Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Àríyànjiyàn Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Lórí Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Àti Ẹ̀kọ́ Ìsìn

Bí Àríyànjiyàn Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Lórí Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Àti Ẹ̀kọ́ Ìsìn

Bí Àríyànjiyàn Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Lórí Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Àti Ẹ̀kọ́ Ìsìn

ONÍMỌ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà ni Nicolaus Copernicus. Ẹni àádọ́rin ọdún lọ́kùnrin náà, ó sì ti sún mọ́ bèbè ikú. Ó wà lórí ibùsùn, ó sì ń gbìyànjú láti tún ìwé kan tó kọ kà kó tó tẹ̀ ẹ́ jáde. Ọdún 1543 ni ọ̀ràn náà wáyé. Ọkùnrin yìí kò mọ̀ pé ìwé òun yìí ǹ bọ̀ wá yí èrò aráyé padà nípa àwọn nǹkan tó wà nínú sánmà. Ìwé náà á sì tún dá àríyànjiyàn ńlá sílẹ̀ láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Ohun tó dá sílẹ̀ náà ṣì ń jà ràn-ìn títí dòní olónìí.

Ọmọ ilẹ̀ Poland ni Copernicus, ẹlẹ́sìn Kátólíìkì sì ni. Ìwé tí Copernicus kọ yìí ni wọ́n pè ní On the Revolutions of the Heavenly Spheres (Bí Àwọn Pílánẹ́ẹ̀tì Ṣe Ń Yí Po). Ìwé náà sọ pé ayé ló ń yí po oòrùn, dípò ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé oòrùn ló ń yí po ayé. Ní kíá mọ́sá, Copernicus ti fi àlàyé tuntun tó rọrùn gan-an láti lóye yìí rọ́pò ohun tó ṣòroó lóye táwọn èèyàn ti gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀ pé oòrùn ló ń yí po ayé.

Lákọ̀ọ́kọ́, kò jọ pé gbọ́nmisi-omi-ò-tó máa wáyé lórí ọ̀ràn náà. Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé, Copernicus lo ọgbọ́n nígbà tó ń sọ èrò rẹ̀ fún àwọn èèyàn. Ìdí mìíràn ni pé, ó dà bíi pé Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì kò ta ko èrò àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ayé ìgbà yẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Ṣọ́ọ̀ṣì gbà gbọ́ ni pé oòrùn ló ń yí po ayé. Kódà póòpù pàápàá gba Copernicus níyànjú pé kó tẹ ìwé rẹ̀ jáde. Nígbà tí Copernicus sì tẹ ìwé náà jáde níkẹyìn, ẹ̀rù bá olóòtú ìwé náà, ohun tó sì kọ sínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú ìwé náà ni pé ìṣirò lásán ni wọ́n ṣe tí wọ́n fi sọ pé ayé ló ń yí po oòrùn, kò jọ pé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà tì í lẹ́yìn.

Àríyànjiyàn Náà Túbọ̀ Le Sí I

Ẹni tó tún dá sí àríyànjiyàn náà ni Galileo Galilei (tó gbé láyé ní ọdún 1564 sí 1642). Ọmọ ilẹ̀ Ítálì ni, ó sì jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà. Ó tún jẹ́ onímọ̀ ìṣirò àti físíìsì. Onísìn Kátólíìkì sì ni. Nígbà tí Galileo fi awò tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe nígbà yẹn sínú ẹ̀rọ awọ̀nà-jíjìn tóun fúnra rẹ̀ ṣe, èyí jẹ́ kó lè rí àwọn ohun tó wà ní gbalasa òfuurufú kọjá ohun táwọn èèyàn tíì rí rí. Ohun tó rí náà jẹ́ kó gbà pé òótọ́ ni ohun tí Copernicus sọ. Galileo tún rí àwọn nǹkan dúdú kan nínú oòrùn, èyí tí wọ́n ń pè ní àwọn ohun tóótòòtó inú oòrùn lónìí. Èyí wá sọ ìgbàgbọ́ táwọn onísìn ti ní tẹ́lẹ̀ pé oòrùn kì í bà jẹ́ di ohun tí ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.

Galileo kò dà bíi Copernicus, onígboyà èèyàn ni Galileo ó sì fi ìtara polongo àwọn èrò rẹ̀. Ìgbà tó sì ń ṣe ìpolongo yìí jẹ́ àkókò tára àwọn onísìn ti gbẹ̀kan, nítorí nígbà yẹn, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti ń ta ko èrò Copernicus. Nítorí ìdí yìí, nígbà tí Galileo sọ pé ayé ló ń yí po oòrùn àti pé èrò yìí bá Ìwé Mímọ́ mu, ńṣe ni wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án pé ó ń sọ ohun tó ta ko ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì. a

Galileo lọ sí Róòmù láti sọ tẹnu rẹ̀ àmọ́ kò kẹ́sẹ járí. Ní ọdún 1616, ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì sọ fún Galileo pé kò gbọ́dọ̀ ti ẹ̀kọ́ Copernicus lẹ́yìn mọ́. Wọ́n pa Galileo lẹ́nu mọ́ fúngbà díẹ̀. Àmọ́, nígbà tó tún di ọdún 1632, ó tẹ ìwé mìíràn jáde tó ti ẹ̀kọ́ Copernicus lẹ́yìn. Ọdún tó tẹ̀ lé e gan-an ni ilé ẹjọ́ Kátólíìkì tó ń fìyà jẹ ẹni tó bá sọ ohun tó ta ko ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ju Galileo sẹ́wọ̀n gbére. Àmọ́ nítorí ọjọ́ orí rẹ̀, wọ́n yí ẹ̀wọ̀n gbére náà padà, wọ́n pàṣẹ fún un pé kò gbọ́dọ̀ jáde kúrò nínú ilé rẹ̀ mọ́.

Ojú tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi wo àríyànjiyàn tó wáyé láàárín Galileo àti ṣọ́ọ̀ṣì ni pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti borí ẹ̀kọ́ ìsìn àti pé ó ti borí ẹ̀kọ́ Bíbélì pàápàá. Bó ti wù kó rí, èrò táwọn èèyàn ní yìí fi hàn pé àwọn ohun pàtàkì kan wà tí kò tíì yé wọn. A óò rí àwọn ohun náà nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Galileo sọ àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn di ọ̀tá ara rẹ̀ nítorí ẹnu rẹ̀ tó mú bérébéré àti bó ṣe ń sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀. Ó tún sọ ara rẹ̀ di aláṣẹ lórí ọ̀ràn ẹ̀sìn nípa ọ̀nà tó gbà sọ ọ́ pé ayé ló ń yí po oòrùn àti pé èrò náà bá Ìwé Mímọ́ mu. Èyí sì túbọ̀ bí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì nínú gidigidi.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Copernicus

[Credit Line]

A mú un látinú ìwé Giordano Bruno and Galilei (Ẹ̀dà ti èdè Jámánì)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Galileo ń sọ tẹnu rẹ̀ níwájú ilé ẹjọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì tó ń fìyà jẹ ẹni tó bá sọ ohun tó ta ko ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì

[Credit Line]

Látinú ìwé The Historian’s History of the World, Ìdìpọ̀ Kẹsàn-án, 1904

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Àwòrán tó hàn fírífírí: Àtẹ ìsọfúnni tó ń fi èrò Copernicus nípa oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí po rẹ̀ hàn