Ọmọ Ọ̀rukàn Tí Kò Lẹ́bí Tí Kò Lárá, Rí Baba Onífẹ̀ẹ́
Ìtàn Ìgbési Ayé
Ọmọ Ọ̀rukàn Tí Kò Lẹ́bí Tí Kò Lárá, Rí Baba Onífẹ̀ẹ́
GẸ́GẸ́ BÍ DIMITRIS SIDIROPOULOS ṢE SỌ Ọ́
Ọ̀gágun náà na ìbọn àgbéléjìká ọwọ́ rẹ̀ sí mi ó sì kígbe mọ́ mi pé: “Ó yá, gbé ìbọn yẹn kó o sì yìn ín.” Mo fohùn pẹ̀lẹ́ dáhùn pé mi ò jẹ́ yìnbọn. Nígbà táwọn sójà tó wà níbẹ̀ rí i bí ọta ìbọn ṣe ń fò jáde látinú ìbọn ọ̀gágun náà tó sì ń gba èjìká mi kọjá, ẹ̀rù bà wọ́n. Ó jọ pé ikú ò lè yẹ̀ lórí mi. Àmọ́ inú mi dùn pé mi ò kú. Síbẹ̀, èyí kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí ẹ̀mí mi máa wà nínú ewu.
ÌDÍLÉ mi wá látinú ẹ̀yà kan tó kéré gan-an tí wọ́n ń gbé nítòsí ìlú Kayseri lágbègbè Kapadókíà lórílẹ̀-èdè Turkey. Ó jọ pé àwọn èèyàn kan di Kristẹni lágbègbè yìí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. (Ìṣe 2:9) Àmọ́ nígbà tó fi máa di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, nǹkan ti yí padà gan-an.
Lẹ́yìn Tá A Sá Kúrò Nílùú, Àwọn Òbí Mi Tún Kú
Kò ju oṣù díẹ̀ lẹ́yìn táwọn òbí mi bí mi lọ́dún 1922 tí ìjà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà kan bẹ́ sílẹ̀. Ni wọ́n bá sá lọ sílẹ̀ Gíríìsìi. Jìnnìjìnnì tó bá wọn kò jẹ́ kí wọ́n lè mú nǹkan kan dání yàtọ̀ sí èmi ọmọ wọn tí mi ò tíì ju ọmọ oṣù díẹ̀ lo. Lẹ́yìn tí baba-ńlá ìyà ti jẹ wọ́n, wọ́n dé abúlé kan tó ń jẹ́ Kiria nítòsí ìlú Drama, lápá àríwá ilẹ̀ Gíríìsì, láìní gá láìní go.
Ọmọ ọdún mẹ́rin péré ni mí nígbà tí bàbá mi kú, kò sì tíì pẹ́ tí wọ́n bí àbúrò mi ọkùnrin nígbà yẹn. Nígbà tí bàbá mi kú yìí, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n péré ni, àmọ́ ìyà tó bá a fínra lákòókò ìpọ́njú yẹn ti jẹ́ kó dà bí àgbàlagbà. Màmá mi wá bẹ̀rẹ̀ sí í ráágó, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà lòun náà bá tún kú. Palaba ìyà wá bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ èmi àti àbúrò mi. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kó wa láti ilé ìtọ́jú ọmọ aláìlóbìí kan lọ sí òmíràn, nígbà tí màá sì fi pé ọmọ ọdún méjìlá, ilé ọmọ aláìlóbìí kan
nílùú Tẹsalóníkà ni mo ti bá ara mi níbi tí mo ti ń kọ́ iṣẹ́ mẹ́káníìkì.Bí mo ti ń dàgbà nílé ìtọ́jú àwọn ọmọ aláìlóbìí, níbi tí kò ti sí ìfẹ́ kankan, mo máa ń rò ó nínú ọkàn mi pé ‘kí ló dé tí ìyà fi ń jẹ àwọn kan ní àjẹyíràá tí ìwà ìrẹ́jẹ sì tún pọ̀ gan-an? Màá tún máa bi ara mi pé, kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba àwọn nǹkan ìbànújẹ́ kó máa ṣẹlẹ̀? Nígbà tá a bá ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìsìn, wọ́n máa ń kọ́ wa pé alágbára gbogbo ni Ọlọ́run, àmọ́ wọn kì í ṣe àlàyé gidi kan nípa ìdí tí ìwàkiwà fi wà tó sì tún gbalẹ̀ kan. Gbólóhùn kan wà tí wọ́n sábà máa ń sọ nígbà yẹn, òun ni pé, Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì ni ìsìn tó dára jù lọ. Nígbà tí mo béèrè pé, “Bó bá jẹ́ ìsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ló dára jù, kí nìdí tí gbogbo èèyàn ò fi máa ṣe é?” Wọn ò fún mi ní ìdáhùn kankan tó ní láárí.
Síbẹ̀, olùkọ́ wa nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì gan-an ó sì máa ń sọ fún wa pé ìwé mímọ́ ni. Ẹni tó ń darí ilé ìtọ́jú ọmọ aláìlóbìí wa náà máa ń sọ ohun kan náà, àmọ́ tá a bá ń ṣe ìsìn kì í bá wa lọ́wọ́ sí i, a ò sì mọ ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀. Nígbà tí mo wádìí, wọ́n sọ fún mi pé ó ti fìgbà kan kẹ́kọ̀ọ́ rí lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣùgbọ́n èmi ò mọ ìsìn tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni mí nígbà tí mo parí ẹ̀kọ́ mi nílé ìtọ́jú àwọn ọmọ aláìlóbìí náà nílùú Tẹsalóníkà. Ogun Àgbáyé Kejì ti bẹ̀rẹ̀ nígbà yẹn, ilẹ̀ Gíríìsì sì ti wà lábẹ́ àkóso ìjọba Násì. Ebi ń pa àwọn èèyàn kú sójú títì. Kí n má bàa kú, mo sá lọ sí àrọko kan mo sì lọ ń ṣe iṣẹ́ lébìrà níbi kàn tí wọ́n ti ń fún mi lówó táṣẹ́rẹ́.
Bíbélì Dáhùn Àwọn Ìbéèrè Mi
Nígbà tí mo padà sílùú Tẹsalóníkà lóṣù April ọdún 1945, obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Paschalia wá sọ́dọ̀ mi. Ẹ̀gbọ́n ọmọ kan témi pẹ̀lú rẹ̀ jọ ṣọ̀rẹ́ ní kékeré tá a sì jọ gbé láwọn ilé ìtọ́jú ọmọ aláìlóbìí kan náà lobìnrin yìí. Ó sọ fún mi pé òun ò rí àbúrò òun ó sì bi mí bóyá mo mọ ibi tó wà. Níbi tá a ti jọ ń sọ̀rọ̀ lọ ló ti sọ fún mi pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun ó sì sọ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwa ẹ̀dá èèyàn gan-an.
Pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni mo fi sọ àwọn ìdí kan tí mi ò fi lè gbà bẹ́ẹ̀. Kí ló dé tíyà fi ń jẹ mí bọ̀ láti kékeré? Kí ló dé tí mo fi dọmọ aláìlóbìí? Níbo ni Ọlọ́run wà nígbà tá a nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ gan-an? Ó wá dá mi lóhùn pé, “Ṣé ó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run ló ni ẹ̀bi gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí?” Ó fi ibì kan hàn mí nínú Bíbélì rẹ̀ pé Ọlọ́run kọ́ ló ń jẹ́ káwọn èèyàn máa jìyà. Èyí wá jẹ́ kí n rí i pé Ẹlẹ́dàá nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn àti pé láìpẹ́ yóò tún ohun gbogbo ṣe. Ó ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bí Aísáyà 35:5-7 àti Ìṣípayá 21:3, 4, ó sì sọ fún mi pé láìpẹ́ ogun, gbọ́nmi-si-omi-ò-to, àìsàn, títí kan ikú pàápàá yóò di àwátì, àti pé àwọn olóòótọ́ èèyàn yóò gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé.
Mo Rí Ìdílé Tó Ràn Mí Lọ́wọ́
Mo gbọ́ lẹ́yìn náà pé àbúrò Paschalia ti kú nínú ìjà kan táwọn ọmọ ogun ajàjàgbara jà. Mo bá lọ sọ́dọ̀ ìdílé obìnrin náà láti lọ tù wọ́n nínú, àmọ́ àwọn gan-an ló tún fi Ìwé Mímọ́ tù mí nínú. Ni mo bá tún padà lọ kí n lè túbọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ ìtùnú sí i látinú Bíbélì, kò sì pẹ́ tí mo fi lọ ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèpàdé. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ lákòókò náà, ìdákọ́ńkọ́ ni wọ́n sì ti ń pàdé láti kẹ́kọ̀ọ́ àti láti jọ́sìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kì í fẹ́ rí àwọn Ẹlẹ́rìí sójú, mo pinnu pé mi ò ní fi wọ́n sílẹ̀.
Àwùjọ àwọn Kristẹni onírẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ ìdílé fún mi, mo rí ìfẹ́ àti ọ̀yàyà tí mi ò rí láti kékeré láàárín wọn. Wọ́n tún ràn mí lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, ohun tí mo sì nílò gan-an nìyẹn. Ọ̀rẹ́ tí kò mọ tara wọn nìkan ni wọ́n, wọ́n sì ṣe tán láti ràn mí lọ́wọ́ àti láti tù mí nínú. (2 Kọ́ríńtì 7:5-7) Olórí rẹ̀ wá ni pé, wọ́n ràn mí lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà, ẹni tí mo wá kà sí Baba mi ọ̀run onífẹ̀ẹ́. Àwọn ànímọ́ tó ní, irú bí ìfẹ́, ìyọ́nú, àti bó ṣe jẹ́ alábàárò ẹni, wù mí gan-an. (Sáàmù 23:1-6) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, èmi náà dẹni tó rí ìdílé tẹ̀mí àti Baba onífẹ̀ẹ́! Èyí múnú mi dùn gan-an. Kò sì pẹ́ rárá tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí fi mú kí n ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà, mo sì ṣèrìbọmi lóṣù September ọdún 1945.
Kì í ṣe pé lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni mú kí ìmọ̀ mi jinlẹ̀ sí i nìkan ni, ó tún jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára. Ẹsẹ̀ làwa kan fi máa ń rin ìrìn kìlómítà márùn-ún láti abúlé wa lọ síbi tá a ti
ń ṣèpàdé nítorí pé kò sí ohun ìrìnnà kankan. Bá a sì ṣe ń lọ, a máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí, èyí tí mi ò lè gbàgbé. Níparí ọdún 1945, nígbà tí mo gbọ́ pé èmi náà lè máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere nígbà gbogbo, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Ó ṣe pàtàkì kí àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i, nítorí pé láìpẹ́ sígbà yẹn, wọ́n máa dán ìgbàgbọ́ mi àti ìṣòtítọ́ mi sí Jèhófà wò débi gẹ́ẹ́.Ibi Tí Wọ́n Fojú sí, Ọ̀nà Ò Gbabẹ̀
Àwọn ọlọ́pàá sábà máa ń wá kó wa níbi tá a ti ń ṣèpàdé, pẹ̀lú ìbọn lọ́wọ́ sì ni. Òfin àwọn ológun ni wọ́n ń lò lórílẹ̀-èdè Gíríìsì lákòókò náà, nítorí pé ogun abẹ́lé ń gbóná girigiri nígbà yẹn. Àwọn aráàlú tó lòdì sí ara wọn bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jà, wọ́n sì kórìíra ara wọn gan-an. Ni àwọn àlùfáà bá lo àǹfààní ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí láti mú kí àwọn aláṣẹ gbà pé àwa Ẹlẹ́rìí ń ṣojú fún ìjọba Kọ́múníìsì kí wọ́n lè fojú wa rí màbo.
Láàárín ọdún méjì péré, àìmọye ìgbà ni wọ́n kó àwa arákùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tá a jọ ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, ẹ̀ẹ̀mẹfà ni wọ́n sì dá ẹ̀wọ̀n tó tó oṣù mẹ́rin fún wa. Àmọ́, àwọn tó ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí ọ̀rọ̀ ìṣèlú ti kún àwọn ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n, ni wọ́n bá dá wa sílẹ̀. A lo òmìnira tá a rí láìròtẹ́lẹ̀ yìí láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa nìṣó, àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n tún fi kó wa, kódà ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni wọ́n mú wa láàárín ọ̀sẹ̀ kan ṣoṣo. A mọ̀ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn arákùnrin wa ni wọ́n ti kó lọ sígbèkùn láwọn erékùṣù tí èèyàn kankan kì í gbé. Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ mi á lágbára tó láti kójú irú ìdánwò yìí?
Nǹkan túbọ̀ wá nira gan-an nígbà táwọn ọlọ́pàá sọ pé kí n máa wá sí àgọ́ wọn lójoojúmọ́. Nítorí káwọn ọlọ́pàá lè máa ṣọ́ mi lọ́wọ́-lẹ́sẹ̀, wọ́n gbé mi lọ sábúlé kan tó ń jẹ́ Evosmos, nítòsí Tẹsalóníkà, níbi tí àgọ́ ọlọ́pàá kan wà. Mo gba yàrá kan nítòsí àgọ́ ọlọ́pàá náà. Kí n lè máa gbọ́ bùkátà ara mi, mo máa ń lọ káàkiri láti bá àwọn èèyàn sọ pọ́ọ̀tù àtàwọn nǹkan ìdáná wọn mìíràn di ọ̀tun tí yóò sì máa dán gbinrin. Iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ mi yìí jẹ́ kó rọrùn fún mi láti máa wọ inú ilé àwọn èèyàn láìsí pé àwọn ọlọ́pàá ń fura sí mi, bí mo ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà láwọn abúlé tó wà lágbègbè náà. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn kan gbọ́ ìhìn rere náà wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn tó ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà lára wọn tí wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀ lé ní mẹ́wàá.
Ọdún Mẹ́wàá, Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Mẹ́jọ
Ìparí ọdún 1949 làwọn ọlọ́pàá tó fi mí sílẹ̀ tí wọn ò ṣọ́ mi mọ́, mo sì yára padà sílùú Tẹsalóníkà kí n lè máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún mi lọ. Bi mo ti ń ronú pé wàhálà mi ti dópin, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n pè mí láìròtẹ́lẹ̀ pé kí n wá wọṣẹ́ ológun lọ́dún 1950. Nítorí pé Kristẹni ni mí, mi ò sì fẹ́ lọ́wọ́ sógun, mo pinnu pé mi ò ní “kọ́ṣẹ́ ogun.” (Aísáyà 2:4) Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbé mi láti ọgbà ẹ̀wọ̀n kan dé òmíràn nìyẹn, ojú mi sì rí màbo, kódà mo bára mi láwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n tó burú jáì nílẹ̀ Gíríìsì.
Ìlú Drama ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ̀wọ̀n. Ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ tí mo débẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà síṣẹ́ ológun ní ìbọn yíyìn. Lọ́jọ́ kan, wọ́n mú mi lọ síbi tí wọ́n ti ń kọ́ èèyàn láti yìnbọn. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀gágun náà na ìbọn àgbéléjìká kan sí mi ó sì ní kí n yìn ín. Nígbà tí mo kọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí yìnbọn sí mi. Nígbà táwọn ọ̀gágun tó kù rí i pé mo ta kú mi ò yin ìbọn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí da ẹ̀ṣẹ́ bò mí. Wọ́n tanná sí sìgá, wọ́n sì ń tẹ iná àwọn sìgá náà mọ́ àtẹ́lẹwọ́ mi. Lẹ́yìn náà ni wọ́n wá sọ mí sí àhámọ́ aládàáwà. Odindi ọjọ́ mẹ́ta ni wọ́n sì fi ń fìyà jẹ mí lọ́nà yìí. Ìrora ọgbẹ́ iná sìgá náà kò ṣeé fẹnu sọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni àpá rẹ̀ sì fi wà lọ́wọ́ mi.
Jeremáyà 1:19 wá sí mi lọ́kàn, èyí tó sọ pé: “Ó . . . dájú pé wọn yóò bá ọ jà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí rẹ, nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘láti dá ọ nídè.’” “Àlàáfíà Ọlọ́run” tí ń túni lára mú ọkàn mi pa rọ́rọ́, ó sì jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀. Èyí jẹ́ kí n túbọ̀ rí i bó ṣe bọ́gbọ́n mu tó láti máa fi gbogbo ọkàn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.—Fílípì 4:6, 7; Òwe 3:5.
Kí wọ́n tó lọ ṣe ẹjọ́ mi nílé ẹjọ́ àwọn ológun, wọ́n kọ́kọ́ mú mi lọ sí àgọ́ àwọn sójà tó wà nílùú Iráklion, lágbègbè Kírétè. Wọ́n lù mí nílùkulù, kí n lè sẹ́ ìgbàgbọ́ mi. Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí bà mí pé mo lè lọ juwọ́ sílẹ̀, ni mo bá fi gbogbo ọkàn gbàdúrà sí Baba mi ọ̀run pé kó fún mi lókun kí n má ṣe juwọ́ sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwéNíbi ìgbẹ́jọ́ mi tí wọ́n wá ṣe lẹ́yìn náà, ẹ̀wọ̀n gbére ni wọ́n dá fún mi. “Ọ̀tá Ìlú” pátápátá ni wọ́n ka àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà yẹn. Ọgbà ẹ̀wọ̀n àwọn ọ̀daràn tó wà ní Itsedin, lẹ́yìn ìlú Canea, ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀wọ̀n yìí, inú àhámọ́ aládàáwà ni wọ́n sì sọ mí sí. Ilé olódi ni Itsedin yìí tẹ́lẹ̀, àwọn eku sì kúnnú àhámọ́ tí wọ́n fi mí sí. Bùláńkẹ́ẹ̀tì kan tó ti já jákujàku ni mo fi máa ń yí ara mi látorí títí dẹ́sẹ̀ káwọn eku náà má bàa máa fara kàn mí bí wọ́n ti ń rìn kiri lórí mi. Àìsàn otútù àyà kọ lù mí, àìsàn náà sì le gan-an. Àwọn dókítà ní mo gbọ́dọ̀ máa jókòó sínú oòrùn, èyí sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti bá ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà níbẹ̀ sọ̀rọ̀ ní gbàgede ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Àmọ́, àìsàn náà ń burú sí i, nígbà tí ẹ̀jẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í dà nínú ẹ̀dọ̀fóró mi, wọ́n gbé mi lọ sílé ìwòsàn ìlú Iráklion.
Àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ mi tí wọ́n jẹ́ ìdílé mi nípa tẹ̀mí tún dìde ìrànwọ́ fún mi lákòókò yìí. (Kólósè 4:11) Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílùú Iráklion máa ń wá sọ́dọ̀ mi déédéé, wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ìtùnú fún mi, wọ́n sì máa ń fún mi níṣìírí. Mo sọ fún wọn pé mo nílò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀ kí n lè máa wàásù fáwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ láti gbọ́. Wọ́n gbé àpótí kan wá tí mo lè máa kó àwọn ìwé náà sí. Àpótí yìí ní àyè mìíràn lábẹ́ tí ẹnikẹ́ni ò lè mọ̀. Inú mi dùn gan-an pé nígbà tí mo wà láwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n wọ̀nyẹn, ó kéré tán, èèyàn mẹ́fà lára àwọn tá a jọ jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n ni mo ràn lọ́wọ́ láti di Kristẹni tòótọ́!
Láìpẹ́, ogun abẹ́lé náà parí, wọ́n sì dín ẹ̀wọ̀n mi kù sí ọdún mẹ́wàá. Àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà nílùú Rethimno, ọgbà ẹ̀wọ̀n ti Genti Koule, àti ti ìlú Cassandra ni mo ti ṣẹ̀wọ̀n mi tó kù. Lẹ́yìn tí mo ti lo nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lọ́gbà ẹ̀wọ̀n mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n dá mi sílẹ̀, mo sì padà sílùú Tẹsalóníkà, níbi táwọn arákùnrin mi ọ̀wọ́n, ìyẹn àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ mi, ti gbà mí tayọ̀tayọ̀.
Ẹgbẹ́ Ará Jẹ́ Kí N Lè Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin
Àwọn Ẹlẹ́rìí nílẹ̀ Gíríìsì ti wá lómìnira díẹ̀ láti jọ́sìn lákòókò tí wọ́n dá mi sílẹ̀ yìí. Mo yára Sáàmù 5:11.
lo àǹfààní yìí láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún mi lọ. Kò pẹ́ sígbà náà ni ìbùkún mìíràn tún wọlé wá. Mo pàdé arábìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́, Katina lorúkọ rẹ̀. Ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ó sì máa ń kópa gan-an nínú iṣẹ́ ìwàásù. A ṣègbéyàwó ní oṣù October ọdún 1959. Nígbà tá a bí ọmọbìnrin wa tá a sọ orúkọ rẹ̀ ní Agape, tí èmi náà sì wá dẹni tó ní ìdílé tèmi tó jẹ́ ìdílé Kristẹni, èyí túbọ̀ jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn tí mo ní nítorí jíjẹ́ tí mo jẹ́ ọmọ aláìlóbìí dín kù. Àmọ́ paríparí rẹ̀ ni pé, ìdílé wa láyọ̀ pé a lè máa sin Jèhófà, Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, bó ti ń bójú tó wa.—Nítorí bí ipò nǹkan ṣe rí fún mi, mo ní láti fi iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà sílẹ̀, àmọ́ mò ń ran ìyàwó mi lọ́wọ́ bó ti ń bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tirẹ̀ lọ. Ohun kan tí mi ò lè gbàgbé látìgbà tí mo ti di Kristẹni ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1969, ìyẹn nígbà tí ìpàdé àgbáyé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wáyé nílùú Nuremberg, lórílẹ̀-èdè Jámánì. Nígbà tí mò ń múra láti lọ, mo lọ sọ́dọ̀ ìjọba láti lọ gba ìwé àṣẹ ìrìn àjò. Nígbà tí ìyàwó mi lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá láti lọ béèrè ìdí tí mi ò fi rí ìwé àṣẹ ìrìn àjò náà gbà láti oṣù méjì, ọ̀gá ọlọ́pàá kan gbé fáìlì dẹ̀ǹkù kan jáde látinú dúrọ́ọ̀ tábìlì rẹ̀ ó sì sọ pé: “Ṣé ọkùnrin yìí lo wá ń béèrè ìwé àṣẹ ìrìn àjò fún, kó lè lọ máa sọ àwọn èèyàn di ajẹ́rìí nílẹ̀ Jámánì, àbí? Rárá o, kò ṣeé ṣe! Ọkùnrin yìí lè ṣe jàǹbá.”
Àmọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà àti ìrànlọ́wọ́ àwọn arákùnrin kan, wọ́n forúkọ mi mọ́ ti ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó fẹ́ gba ìwé àṣẹ ìrìn àjò, ó sì ṣeé ṣe fún mi láti lọ sí ìpàdé àgbáyé tó jẹ́ mánigbàgbé yẹn. Àwọn èèyàn tó wá síbẹ̀ lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́jọ [150, 000] mo sì fojú ara mi rí bí ẹ̀mí Jèhófà ṣe ń darí ìdílé tẹ̀mí tó karí ayé yìí tó sì tún jẹ́ kó wà níṣọ̀kan. Lọ́jọ́ iwájú mo ṣì tún máa mọyì ẹgbẹ́ ara yìí jù báyìí lọ.
Lọ́dún 1977, aya mi ọ̀wọ́n, tó tún jẹ́ aládùúrótì mi kú. Mo sa gbogbo ipá mi láti tọ́ ọmọ mi níbàámu pẹ̀lú ìlànà Bíbélì, àwọn ará ò sì fi mí sílẹ̀. Ìdílé mi nípa tẹ̀mí tún dìde ìrànwọ́. Títí ayé ni n ó máa mọyì ìrànlọ́wọ́ táwọn ará ṣe fún mi lákòókò tí nǹkan nira fún mi yẹn. Kódà àwọn kan lára wọn wá gbé nílé wa fúngbà díẹ̀ kí wọ́n lè bá mi tọ́jú ọmọ mi. Mi ò lè gbàgbé ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan tí wọ́n fi hàn sí mi yìí.—Jòhánù 13:34, 35.
Agape, ọmọbìnrin mi ti dàgbà báyìí, ó sì fẹ́ arákùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elias. Wọ́n bí ọmọkùnrin mẹ́rin, gbogbo àwọn ọmọ náà ló sì wà nínú òtítọ́. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ó níye ìgbà tí àìsàn rọpárọsẹ̀ ti kọ lù mí, mi ò sì fi bẹ́ẹ̀ gbádùn ara mi mọ́. Ọmọ mi àti ìdílé rẹ̀ ń tọ́jú mi gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn ò jẹ́ kí n gbádùn, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nǹkan ṣì máa ń fún mi láyọ̀. Mo rántí ìgbà tó jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní gbogbo ìlú Tẹsalóníkà kò ju bí ọgọ́rùn-ún lọ, tó sì jẹ́ pé inú àwọn ilé àdáni la ti máa ń pàdé ní ìdákọ́ńkọ́. Àmọ́ báyìí, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún làwọn Ẹlẹ́rìí tó ń wàásù lágbègbè yẹn. (Aísáyà 60:22) Àwọn arákùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́ máa ń wá bá mi láwọn ìpàdé àgbègbè wa, wọ́n á sì bi mí pé: “Ṣé ẹ rántí ìgbà tẹ́ ẹ máa ń mú ìwé ìròyìn wá sílé wa?” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe káwọn òbí wọn má ka àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyẹn, àwọn ọmọ wọn kà á, wọ́n sì tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí!
Bí mo ti ń rí i tí ètò Jèhófà ń gbèrú, mo rí i pé mi ò ṣàṣìṣe rárá pé mo fara da àwọn ìdánwò yẹn. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń sọ fáwọn ọmọ ọmọ mi àtàwọn ọ̀dọ́ mìíràn pé kí wọ́n rántí Baba wọn ọ̀run nígbà tí wọ́n ṣì wà léwe, kò sì ní fi wọ́n sílẹ̀ láé. (Oníwàásù 12:1) Jèhófà mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, ó di “baba àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba” fún mi. (Sáàmù 68:5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ní kùtùkùtù ọjọ́ ayé mi, ọmọ òrukàn tí kò lẹ́bí tí kò sì lára ni mí, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, mo rí Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ mi!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Mo ṣiṣẹ́ agbọ́únjẹ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ti ìlú Drama
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Èmi àti Katina lọ́jọ́ ìgbéyàwó wa lọ́dún 1959
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìpàdé kan tá a ṣe nínú igbó kan nítòsí ìlú Tẹsalóníkà níparí ọdún 1960
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwa àtọmọ wa lọ́dún 1967