Ṣé Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Àti Ẹ̀kọ́ Bíbélì Ta Ko Ara Wọn Lóòótọ́?
Ṣé Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Àti Ẹ̀kọ́ Bíbélì Ta Ko Ara Wọn Lóòótọ́?
OHUN tó fa ìjà láàárín Galileo àti Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti wà nílẹ̀ tipẹ́tipẹ́ kí Copernicus àti Galileo tó dáyé. Ọ̀dọ̀ àwọn ará Gíríìsì ìgbàanì ni èrò pé oòrùn ń yí po ayé ti wá. Ọ̀mọ̀ràn tó ń jẹ́ Aristotle (tó gbé ayé ní ọdún 384 sí ọdún 322 ṣáájú Sànmánì Tiwa) ló jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ nípa rẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn ni Ptolemy (tó gbé ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Tiwa) tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà àti ìràwọ̀ tún tan èrò náà kálẹ̀. a
Èrò Pythagoras ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì nì, (tó gbé ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà ṣáájú Sànmánì Tiwa) tó jẹ́ onímọ̀ ìṣirò àti ọ̀mọ̀ràn ló mú kí Aristotle ní èrò tó ní nípa àwọn nǹkan tó wà nínú sánmà. Aristotle tẹ́wọ́ gba èrò Pythagoras pé ohun tó bá rí roboto kì í ní igun rárá. Èyí ló mú kí Aristotle gbà gbọ́ pé ńṣe ni àwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó wà nínú sánmà rí roboto roboto tí wọ́n sì ń yí po ara wọn lọ́nà tí àwọn awẹ́ àlùbọ́sà gbà yí po ara wọn. Ó gbà pé ńṣe ni pílánẹ́ẹ̀tì kọ̀ọ̀kan tó rí roboto yìí ń dán gbinrin, ayé sì wá wà ní àárín wọn. Ó tún ní àwọn ìràwọ̀ máa ń yí po ara wọn, àti pé bí wọ́n ṣe ń yí po ara wọn yẹn, agbára Ọlọ́run wà nínú èyí tó kángun síta pátápátá lára wọn, òun ló sì ń mú kí wọ́n máa yí po. Aristotle tún gbà gbọ́ pé oòrùn àtàwọn nǹkan mìíràn tó wà nínú sánmà kì í ní àbààwọ́n tàbí kí wọ́n bà jẹ́.
Èrò orí lásán ni gbogbo ohun tí Aristotle gbà gbọ́ yìí, wọn ò bá
ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu. Lérò tirẹ̀, kò gbà pé ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé ayé ń yí. Ó tún sọ pé a ò lè so ayé rọ̀ sórí òfo. Ó sọ pé tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni ayé ń yí tó bá yá kò ní lè yí mọ́ lórí ohun tó gbé e dúró, àyàfi tí nǹkan kan bá wà tó ń tì í nígbà gbogbo. Nítorí pé èrò Aristotle dà bí èyí tó bọ́gbọ́n mu lójú àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ayé ìgbà yẹn níwọ̀nba ibi tí òye wọn mọ, àwọn èèyàn gba èrò náà gbọ́ fún nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún. Kódà ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún pàápàá, ọ̀mọ̀ràn ọmọ ilẹ̀ Faransé nì, Jean Bodin ṣì sọ ohun kan tó fi hàn pé ó fara mọ́ èrò táwọn èèyàn gbà gbọ́ yẹn, ó ní: “Kò sẹ́nì kan tí orí rẹ̀ pé tàbí ẹnì kan tó nímọ̀ físíìsì díẹ̀ tó máa ronú pé bí ayé ṣe tóbi tó yìí, tó sì wúwo . . . , ó lè máa yí lọ . . . ní ipa ọ̀nà rẹ̀ kó sì tún máa yí po oòrùn; nítorí pé táyé bá fi lè sún díẹ̀ kẹ́rẹ́, ńṣe ni àwọn ìlú ńlá àtàwọn odi, àwọn ìlú kéékèèké àtàwọn òkè ńlá máa wó dà nù.”Ṣọ́ọ̀ṣì Tẹ́wọ́ Gba Èrò Aristotle
Ohun mìíràn tó fa àríyànjiyàn láàárín Galileo àti ṣọ́ọ̀ṣì ni ohun kan tó ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹtàlá kí Galileo tiẹ̀ tó dáyé. Ẹni tó dá ọ̀ràn náà sílẹ̀ ni Thomas Aquinas (tó gbé ayé ní ọdún 1225 sí 1274) tó sì jẹ́ ẹnì kan tẹ́nu rẹ̀ múlẹ̀ nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì. Aquinas ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Aristotle, Ọ̀mọ̀ràn tí kò lẹ́gbẹ́ ló sì máa ń pè é. Ọdún márùn-ún ni Aquinas fi jà fitafita láti pa èrò Aristotle pọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì. Gẹ́gẹ́ bí Wade Rowland ti sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Galileo’s Mistake (Àṣìṣe tí Galileo Ṣe), ó ní nígbà tó máa fi di àkókò Galileo, “ẹ̀kọ́ ìsìn tí Aquinas ti fi ń kọ́ àwọn èèyàn, èyí tó jẹ́ àdàpọ̀ ẹ̀kọ́ Aristotle àti ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì, ti wá di ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Róòmù.” Má gbàgbé pé láyé ìgbà yẹn, kò sí àwùjọ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ń dá nǹkan ṣe. Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ló ń bójú tó ọ̀ràn ẹ̀kọ́. Tó bá sì kan ọ̀ràn ìsìn àti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì yìí náà ló ń bójú tó o.
Àwọn nǹkan wọ̀nyí ló pilẹ̀ àríyànjiyàn tó wáyé láàárín ṣọ́ọ̀ṣì àti Galileo. Àní kó tó di pé Galileo ki ara bọ ọ̀rọ̀ nípa sánmà ló ti kọ ìwé kan lórí ọ̀rọ̀ náà. Ìwé náà ta ko ọ̀pọ̀ èrò tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ èyí tí Aristotle tí ọ̀pọ̀ èèyàn gba tiẹ̀ gbé kalẹ̀. Àmọ́ ṣá o, nítorí pé Galileo ò yéé sọ pé ayé ló ń yí po oòrùn tó sì tún ń tẹnu mọ́ ọn pé èrò náà bá Ìwé Mímọ́ mu ni wọ́n ṣe mú un ní ọdún 1633 tí wọ́n sì gbé e lọ sí ilé ẹjọ́ ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì níbi tí wọ́n ti ń fìyà jẹ ẹni tó bá sọ ohun tó ta ko ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì náà.
Nígbà tí Galileo ń sọ tẹnu rẹ̀, ó sọ pé òun gba Bíbélì gbọ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí ni. Ó tún tẹnu mọ́ ọn pé a ò kọ Ìwé Mímọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ayé àti pé nígbà tí Bíbélì sọ ohun kan tó jọ pé oòrùn ló ń yí po ayé, a kò gbọ́dọ̀ gbà pé ohun tó túmọ̀ sí gẹ́lẹ́ náà nìyẹn. Àmọ́ asán ni àríyànjiyàn rẹ̀ yìí já sí o. Nítorí pé Galileo kò fara mọ́ bí wọ́n ṣe ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn, èyí tí wọ́n gbé karí èrò àwọn Gíríìkì, wọ́n dá a lẹ́jọ́ pé ó jẹ̀bi! Ọdún 1992 ni Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà pé àwọn ṣàṣìṣe nínú ẹjọ́ táwọn dá Galileo.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́
Ẹ̀kọ́ wo lá rí kọ́ nínú àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Kókó kan tó ṣe pàtàkì ni pé, Galileo ò bá Bíbélì jà. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ẹ̀kọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fi ń kọ́ni ló ń gbéjà kò. Ẹnì kan tó máa ń kọ̀wé nípa ìsìn sọ pé: “Ó jọ pé ohun tá a rí kọ́ nínú ọ̀ràn Galileo ni pé Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì rọ̀ mọ́ òtítọ́ inú Bíbélì; ṣùgbọ́n kò rọ̀ mọ́ ọn tó.” Nítorí pé ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì jẹ́ kí èrò àwọn Gíríìkì darí ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ni, ṣọ́ọ̀ṣì náà fàyè gba ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ dípò kó tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì.
Gbogbo èyí rán wa létí ìkìlọ̀ tí Bíbélì fún wa pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.”—Kólósè 2:8.
Kódà lónìí pàápàá, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ni ò jáwọ́ nínú àwọn èrò àtàwọn ẹ̀kọ́ tó dá lórí ọgbọ́n orí èèyàn tó ta ko Bíbélì. Àpẹẹrẹ kan ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tí Darwin gbé kalẹ̀, èyí tí wọ́n wá b
fi rọ́pò àkọsílẹ̀ tá a rí nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì tó sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn nǹkan. A lè sọ pé ohun táwọn olórí ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì ṣe yìí ti mú kí wọ́n sọ Darwin di Aristotle òde òní, wọ́n sì sọ ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n di ara ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì.Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Tó Jẹ́ Òótọ́ Bá Ẹ̀kọ́ Bíbélì Mu
Àwọn ohun tá a ti jíròrò wọ̀nyí kò sọ pé kéèyàn máà nífẹ̀ẹ́ sí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì o. Ká sòótọ́, Bíbélì fúnra rẹ̀ rọ̀ wá pé ká kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, ká sì lóye àwọn àgbàyanu ànímọ́ Ọlọ́run látinú àwọn ohun tá à ń rí. (Aísáyà 40:26; Róòmù 1:20) Àmọ́ ṣá o, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kọ́ ni Bíbélì ń kọ́ni o. Dípò ìyẹn, àwọn ìlànà Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé, èyí tí àwọn ohun ìṣẹ̀dá ò lè kọ́ni ló ń jẹ́ ká mọ̀. (Sáàmù 19:7-11; 2 Tímótì 3:16) Síbẹ̀síbẹ̀, tí Bíbélì bá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá, ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń tọ̀nà nígbà gbogbo. Galileo fúnra rẹ̀ sọ pé: “Àtọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Ìwé Mímọ́ àtàwọn ìṣẹ̀dá ti wá . . . Àwọn méjèèjì yìí kò lè ta ko ara wọn láé.” Gbé àwọn àpẹẹrẹ tá a fẹ́ mẹ́nu kàn wọ̀nyí yẹ̀ wò.
Ohun kan wà tó ṣe pàtàkì ju bí àwọn ìràwọ̀ àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì ṣe ń yí po, ohun náà ni àwọn ìlànà tó ń darí gbogbo ohun tó wà láyé àtọ̀run, irú bí ìlànà tó ń mú kí àwọn nǹkan tó bá lọ sókè padà wá sílẹ̀. Pythagoras sọ pé téèyàn bá ṣe gbé ìṣirò lé e, èèyàn lè mọ ìrìn àwọn nǹkan tó wà nínú sánmà. Yàtọ̀ sí àkọsílẹ̀ tó wà nínú Bíbélì, òun lẹni àkọ́kọ́ tó mẹ́nu kàn án pé àwọn ìlànà kan ló ń darí àwọn nǹkan tó wà láyé àtọ̀run. Ẹgbẹ̀rún ọdún méjì lẹ́yìn náà ni Galileo, Kepler, àti Newton wá fi hàn pé lóòótọ́, àwọn ìlànà tó bọ́gbọ́n mu ló ń dárí àwọn ohun tó wà láyé àtọ̀run.
Ìgbà àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìlànà tó ń darí àwọn nǹkan tó wà láyé àtọ̀run ni àkọsílẹ̀ tá a rí nínú ìwé Jóòbù. Ní nǹkan bí ọdún 1600 ṣáájú Sànmánì Tiwa, Ọlọ́run bi Jóòbù léèrè pé: “Ìwọ ha ti wá mọ àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ [tàbí àwọn òfin] ọ̀run?” (Jóòbù 38:33) Ìwé Jeremáyà tí wọ́n kọ ni ọgọ́rùn-ún ọdún keje ṣáájú Sànmánì Tiwa pe Jèhófà ní Ẹlẹ́dàá “àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀” àti “àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jeremáyà 31:35; 33:25) Nítorí ohun tí àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí wí, alálàyé nípa Bíbélì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ George Rawlinson sọ pé: “Àwọn tó kọ Bíbélì àti ohun tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní wí fi hàn pé àwọn ìlànà wà lóríṣiríṣi tó ń darí gbogbo ohun tá a lè fojú rí láyé àtọ̀run.”
Wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Jóòbù yẹn ní ẹgbẹ̀rún ọdún kan kí Pythagoras tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà tó ń darí àwọn nǹkan tó wà láyé àtọ̀run. Rántí pé kì í ṣe àwọn nǹkan téèyàn lè fojú rí nìkan ni Bíbélì fẹ́ ká mọ̀ nípa wọn, àmọ́ olórí ohun tó fẹ́ ká mọ̀ ni pé Jèhófà ni Ẹni tó dá gbogbo nǹkan, òun ló ṣe àwọn ìlànà tó ń darí gbogbo wọn.—Jóòbù 38:4, 12; 42:1, 2.
Àpẹẹrẹ mìíràn tá a lè gbé yẹ̀ wò ni bí omi tó wà láyé ṣe máa ń yí po, èyí tí wọ́n ń pè ní àyípoyípo omi. Ọ̀nà tó rọrùn tá a lè gbà sọ ọ́ ni pé, oòrùn á fa omi kúrò nínú òkun, á di ìkùukùu, á sì wá rọ òjò sórí ilẹ̀, níkẹyìn á tún wá padà sínú òkun. Ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin ṣáájú Sànmánì Tiwa ni ìgbà àkọ́kọ́ táwọn èèyàn mẹ́nu kan àyípoyípo omi yàtọ̀ sí àkọsílẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. Bó ti wù kó rí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn ni Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkànlá ṣáájú Sànmánì Tiwa, Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì kọ̀wé pé: “Odò gbogbo ni nṣan sinu okun; ṣugbọn okun kò kún, nibiti awọn odò ti nṣàn wá, nibẹ ni nwọn si tun pada lọ.”—Oníwàásù 1:7, Bibeli Mimọ.
Bákan náà, ní nǹkan bí ọdún 800 ṣáájú Sànmánì Tiwa, wòlíì Ámósì tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn àti àgbẹ̀, kọ̀wé pé Jèhófà ni “Ẹni tí ń pe omi òkun, kí ó lè dà wọ́n sórí ilẹ̀ ayé.” (Ámósì 5:8) Ọ̀nà tó yàtọ̀ síra ni Sólómọ́nì àti Ámósì gbà ṣàlàyé bí oòrùn ṣe ń fa omi òkun tó sì ń rọ̀ sílẹ̀ bí òjò, àmọ́ àlàyé wọn tọ̀nà gan-an, wọn ò lo èdè tó díjú, ọ̀rọ̀ wọn sì yéni kedere.
Bíbélì tún sọ pé Ọlọ́run “so ilẹ̀ ayé rọ̀ sórí òfo.” (Jóòbù 26:7) Nítorí pé ìmọ̀ àwọn èèyàn ṣì kéré gan-an nígbà tí Bíbélì sọ̀rọ̀ yìí ní ọdún 1600 ṣáájú Sànmánì Tiwa, ó lójú ẹni tó máa lè fi ìdánilójú sọ lákòókò yẹn pé nǹkan kan lè wà lójú òfuurufú láìjẹ́ pé ohun kan gbé e dúró. Gẹ́gẹ́ bá a ti sọ níṣàájú, Aristotle pàápàá kò gbà pé nǹkan lè dúró sójú sánmà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ̀fà [1, 200] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n ti sọ̀rọ̀ yìí ló dáyé!
Ǹjẹ́ kò yà ọ́ lẹ́nu gan-an pé Bíbélì sọ ọ̀rọ̀ tó tọ̀nà yìí lákòókò táwọn èèyàn gba èrò òdì gbọ́, tí wọ́n sì rò pé ohun tí àwọn gbà gbọ́ náà bọ́gbọ́n mu? Lójú àwọn olóye èèyàn, àfikún ẹ̀rí lèyí jẹ́ pé Ọlọ́run mí sí Bíbélì. Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu ka má ṣe jẹ́ kí ẹ̀kọ́ kan tàbí èrò kan tó ta ko Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run darí wa. Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ti jẹ́ ká rí i lọ́pọ̀ ìgbà pé, èrò àwọn èèyàn, àní ti àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n pàápàá kàn máa ń wà fúngbà díẹ̀ ni, àmọ́ “àsọjáde Jèhófà wà títí láé.”—1 Pétérù 1: 25.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta ṣáájú Sànmánì Tiwa, ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan tó ń jẹ́ Aristarchus tó ń gbé ìlú Samos sọ pé ayé ló ń yí po oòrùn, àmọ́ àwọn èèyàn ò gba ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n ní èrò ti Aristotle ló tọ̀nà.
b Láti lè túbọ̀ lóye kókó yìí dáadáa, wo àkòrí 15, nínú ìwé Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? èyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ohun Táwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Tí Kì í Ṣe Kátólíìkì Sọ
Àwọn tó jẹ́ aṣáájú nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó yàtọ̀ sí Kátólíìkì kò fara mọ́ èrò pé ayé ló ń yí po oòrùn. Díẹ̀ lára àwọn aṣáájú náà ni Martin Luther (ó gbé ayé lọ́dún1483 sí 1546), Philipp Melanchthon (ó gbé ayé lọ́dún 1497 sí 1560), àti John Calvin (ó gbé ayé lọ́dún 1509 sí 1564). Ohun tí Luther sọ nípa Copernicus ni pé: “Òmùgọ̀ yìí fẹ́ yí gbogbo ohun tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ nípa sánmà padà.”
Àwọn alátùn-únṣe ìsìn gbé àríyànjiyàn wọn ka ọ̀nà olówuuru tí wọ́n gbà ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan bí irú èyí tó wà nínú ìwé Jóṣúà orí kẹwàá tó sọ pé oòrùn àti òṣùpá “dúró sójú kan.” c Kí ló fà á táwọn Alátùn-únṣe náà fi ní irú èrò yìí? Ìwé Galileo’s Mistake (Àṣìṣe tí Galileo Ṣe) ṣàlàyé pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì yòókù tó jẹ́ ti Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe kúrò nínú Ìjọ Kátólíìkì, wọ́n ò “já ara wọn gbà kúrò lọ́wọ́ àwọn àṣẹ pàtàkì” tí Aristotle àti Thomas Aquinas gbé kalẹ̀, nítorí pé èrò àwọn méjèèjì yìí “dára lójú Ìjọ Kátólíìkì àtàwọn Ìsìn yòókù.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
c Tá a bá ni ká fi ojú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì wò ó, gbólóhùn náà tá a máa ń sọ pé “oòrùn yọ” tàbí “oòrùn wọ̀” kò tọ̀nà. Àmọ́ nínú ọ̀rọ̀ tá à ń sọ lójoojúmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tọ̀nà, àwọn èèyàn sì tẹ́wọ́ gbà wọ́n, nítorí pé ilẹ̀ ayé la wà tá a ti ń wo ohun tó fara hàn lójú sánmà. Bí ọ̀ràn ti rí lójú Jóṣúà náà nìyẹn, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà ló ń sọ; ó kàn ń ṣàpèjúwe àwọn nǹkan tó rí ni.
[Àwọn àwòrán]
Luther
Calvin
[Credit Line]
Látinú ìwé Servetus and Calvin, 1877
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Aristotle
[Credit Line]
Látinú ìwé A General History for Colleges and High Schools, 1900
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Thomas Aquinas
[Credit Line]
Látinú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopedia of Religious Knowledge, 1855
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Isaac Newton
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ó ti lé lẹ́gbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn tí Bíbélì ti ṣàpèjúwe àyípoyípo omi