Kọ́ríńtì 6:3; 1 Tímótì 1:5.