Ǹjẹ́ Ò Ń Fi Iṣẹ́ Ti Ìgbàgbọ́ Rẹ Lẹ́yìn?
Ǹjẹ́ Ò Ń Fi Iṣẹ́ Ti Ìgbàgbọ́ Rẹ Lẹ́yìn?
Ọ̀GÁ ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan gbà gbọ́ pé Jésù lè wo ẹrú òun tó lárùn ẹ̀gbà sàn. Àmọ́, ọ̀gágun náà ò fẹ́ kí Jésù wọnú ilé òun, bóyá nítorí ó rò pé òun ò yẹ lẹ́ni tí Jésù lè wọlé rẹ̀ tàbí nítorí pé òun jẹ́ Kèfèrí. Ohun tó wá ṣe ni pé, ó rán àwọn àgbà ọkùnrin kan tó jẹ́ Júù pé kí wọ́n lọ sọ fún Jésù pé: “Ọ̀gá, èmi kì í ṣe ọkùnrin tí ó yẹ fún ọ láti wọ abẹ́ òrùlé [rẹ̀], ṣùgbọ́n sáà sọ ọ̀rọ̀ náà, ara ìránṣẹ́kùnrin mi yóò sì dá.” Nígbà tí Jésù rí i pé ọ̀gágun náà gbà gbọ́ pé òun lè ṣe ìwòsàn, àní láti ọ̀nà jíjìn pàápàá, ó sọ fún ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó ń tẹ̀ lé e pé: “Mo sọ òtítọ́ fún yín pé, Kò sí ẹnì kan ní Ísírẹ́lì tí èmi tíì rí tí ó ní ìgbàgbọ́ tí ó tóbi tó bẹ́ẹ̀.”—Mátíù 8:5-10; Lúùkù 7:1-10.
Ìtàn yìí lè jẹ́ ká ronú jinlẹ̀ lórí ohun pàtàkì kan téèyàn ní láti mọ̀ nípa ìgbàgbọ́. Ojúlówó ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun téèyàn kàn ń sọ lẹ́nu lásán; èèyàn gbọ́dọ̀ fi iṣẹ́ tì í lẹ́yìn. Òǹkọ̀wé Bíbélì tó ń jẹ́ Jákọ́bù sọ pé: “Ìgbàgbọ́, bí kò bá ní àwọn iṣẹ́, jẹ́ òkú nínú ara rẹ̀.” (Jákọ́bù 2:17) Ọ̀rọ̀ yìí á túbọ̀ ṣe kedere sí wa tá a bá gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tá ò bá fi iṣẹ́ ti ìgbàgbọ́ wa lẹ́yìn.
Lọ́dún 1513 ṣáájú Sànmánì Tiwa, Jèhófà Ọlọ́run bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú Òfin. Mósè tó jẹ́ alárinà májẹ̀mú náà jíṣẹ́ Ọlọ́run Ẹ́kísódù 19:3-6) Èyí túmọ̀ sí pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó lè di orílẹ̀-èdè mímọ́, wọ́n ní láti jẹ́ onígbọràn.
fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó ní: “Bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn mi, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́ ní ti gidi, dájúdájú, nígbà náà, ẹ̀yin yóò di . . . orílẹ̀-èdè mímọ́.” (Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn èyí, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí ka kíkẹ́kọ̀ọ́ Òfin Mósè sí ohun tó ṣe pàtàkì ju fífi ohun tó wà nínú Òfin ọ̀hún sílò lọ. Nínú ìwé The Life and Times of Jesus the Messiah (Ìgbésí Ayé àti Àkókò Jésù Tí Í Ṣe Mèsáyà) tí Alfred Edersheim kọ, ó ní: “Àwọn [rábì], ìyẹn àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, ti fi òte lé e tipẹ́tipẹ́ pé, ẹ̀kọ́ kíkọ́ ṣe pàtàkì ju fífi ohun téèyàn ń kọ́ sílò lọ.”
Lóòótọ́, Ọlọ́run pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un pé kí wọ́n máa fi gbogbo ọkàn wọn kẹ́kọ̀ọ́ àwọn òfin òun. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ pé: “Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí . . . wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” (Diutarónómì 6:6, 7) Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ìgbà kan wà tí Jèhófà sọ pé kíkẹ́kọ̀ọ́ Òfin Mósè ṣe pàtàkì ju fífi ohun tó wà nínú Òfin náà sílò lọ? Ẹ jẹ́ ká gbé ìbéèrè yìí yẹ̀ wò ná.
Tọ̀sántòru Ni Wọ́n Fi Ń Kẹ́kọ̀ọ́
Báwọn aṣáájú ìsìn ṣe máa ń fìgbà gbogbo tẹnu mọ́ ọn pé ó pọn dandan kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ Òfin Mósè lè má burú lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítorí pé òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù kan sọ pé Ọlọ́run gan-an fúnra rẹ̀ máa ń fi nǹkan bíi wákàtí mẹ́ta kẹ́kọ̀ọ́ Òfin lójoojúmọ́. O lè wá rí ìdí táwọn Júù kan fi lè máa sọ pé, ‘Bí Ọlọ́run bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Òfin déédéé, ṣé kò wá yẹ káwa ẹ̀dá èèyàn náà máa kẹ́kọ̀ọ́ Òfin ọ̀hún tọ̀sántòru?’
Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Mátíù 23:2-4) Àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyẹn máa ń ka àwọn òfin àti ìlànà sílẹ̀ lọ bẹẹrẹbẹ fáwọn èèyàn láti tẹ̀ lé, àmọ́ ńṣe làwọn máa ń dọ́gbọ́n yẹ àwọn òfin náà sílẹ̀. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn tó ń kọ́ ẹ̀kọ́ lójú méjèèjì yìí kò “ka àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo àti àánú àti ìṣòtítọ́.”—Mátíù 23:16-24.
Tiwa, àwọn rábì ti jẹ́ kí ṣíṣe ọ̀rínkinniwín Òfin àti ṣíṣe ọ̀pọ̀ àlàyé lórí rẹ̀ gbà wọ́n lọ́kàn débi pé èrò wọn nípa òfin ọ̀hún ti wá yàtọ̀ pátápátá sí ti Ọlọ́run. Jésù sọ pé: “Àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí . . . a máa wí, ṣùgbọ́n wọn kì í ṣe. Wọ́n di àwọn ẹrù wíwúwo, wọ́n sì gbé wọn lé èjìká àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn kò fẹ́ láti fi ìka wọn sún wọn kẹ́rẹ́.” (Ẹ ò rí nǹkan! Àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí ń gbé ohun tó tọ́ lójú wọn kalẹ̀, àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń fi ìyẹn rú Òfin tí wọ́n sọ pé àwọn ń pa mọ́. Pẹ̀lú gbogbo ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n fi ṣe atótónu lórí Òfin àtàwọn ọ̀rọ̀ mìíràn, wọn ò sún mọ́ Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n jìnnà sí i gẹ́gẹ́ bí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pè ní “àwọn òfìfo ọ̀rọ̀,” “àwọn ìtakora,” àti “ìmọ̀” èké ṣe mú káwọn kan yapa kúrò nínú ìgbàgbọ́. (1 Tímótì 6:20, 21) Ìṣòro ńlá mìíràn tí wọ́n tún ní ni pé, pẹ̀lú gbogbo ẹ̀kọ́ àkọ́ọ̀kọ́tán náà, wọn ò ní ìgbàgbọ́ tó lè mú wọn ṣe ohun tó tọ́.
Àwọn Ọ̀mọ̀wé Tí Kò Ní Ìgbàgbọ́ Kankan
Ẹ ò rí i pé èrò àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ò bá ti Ọlọ́run mu rárá! Nígbà tó kù díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Mósè sọ fún wọn pé: “Ẹ fi ọkàn-àyà yín sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ láti fi kìlọ̀ fún yín lónìí, kí ẹ̀yin lè máa pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti máa kíyè sí pípa gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí mọ́.” (Diutarónómì 32:46) Ó ṣe kedere pé, kì í ṣe pé kí wọ́n kàn máa kẹ́kọ̀ọ́ Òfin lójú méjèèjì nìkan ni, wọ́n tún gbọ́dọ̀ máa pa Òfin náà mọ́.
Ṣùgbọ́n o, àìmọye ìgbà ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà. Dípò káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣe àwọn ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run, wọn ò “lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni [wọn] kò fetí sí ohùn rẹ̀.” (Diutarónómì 9:23; Onídàájọ́ 2:15, 16; 2 Kíróníkà 24:18, 19; Jeremáyà 25:4-7) Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn Júù hu ìwà àìṣòótọ́ tó burú jù lọ nígbà tí wọ́n kọ Jésù ní Mèsáyà. (Jòhánù 19:14-16) Ìdí nìyí tí Jèhófà Ọlọ́run fi kọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀, tó sì yíjú sáwọn orílẹ̀-èdè.—Ìṣe 13:46.
Nítorí náà, ó yẹ ká kíyè sára káwa náà má bàa ṣe irú àṣìṣe kan náà, ìyẹn ká máa ronú pé a lè máa fi ìmọ̀ orí nìkan jọ́sìn Ọlọ́run bí a ò tiẹ̀ ní ìgbàgbọ́. Ohun tá à ń sọ ni pé, ẹ̀kọ́ Bíbélì tá à ń kọ́ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kíkó ìmọ̀ sórí nìkan. Ìmọ̀ pípéye gbọ́dọ̀ dénú ọkàn wa kó lè ṣe wá láǹfààní nígbèésí ayé wa. Ǹjẹ́ ó mọ́gbọ́n dání kéèyàn lọ kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ ọ̀gbìn kí onítọ̀hún má sì gbin irúgbìn kankan? Òótọ́ ni pé onítọ̀hún lè mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ ọ̀gbìn, àmọ́ kò ní kórè ohunkóhun láé tí kò bá gbin irúgbìn kankan! Lọ́nà kan náà, àwọn tó bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n lè mọ̀ nípa àwọn ìlànà Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ kí irúgbìn ẹ̀kọ́ òtítọ́ dénú ọkàn wọn. Èyí ni yóò jẹ́ káwọn irúgbìn náà dàgbà lọ́kàn wọn, tí yóò sì mú kí wọ́n fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò.—Mátíù 13:3-9, 19-23.
“Ẹ Di Olùṣe Ọ̀rọ̀ Náà”
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.” (Róòmù 10:17) Tí ẹnì kan bá gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ohun tó gbọ́ sì mú kó gba Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ gbọ́, onítọ̀hún yóò lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. A lè wá rí i báyìí pé ọ̀rọ̀ yìí kọjá kéèyàn wulẹ̀ máa sọ pé, ‘Mo gba Ọlọ́run àti Kristi gbọ́.’
Jésù rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó yẹ, ìyẹn ni pé kí wọ́n máa fi iṣẹ́ ti ìgbàgbọ́ wọn lẹ́yìn. Ó ní: “A yin Baba mi lógo nínú èyí, pé ẹ ń bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀, tí ẹ sì fi ara yín hàn ní ọmọ ẹ̀yìn mi.” (Jòhánù 15:8) Lẹ́yìn ìgbà náà, Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ìyá Jésù kọ̀wé pé: “Ẹ di olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan.” (Jákọ́bù 1:22) Àmọ́, báwo la ṣe lè mọ ohun tó yẹ ká ṣe? Nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ àti àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀, ó jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe tó máa dùn mọ́ Ọlọ́run nínú.
Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti gbé Ìjọba Ọlọ́run lárugẹ àti láti yin orúkọ Baba rẹ̀ lógo. (Jòhánù 17:4-8) Báwo ló ṣe ṣe é? Ọ̀pọ̀ èèyàn lè rántí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, irú bó ṣe wo àwọn aláìsàn àtàwọn aláàbọ̀ ara sàn. Àmọ́, Ìhìn Rere Mátíù jẹ́ ká mọ ọ̀nà pàtàkì tó gbà gbé Ìjọba Ọlọ́run lárugẹ, tó sì fi yin orúkọ Baba rẹ̀ lógo. Mátíù kọ̀wé pé: “Jésù . . . mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n nínú ìrìn àjò ìbẹ̀wò sí gbogbo àwọn ìlú ńlá àti àwọn abúlé, ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn, ó sì ń wàásù ìhìn rere ìjọba náà.” Èyí fi hàn pé Jésù ò kàn fi ìwàásù rẹ̀ mọ sórí fífọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ bíi mélòó kan tàbí àwọn aládùúgbò rẹ̀ nígbàkigbà tí àyè rẹ̀ bá yọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ nínú iṣẹ́ yìí, ó sì lo gbogbo àǹfààní tó bá yọ láti lọ wàásù fáwọn èèyàn “jákèjádò Gálílì.”—Mátíù 4:23, 24; 9:35.
Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé káwọn náà máa ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Ó sì fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún wọn láti tẹ̀ lé. (1 Pétérù 2:21) Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”—Mátíù 28:19, 20.
Gbogbo wa la mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù kò rọrùn láti ṣe. Kódà, Jésù gan-an fúnra rẹ̀ sọ pé: “Wò ó! Èmi ń rán yín jáde gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn sí àárín àwọn ìkookò.” (Lúùkù 10:3) Nígbà táwọn kan bá ń ṣe àtakò wa, ó lè máa dà bíi pé ká fà sẹ́yìn ká má bàa kó ara wa sí wàhálà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn àpọ́sítélì lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n mú Jésù nìyẹn. Ẹ̀rù bà wọ́n ni wọ́n bá fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù sọ pé òun ò mọ Jésù rí.—Mátíù 26:56, 69-75.
Láfikún sí i, ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti gbọ́ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pàápàá sọ pé iṣẹ́ ìwàásù ò rọrùn fóun náà. Ó kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Tẹsalóníkà pé: “[A] máyàle nípasẹ̀ Ọlọ́run wa láti sọ ìhìn rere Ọlọ́run fún yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìjàkadì.”—1 Tẹsalóníkà 2:1, 2.
Pọ́ọ̀lù àtàwọn àpọ́sítélì bíi tirẹ̀ borí ìbẹ̀rù tí wọn ní nípa iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn. Ìwọ náà lè borí ìbẹ̀rù tó o bá ní. Báwo lo ṣe lè ṣe é? Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé kó o gbára lé Jèhófà. Bí a bá fi gbogbo ọkàn wa gbára lé Jèhófà, èyí kò ní jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa di òkú, a ó sì lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Ìṣe 4:17-20; 5:18, 27-29.
Èrè Wà fún Iṣẹ́ Yín
Jèhófà ń rí gbogbo ìsapá tá à ń ṣe láti sìn ín. Bí àpẹẹrẹ, ó mọ ìgbà tó bá rẹ̀ wá tàbí tí àìsàn bá ń ṣe wá. Ó mọ àwọn ohun tó ń mú ká máa ṣàníyàn, ì báà jẹ́ ẹrù ìnáwó tàbí àìsàn tàbí ẹ̀dùn ọkàn. Gbogbo ẹ̀ ni Jèhófà rí.—2 Kíróníkà 16:9; 1 Pétérù 3:12.
Kò sí àní-àní pé inú Jèhófà máa ń dùn gan-an tó bá rí i pé ìgbàgbọ́ wa kì í ṣe òkú bó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ aláìpé a sì láwọn ìṣòro tá à ń bá yí! Kì í ṣe pé àánú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ olóòótọ́ máa ń ṣe é nìkan ni, ó tún ṣèlérí pé òun á ṣe nǹkan kan nípa ìṣòro wọn. Ẹ̀mí mímọ́ darí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.”—Hébérù 6:10.
Bíbélì pe Jèhófà ní “Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀” àti “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” Ohun tí Bíbélì sọ yìí ṣeé gbára lé. (Diutarónómì 32:4; Hébérù 11:6) Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ California lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ọdún mẹ́wàá ni bàbá mi fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kó tó gbéyàwó tó sì bímọ. Mo máa ń gbádùn àwọn ìtàn tó máa ń sọ fún mi nípa bí Jèhófà ṣe bójú tó òun nígbà tóun ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń fi gbogbo owó tó kù sí i lápò ra epo sí ọkọ̀ tó máa gbé lọ sí òde ìwàásù. Síbẹ̀, tó bá máa fi ti òde ìwàásù dé, á ti bá ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tí kò retí lẹ́nu ọ̀nà.”
Yàtọ̀ sí ìpèsè àwọn nǹkan tara, “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” ń fún wa ní ìṣírí, ó sì ń pèsè àwọn nǹkan tẹ̀mí tó lè fún wa lókun. (2 Kọ́ríńtì 1:3) Obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ti fara da ìṣòro fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: “Ó máa ń dára gan-an kéèyàn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé e, a ó lè rí bó ṣe ń ràn wá lọ́wọ́.” Tó o bá ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ gbàdúrà sí “Olùgbọ́ àdúrà” nípa ohun tó ń mú kó o ṣàníyàn, mọ̀ dájú pé yóò dáhùn àdúrà rẹ.—Sáàmù 65:2.
Àwọn ìbùkún àti èrè táwọn olùkórè tẹ̀mí ń rí gbà pọ̀ gan-an ni. (Matthew 9:37, 38) Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ni iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe máa ń mú kára wọn dá ṣáṣá sí i, ó sì lè rí bẹ́ẹ̀ fún ìwọ náà. Àmọ́, ju gbogbo rẹ̀ lọ, tá a bá ń wàásù fáwọn ẹlòmíràn, èyí á jẹ́ ká ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run.—Jákọ́bù 2:23.
Máa Ṣe Rere Nìṣó
Àṣìṣe ńlá ló máa jẹ́ tí ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan bá lọ ń ronú pé Jèhófà ò ní fojú rere wo òun nítorí pé àìlera tàbí ọjọ́ ogbó ò jẹ́ kóun lè ṣe gbogbo ohun tóun ì bá ṣe nínú iṣẹ́ Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ náà ni kò ṣe yẹ káwọn tí kò lè ṣe tó bí wọ́n ṣe fẹ́ nítorí àìsàn, bùkátà ìdílé tàbí àwọn nǹkan mìíràn máa ronú bẹ́ẹ̀.
Rántí pé nígbà tí àìlera tàbí ohun ìdènà kan kò jẹ́ kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lè ṣe tó bó ṣe ń fẹ́, ‘ìgbà mẹ́ta ló pàrọwà sí Olúwa pé kí ohun náà lè kúrò lára òun.’ Dípò kí Ọlọ́run mú ohun náà kúrò lára Pọ́ọ̀lù kó bàa lè túbọ̀ ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Jèhófà, ó sọ pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ; nítorí agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.” (2 Kọ́ríńtì 12:7-10) Nítorí náà, jẹ́ kó dá ọ lójú pé ìṣòro yòówù kó o máa bá yí, Baba rẹ ọ̀run mọrírì ohunkóhun tó o bá ń ṣe láti gbé Ìjọba rẹ̀ lárugẹ.—Hébérù 13:15, 16.
Ohun tí Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ ń fẹ́ ká ṣe kò kọjá agbára wa. Ohun tó kàn ń fẹ́ ni pé ká máa fi iṣẹ́ ti ìgbàgbọ́ wa lẹ́yìn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ǹjẹ́ bí wọ́n ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Òfin Mósè nìkan tó?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
A gbọ́dọ̀ fi iṣẹ́ ti ìgbàgbọ́ wa lẹ́yìn