Ẹ̀kọ́ Kíkọ́ Nísinsìnyí Àti Títí Láé
Ẹ̀kọ́ Kíkọ́ Nísinsìnyí Àti Títí Láé
ONÍṢÈGÙN ọmọ ilẹ̀ Jámánì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ulrich Strunz ṣe ọ̀wọ́ àwọn ìwé kan tó pè ní Forever Young (Àjídèwe). Ó sọ ọ́ nínú ìwé náà pé téèyàn bá ń ṣe eré ìmárale, tó ń jẹ oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀, tó sì ń gbé ìgbé ayé ọmọlúwàbí, ara èèyàn á le, ó sì ṣeé ṣe kí ẹ̀mí èèyàn gùn sí i. Síbẹ̀, oníṣègùn yìí ò sọ pé táwọn èèyàn bá kàwé òun tí wọ́n sì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú rẹ̀, wọ́n á wà láàyè títí láé.
Ṣùgbọ́n ìmọ̀ kan wà tó jẹ́ pé tó o bá ní in, wàá wà láàyè títí láé. Tó o bá sì wà láàyè títí láé, á jẹ́ pé títí ayé ni wàá lè máa kọ́ ẹ̀kọ́ tó wúlò nìyẹn. Nínú àdúrà tí Jésù gbà sí Ọlọ́run, ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ ohun tí ọ̀rọ̀ náà “ìyè àìnípẹ̀kun” túmọ̀ sí, lẹ́yìn náà ká wá sọ àwọn nǹkan mìíràn tí ìmọ̀ náà kó mọ́ra, àti bó o ṣe lè ní ìmọ̀ ọ̀hún.
Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, Ẹlẹ́dàá ò ní pẹ́ sọ ayé yìí di Párádísè, níbi téèyàn yóò ti lè wà láàyè títí láé. Àmọ́ ṣá, kí Ọlọ́run tó sọ ayé yìí di Párádísè, ó máa kọ́kọ́ ṣe ohun ńláǹlà kan, irú èyí tó ṣe nígbà Ìkún Omi ọjọ́ Nóà. Nínú Mátíù orí kẹrìnlélógún, ẹsẹ kẹtàdínlógójì sí ìkọkàndínlógójì, Jésù fi ìgbà tiwa wé “ọjọ́ ayé Nóà.” Ìdí ni pé àwọn èèyàn tó wà nígbà ayé Nóà ò “fiyè sí” i pé ìparun rọ̀ dẹ̀dẹ̀, wọn ò sì kọbi ara sí ìwàásù Nóà. Bó ṣe “di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì” nìyẹn, tí Ìkún Omi sì pa gbogbo àwọn tí ò gba ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àmọ́ nǹkan kan ò ṣe Nóà àtàwọn tí wọ́n jọ wà nínú ọkọ̀ áàkì.
Jòhánù 5:28, 29) Wo bí Jésù ṣe ṣàlàyé kókó méjì yẹn ná. Nígbà tí Jésù ń bá Màtá sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde àwọn òkú, ó ní: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè; àti olúkúlùkù ẹni tí ń bẹ láàyè, tí ó sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, kì yóò kú láé.” Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló fi hàn pé “ọjọ́” tí Jésù ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé, tó túmọ̀ sí pé ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan lè má “kú láé.”—Jòhánù 11:25-27.
Jésù sọ pé “ọjọ́” kan ń bọ̀ lákòókò tiwa yìí tó máa dà bí ti ọjọ́ Nóà yẹn. Àwọn tó bá kọbi ara sí ìmọ̀ nípa ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ tí wọ́n sì ṣègbọràn yóò rí ìgbàlà, wọ́n á sì tún láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Ní àfikún sí i, gbogbo àwọn tí Ọlọ́run fẹ́ rántí wọn láti jí dìde yóò ní àjíǹde, wọ́n á sì lè wà láàyè títí láé. (Lẹ́yìn tí Jésù sọ̀rọ̀ yẹn tán, ó bi Màtá pé: “Ìwọ ha gba èyí gbọ́ bí?” Màtá fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa.” Ká wá ní Jésù bi ọ́ ní ìbéèrè tó bi Màtá yẹn lónìí, kí ni wàá fi dá a lóhùn? Ó ṣeé ṣe kó ṣòro fún ọ láti gbà gbọ́ pé ìgbà kan ń bọ̀ téèyàn ò ní kú mọ́ láé. Àmọ́ bó bá tiẹ̀ ṣòro fún ọ láti gbà pé yóò rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, ó dájú pé á wù ẹ́ pé kó o lè gbà á gbọ́. Ìwọ wo bí ohun tí wàá lè kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣe máa pọ̀ tó tó bá di pé o ò ní “kú láé”! Fojú inú wò ó pé o wà níbi tó o ti ń gbádùn gbogbo nǹkan tí ọkàn rẹ fẹ́ láti gbádùn nísinsìnyí àmọ́ tí kò sí àkókò fún ọ láti gbádùn wọn! Tún fojú inú wo bó ṣe máa rí nígbà tó o bá padà rí àwọn èèyàn rẹ tó ti kú! Irú ìmọ̀ wo lo lè ní tó máa jẹ́ kí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣeé ṣe fún ọ, báwo lo sì ṣe lè dẹni tó ní ìmọ̀ yìí?
Ìmọ̀ Tó Máa Jẹ́ Ká Jèrè Ìyè Àìnípẹ̀kun Kò Ju Ohun Tá A Lè Ní
Ǹjẹ́ níní ìmọ̀ nípa Ọlọ́run àti Kristi kọjá ohun téèyàn lè ṣe? Rárá o. Lóòótọ́, ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá kò lópin. Síbẹ̀, kì í ṣe ẹ̀kọ́ nípa sánmà tàbí ẹ̀kọ́ nípa ìṣẹ̀dá ni Jésù ń tọ́ka sí nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa “ìmọ̀” àti “ìyè àìnípẹ̀kun.” Ìwé Òwe orí kejì ẹsẹ kìíní àti ìkarùn-ún jẹ́ ká mọ̀ pé “àwọn àsọjáde” àti “àṣẹ” tó wà nínú Bíbélì ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ ní “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.” Jòhánù 20:30, 31 fi hàn pé àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì nípa Jésù ni ohun tó yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ká “lè ní ìyè.”
Nítorí náà, ẹ̀kọ́ tó o bá kọ́ nínú Bíbélì nípa Jèhófà àti Jésù Kristi ti tó láti jẹ́ kó o mọ ohun tí wàá ṣe láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Bíbélì jẹ́ ìwé kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ẹlẹ́dàá mí sí i lọ́nà kan tó jẹ́ pé àwọn tí ò kàwé rẹpẹtẹ pàápàá lè kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ kí wọ́n sì ní ìyè àìnípẹ̀kun. Bákan náà, gbogbo ìgbà làwọn tí nǹkan tètè máa ń yé, tí wọ́n ráyè fún ẹ̀kọ́ kíkọ́, tí wọ́n sì ní àwọn ohun tí wọ́n lè fi ṣèwádìí lórí ohun tí wọ́n kà yóò máa rí nǹkan tuntun kọ́ nínú Ìwé Mímọ́. Pé o tiẹ̀ lè ka àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ẹ̀rí kan pé o lè kọ́ ẹ̀kọ́, àmọ́ ọ̀nà wo ló yẹ kó o gbà kọ́ ẹ̀kọ́ yìí?
Ohun tá a rí látinú bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé fi hàn pé ọ̀nà tó dára jù lọ téèyàn lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ kó sì ní ìmọ̀ yìí ni pé kẹ́nì kan tó ní ìmọ̀ ọ̀hún dáadáa wá máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Bí Nóà ṣe gbìyànjú láti jẹ́ káwọn tí ń bẹ nígbà ayé rẹ̀ mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, bẹ́ẹ̀ náà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe tán láti wá sílé rẹ láti bá ọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ nínú Bíbélì. Wọ́n lè lo ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. a Bó tilẹ̀ ṣòro fún ọ láti gbà pé àwọn olóòótọ́ èèyàn ò ní “kú láé” nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí lè jẹ́ kó o gbà gbọ́ pé ìlérí náà yóò ṣẹ. Nítorí náà tó bá wù ọ́ láti wà láàyè títí láé tàbí tó o bá kàn fẹ́ mọ̀ bóyá ó bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé o lè wà láàyè títí láé, kí ló yẹ kó o ṣe? Má ṣe jẹ́ kí àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí lọ mọ́ ẹ lọ́wọ́.
Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó kó o tó parí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà? Ẹ̀kọ́ kúkúrú mẹ́rìndínlógún ló wà nínú ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tó lójú ewé méjìlélọ́gbọ̀n, ó sì wà ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè. Tó bá sì jẹ́ ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun lo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, tó o bá lè máa ya nǹkan bíi wákàtí kan sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, kò ní gbà ọ́ ju oṣù mélòó kan tí wàá fi kẹ́kọ̀ọ́ àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú Bíbélì. Àwọn ìwé tá a dárúkọ yìí ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìmọ̀ púpọ̀, ó sì ti mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run jinlẹ̀jinlẹ̀. Ó sì dájú pé Ẹlẹ́dàá yóò fi ìwàláàyè títí láé jíǹkí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn.
A lè wá rí i báyìí pé ìmọ̀ tó máa jẹ́ ká jèrè ìyè àìnípẹ̀kun kò ju ohun tá a lè ní, ìmọ̀ ọ̀hún sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Ó kéré tán, èdè tí wọ́n ti túmọ̀ Bíbélì sí ti lé ní ẹgbẹ̀rún méjì, yálà lódindi tàbí lápá kan. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń bẹ ní igba ó lé márùnlélọ́gbọ̀n [235] orílẹ̀-èdè yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́, àti láti fún ọ láwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí ìmọ̀ rẹ bàa lè pọ̀ sí i.
Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Bíbélì
Àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ọ̀rọ̀ àárín ìwọ àti Ẹlẹ́dàá rẹ. Bí àjọṣe ọ̀hún yóò bá dára, ọwọ́ rẹ ló wà, bó o bá sì máa ní ìyè àìnípẹ̀kun, ọwọ́ Ọlọ́run ló wà. Nítorí náà, má ṣe dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ nínú Bíbélì dúró. Tó o bá sì gbà kí ẹnì kan máa wá sílé rẹ láti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́, yóò túbọ̀ rọrùn fún ọ láti ya àkókò kan sọ́tọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ yẹn.
“Ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an” ló wà nínú Bíbélì àtàwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì, ìdí nìyẹn tí ò fi yẹ kó o lò wọ́n bà jẹ́. (Òwe 2:5) Tó o bá tọ́jú wọn dáadáa, wàá lè lò wọ́n pẹ́. Tó bá jẹ́ orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lò ń gbé, ó ṣeé ṣe kí ìwé tó o lò nígbà tó o wà nílé ìwé má fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, kó jẹ́ pé ohun tó o bá gbọ́ lẹ́nu tíṣà rẹ àtèyí tó o bá rí nìkan lo máa fi kẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, èdè tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè Benin lé ní àádọ́ta. Torí náà, kì í ṣe nǹkan tuntun láti rí ẹnì kan tó lè sọ èdè mẹ́rin sí márùn-ún dáadáa, bẹ́ẹ̀, ó lè má tíì ka ìwé kankan tó wà láwọn èdè wọ̀nyẹn rí o. Ẹ̀bùn ńlá ló jẹ́ pé láìlo ìwé, o lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa fífetí sílẹ̀, nípa ṣíṣe àkíyèsí nǹkan àti nípa fífọkàn sí nǹkan. Síbẹ̀, wàá rí i pé ìrànlọ́wọ́ ńlá ni ìwé lè ṣe fún ọ nínú ẹ̀kọ́ kíkọ́.
Bí ò tilẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ sáyè nílé rẹ, gbìyànjú láti wá ibì kan tó o lè máa kó Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mìíràn sí. Jẹ́ kí àwọn ìwé náà wà ní àrọ́wọ́tó, àmọ́ má ṣe kó wọn síbi tó ti máa bà jẹ́ o.
Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Pẹ̀lú Ìdílé Rẹ
Tó o bá lọ́mọ, ó yẹ kó o wá bó o ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́ káwọn náà lè kẹ́kọ̀ọ́ kan náà tó ò ń kọ́. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, àwọn òbí sábà máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó máa wúlò fún wọn nígbèésí ayé. Lára ohun tí wọ́n ń kọ́ wọn ni oúnjẹ sísè, igi ṣíṣẹ́, omi pípọn, iṣẹ́ oko, ẹja pípa àti ọjà títà. Ẹ̀kọ́ tó sì máa ṣe wọ́n láǹfààní nígbèésí ayé làwọn nǹkan wọ̀nyẹn. Àmọ́, ọ̀pọ̀ òbí ni kì í kọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ tó máa jẹ́ kí wọ́n lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.
O lè máa sọ pé o ò fi bẹ́ẹ̀ ráyè tó láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ nítorí ipò tó o wà. Ẹlẹ́dàá náà mọ̀ pé ó máa ń rí bẹ́ẹ̀. Gbọ́ ohun tí Ẹlẹ́dàá ti sọ láti ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn nípa bí àwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ọ̀nà tóun fẹ́. Ó ní: “Kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” (Diutarónómì 6:7) Níbàámu pẹ̀lú ohun tí ẹsẹ yìí sọ, o ò ṣe wá ọ̀nà tí wàá gbà máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ. Àwọn àpẹẹrẹ kan ló wà nísàlẹ̀ yìí:
1. “Nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ”: Gbìyànjú láti máa fi Bíbélì kọ́ àwọn ọmọ rẹ nílé
bí ẹnì kan ṣe wá ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ nílé. O lè máa ṣe èyí lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì téèyàn lè lò láti máa fi kọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ bó ti wù kí ọjọ́ orí wọn mọ.2. “Nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà”: Máa bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà láìjẹ́ pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ pè wọ́n jókòó, gẹ́gẹ́ bó o ṣe máa ń ṣe nígbà míì tó o bá ń kọ́ wọn láwọn ohun pàtàkì nípa ìgbésí ayé tàbí tó o bá ń fún wọn nítọ̀ọ́ni.
3. “Nígbà tí o bá dùbúlẹ̀”: Máa gbàdúrà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ lálaalẹ́.
4. “Nígbà tí o bá dìde”: Ọ̀pọ̀ ìdílé ló ti jàǹfààní púpọ̀ nítorí pé wọ́n máa ń jíròrò ẹsẹ Bíbélì kan láràárọ̀. Ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ b làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lò fún ìjíròrò yìí.
Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ọ̀pọ̀ òbí ló máa ń sapá gidigidi láti rí i pé wọ́n rán ọ̀kan lára ọmọ wọn lọ sílé ìwé gíga. Nípa bẹ́ẹ̀, ọmọ náà á lè rówó tọ́jú àwọn òbí rẹ̀ nígbà táwọn òbí náà bá darúgbó. Àmọ́, tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó o sì ran gbogbo àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá lè ní ìmọ̀ tí yóò mú kí ìwọ àti ìdílé rẹ wà láàyè títí láé.
Ǹjẹ́ ìgbà kan máa wà téèyàn máa mọ gbogbo nǹkan tán? Rárá o. Bí ayé wa yìí tó ń yí lọ lójú òfuurufú yìí ò ṣe ní dúró, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀kọ́ kíkọ́ ò ṣe ní lópin. Oníwàásù 3:11 tiẹ̀ sọ pé: “Ohun gbogbo ni [Ọlọ́run] ti ṣe rèterète ní ìgbà tirẹ̀. Àní àkókò tí ó lọ kánrin ni ó ti fi sínú ọkàn-àyà wọn, kí aráyé má bàa rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.” Ẹ̀kọ́ kíkọ́ jẹ́ ohun àtàtà kan tí a óò máa ṣe lọ títí ayérayé.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé méjèèjì.
b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé náà.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
“Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ . . . ”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ran ìdílé rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè gba ìmọ̀ nísinsìnyí kí wọ́n bàa lè máa gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ títí láé