Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọ̀rọ̀ Jèhófà
Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọ̀rọ̀ Jèhófà
“Mo gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ.”—SÁÀMÙ 119:42.
1. Kí lo mọ̀ nípa ẹni tó kọ Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà [119], irú èèyàn wo sì ni onítọ̀hún?
ẸNI tó kọ Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà [119] fẹ́ràn ọ̀rọ̀ Jèhófà gan-an ni. Àfàìmọ̀ kó má jẹ́ Hesekáyà ló kọ ọ́ kó tó di ọba Júdà. Ìdí ni pé orin onímìísí yìí bá ìwà Hesekáyà mu, nítorí pé ó jẹ́ ẹni tó “ń bá a nìṣó ní fífà mọ́ Jèhófà” nígbà tó jẹ́ ọba Júdà. (2 Ọba 18:3-7) Lẹ́nu kan ṣá, ẹni tí nǹkan tẹ̀mí jẹ lọ́kàn ló kọ orin yìí.—Mátíù 5:3.
2. Kí ni kókó pàtàkì inú Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà, báwo ni wọ́n sì ṣe to orin yìí?
2 Kókó inú Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà ni pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe pàtàkì gan-an. Nínú Bíbélì èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀, ńṣe lẹni tó kọ orin yìí pín orin náà sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, álífábẹ́ẹ̀tì èdè Hébérù ló sì fi to orin náà bóyá torí kó bàa lè rọrùn láti rántí. Àwọn lẹ́tà a, b, d, èdè Hébérù yìí ló fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹsẹ mẹ́rìndínlọ́gọ́sàn-án [176] tí orin yìí ní. Ìsọ̀rí méjìlélógún ló pín orin náà sí. Ẹsẹ mẹ́jọ ló wà nínú ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan, lẹ́tà kan náà ló sì fi bẹ̀rẹ̀ ẹsẹ mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ. Sáàmù yìí mẹ́nu kan àwọn nǹkan bí ọ̀rọ̀, òfin, ìránnilétí, ọ̀nà, àṣẹ ìtọ́ni, ìlànà, àṣẹ, ìpinnu ìdájọ́, àsọjáde àti ìlànà àgbékalẹ̀ Ọlọ́run. A ó fi àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e ṣàlàyé Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà, Bíbélì tá a sì túmọ̀ lọ́nà tó péye látinú Bíbélì lédè Hébérù la ó fi ṣe àlàyé yìí. Tá a bá ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láyé àtijọ́ àti lóde òní, á jẹ́ ká túbọ̀ mọyì orin tí Ọlọ́run mí sí yìí, á sì tún jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Pa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Mọ́ Kó O Lè Láyọ̀
3. Ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí tá a bá sọ pé èèyàn kan jẹ́ aláìní-àléébù, kó o sì mú àpẹẹrẹ wá.
3 Ẹni tó bá fẹ́ láyọ̀ gidi gbọ́dọ̀ máa rìn nínú òfin Ọlọ́run. (Sáàmù 119:1-8) Tá a bá ń rìn nínú òfin Ọlọ́run, Jèhófà yóò gbà pé a jẹ́ ‘aláìní-àléébù ní ọ̀nà wa.’ (Sáàmù 119:1) Tá a bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ aláìní àléébù, kò túmọ̀ sí pé onítọ̀hún jẹ́ ẹni pípé, ńṣe ló kàn fi hàn pé ó ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Nóà “fi ara rẹ̀ hàn ní aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀” ní ti pé ó “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” Nítorí pé baba ńlá olóòótọ́ yìí gbé ìgbé ayé rẹ̀ bí Jèhófà ṣe fẹ́, òun àti ìdílé rẹ̀ ò sí lára àwọn tí Ìkún Omi pa. (Jẹ́nẹ́sísì 6:9; 1 Pétérù 3:20) Tí àwa náà yóò bá la òpin ayé yìí já, a gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ń ‘fi tọkàntara pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́,’ ìyẹn ni pé ká máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—Sáàmù 119:4.
4. Kí la ní láti ṣe ká tó lè láyọ̀ kí ọ̀nà wa sì yọrí sí rere?
4 Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ láé tá a bá ń fi ‘ìdúróṣánṣán ọkàn-àyà gbé e lárugẹ’ tá a sì ‘ń pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́.’ (Sáàmù 119:7, 8) Ọlọ́run ò fi Jóṣúà aṣáájú Ísírẹ́lì sílẹ̀, torí ó ṣe bí Ọlọ́run ṣe wí, ó ń ‘ka ìwé òfin Ọlọ́run ní ọ̀sán àti ní òru kó bàa lè ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀.’ Ohun tó ṣe yìí jẹ́ kí ọ̀nà rẹ̀ yọrí sí rere, ó sì mú kó hùwà ọlọ́gbọ́n. (Jóṣúà 1:8) Títí tí Jóṣúà fi darúgbó kùjọ́kùjọ́ ló ṣì ń gbé Ọlọ́run ga, àní ó tiẹ̀ tún rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé: “Ẹ̀yin . . . mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín.” (Jóṣúà 23:14) Bíi ti Jóṣúà àti ẹni tó kọ Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà lọ̀ràn tiwa náà rí. Ká tó lè láyọ̀ kí ọ̀nà wa sì yọrí sí rere, a ní láti máa yin Jèhófà ká sì gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ń Mú Ká Jẹ́ Ẹni Tó Mọ́
5. (a) Ṣàlàyé ọ̀nà tá a lè gbà jẹ́ ẹni tó mọ́ nípa tẹ̀mí. (b) Kí ló lè ran ọ̀dọ́ tó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ burúkú lọ́wọ́?
5 A lè jẹ́ ẹni tó mọ́ nípa tẹ̀mí tá a bá ń ṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Sáàmù 119:9-16) Kódà bí àwọn òbí wa ò bá tiẹ̀ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa, a ṣì lè jẹ́ ẹni tó mọ́ nípa tẹ̀mí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé abọ̀rìṣà ni bàbá Hesekáyà, síbẹ̀ Hesekáyà “mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́,” bóyá ní ti pé kò jẹ́ kí àṣà ìbọ̀rìṣà ran òun. Tí ọ̀dọ́ kan tó ń sin Jèhófà lóde òní bá dá ẹ̀ṣẹ̀ burúkú ńkọ́? Tó bá ronú pìwà dà, tó gbàdúrà, tó sì lọ bá àwọn òbí rẹ̀ àtàwọn alàgbà pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́, ìyẹn yóò jẹ́ kó lè ṣe bíi ti Hesekáyà, kí ó ‘mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́ kí ó sì máa ṣọ́ra.’—Jákọ́bù 5:13-15.
6. Àwọn obìnrin wo ló ‘mú ipa ọ̀nà wọn mọ́ tí wọ́n sì ṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’?
6 Ìgbà tí Ráhábù àti Rúùtù gbé láyé jìnnà gan-an sígbà tí onísáàmù kọ Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà, síbẹ̀ àwọn méjèèjì ‘mú ipa ọ̀nà wọn mọ́.’ Aṣẹ́wó ni Ráhábù ọmọ Kénáánì, àmọ́ ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú kó dẹni tá a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùjọsìn Jèhófà. (Hébérù 11:30, 31) Rúùtù ará Móábù fi òòṣà bíbọ sílẹ̀ ní tiẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí sin Jèhófà, ó sì ń pa Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́. (Rúùtù 1:14-17; 4:9-13) Àwọn obìnrin méjèèjì tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì yìí ‘ṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,’ ìyẹn sì mú kí Ọlọ́run dá wọn lọ́lá ní ti pé wọ́n di ìyá ńlá Jésù Kristi.—Mátíù 1:1, 4-6.
7. Kí ni Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta mìíràn ṣe kí àbàwọ́n kankan má bàa ta bá wọn nípa tẹ̀mí, èyí tó jẹ́ àpẹẹrẹ tó dára fún wa?
7 Lóòótọ́, “ìtẹ̀sí èrò ọkàn-àyà ènìyàn jẹ́ búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá,” ṣùgbọ́n àwọn ọ̀dọ́ ṣì lè máa tọ ipa ọ̀nà tó mọ́, àní nínú ayé oníwà ìbàjẹ́ tí Sátánì ń ṣàkóso yìí. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21; 1 Jòhánù 5:19) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbèkùn ni Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta mìíràn wà ní Bábílónì, wọ́n ‘ṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.’ Bí àpẹẹrẹ, wọn ò jẹ “àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba” kí wọ́n má bàa di aláìmọ́. (Dáníẹ́lì 1:6-10) Ìdí ni pé ẹran aláìmọ́ tí Òfin Mósè kà léèwọ̀ làwọn ará Bábílónì máa ń jẹ. (Léfítíkù 11:1-31; 20:24-26) Wọn kì í sábà dúńbú ẹran tí wọ́n ń jẹ, èyí tó lòdì sí òfin Ọlọ́run tó ka ẹ̀jẹ̀ jíjẹ léèwọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4) Ẹ ò rí i pé ó tọ́ bí àwọn ọmọ Hébérù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí ṣe kọ̀ tí wọn ò jẹ àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba! Àwọn ọ̀dọ́ tó bẹ̀rù Ọlọ́run yìí kò jẹ́ kí àbàwọ́n kankan ta bá wọn nípa tẹ̀mí, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ àwòkọ́ṣe tó dára láti tẹ̀ lé.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Jẹ́ Olóòótọ́
8. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ lóye òfin Ọlọ́run ká sì máa pa á mọ́?
8 Ọ̀kan lára ohun pàtàkì tó ń jẹ́ kéèyàn lè máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà ni pé kéèyàn fẹ́ràn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an. (Sáàmù 119:17-24) Tá a bá fẹ́ràn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bíi tẹni tó kọ sáàmù tí Ọlọ́run mí sí yìí, yóò máa wù wá ká mọ “àwọn ohun àgbàyanu” inú òfin Ọlọ́run. Gbogbo ìgbà la óò máa ‘yán hànhàn fún àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀,’ a ó sì ‘fẹ́ràn àwọn ìránnilétí rẹ̀.’ (Sáàmù 119:18, 20, 24) Tá a bá ti yara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, ì báà jẹ́ látọjọ́ pípẹ́ tàbí lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ǹjẹ́ a máa ‘ń yán hànhàn fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà’? (1 Pétérù 2:1, 2) Á dára ká lóye àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú Bíbélì nítorí ìyẹn ni yóò jẹ́ ká mọ òfin Ọlọ́run dáadáa ká sì máa pa á mọ́.
9. Kí la ó ṣe táwọn aláṣẹ bá ní ká ṣe ohun tó ta ko òfin Ọlọ́run?
9 Tá a bá fẹ́ràn àwọn ìránnilétí Ọlọ́run, tí “àwọn ọmọ aládé” wá ń sọ̀rọ̀ wa láìdáa ńkọ́? (Sáàmù 119:23, 24) Lóde òní, àwọn aláṣẹ sábà máa ń fẹ́ fipá mú wa ká lè ka òfin èèyàn sí pàtàkì ju òfin Ọlọ́run lọ. Kí la ó ṣe tí wọ́n bá ní ká ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́? Ìfẹ́ tá a ní sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò mú ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà. A óò ṣe bíi ti àwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi táwọn aláṣẹ ṣenúnibíni sí, tí wọ́n sọ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.
10, 11. Sọ ohun tá a lè ṣe ká lè máa bá ìwà títọ́ wa nìṣó bí òkè ìṣòro tiẹ̀ wà níwájú wa.
10 A lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láìyẹhùn bí òkè ìṣòro tiẹ̀ wà níwájú wa. (Sáàmù 119:25-32) Àmọ́ ká lè máa bá ìwà títọ́ wa nìṣó, a ní láti jẹ́ kí Jèhófà máa kọ́ wa, ká sì máa gbàdúrà tọkàntọkàn pé kó tọ́ wa sọ́nà. A tún ní láti yan “ọ̀nà ìṣòtítọ́” bá kan náà.—Sáàmù 119:26, 30.
11 Hesekáyà, ẹni tó jọ pé ó kọ Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà, yan “ọ̀nà ìṣòtítọ́.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárín àwọn abọ̀rìṣà ló ń gbé, àwọn tó wà láàfin sì lè máa fi ṣẹlẹ́yà, síbẹ̀ kò kúrò ní ọ̀nà ìṣòtítọ́ tó ń tọ̀. Ó jọ pé nǹkan wọ̀nyí ló fà á tí ‘ọkàn rẹ̀ kò fi lè sùn nítorí ẹ̀dùn ọkàn.’ (Sáàmù 119:28) Ṣùgbọ́n Hesekáyà gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, ó jẹ́ ọba rere, ó sì ṣe “ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà.” (2 Àwọn Ọba 18:1-5) Táwa náà bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, a ó lè fara da ìṣòro, a ó sì lè máa bá ìwà títọ́ wa nìṣó.—Jákọ́bù 1:5-8.
Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ń Fún Wa Ní Ìgboyà
12. Báwo làwa fúnra wa ṣe lè fi Sáàmù 119:36, 37 sílò?
12 Tí a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a óò ní ìgboyà tá a ó fi lè máa fara da àwọn ìṣòro tá a bá ní. (Sáàmù 119:33-40) Tá a bá ń fi ìrẹ̀lẹ̀ wá ìtọ́ni Jèhófà, a ó lè “máa fi gbogbo ọkàn àyà” pa òfin rẹ̀ mọ́. (Sáàmù 119:33, 34) Ó yẹ ká máa bẹ Ọlọ́run bí onísáàmù náà ṣe bẹ̀ ẹ́ pé: “Tẹ ọkàn-àyà mi síhà àwọn ìránnilétí rẹ, kí ó má sì jẹ́ sí èrè” àbòsí. (Sáàmù 119:36) Ó yẹ ká tún máa ṣe bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ká máa “hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Bí ọ̀gá wa níbi iṣẹ́ bá fẹ́ ká hùwà àbòsí kan, kò yẹ ká gbà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká fi ìgboyà tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run. Jèhófà sì máa ń bù kún àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà tí èròkérò bá sọ sí wa lọ́kàn, Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè kápá rẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa gbà á ládùúrà pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí.” (Sáàmù 119:37) Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé a ò ka ohun tí Jèhófà kórìíra sí ohun tó dára. (Sáàmù 97:10) Nígbà tó ti jẹ́ pé ohun tá a kì í jẹ, a kì í fi í runmú, ńṣe ló yẹ ká yàgò pátápátá fún àwòrán oníhòòhò àtohun tó bá lè fa ọkàn ẹni sí ìṣekúṣe àti àṣà bíbá ẹ̀mí lò.—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Ìṣípayá 21:8.
13. Báwo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe dẹni tó nígboyà tí wọ́n fi ń wàásù láìṣojo nígbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wọn?
13 Tí a bá mọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, a óò máa fi ìgboyà wàásù. (Sáàmù 119:41-48) A sì ní láti jẹ́ onígboyà láti lè ‘dá ẹni tí ń gàn wá lóhùn.’ (Sáàmù 119:42) Nígbà mìíràn, ọ̀rọ̀ wa lè dà bíi tàwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n gbàdúrà nígbà inúnibíni pé: “Jèhófà, . . . yọ̀ǹda fún àwọn ẹrú rẹ láti máa bá a nìṣó ní fífi àìṣojo rárá sọ ọ̀rọ̀ rẹ.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn àdúrà wọn yìí? Ńṣe ni “gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan . . . kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì ń fi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Olúwa Ọba Aláṣẹ kan náà ló ń fún wa nígboyà tá a fi ń sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ láìṣojo.—Ìṣe 4:24-31.
14. Kí ló ń jẹ́ ká lè máa fi ìgboyà wàásù gẹ́gẹ́ bíi ti Pọ́ọ̀lù?
14 Láti dẹni tó ní ìgboyà láti máa wàásù láìsí pé à ń tijú, a ní láti fẹ́ràn “ọ̀rọ̀ òtítọ́” tọkàntọkàn, ká sì máa ‘pa òfin Ọlọ́run mọ́ nígbà gbogbo.’ (Sáàmù 119:43, 44) Bí a bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ó lè ‘sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìránnilétí rẹ̀ ní iwájú àwọn ọba.’ (Sáàmù 119:46) Àdúrà gbígbà àti ẹ̀mí Jèhófà yóò sì ràn wá lọ́wọ́ ká lè sọ ohun tó tọ́ lọ́nà tó yẹ. (Mátíù 10:16-20; Kólósè 4:6) Pọ́ọ̀lù fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìránnilétí Ọlọ́run fáwọn alákòóso ní ọ̀rúndún kìíní. Bí àpẹẹrẹ, ó wàásù fún Fẹ́líìsì ará Róòmù tó jẹ́ gómìnà, Fẹ́líìsì sì “fetí sí i lórí èrò ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù.” (Ìṣe 24:24, 25) Pọ́ọ̀lù tún wàásù fún Fẹ́sítọ́ọ̀sì tó jẹ́ gómìnà àti Ágírípà Ọba. (Ìṣe 25:22–26:32) Jèhófà ń bẹ lẹ́yìn àwa náà, ìyẹn ló ń jẹ́ ká lè máa fi ìgboyà wàásù, láìsí pé à ń “tijú ìhìn rere.”—Róòmù 1:16.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Tù Wá Nínú
15. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè tù wá nínú nígbà tí àwọn èèyàn bá ń fi wá ṣẹ̀sín?
15 Ìtùnú gidi ni Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Jèhófà máa ń fún wa. (Sáàmù 119:49-56) Àwọn ìgbà kan wà tá a máa ń fẹ́ ìtùnú gan-an. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fìgboyà wàásù, nígbà mìíràn “àwọn oníkùgbù,” ìyẹn àwọn tó ń tàpá sí Ọlọ́run, máa ń ‘fi wá ṣẹ̀sín dé góńgó.’ (Sáàmù 119:51) Ṣùgbọ́n tá a bá ń gbàdúrà, a lè rántí àwọn ohun tí ń gbéni ró tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ó sì tipa bẹ́ẹ̀ “rí ìtùnú” gbà. (Sáàmù 119:52) Nígbà tá a bá ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀, a lè rántí òfin tàbí ìlànà Ìwé Mímọ́ kan tó máa tù wá nínú tó sì máa fún wa nígboyà tá a nílò nígbà ìnira.
16. Kí làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ò ṣe bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wọn?
16 Ẹ jẹ́ mọ̀ pé ọmọ Ísírẹ́lì, ìyẹn àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè tá a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run, làwọn oníkùgbù tó ń fi onísáàmù yìí ṣẹ̀sín. Ìyẹn mà kúkú burú o! Ní tiwa, ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé a ò yà kúrò nínú òfin Ọlọ́run. (Sáàmù 119:51) Bí inúnibíni látọ̀dọ̀ ìjọba Násì àti ìyà táwọn mìíràn fi ń jẹ àwọn èèyàn Ọlọ́run láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ṣe pọ̀ tó, ọ̀kẹ́ àìmọye wọn ò yà kúrò nínú àwọn òfin àti ìlànà tó wà nínú Bíbélì. (Jòhánù ) Kò lè ṣàìrí bẹ́ẹ̀, nítorí pé kì í ṣe ẹrù ìnira fún wa láti ṣègbọràn sí Jèhófà, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe làwọn ìlànà rẹ̀ dà bí orin atunilára fún wa.— 15:18-21Sáàmù 119:54; 1 Jòhánù 5:3.
Mọrírì Ọ̀rọ̀ Jèhófà
17. Tá a bá mọrírì ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí la óò máa ṣe?
17 Bí a ṣe lè fi hàn pé a mọrírì ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni pé ká máa pa á mọ́. (Sáàmù 119:57-64) Onísáàmù yìí ‘ṣèlérí pé òun á máa pa àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà mọ́,’ ó sì sọ pé ‘ní ọ̀gànjọ́ òru pàápàá, òun dìde láti fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nítorí àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀ tó jẹ́ òdodo.’ Bó bá ṣẹlẹ̀ pé a jí lóru, á mà dára gan-an o tá a bá lo àsìkò yẹn láti fi gbàdúrà láti fọpẹ́ fún Ọlọ́run! (Sáàmù 119:57, 62) Tá a bá mọyì ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a óò máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lójú méjèèjì, yóò sì dùn mọ́ wa láti jẹ́ ‘alájọṣe pẹ̀lú àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà’ tọkàntọkàn. (Sáàmù 119:63, 64) Ó dájú pé kò sáwọn alájọṣe tó tún lè dáa tó àwọn èèyàn Jèhófà láyé, àbí ó wà?
18. Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà wa nígbà tí ‘ìjàrá àwọn ẹni burúkú bá yí wa ká’?
18 Bí a bá gbàdúrà tọkàntọkàn, tá a sì bẹ Jèhófà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé kó kọ́ wa, ńṣe là ń ‘tu Jèhófà lójú’ ká lè rí ojú rere rẹ̀. Ó yẹ ká gbàdúrà pàápàá nígbà tí ‘ìjàrá àwọn ẹni burúkú bá yí wa ká.’ (Sáàmù 119:58, 61) Jèhófà lè já okùn ìkánilọ́wọ́kò táwọn ọ̀tá wa bá ta, kí ó sì gbà wá sílẹ̀ ká lè máa bá iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ-ẹ̀yìn tá à ń ṣe nìṣó. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) A sì ń rí i léraléra pé Jèhófà ń gbà wá sílẹ̀ láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa.
Gba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Gbọ́
19, 20. Báwo la ṣe lè jàǹfààní tí wọ́n bá ń ṣẹ́ wa níṣẹ̀ẹ́?
19 Tá a bá gba Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, a óò ní ìfaradà, a ó sì máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nìṣó tí wọ́n bá ń ‘ṣẹ́ wa níṣẹ̀ẹ́.’ (Sáàmù 119:65-72) Àwọn oníkùgbù ń ‘fi èké rẹ́ onísáàmù yìí lára,’ síbẹ̀ ó kọrin pé: “Ó dára fún mi pé a ti ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́.” (Sáàmù 119:66, 69, 71) Ṣé ó dáa káwọn èèyàn máa ṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà níṣẹ̀ẹ́?
20 Tí wọ́n bá ń ṣẹ́ wa níṣẹ̀ẹ́, kò sí àní-àní pé a máa ń ké pe Jèhófà tọkàntọkàn, ìyẹn sì ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. A tiẹ̀ lè túbọ̀ wáyè láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí i ká sì túbọ̀ gbìyànjú láti fi í sílò. Èyí á sì jẹ́ ká túbọ̀ láyọ̀. Ṣùgbọ́n ká ní a ti wá ṣìwà hù nígbà tí wọ́n ń ṣẹ́ wa níṣẹ̀ẹ́ ńkọ́, bóyá a ò ní sùúrù tàbí a hùwà ìgbéraga? Tá a bá gbàdúrà àtọkànwá, tá a túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì wá ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́, a ó lè borí irú ìwà bẹ́ẹ̀, a ó sì lè túbọ̀ ‘fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara wa láṣọ.’ (Kólósè 3:9-14) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, tá a bá fara da ìnira, ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ lágbára. (1 Pétérù 1:6, 7) Inúnibíni tí wọ́n ṣe sí Pọ́ọ̀lù ṣe é láǹfààní ní ti pé ó mú kó túbọ̀ gbára lé Jèhófà. (2 Kọ́ríńtì 1:8-10) Ǹjẹ́ a máa ń fara da ìṣòro kó lè ṣe wá láǹfààní lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn?
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Nígbà Gbogbo
21. Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run bá jẹ́ kí ojú ti àwọn oníkùgbù?
21 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká rí ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Sáàmù 119:73-80) Bí a bá fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé Ẹlẹ́dàá wa, kò ní sí ohunkóhun tó máa mú kí ojú tì wá. Àmọ́, ìwà táwọn ẹlòmíràn ń hù lè mú ká dẹni tó ń fẹ́ ìtùnú, tá a ó fi fẹ́rẹ̀ẹ́ lè máa gbàdúrà pé: “Kí ojú ti àwọn oníkùgbù.” (Sáàmù 119:76-78) Tí Jèhófà bá fẹ́ dójú ti irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, ó máa ń jẹ́ kí àṣírí ìwà burúkú wọn tú, orúkọ mímọ́ Jèhófà á sì di èyí tá a wẹ̀ mọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé ńṣe làwọn tó ń ṣenúnibíni sí àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ń pòfo níkẹyìn. Bí àpẹẹrẹ, wọn kò rí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé ṣe rí, wọ́n ò sì lè pa wá run láéláé, nítorí pé gbogbo ọkàn wa la fi gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run.—Òwe 3:5, 6.
22. Ọ̀nà wo ni onísáàmù náà gbà “dà bí ìgò awọ nínú èéfín”?
22 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run nígbà tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa. (Sáàmù 119:81-88) Inúnibíni táwọn oníkùgbù ń ṣe sí onísáàmù náà mú kó “dà bí ìgò awọ nínú èéfín.” (Sáàmù 119:83, 86) Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, wọ́n máa ń fi ìgò tí wọ́n fi awọ ẹran ṣe rọ omi, wáìnì àtàwọn nǹkan olómi mìíràn. Tí wọ́n bá gbé ìgò awọ yìí sún mọ́ ibi tí iná wà láìjẹ́ pé omi tàbí wáìnì wà nínú rẹ̀, ó lè sún kì. Ṣé ìnira àti inúnibíni tìrẹ náà pọ̀ débi pé o fẹ́rẹ̀ẹ́ “dà bí ìgò awọ nínú èéfín”? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kó o sì gbàdúrà pé: “Pa mí mọ́ láàyè ní ìbámu pẹ̀lú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́, kí n lè máa pa ìránnilétí ẹnu rẹ mọ́.”—Sáàmù 119:88.
23. Kí làwọn nǹkan tá a ti gbé yẹ̀ wò nínú Sáàmù 119:1-88, kí ni yóò sì dára ká bi ara wa bí a ṣe máa kẹ́kọ̀ọ́ ohun tó wà nínu Sáàmù 119:89-176?
23 Ohun tá a ti gbé yẹ̀ wò nínú Sáàmù 119:1-88 fi hàn pé Jèhófà máa ń fi inú rere onífẹ̀ẹ́ hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì fẹ́ràn àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀, ìránnilétí rẹ̀, àṣẹ rẹ̀ àti òfin rẹ̀. (Sáàmù 119:16, 47, 64, 70, 77, 88) Inú rẹ̀ máa ń dùn pé àwọn tó ya ara wọn sí mímọ́ fún òun máa ń ṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ òun. (Sáàmù 119:9, 17, 41, 42) Bó o ṣe ń wọ̀nà fún ìgbà tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ ẹsẹ yòókù nínú sáàmù tó ń tuni lára yìí, á dára kó o bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ lóòótọ́ ni mò ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Jèhófà tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà mi?’
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí léèyàn ní láti ṣe kó tó lè ní ayọ̀ tòótọ́?
• Báwo ni ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe ń mú ká jẹ́ ẹni tó mọ́ nípa tẹ̀mí?
• Ọ̀nà wo ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà ń fún wa ní ìgboyà àti ìtùnú?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká gba Jèhófà àti ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Rúùtù, Ráhábù, àtàwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta tí wọ́n kó nígbèkùn lọ sí Bábílónì ‘ṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Pọ́ọ̀lù fi ìgboyà ‘sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìránnilétí Ọlọ́run níwájú àwọn ọba’