Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Lè Mú Kí Iṣẹ́ Ìtumọ̀ Èdè Rọrùn

Ohun Tó Lè Mú Kí Iṣẹ́ Ìtumọ̀ Èdè Rọrùn

Ohun Tó Lè Mú Kí Iṣẹ́ Ìtumọ̀ Èdè Rọrùn

JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN tó ni Bíbélì fẹ́ kí “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn” gbọ́ ìhìn rere Ìjọba rẹ̀. (Ìṣípayá 14:6) Ó sì fẹ́ kí gbogbo èèyàn ní Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kí èyí lè ṣeé ṣe, Ọlọ́run mú káwọn atúmọ̀ èdè tú Bíbélì sí èdè tó pọ̀ gan-an tó fi jẹ́ pé òun ni ìwé tí wọ́n túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù lọ láyé. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn atúmọ̀ èdè ti ṣe iṣẹ́ àṣekára kí wọ́n lè tú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí onírúurú èdè.

Àmọ́, Bíbélì kì í ṣe ìwé táwọn atúmọ̀ èdè kàn lè tú bó ṣe wù wọ́n o. Ìdí ni pé lọ́pọ̀ ìgbà, Bíbélì gan-an làwọn atúmọ̀ èdè máa ń lò tí wọ́n bá fẹ́ tú àwọn ìwé mìíràn. Ọ̀pọ̀ àwọn atúmọ̀ èdè máa ń fi ìtumọ̀ Bíbélì ní èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wéra kí wọ́n lè rí ìtumọ̀ tó dára tí wọ́n lè lò fún àwọn ọ̀rọ̀ kan. Nítorí pé Bíbélì jẹ́ ohun tó ń mú kí iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè rọrùn gan-an, wọ́n ti ń lò ó báyìí nínú iṣẹ́ fífi ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà ṣètumọ̀.

Kọ̀ǹpútà ò lè ṣe ìtumọ̀ tó dára. Kódà, àwọn ọ̀mọ̀wé kan tiẹ̀ sọ pé kọ̀ǹpútà ò lè ṣètumọ̀ rárá. Kí nìdí tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé kì í ṣe pé kéèyàn kàn kó ọ̀rọ̀ jọ lásán ni èdè. Èdè kọ̀ọ̀kan ló ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà to ọ̀rọ̀ pọ̀ tó máa fi di gbólóhùn. Bákan náà, èdè kọ̀ọ̀kan ló ní ìlànà tó ń tẹ̀ lé, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n mọ ìgbà tí wọn kò ní tẹ̀ lé ìlànà ọ̀hún. Gbogbo èdè ló sì ní àkànlò èdè àti àpèjúwe. Àwọn kan ti gbìyànjú láti ṣe kọ̀ǹpútà tó máa lè ṣe gbogbo èyí ṣùgbọ́n wọn ò tíì rí i ṣe. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìtumọ̀ tí kọ̀ǹpútà ṣe ló jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ yéni, ìyẹn tó bá tiẹ̀ ṣeé kà rárá.

Àmọ́ ṣá o, Franz Josef Och tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ògúnná-gbòǹgbò nínú iṣẹ́ fífi kọ̀ǹpútà ṣètumọ̀ sọ pé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa kọ̀ǹpútà ti ń dá àwọn ọgbọ́n tuntun kan báyìí. Jẹ́ ká sọ pé o fẹ́ tú èdè Hindi sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, ńṣe ni wàá kọ́kọ́ wá ìwé kan tó wà lédè méjèèjì. Lẹ́yìn náà, wàá tẹ ọ̀rọ̀ inú ìwé èdè méjèèjì yìí sínú kọ̀ǹpútà. Ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà yóò wá wo ọ̀rọ̀ tó wà lédè méjèèjì yìí síra. Bí àpẹẹrẹ, bí kọ̀ǹpútà bá ń rí ọ̀rọ̀ Hindi kan náà ní gbogbo ibi tó bá ti ń rí ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan, irú bí “ilé,” yóò gbà pé “ilé” ni ọ̀rọ̀ Hindi náà túmọ̀ sí lédè Gẹ̀ẹ́sì. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ aṣàpèjúwe bí “ńlá,” “kékeré,” “àtijọ́” tàbí “tuntun” ló wà nítòsí ọ̀rọ̀ yìí. Kọ̀ǹpútà yóò wá kó àwọn ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn tó bára wọn dọ́gba nínú èdè méjèèjì yìí jọ. Lẹ́yìn tó bá ti ṣe àkójọ àwọn ọ̀rọ̀ tó pọ̀ tó, èyí tó lè jẹ́ láàárín ọjọ́ mélòó kan tàbí ọ̀sẹ̀ díẹ̀ péré, kọ̀ǹpútà náà yóò lè lo ohun tó ti kó jọ yìí láti fi ṣe ìtumọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtumọ̀ tí kọ̀ǹpútà bá ṣe lè máà dára tó tá a bá ní ká wo ìlànà gírámà àti ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé èèyàn ṣì lè fi òye gbé ohun tí kọ̀ǹpútà túmọ̀ yìí kéèyàn sì mọ àwọn kókó pàtàkì ibẹ̀.

Bí ọ̀rọ̀ tá a tẹ̀ sínú kọ̀ǹpútà níbẹ̀rẹ̀ bá ṣe pọ̀ tó àti bí ìtumọ̀ tí wọ́n ṣe síbẹ̀ tẹ́lẹ̀ bá ṣe dára tó ni ìtumọ̀ tí kọ̀ǹpútà ṣe yóò ṣe dára tó. Ibí yìí gan-an ni Bíbélì ti wúlò fún àwọn olùṣèwádìí. Àwọn atúmọ̀ èdè ti fara balẹ̀ túmọ̀ Bíbélì sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní in lọ́wọ́, ọ̀rọ̀ tó sì wà nínú rẹ̀ kì í ṣe kékeré. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé Bíbélì làwọn olùṣèwádìí máa ń kọ́kọ́ wá tí wọ́n bá fẹ́ kí kọ̀ǹpútà máa tú èdè tuntun.