Ǹjẹ́ Ẹ̀kọ́ Ò Ti Wá Pọ̀ Jù fún Ọmọ Èèyàn?
Ǹjẹ́ Ẹ̀kọ́ Ò Ti Wá Pọ̀ Jù fún Ọmọ Èèyàn?
Lọ́jọ́ kan, tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì jókòó sí etíkun kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, wọ́n ń wo òṣùpá tó mọ́ roro lójú ọ̀run. Èyí ọkọ béèrè pé: “Kí lọmọ aráyé tiẹ̀ tíì mọ̀ nípa òṣùpá ná? Báwo làwọn ohun tó kù kéèyàn mọ̀ nípa òṣùpá sì ṣe pọ̀ tó?”
Aya rẹ̀ fèsì pé: “Ká sì wá ní pé èèyàn lè wà níbì kan kó máa wo ayé yìí bó ṣe ń yí lọ gẹ́gẹ́ bá a ṣe ń wo òṣùpá tó ń yí lọ yìí—ibo la lè sọ pé ọmọ aráyé tíì mọ ayé ọ̀hún dé ná? Ẹ sì máa wò ó o, yàtọ̀ sí pé ayé yìí ń yí po oòrùn, oòrùn àtàwọn ọ̀wọ́ rẹ̀, ìyẹn àwọn pílánẹ́ẹ̀tì, náà ń yí pẹ̀lú. Èyí túmọ̀ sí pé ó ṣeé ṣe ká má padà sí ọ̀gangan ibi tí ayé wà báyìí mọ́ láé. Tá a bá tiẹ̀ ní ká sọ ọ́, oòrùn àtàwọn ìràwọ̀ là ń wò tá a fi ń mọ ọ̀gangan ibi tí ayé wà lójú òfuurufú. Béèyàn ṣe mọ ọ̀pọ̀ nǹkan tó, ẹ jẹ́ mọ̀ pé èèyàn ò mọ ibi tí ayé tá a wà nínú rẹ̀ yí dé!”
ÒDODO ọ̀rọ̀ ni tọkọtaya yìí sọ o. Àìmọye nǹkan ló ṣì wà fún wa láti kọ́. Ojúmọ́ kan ò lè mọ́ kí kálukú wa máà kọ́ nǹkan tuntun. Àmọ́, láìka bí àwọn ohun tá a ti mọ̀ ṣe pọ̀ tó, ó jọ pé a ò lè kọ́ gbogbo ohun tó wù wá láti kọ́ tán.
Yàtọ̀ sí pé èèyàn ń kọ́ nǹkan tuntun, ohun téèyàn lè fi tọ́jú ìsọfúnni ti túbọ̀ pọ̀ gan-an. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ń mú kí ìsọfúnni téèyàn lè tọ́jú pọ̀ sí i. Kọ̀ǹpútà tí wọ́n ń ṣe láyé ìsinsìnyí máa ń gba ìsọfúnni tó pọ̀ gan-an, gbogbo ìgbà ni wọ́n sì ń ṣe àwọn kọ̀ǹpútà tuntun tó lè gba ìsọfúnni tó ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
Agbára àwọn ohun tí wọ́n fi ń gbé ìsọfúnni jáde láyé ìsinsìnyí pọ̀ kọjá sísọ. Ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ńlá ayára-bí-àṣá kan wà tó máa ń da ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé míì jáde wìtìwìtì. Tó bá sì jẹ́ tàwọn tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, kí wọ́n má tíì tẹ bọ́tìnnì kọ̀ǹpútà ni, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìsọfúnni á ti jáde fún wọn láti kà. Àwọn nǹkan tá a mẹ́nu kàn wọ̀nyí àtàwọn nǹkan mìíràn bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ ká rí ìsọfúnni gbà, àwọn ìsọfúnni tó ń jáde yìí sì pọ̀ ju ohun téèyàn lè kà lọ. Ńṣe ni ìsọfúnni ọ̀hún pọ̀ lọ salalu bí omi òkun, tó fi jẹ́ pé èèyàn gbọ́dọ̀ mọ èyí tó yẹ kóun mú, kó máà jẹ́ gbogbo ẹ̀ lèèyàn ronú pé òun á kó sórí. Èyí mú kó di dandan fún wa láti mú ìwọ̀nba tá a nílò ká sì fi èyí tó kù sílẹ̀.
Ìdí mìíràn tí kò fi yẹ ká máa ka gbogbo ìwé tá a bá rí ni pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ìsọfúnni náà ni kò wúlò. Ká sòótọ́, Ìṣe 19:35, 36) Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará ìlú náà ti gbọ́ nípa ohun tó sọ yìí, tàbí kí ọ̀pọ̀ èèyàn tiẹ̀ máa sọ pé òótọ́ ló ṣẹlẹ̀, síbẹ̀ irọ́ ńlá ni pé ère kan jábọ́ látọ̀run. Abájọ tí Bíbélì fi kìlọ̀ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n yẹra fún “ohun tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀.’”—1 Tímótì 6:20.
àwọn kan nínú wọn kò dára rárá, kò sì yẹ kí ọmọlúwàbí tiẹ̀ mọ̀ nípa rẹ̀. Rántí pé ohun téèyàn bá rí, èyí tó bá kà tàbí tó bá gbọ́ ló máa ń jẹ́ kéèyàn ní ìmọ̀, yálà ìsọfúnni ọ̀hún dáa tàbí kò dáa. Ohun tó túbọ̀ wá mú kí ọ̀ràn náà burú sí i ni pé àwọn nǹkan mìíràn tí ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ó jóòótọ́ ni kì í ṣòótọ́ rárá. Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn tó jẹ́ àká ìmọ̀ láwùjọ máa ń sọ ohun tó jẹ́ pé nígbà tó bá yá, àwọn èèyàn á rí i pé kì í ṣòótọ́! Wo àpẹẹrẹ akọ̀wé ìlú Éfésù àtijọ́ táwọn èèyàn ìlú náà kà sí ọ̀jọ̀gbọ́n. Akọ̀wé náà sọ pé: “Ta ni ó wà tí kò mọ̀ ní ti gidi pé ìlú ńlá àwọn ará Éfésù ni olùpa tẹ́ńpìlì mọ́ fún Átẹ́mísì ńlá àti fún ère tí ó jábọ́ láti ọ̀run?” (Ìdí pàtàkì kan tó fi yẹ kó jẹ́ pé ìsọfúnni tó máa wúlò fún wa nìkan ló yẹ ká máa kà ni pé àkókò téèyàn ń lò láyé ò tó nǹkan. Yálà ọmọdé ni ọ́ tàbí àgbàlagbà, ó dájú pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni wàá fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀, àmọ́ o lè wá rí i pé ọjọ́ tó o máa lò láyé lè máà tó ẹ láti kọ́ ọ.
Ṣé bí nǹkan yóò ṣe máa rí lọ nìyẹn? Ǹjẹ́ ìmọ̀ kan wà tá a lè ní tí yóò fún wa lẹ́mìí gígùn, táá sì mú ká wà láàyè títí láé? Ǹjẹ́ irú ìmọ̀ yẹn wà láyé yìí? Tó bá wà, ǹjẹ́ gbogbo èèyàn ló máa ní in? Ǹjẹ́ ìgbà kan máa wà tí gbogbo ìsọfúnni tá a bá ń rí gbà yóò jẹ́ òótọ́? Tọkọtaya tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí rí ìdáhùn tó mọ́yán lórí sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn, ìwọ náà sì lè rí i. Jọ̀wọ́ ka àpilẹ̀kọ tó kàn, yóò jẹ́ kó o mọ bó ṣe lè ṣeé ṣe fún ọ láti máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ títí ayé.